Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Wọ́n Ṣe Borí Jìnnìjìnnì Tó Bá Wọn Nígbà Táwọn Apániláyà Yin Bọ́ǹbù

Bí Wọ́n Ṣe Borí Jìnnìjìnnì Tó Bá Wọn Nígbà Táwọn Apániláyà Yin Bọ́ǹbù

Bí Wọ́n Ṣe Borí Jìnnìjìnnì Tó Bá Wọn Nígbà Táwọn Apániláyà Yin Bọ́ǹbù

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ

NÍ March 11 ọdún 2004, ìlú Madrid, lórílẹ̀-èdè Sípéènì mì tìtì nígbà táwọn èèyàn ń gbúròó bọ́ǹbù mẹ́wàá tó bú gbàù ní ibùdókọ̀ ojú irin mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìgbà kan náà làwọn bọ́ǹbù táwọn apániláyà kẹ́ sínú ọkọ̀ ojú irin mẹ́rin yìí bú gbàù, igba ó dín mẹ́wàá [190] èèyàn ló bá a rìn, tí ẹgbàásàn-án [1,800] èèyàn sì fara pa.

Ọwọ́ àárọ̀ táwọn èèyàn máa ń dà gìrìgìrì làwọn bọ́ǹbù náà bú gbàù. Ìyẹn ló jẹ́ kí ọṣẹ́ tí ìjàǹbá náà ṣe pọ̀ gan-an nítorí pé ńṣe làwọn èrò kún inú àwọn ọkọ̀ ojú irin náà fọ́fọ́. Aroa, tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣojú ẹ̀, sọ pé: “Bọ́ǹbù tó bú gbàù yẹn lágbára débi pé ó gbé odidi wágùnnù ọkọ̀ ojú irin kan lọ sókè bíi mítà kan tàbí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta. Nígbà tí mo jáde nínú wágùnnù ọkọ̀ ojú irin tí mo wọ̀, ńṣe ni gbogbo ibi tá a wà rí bí ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀ṣẹ̀ jagun tán. Kódà béèyàn jẹ orí ahun, bó bá rí báwọn èèyàn ṣe kú ikú oró báyìí, àánú á ṣe é.” Irú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi báyìí ṣẹlẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, inú wágùnnù mẹ́wàá làwọn bọ́ǹbù náà sì ti yìn. Àwọn apániláyà ti kọ́kọ́ lọ gbé àwọn báàgì tó kún fún bọ́ǹbù sínú àwọn ọkọ̀ ojú irin, wọ́n kẹ́ àwọn bọ́ǹbù náà, lẹ́yìn yẹn ni wọ́n wá fi tẹlifóònù alágbèéká yìn wọ́n.

Àwọn kan lára àwọn èrò ọkọ̀ rí ọpẹ́ dá pé wọn ò rántí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó ṣẹlẹ̀ sí wọ́n yìí mọ́. Ṣùgbọ́n ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ kò kúrò lára àìmọye àwọn míì bí Aroa. Ó sọ pé: “Ìró bọ́ǹbù yẹn ò jẹ́ kí n lè gbọ́ràn dáadáa mọ́, ṣùgbọ́n ohun tó ń dà mí láàmú jù ni tàwọn nǹkan burúkú tí mo fojú mi rí lọ́jọ́ yẹn tó ṣì máa ń sọ sí mi lọ́kàn.

“Mo dúpẹ́ pé mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ará ò dá mi dá ohun tó ń ṣe mí. Àìmọye àwọn ará ló ń ké sí mi lórí tẹlifóònù tí wọ́n sì ń kọ̀wé ránṣẹ́ sí mi láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, èyí sì rán mi létí pé lóòótọ́ la jẹ́ ẹgbẹ́ ara kárí ayé. Pẹ̀lúpẹ̀lù, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀dí táwọn láabi wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀. Mo ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ fáwọn ara ibi iṣẹ́ wa, pé ní ‘àwọn ọjọ́ ìkẹyìn’ àwọn èèyàn á jẹ́ òǹrorò àti aláìní ìfẹ́ni àdánidá. Mo tún rí i pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí mò ń ṣe ti jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn mi dín kù gan-an.”—2 Tímótì 3:1-3.

