Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Àníyàn Ṣíṣe Dá Ọ Lágara
Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Àníyàn Ṣíṣe Dá Ọ Lágara
“ÀWỌN èèyàn ti túbọ̀ ń sapá gidigidi kí ọ̀kan má bàa pa èkejì lára nínú iṣẹ́ wọn, àbójútó ilé, àtàwọn ojúṣe míì láti bí ọdún mélòó kan báyìí.” Ohun tí ìwé kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ lórí ọ̀ràn ìdílé sọ nìyẹn. Dájúdájú, àkókò onípákáǹleke là ń gbé. Àmọ́ ṣá, èyí kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà.”—2 Tímótì 3:1-5.
Bàbá kan tó ń jẹ́ Jesús, tó sì ti bímọ mẹ́ta, sọ pé: “Kò sí ohun tó burú nínú ṣíṣàníyàn. Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ mọ bó ò ṣe ní jẹ́ kó dá ọ lágara.” Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti kó àníyàn kúrò lọ́kàn. Bí ọ̀ràn bá tiẹ̀ wá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àbá tó wúlò àtàwọn ìlànà Bíbélì wà tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
Bí Àníyàn Ṣíṣe Lẹ́nu Iṣẹ́ Ò Ṣe Ní Dá Ọ Lágara
Ṣé bí nǹkan ṣe rí lẹ́nu iṣẹ́ rẹ ń mú kí agara máa dá ọ? Bó o bá bo ohun tó ń ṣe ọ́ mọ́ra, ọrùn á túbọ̀ máa wọ̀ ọ́ sí i ni o. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ nínú Òwe 15:22, “àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.”
Àwọn tó ń ṣèwádìí lórí àníyàn ṣíṣe lẹ́nu iṣẹ́ dámọ̀ràn pé kó o sọ ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ fún ọ̀gá rẹ, nítorí pé ó ṣeé ṣe kó ràn ọ́ lọ́wọ́ bó bá mọ ohun tó ń yọ ọ́ lẹ́nu. Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kó o máa fìbínú da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ o. Ìwé Oníwàásù 10:4 tiẹ̀ sọ pé: “Ìparọ́rọ́ ń pẹ̀tù sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.” Nítorí náà, má ṣe gbàgbé pé ọ̀gá ẹ lò ń bá sọ̀rọ̀, má gbéjà kò ó. O sì lè jẹ́ kó dá ọ̀gá rẹ lójú pé bí àníyàn ṣíṣe ò bá pọ̀ jù lẹ́nu iṣẹ́, iṣẹ́ á yá.
Fífi ohùn tútù sọ̀rọ̀ tún lè ṣèrànwọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro míì lẹ́nu iṣẹ́, irú bíi káwọn òṣìṣẹ́ máà fẹ́ ríra wọn sójú kí wọ́n sì máa bara wọn jà. Wá àwọn ọ̀nà tó dáa tó o lè gbà bójú tó irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, bóyá nípa ṣíṣe ìwádìí, bó bá pọn dandan. Ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ tá a ti tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. a Bó bá wá jẹ́ pé ibi pẹlẹbẹ náà ni ọ̀bẹ ń fi lélẹ̀, bóyá á kúkú dáa kó o wá iṣẹ́ sí ibòmíì.
Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ṣíṣàníyàn Nípa Ìṣúnná Owó Dá Ọ Lágara
Ìmọ̀ràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tí àníyàn nípa ìṣúnná owó ò fi ní dá ọ lágara tún wà nínú Bíbélì. Jésù Kristi gbani níyànjú pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.” (Mátíù 6:25) Báwo lo ṣe lè dẹ́kun ṣíṣàníyàn? Nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà Ọlọ́run á pèsè àwọn nǹkan tó jẹ́ kòṣeémánìí fún ọ ni. (Mátíù 6:33) Ìlérí Ọlọ́run kì í ṣe ìlérí oréfèé lásán. Ìlérí tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni lónìí gbára lé ni.
