Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aṣọ Hanbok Aṣọ Àwọn Ará Korea

Aṣọ Hanbok Aṣọ Àwọn Ará Korea

Aṣọ Hanbok Aṣọ Àwọn Ará Korea

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Orílẹ̀-èdè Korea

LÓJÚ àwọn ará Korea, aṣọ kọjá ohun téèyàn fi ń bàṣírí ara. Àpẹẹrẹ kan tá a lè fi ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yìí ni ti aṣọ ìbílẹ̀ àwọn ará Korea tí wọ́n ń pè ní hanbok.

Àrà Ọ̀tọ̀ Gbáà Ni

Bíláòsì tí ọrùn rẹ̀ fẹ̀ débi àyà àti síkẹ́ẹ̀tì gígùn tó dúró sẹpẹ́ lára ni aṣọ tí wọ́n ń pè ní hanbok yìí. a Síkẹ́ẹ̀tì aṣọ náà máa ń fi ìlọ́po mẹ́rin gùn ju bíláòsì lọ nígbà míì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bí obìnrin tó kúrú bá wọ̀ ọ́, á mú kó rí bí ẹni tó ga.

Aṣọ hanbok rọra máa ń ṣẹ́ léra bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lórí omi, tí omi wá ń ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Wọ́n ṣe bíláòsì rẹ̀ ní alápá labalábá, síkẹ́ẹ̀tì rẹ̀ sì máa ń gùn láti ibi àyà dé apá ìsàlẹ̀ ó sì máa ń fẹ́ lẹlẹ. Wọ́n ta aṣọ róbótó kan bíi táì mọ́ ọrùn aṣọ náà kó bàa lè gbé ẹwà ẹ̀ yọ dáadáa. Aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n ta mọ́ aṣọ róbótó yìí gba iwájú bíláòsì kọjá, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn dé kókósẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn aṣọ hanbok yìí ni wọ́n tún fi bátànì oríṣiríṣi tàbí àwòrán òdòdó dárà sí lọ́rùn ọwọ́, ní ọrùn, àti lára síkẹ́ẹ̀tì. Dájúdájú, bí aṣọ yìí ṣe gún régé, bí wọ́n ṣe rán an, àti àwọ̀ tó ní ló mú kó jẹ́ aṣọ ńlá.

Aṣọ Tó Ṣeé Wọ̀ Tòjò Tẹ̀ẹ̀rùn Ni

Ohun tó tún fi kún ẹwà aṣọ yìí ni pé wọ́n rán an tá á fi ṣeé wọ̀ nígbà gbogbo. Nítorí pé ìko wà lára ohun tí wọ́n sábà máa ń fi ṣe aṣọ yìí, ó rọrùn láti wọ̀ nígbàkigbà. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ hanbok tí wọ́n bá fi àwọn ohun tí wọ́n mú lára ewé tí wọ́n ń pè ní ramie tàbí hemp ṣe máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ àlàáfíà fẹ́ sára, kì í sì í jẹ́ kí ooru mú ẹni tó bá wọ̀ ọ́ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ náà bò ó ní gbogbo ara. Àwọn míì sì wà tí ohun tí wọ́n fi ṣe wọ́n máa ń mú kí wọ́n dá ooru múni, èyí tó ń mú kí wọ́n dùn wọ̀ nígbà òtútù.

Aṣọ yìí tún fúyẹ́ lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé báṣọ ṣe fúyẹ́ sí lára kọ́ làwọn èèyan máa ń wò kí wọ́n tó yan aṣọ tí wọ́n á wọ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Korea ń lo ẹṣin, ló mú kí wọ́n máa wo bí aṣọ ṣe fúyẹ́ sí lára. Ìwé ìròyìn Culture & I sọ pé: “Wọ́n ṣe aṣọ náà tá á fi lè ṣeé wọ̀ nígbà òtútù, tá á fi ṣeé wọ̀ lọ ṣọdẹ, táwọn tó ń ṣí kiri náà á sì lè lò ó.” Ìdí nìyẹn táwọn agẹṣin ará Korea kì í fẹ́ láti wọ aṣọ tí ò ní jẹ́ kí wọ́n rìn bó ṣe wù wọ́n. Dájúdájú, ṣe ló yẹ káwọn ará Korea tí wọ́n gbádùn àtimáa wọ aṣọ hanbok lóde òní máa dúpẹ́ pé àwọn jogún aṣọ tó rọrùn láti wọ̀ lọ́wọ́ àwọn baba ńlá àwọn!