Pedro wà lára àwọn èrò tó fára pa yánnayànna. Ìdí ni pé ibi tó wà nínú wágùnnù ọkọ̀ ojú irin tó wọ̀ kò tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ibi tí bọ́ǹbù náà ti yìn. Bọ́ǹbù náà fọ́ ọ mọ́lẹ̀, ó sì fi orí ṣèṣe, kò tún lè mí dáadáa mọ́. Ó lo ọjọ́ márùn-ún ní wọ́ọ̀dù tí wọ́n ti ń bójú tó àwọn tọ́rọ̀ wọn bá lé kenkà kó tó bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn díẹ̀díẹ̀. Rírọ́ táwọn ajẹ́rìí ẹgbẹ́ ẹ̀ ń rọ́ lọ síbẹ̀ mú kó tètè gbọnra nù, èyí sì jọ àwọn nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú ẹ̀ lójú. Ọ̀rọ̀ náà ya nọ́ọ̀sì kan lẹ́nu, ó sì sọ pé: “Láti bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, mi ò tíì rí ẹnì kankan tí wọ́n ń rọ́ wá kí báyìí, tó sì gbẹ̀bùn tó pọ̀ tó báyìí rí!” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, Pedro náà sọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà dáadáa. Ó sọ pé: “Wọ́n ṣe bẹbẹ. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ gan-an tí mo fi tètè gbádùn.”

Àwọn àjèjì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá sí orílẹ̀-èdè Sípéènì pọ̀ lára àwọn tó fara gbá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, bọ́ǹbù tó kọ́kọ́ bú gbàù ní ibùdókọ̀ ojú irin Atocha ṣe Manuel ọmọ orílẹ̀-èdè Cuba léṣe gan-an ni, ó sì dá kú lọ rangbandan nígbà tí èkejì bú gbàù. Ó ṣàlàyé pé: “Nígbà tọ́rọ̀ di bóò-lọ-o-yà-ń-mi, ńṣe làwọn èèyàn ń gborí mi kọjá níbi tí mo sùn gbalaja sí níbi táwọn èrò máa ń gbà wọnú ọkọ̀ ojú irin. Nígbà tí mo fi máa ta jí, eegun ìhà mi méjì ti kán, bákan náà ni mo fi ẹsẹ̀ pa, etí mi kan sì di pátápátá.

“Kó tó pé ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì, ìyẹn àwọn ọlọ́pàá, àwọn tó ń wakọ̀ áńbúláǹsì, àtàwọn panápaná, ti débẹ̀, wọ́n sì fi gbogbo ohun tó wà lágbára wọn ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ wọn páápààpá tí wọ́n sì ń jára mọ́ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó mọṣẹ́ dunjú mú kí dídà gìrìgìrì yẹn rọlẹ̀ díẹ̀. Wọ́n rí i dájú pé mo rí ìtọ́jú tó yẹ gbà, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ṣe mí jẹ́jẹ́ wọ́n sì ṣàánú mi.”

Àwọn Tí Ìpayà Bá Lẹ́yìn Náà

Bíi ti Aroa, inú fu, ẹ̀dọ̀ fu ni Manuel náà wà. Ó sọ pé: “Mo díjì láìpẹ́ yìí nígbà tí mo wà nínú ọkọ̀ ojú irin. Kíá ni mo yáa bọ́ sílẹ̀. Kódà, nígbàkigbà tí mo bá rẹ́ni tó fi báàgì gbẹ́rù tàbí nǹkan míì tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú ọkọ̀ èrò, ara ṣì máa ń fu mí sí onítọ̀hún. Àmọ́, mo rẹ́ni ràn mí lọ́wọ́ ju àwọn tó kù lọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ará ilé mi kankan tó ń gbé ní Sípéènì. Bá a bá kà á ní méní méjì, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló pè mí lórí tẹlifóònù, àwọn ìdílé kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí sì pè mí pé kí n wá lo ọjọ́ mélòó kan nílé àwọn kó má bàa ṣe èmi nìkan. Ìrànlọ́wọ́ tí ò ṣeé fẹnu sọ táwọn ẹgbẹ́ ará kárí ayé ṣe fún mi yìí ràn mí lọ́wọ́ láti sinmẹ̀dọ̀.”

Sergio wà lára àwọn tí kò fara pa, ṣùgbọ́n ojoojúmọ́ láwọn nǹkan tó rí láyìíká ẹ̀ ṣì máa ń da ọkàn rẹ̀ rú. Bọ́ǹbù kan yìn nínú wágùnnù ojú irin tó wà níwájú ẹ̀, òmíràn sì yìn nínú èyí tó wà lẹ́yìn rẹ̀ ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé. Bíi ti Manuel, òun náà lóun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹbí òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí bíi tòun. Ó sọ pé: “Kì í ṣe pé wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí mi nìkan ni, wọ́n tún rán mi létí pé inú ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan táwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà sì ń tọ́jú ara wọn ni mo wà. Wọn ò fi mí sílẹ̀ lọ́jọ́ kan ṣoṣo, bí wọ́n ṣe ń pè mí lórí tẹlifóònù sì ń jẹ́ kí n lè sọ ohun tó ń ṣe mí fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣe bẹ́ẹ̀.”