Àmọ́ ṣá o, o tún nílò “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” bó bá dọ̀ràn olówó dé. (Òwe 2:7; Oníwàásù 7:12) Bíbélì rán wa létí pé: “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:7, 8) Ohun tó bọ́gbọ́n mu tó sì dáa jù ni pé kéèyàn kọ́ láti jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tó òun. Rántí Leandro, tí jàǹbá sọ dẹni tí wọ́n ń fi kẹ̀kẹ́ tì. Òun àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ owó wọn ná. Leandro ṣàlàyé pé: “A sapá láti máa ṣọ́ owó ná. Bí àpẹẹrẹ, pípa la máa ń pa iná tá ò bá lò ká bàa lè dín owó tá à ń san lórí iná mànàmáná kù. Ní ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, ńṣe la máa ń fètò sí gbogbo ibi tá a bá ń lọ, tá ó sì pa ìrìn àjò pọ̀ ká bàa lè dín owó tá à ń ná lórí epo ọkọ̀ kù.”
Àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè máa hùwà ọmọlúwàbí. Carmen, ọmọbìnrin Leandro, sọ pé ohun tí òun bá ṣáà ti rí lòun máa ń fẹ́ rà, ṣùgbọ́n àwọn òbí òun ti wá ran òun lọ́wọ́ láti máa fòye mọ ohun tó yẹ ni rírà àtèyí tí kò yẹ ní rírà. Ó sọ pé ó kọ́kọ́ nira fún òun láti fara mọ́ ohun tí wọ́n ń sọ. Ó wá sọ pé lẹ́yìn náà lòun kọ́ láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí òun ń fẹ́ àti ohun tí òun nílò.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Máa Ń Dín Ṣíṣàníyàn Kù
Kò yẹ kí àníyàn ṣíṣe tiẹ̀ máa bá èèyàn dé inú ilé rárá, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, inú ilé gan-an ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìwé Survival Strategies for Couples, sọ pé: “Àwọn tọkọtaya . . . tó ṣeé ṣe kí ọkàn wọn máà lélẹ̀, tàbí àwọn tó máa ń bára wọn jiyàn, sọ pé ohun tó sábà máa ń fa àìgbọ́ra ẹni yé ni àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀.”
Àwọn ìlànà Bíbélì lè ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà, ó sì tún sọ pé “ọ̀rọ̀ tí ó . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Oníwàásù 3:1, 7; Òwe 15:23) Látàrí ohun tí Bíbélì sọ yìí, ìwọ náà ò ní fẹ́ láti dá ọ̀rọ̀ tó máa bí ọkọ tàbí aya rẹ nínú sílẹ̀, lẹ́yìn tó ti rẹ̀ ẹ́, tàbí tó ti ṣiṣẹ́ tó gbomi mu. Ṣé kò wá ní bọ́gbọ́n mu kó o kúkú dúró dìgbà tó bá yẹ, nígbà tí ara ọkọ tàbí aya rẹ á wà lọ́nà láti gbọ́ ohun tó o bá ní sọ?
Òótọ́ ni pé bí iṣẹ́ bá gbomi mu fún ọ lọ́jọ́ kan, bó o bá délé, ó lè máà rọrùn fún ọ láti máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ kó o sì máa ṣe sùúrù. Ṣùgbọ́n kí ló lè ṣẹlẹ̀ nítorí inú tó ń bí wa bá a bá fi ìkanra mọ́ ọkọ tàbí aya wa nípa sísọ̀rọ̀ líle sí i? Bíbélì rán wa létí pé “ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, “àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni jẹ́ afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.” (Òwe 16:24) Ó lè gba pé kí tọkọtaya pinnu pé àwọn ò ní jẹ́ kí “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú” máa wọ inú ìjíròrò àwọn. (Éfésù 4:31) Àǹfààní púpọ̀ ló sì ń tìdí ẹ̀ wá. Bí tọkọtaya bá ń bára wọn sọ̀rọ̀, àwọn méjèèjì á máa tu ara wọn nínú wọ́n á sì máa ti ara wọn lẹ́yìn. Ìwé Òwe 13:10 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” b
Kì Í Rọrùn fún Òbí Àtọmọ Láti Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀
Ìṣòro ńlá ni bíbá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀ jẹ́, pàápàá nígbà tí ò bá fi bẹ́ẹ̀ sí àkókò. Bíbélì rọ àwọn òbí láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà, bíi nígbà tí wọ́n bá ‘jókòó nínú ilé àti nígbà tí wọ́n bá ń rìn ní ojú ọ̀nà.’ (Diutarónómì 6:6-8) Leandro sọ pé: “Àfi kéèyàn máa wá bó ṣe máa bá wọn sọ̀rọ̀. Bí èmi àti ọmọ mi ọkùnrin bá wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, mo máa ń lo àǹfààní yẹn láti bá a sọ̀rọ̀.”