Ohun mìíràn tó tún mú kí aṣọ yìí fani mọ́ra ni ti àṣà tó ti wà látọjọ́ pípẹ́ pé kí àwọn èèyàn máa lo oríṣiríṣi àwọ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì. Látijọ́, àwọn alákòóso nílẹ̀ Korea máa ń sábàá wọ aṣọ tí àwọ̀ ẹ̀ ń tàn yanyan-anyan, àṣọ funfun làwọn mẹ̀kúnnù sì máa ń wọ̀ jù ní tiwọn. Bákan náà, aṣọ hanbok tó láwọ̀ ìyeyè àti pupa ni wọ́n fi máa ń dá obìnrin tí ò bá tíì lọ́kọ mọ̀. Lẹ́yìn tó bá lọ́kọ, àwọ̀ aṣọ hanbok tá á máa wọ̀ lèèyàn á fi mọ ipò tí ọkọ ẹ̀ wà láwùjọ. Níbi àwọn ìgbéyàwó tí wọ́n ń ṣe lódè tòní, ìyá ìyàwó ló máa ń wọ aṣọ aláwọ̀ osùn, ìyá ọkọ ló sì sábà máa ń wọ aṣọ aláwọ̀ aró. Àṣà yìí ló máa ń mú kó rọrùn láti tètè dá wọn mọ̀.

Aṣọ Hanbok Lóde Tòní

Lẹ́yìn tí ogun tó jà nílẹ̀ Korea (lọ́dún 1950 sí ọdún 1953) parí, wọ́n dáwọ́ lé ètò sísọ àwọn nǹkan di ti ìgbàlódé. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde èyí, nígbà tó fi máa di ọdún 1970 àwọn èèyàn ò dá aṣọ hanbok mọ́, aṣọ tí wọ́n máa ń wọ̀ ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé ló kù tí wọ́n ń wọ̀. Ìdí nìyẹn tí aṣọ ìwọ́lẹ̀ yìí fi wá di aṣọ ìtẹ́lẹ̀ àpótí, àyàfi lọ́jọ́ ìgbéyàwó, nígbà ọdún tàbí tí wọ́n bá ní òde ńlá mìíràn ni wọ́n máa ń wọ̀ ọ́.

Àmọ́ ṣá o, látẹnu bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn èèyàn tún ti ń padà lo aṣọ hanbok báyìí o. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1996, wọ́n ṣe gudugudu méje kí wọ́n lè sọ ọ́ di aṣọ tó tún gbajumọ̀ nípa sísọ gbogbo Sátidé àkọ́kọ́ nínú oṣù di “ọjọ táwọn èèyàn á máa wọ aṣọ hanbok.” Àwọn ilé iṣẹ́ aṣọ dìídì ṣe àwọn aṣọ hanbok tuntun lọ́nà tá á fi máa dá àwọn ọ̀dọ́ lọ́rùn. Dájúdájú, ohun kan wà tó máa ń wu èèyàn nínú pé kó padà sí àṣà àtijọ́, nítorí pé aṣọ hanbok tí wọ́n ń ṣe lóde òní ti wá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta. Lákòókò wa yìí tó jẹ́ pé ìránkúràn-án ló tún kù tí wọ́n ń fi aṣọ rán, ọ̀kan ni aṣọ hanbok jẹ́ lára àwọn aṣọ tó buyì kúnni tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì.—1 Tímótì 2:9.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Aṣọ hanbok tàwọn ọkùnrin wà, tàwọn obìnrin náà sì wà. Àmọ́, tàwọn obìnrin ni ìjíròrò wa dá lé lórí.