A sì rí àwọn míì lára èrò tó wà nínú àwọn ọkọ ojú irin náà tó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lohun tó ń dà wọ́n láàmú. Diego ò mọ̀ pé ẹ̀gbẹ́ ọ̀kan lára àwọn bọ́ǹbù mẹ́rin tí kò yìn lòun jókòó sí. Ó ráyè sá jáde nínú ọkọ̀ ojú irin yẹn láìfarapa. Àmọ́, ó jẹ́wọ́ pé ọkàn òun ń dá òun lẹ́bi pé òun ò dúró ran àwọn tó fara pa lọ́wọ́. Ó ní: “Nígbà tọ́rọ̀ di pàá kìràkìtà, mi ò mọ bí mo ṣe jáde láàárín ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn yòókù, tí gbogbo wa ń wá bá a ṣe máa sá jìnnà sí ibùdókọ̀ ojú irin náà.”

Bọ́ǹbù tó bú gbàù nínú ọkọ̀ ojú irin tí Ramón, ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti orílẹ̀-èdè Brazil, wọ̀ já a láyà débi pé kò lè mira. Síbẹ̀, lọ́jọ́ kẹ́ta tí bọ́ǹbù náà yìn, ó pinnu pé òun á lọ wàásù Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn. Ó pàdé ọkùnrin ará ilẹ̀ Potogí kan tó sọ fún un pé òun ń wá ìsìn tòótọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kíá lọkùnrin yẹn sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé ìjọ. Ramón wá sọ pé: “Tó o bá lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ìwọ fúnra rẹ á gbádùn ara ẹ.”

Ó dájú pé á ṣe díẹ̀ kí ìròra àti àìbàlẹ̀ ọkàn tó lè tán lára gbogbo àwọn tó fara gbá nínú ìjàǹbá náà. Ó dunni pé lákòókò tá à ń gbé yìí, ibikíbi ni wàhálà ti lè bẹ́ sílẹ̀ láìnídìí. Àti pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lè jẹ́ káwọn tí ìpayà bá mọ́kàn, síbẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa kásẹ̀ gbogbo àjálù wọ̀nyí nílẹ̀.—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

OHUN TÓ FÚN WỌN LÓKUN TẸ̀MÍ LÁTI BORÍ JÌNNÌJÌNNÌ TÓ BÁ WỌN

Manuel Suárez

“Nígbà tí ojora ṣì ń mú mi tí mo sì ń dúró dìgbà tí mo máa lọ sílé ìwòsàn, mi ò yé rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 18:10 pé: ‘Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.’ Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fún mi lókun gan-an ni.”

Aroa San Juan

“Nígbà tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, wàá lè túbọ̀ máa fi sọ́kàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí àti pé ó yẹ ká máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sọ́kàn. Mo dúpẹ́ pé mo wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, jìnnìjìnnì yẹn ti ń kúrò lára mi báyìí.”

Fermín Jesús Mozas

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo forí pa, mo ṣì ran àwọn tá a jọ wà nínú ọkọ̀ ojú irin lọ́wọ́ mo sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ó dà bíi pé ohun tí ò jẹ́ kẹ́rù bà mí ni ìrètí tá a ní pé Ọlọ́run á jí àwọn òkú dìde, ìrètí yìí ló máa ń fún wa lókun nírú àkókò báyìí.”

Pedro Carrasquilla

“Nígbà tí wọ́n tẹ́ mi sí wọ́ọ̀dù ìtọ́jú àkànṣe, tí àyà ń ro mí burúkú burúkú, ńṣe lọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Tímótì 6:19 ń sọ sí mi lọ́kàn ṣáá. Ibẹ̀ rọ̀ wá pé ká máa to ìṣúra jọ fún ara wa gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ tó jíire fún ẹ̀yìn ọ̀la ká bàa lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí. Ẹsẹ Bíbélì yìí rán mi létí Párádísè tá à ń retí, èyí tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ohun tí gbogbo wa ń lé nìyẹn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Òkè: Àwọn òṣìṣẹ́ agbẹ̀mílà tó ń tọ́jú àwọn tó fara pá àti àwọn tó ń kú lọ lójú irin ní ìbúdókọ̀ ojú irin Atocha

[Credit Line]

Tòkè: CORDON PRESS

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Lápá ọ̀tún: Ilé tí wọ́n tún ṣe ní ìrántí àwọn tó ṣègbé