Lóòótọ́, gbogbo òbí kọ́ ló rọrùn fún láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Alejandra, tó jẹ́ ìyá àwọn ọmọ mẹ́ta, tiẹ̀ jẹ́wọ́ ara ẹ̀, ó sọ pé: “Mi ò mọ béèyàn ṣeé tẹ́tí sí ọmọdé. Àìkìí bá ara wa sọ̀rọ̀ máa ń mú kí inú bí mi, ọkàn mi sì máa ń dá mi lẹ́bi.” Kí wá làwọn òbí lè ṣe síyẹn? Kọ́kọ́ mọ béèyàn ti í “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́.” (Jákọ́bù 1:19) Ọ̀mọ̀wé Bettie B. Youngs sọ pé: “Títẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ ni irinṣẹ́ tó gbéṣẹ́ jù lọ fún dídín àníyàn ṣíṣe kù.” O gbọ́dọ̀ kíyè sí bó o ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀. Máa wojú ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀. Má máa fojú kéré ìṣòro àwọn ọmọ rẹ. Fún wọn lómìnira láti máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Máa béèrè àwọn ìbéèrè tá mú kí wọ́n sọ tinú wọn jáde. Máa sọ fún wọn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, kó o sì máa mú un dá wọn lójú pé o gbà pé ohun tó tọ́ ni wọ́n á ṣe. (2 Tẹsalóníkà 3:4) Máa bá àwọn ọmọ rẹ gbàdúrà pọ̀.
Ó gba ìsapá kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó mọ́yán lórí tó lè máa wáyé déédéé. Síbẹ̀, jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ lè dín àníyàn ṣíṣe kù nínú ìdílé yín. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fòye mọ̀ bí àwọn ọmọ rẹ bá ń ṣàníyàn jù. Á túbọ̀ rọrùn fún ọ láti máa fi ọgbọ́n tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà bó o bá mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn àti ohun tí ọ̀rọ̀ wọn gbà. Lákòótán, bí ẹ̀yin òbí bá fáwọn ọmọ lómìnira láti máa sọ tinú wọn jáde, bí ohunkóhun bá ń kó wọn lọ́kàn sókè, wọn ò ní máa fi hùwà tí kò dáa.
Ẹ Máa Pawọ́ Pọ̀ Ṣiṣẹ́ Ilé
Bó bá jẹ́ pé tọkọtaya ló máa ń lọ síbi iṣẹ́, bíbójú tó iṣẹ́ ilé lè di ohun mìíràn tá á mú kí wọ́n máa ṣàníyàn. Ọgbọ́n táwọn ìyá kan tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti mówó wọlé ń dá sí i ni pé wọ́n máa ń dín iṣẹ́ ilé kù. Wọ́n lè pinnu pé àwọn ò ní máa gbọ́únjẹ tó pọ̀ nítorí pé àwọn ò ní àkókò tó pọ̀. Rántí ìmọ̀ràn tí Jésù fún obìnrin kan tó ń se àsè. Ó wí fún un pé: “Nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò.” (Lúùkù 10:42) Nítorí náà, ṣe ohun gbogbo níwọ̀n. Ìwé The Single-Parent Family dámọ̀ràn pé: “O lè máa se oúnjẹ nínú ìkòkò ọbẹ̀ kan náà dípò tí wàá fi máa sè wọ́n sínú ìkòkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kí abọ́ tó o máa fọ̀ lè dín kù.” Bẹ́ẹ̀ ni o, jíjẹ́ kí iṣẹ́ ilé mọ níwọ̀n á dín pákáǹleke kù.
