Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Ń Lọ À Ń Tọ̀ Ọ́ Lọ̀rọ̀ Àwọn Dókítà

Ayé Ń Lọ À Ń Tọ̀ Ọ́ Lọ̀rọ̀ Àwọn Dókítà

Ayé Ń Lọ À Ń Tọ̀ Ọ́ Lọ̀rọ̀ Àwọn Dókítà

Ní ọdún 1174, wọ́n yan Maimonides gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn tá á máa tọ́jú àwọn ọba ilẹ̀ Íjíbítì, ààfin ló sì máa ń sábàá wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Nígbà tó ń sọ bó ṣe máa ń rẹ òun tó lójoojúmọ́ tó bá tibi iṣẹ́ dé, ó kọ̀wé pé: “Mo kàn máa ń wá nǹkan díẹ̀ panu ni, oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí mo sì máa ń jẹ lójúmọ́ nìyẹn. Bí mo bá sì ṣe ń jẹun tán ni màá padà lọ máa dá àwọn aláìsàn tí mo fẹ́ tọ́jú lóhùn. Màá máa kọ oògùn tí wọ́n á lò fún wọn máà sì máa ṣàlàyé tó jẹ mọ́ ohun tó ń ṣe wọ́n. Bí aláìsàn kan bá ṣe ń lọ ni òmíràn á máa dé títí ilẹ̀ á fi ṣú, nígbà míì sì rèé . . . ó máa ń rẹ̀ mí tẹnutẹnu tí àtisọ̀rọ̀ á sì dìṣòro.”

IṢẸ́ dókítà gba kéèyàn lè sẹ́ ara rẹ̀, bó sì ṣe wà látìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n, nítorí pé bìrí layé ń yí, ìyàtọ̀ ti dé bá iṣẹ́ ìṣègùn báyìí. Iṣẹ́ wọn ṣì lè gbomi mu bíi ti Maimonides. Àmọ́, ṣé wọ́n ṣì ń bọ̀wọ̀ fún wọn bí wọ́n ti máa ń ṣe fáwọn dókítà látijọ́? Báwo ni ìgbà tó ń yí ṣe ń kan ọ̀nà táwọn dókítà gbà ń gbé ìgbésí ayé wọn? Báwo làwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí sì ṣe mú kí àárín dókítà àti aláìsàn yí padà?

Àárín Dókítà àti Aláìsàn Ò Rí Bíi Ti Tẹ́lẹ̀ Mọ́

Àwọn kan ṣì lè rántí ìgbà kan tí dókítà á kó gbogbo nǹkan tá á fi tọ́jú aláìsàn sínú báàgì dúdú. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lèrò àwọn èèyàn nípa àwọn dókítà nígbà yẹn, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí títí di ìsinsìnyí. Wọ́n máa ń gbóṣùbà fún ọ̀pọ̀ nínú wọn nítorí òye tí wọ́n ní, wọn ò sì kóyán wọn kéré láwùjọ, bákan náà èèyàn iyì ni wọ́n kà wọ́n sí nítorí ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Àmọ́ nígbà míì, àwọn èèyàn lè máa sọ pé owó iṣẹ́ wọn ti pọ̀ jù, wọ́n lè máa bú wọn tí wọn ò bá rí àìsàn kan wò, wọ́n sì lè máa fẹ̀sùn kàn wọ́n torí bó ṣe dà bíi pé wọn ò lójú àánú.

Síbẹ̀, ó máa ń dùn mọ́ ọ̀pọ̀ dókítà pé àwọn ló ń tọ́jú ìdílé kan náà látìrandíran. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ya ojúlé kiri láti lọ tọ́jú àwọn aláìsàn. Nígbà míì láwọn ìlú kéékèèké, wọ́n máa ń dúró jẹun, kódà wọ́n lè sun ibẹ̀ mọ́jú tí wọ́n bá ń gbẹ̀bí. Fúnra ọ̀pọ̀ dókítà ni wọ́n máa ń po oògùn tí ẹni tí wọ́n ń tọ́jú á lò. Àwọn oníṣègùn tí kì í fi ìmọtara ẹni nìkan ṣiṣẹ́ máa ń tọ́jú àwọn tí ò rọ́wọ́ họrí lọ́fẹ̀ẹ́, kò sì sígbà kan táwọn èèyàn dé ọ̀dọ̀ wọn tí wọn ò ní dá wọn lóhùn.

A mọ̀ pé àwọn oníṣègùn kan ṣì ń ṣiṣẹ́ wọn lọ́nà yìí o. Àmọ́ ó dà bíi pé láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sí ogójì ọdún báyìí, àárín àwọn dókítà àtàwọn aláìsàn ò rí bó ṣe rí ní bí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn mọ́. Kí ló wá fà á tí nǹkan fi yí padà bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa báwọn dókítà ṣe máa ń lọ tọ́jú àwọn aláìsàn nílé.

Báwo Lọ̀rọ̀ Bíbẹ Aláìsàn Wò Nílé Ti Rí Nísinsìnyí?

Ìgbà kan wà táwọn èèyàn gbà pé ńṣe ló yẹ káwọn oníṣègùn máa lọ tọ́jú àwọn aláìsàn nílé. Kódà wọ́n ṣì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí dòní láwọn ibì kan. Ṣùgbọ́n jákèjádò ayé ni àṣà yẹn ti ń dín kù. Ìwé ìròyìn The Times of India sọ pé: “Kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́ ká máa rí dókítà ìdílé, tá á máa kẹ́ aláìsàn, tá á mọ tiwá tẹ̀yìn ìdílé tó ń tọ́jú, tá á sì múra tán láti máa lọ bá àwọn aláìsàn nílé nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ gbàtọ́jú. Ohun tó fà á ni báwọn dókítà ṣe ń gbájú mọ́ ẹ̀ka kan ṣoṣo nínú ìmọ̀ ìṣẹ̀gùn, tó sì jẹ́ ìyẹn ni wọ́n á mọ̀ dunjú.”

