Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ

Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ

ǸJẸ́ Ọmọ Ọlọ́run tiẹ̀ ráyè gbọ́ tàwọn ọmọdé? Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò rò bẹ́ẹ̀. Nígbà kan, wọ́n gbìyànjú láti lé àwọn ọmọdé padà kí wọ́n má bàa wá sọ́dọ̀ Jésù. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Lẹ́yìn náà ló kó àwọn ọmọdé kan tí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́ra, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. (Máàkù 10:13-16) Lọ́nà yìí, Jésù fi hàn pé ọwọ́ òun ò dí kọjá kí òun gbọ́ tàwọn ọmọdé. Báwo làwọn òbí ayé òde òní ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Nípa kíkọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó jíire àti wíwá àyè láti máa gbọ́ tiwọn ni.

A mọ̀ pé àwọn òbí tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ kì í fọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn ṣeré wọn kì í sì í fìyà jẹ wọ́n. Kódà, a tiẹ̀ lè sọ pé ohun táwọn òbí máa ń fẹ́ ni pé káwọn máa fi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò bá ọmọ wọn lò. Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ pé ní ọjọ́ tiwa àwọn èèyàn á jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1-3) Ọ̀pọ̀ nǹkan sì làwọn òbí tí wọ́n ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ wọn á máa rí kọ́ nípa àbójútó ọmọ. Nítorí náà, àwọn ìlànà Bíbélì tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí yìí jẹ́ ìránnilétí táwọn òbí tí wọ́n fẹ́ ohun tó dára jù lọ fáwọn ọmọ wọn á mọrírì gidigidi.

Bá A Ṣe Lè Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Láìmú Inú Bí Wọn

Ọ̀mọ̀wé Robert Coles, ìlúmọ̀ọ́ká olùkọ́ àti olùṣèwádìí nípa àìsàn ọpọlọ, sọ nígbà kan pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ báwọn ọmọdé ṣe ń dàgbà ni wọ́n máa ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Lérò tèmi, Ọlọ́run ló dá ìfẹ́ yìí mọ́ wọn, ìyẹn ni wọ́n fi máa ń fẹ́ kí wọ́n rẹ́ni tọ́ wọn sọ́nà.” Ta ni yóò wá fún àwọn ọmọ ní ìtọ́sọ́nà tó jẹ́ kòṣeémánìí yìí?

Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú nínú Éfésù 6:4 pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ní pàtó pé ojúṣe baba ni pé kó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún àwọn ìlànà Rẹ̀? Ní ẹsẹ kìíní nínú Éfésù orí 6, bàbá àti ìyá ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ‘kí àwọn ọmọ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí wọn.’ a

Àmọ́ ṣá o, bí baba ò bá sí níbẹ̀, a jẹ́ pé ọpọ́n sún kan ìyá nìyẹn láti ṣe ojúṣe gẹ́gẹ́ bí olórí. Ọ̀pọ̀ ìyá tó ń dá tọ́mọ, ti kẹ́sẹ járí nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́, bí irú ìyá bẹ́ẹ̀ bá wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ, ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni ló ní láti máa mú ipò iwájú. Ìyá sì gbọ́dọ̀ ṣe tán láti kọ́wọ́ ti ọkọ bó ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ tó sì ń bá wọn wí.

Báwo lo ṣe ń bá àwọn ọmọ rẹ wí, báwo lo sì ṣe ń kọ́ wọn láì ‘mú wọn bínú’? Kò sí idán kankan níbẹ̀, àgàgà níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sọ́mọ méjì tó rí bákan náà. Ṣùgbọ́n àwọn òbí gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn ọmọ wí. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ, kí wọ́n sì máa fọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń bá wọn wí. Wẹ́kú ló sì ṣe pé Ìwé Mímọ́ tún sọ ọ́ nínú Kólósè 3:21 pé káwọn òbí má ṣe máa mú àwọn ọmọ bínú. Ohun tí ibẹ̀ tún sọ fún àwọn baba ni pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”

Àwọn òbí kan máa ń pariwo wọ́n sì tún máa ń lọgun lé àwọn ọmọ wọn lórí. Dájúdájú, èyí máa ń mú inú bí àwọn ọmọdé. Ṣùgbọ́n Bíbélì rọ̀ wá pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Bíbélì tún sọ pé “kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—2 Tímótì 2:24.

Yọ̀ọ̀da Àkókò Rẹ fún Wọn

Ohun tí wíwá àyè gbọ́ tàwọn ọmọ rẹ tún túmọ̀ sí ni pé kó o má ṣe jẹ́ kí ìgbádùn àti ìtura ara tìẹ jẹ ọ́ lógún ju ọ̀rọ̀ tàwọn ọmọ rẹ lọ. Bíbélì sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:6, 7.

Lóde tòní, àtirí owó ná, rí owó lò kò tún jẹ́ kí ọ̀pọ̀ òbí ráyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn mọ́. Bí wọ́n bá ti jáde nílé láàárọ̀ ó tún dalẹ́. Síbẹ̀, ìwé Diutarónómì tẹnu mọ́ ọn pé káwọn òbí máa wáyè gbọ́ tàwọn ọmọ wọn. Ó lè gba pé káwọn òbí létò tó dáa kí wọ́n sì fi àwọn nǹkan kan du ara wọn kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, kò yẹ kí wọ́n máa fi àwọn ọmọ sílẹ̀ láìbójú tó wọn.

Ìwọ ṣàkíyèsí àbájáde ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ẹgbàafà [12,000] ọ̀dọ́. Àwọn olùṣèwádìí náà sọ pé: “Bí ọkàn ọ̀dọ́ kan bá fà tímọ́tímọ́ mọ́ òbí rẹ̀, kò ní jẹ́ kó máa ká gúọ́gúọ́ kiri, kò sì ní hùwà ìpáǹle tó lè kó bá a.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọmọ kì í fẹ́ káwọn òbí àwọn pa àwọn tì. Ìyá kan béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ rí pé, “Bí mo bá ní kẹ́ ẹ sọ ohunkóhun tó bá wù yín, kí lẹ máa sọ pé ẹ fẹ́ràn jù lọ?” Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dáhùn pé, “Kí Mọ́mì àti Dádì máa lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú wa.”

Nítorí náà, ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ òbí rere ni pé kéèyàn rí i dájú pé òun ń ṣe ohun táwọn ọmọ òun ń fẹ́ fún wọn, tó fi mọ́ kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Ó tún túmọ̀ sí ríran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti jáfáfá, kí wọ́n nítẹríba, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tó láàánú ọmọnìkejì lójú, àtẹni tó ń fògo fún Ẹlẹ́dàá wọn. (1 Sámúẹ́lì 2:26) Ó dájú gbangba pé báwọn òbí bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ wọn tí wọ́n sì ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá wọn wí, a jẹ́ pé òbí tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ ni wọn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Níbí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì, go·neuʹsin tó wá látara go·neusʹ, tó túmọ̀ sí “òbí” ni Pọ́ọ̀lù lò. Ṣùgbọ́n ní ẹsẹ kẹrin ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pa·teʹres, tó túmọ̀ sí “àwọn bàbá” ló lò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Pípariwo àti lílọgun lé àwọn ọmọ lórí lè kó ìdààmú bá wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Máa wáyè gbọ́ tàwọn ọmọ rẹ