Nítorí pé ìmọ̀ ìṣègùn ń jinlẹ̀ sí i, ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn ń fọwọ́ mú ẹ̀ka kan nínú ìmọ̀ ìṣègùn, wọ́n sì ń bá àwọn mìíràn tó mọ ẹka míì daṣẹ́ pọ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, nígbàkigbà tí ara ẹnì kan ò bá yá, ńṣe lá á lọ rí dókítà èyíkéyìí tó bá mọ̀ nípa àìsàn tó ń ṣe é. Nítorí èyí, kò ṣeé ṣe fáwọn dókítà mọ́ láti máa tọjú ìdílé kan ṣoṣo bíi ti tẹ́lẹ̀.

Ó ti tó bí ọgọ́rùn-ún ọdún táwọn dókítà ti ń pa àṣà lílọ máa bá àwọn aláìsàn nílé tì, ìyẹn nígbà táwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ sí tẹra mọ́ ṣíṣàyẹ̀wò nílé ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n sì ń lo àwọn irin iṣẹ́ ìṣègùn láti yẹ ara àwọn èèyàn wò. Níbi tó pọ̀ làwọn elétò ìlera ti rí i pé fífàkókò ṣòfò ni báwọn oníṣègùn ṣe ń lọ tọ́jú àwọn aláìsàn nílé. Lóde òní, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn aláìsàn ló lè rí ọkọ̀ wọ̀ lọ sí ọ́fíìsì dókítà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn olùtọ́jú èèyàn ní pàjáwìrì ti ń ṣe lára iṣẹ́ táwọn dókítà nìkan máa ń ṣe látijọ́.

Agbára Wọn Ti Dín Kù

Lóde òní, ó lójú àwọn dókítà tó dá wà láàyè ara wọn. Àwọn ilé ìwòsàn ìjọba àti ti aládàáni tí wọ́n sábà máa ń gba àwọn dókítà sí láti máa tọ́jú àwọn aláìsàn làwọn èèyàn ti lọ ń tọ́jú ara wọn. Àmọ́, kò wu ọ̀pọ̀ dókítà kó jẹ́ pé ẹnì kan lá máa pinnu iye aláìsàn tí wọ́n gbọ́dọ̀ dá lóhùn. Àwọn aláṣẹ irú àwọn ilé ìwòsàn bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fẹ́ káwọn dókítà dá àwọn aláìsàn tó pọ̀ lóhùn láàárín àkókò díẹ̀. Dókítà Sheila Perkins, tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó ń tọ́jú gbogbo onírúurú àìsàn sọ pé: “Mo ní láti dá ẹnì kan lóhùn láàárín ìṣẹ́jú méje sí mẹ́wàá. Èyí tó sì pọ̀ lára àkókò yìí ni máà fi tẹ àwọn nǹkan tí wọ́n bá sọ fún mi sínú kọ̀ǹpútà o. Àyè tó kù sílẹ̀ kò tó láti fi mọwọ́ àwọn tí mò ń tọ́jú dáadáa. Ó máa ń fi gbogbo nǹkan sú èèyàn ni jàre.”

Ara ohun tó mú ìyípadà bá iṣẹ́ dókítà ni pé ẹ̀tọ́ àwọn aláìsàn ti pọ̀ sí i. Nígbà kan rí, àṣẹ tí dókítà bá pa labẹ gé. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ilẹ̀ lónìí, ó di dandan fún dókítà láti ṣàlàyé oríṣiríṣi ọ̀nà ìtọ́jú tó wà fẹ́ni tó ń tọ́jú, ó sì gbọ́dọ̀ sọ ohun tó ṣeé ṣe kó tẹ̀yìn ọ̀kọ̀ọ̀kan wá fún un. Èyí lá jẹ́ kí ẹni náà yan ọ̀nà tó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn pé kí dókítà gbà tọ́jú òun. Nítorí náà ojú tí dókítà àti aláìsàn fi ń wo ara wọn ti yàtọ̀. Lójú àwọn kan, ńṣe ni dókítà kàn dà bí oníṣẹ́ ọwọ́ tẹ́ni tó gbéṣẹ̀ fún un lè yàn lé lọ́wọ́.

Ní àsìkò tó lòde báyìí, obìnrin ti pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìṣègùn bíi rẹ́rẹ. Àwọn èèyàn gba tàwọn dókítà obìnrin torí pé lójú wọn, elétí gbáròyé ni wọ́n. Nítorí náà, wíwà tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí ti mú kí ojú àánú wọ̀ ọ́.

Àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ máa ń mọyì dókítà tó bá lójú àánú, tó sì máa ń tètè lóye ohun tó ń ṣe àwọn tó ń tọ́jú àti ohun tó ń dà wọ́n láàmú. Ṣùgbọ́n ṣé kò yẹ ká béèrè pé, Agbàwòsàn mélòó ló lóye ohun tó ń ṣe dókítà àti ohun tó ń dà á láàmú? Dájúdájú ìyẹn á mú kí àárín dókítà àti agbàwòsàn túbọ̀ dán mọ́rán sí i. Àpilẹ̀kọ tó kàn lè ràn wá lọ́wọ́ lórí ìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Maimonides

[Credit Line]

Brown Brothers

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Látijọ́, ńṣe làwọn dókítà máa ń lọ kàn sáwọn èèyàn nílé