Síbẹ̀, àwọn nǹkan míì ṣì wà tá á dáa kó o ṣe o. Ìyá kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ sọ bọ́ràn tiẹ̀ ṣe rí, ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà léwe, kò sí ohun tí mi ò lè ṣe tán. Àmọ́, nísinsìnyí tí mo ti dàgbà, ó wá túbọ̀ nira fún mi. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń mọ ìgbésí ayé oní-ságbà-súlà tí mo ti gbé lára ni. Nítorí náà, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tọ̀tún tòsì nínú ìdílé ló ń fi hàn pé wọ́n gba tèmi rò, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí àníyàn ṣíṣe dá mi lágara.” Bẹ́ẹ̀ ni o, bí tọ̀tún tòsì bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ìdílé, wẹ́rẹ́ báyìí lẹ ó máa bójú tó àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé láìfi iṣẹ́ pá ẹnikẹ́ni lórí. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ lórí béèyàn ṣe lè jẹ́ òbí sọ pé: “Yíyan iṣẹ́ ilé fáwọn ọmọ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn fi lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé . . . àwọn náà tóótun. Béèyàn bá ń ṣe iṣẹ́ ilé déédéé, á kọ́ èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ tó jíire, kò sì ní jẹ́ kéèyàn ṣọ̀lẹ.” Bí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ bá jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ ilé, á jẹ́ kó o lè máa wà pẹ̀lú wọn.
Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Julieta sọ pé: “Mo rí i pé ara máa ń tu màmá mi bí mo bá bá a ṣe díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ tó yẹ ní ṣíṣe. Ìyẹn máa ń mú inú mi dùn, mo sì máa ń rí ara mi bí ẹni tó ṣeé gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́. Ó ń mú kí n mọrírì inú ilé tí mo ti jáde wá. Ẹ̀kọ́ tí mo ti kọ́ nípa béèyàn ṣe ń bójú tó àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé sì ti jẹ́ kí n mọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí màá bá pàdé lọ́jọ́ iwájú.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Mary Carmen náà sọ pé: “Látìgbà tá a ti wà ní kékeré làwọn òbí mi ti kọ́ wa bá ṣe lè máa bójú tó ara wa. Àǹfààní ńláǹlà nìyẹn sì ti jẹ́ fún wa.”
Bí Àníyàn Ṣíṣe Ò Ṣe Ní Dá Ọ Lágara
Gbogbo èèyàn ló ń ṣàníyàn; kò sì ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, o lè kọ́ bí ò ṣe ní dá ọ lágara. (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 10.) Àwọn ìlànà Bíbélì lè ran èèyàn lọ́wọ́ béèyàn bá tẹ̀ lé wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn ipò kan bá ga ọ́ lára, rántí pé “ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” (Òwe 18:24) O lè bá ọ̀rẹ́ ẹ tó dàgbà dénú, ọkọ rẹ tàbí aya rẹ jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Ronald L. Pitzer, sọ pé: “Má bò ó mọ́ra o. Bó o bá rí olórí pípé èèyàn kàn tó ṣeé ṣe kó lóye ẹ̀ kó sì gbọ̀rọ̀ rẹ rò, sọ bó ṣe ń ṣe ọ́ fún un.”
Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa bíbá “ọkàn ara [ẹni] lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.” (Òwe 11:17) Dájúdájú, ó dára kó o máa wáyè gbọ́ tara rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Wíwá àkókò fún ara rẹ, lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti dín àníyàn ṣíṣe kù, ì báà jẹ́ ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, kó o bàa lè wá nǹkan panu, kó o lè kàwé, kó o lè gbàdúrà, tàbí kó o lè ṣàṣàrò nírọ̀wọ́ rọsẹ̀.
Ṣíṣe eré ìdárayá níwọ̀n àti jíjẹ oúnjẹ tó dáa tún ní ìrànlọ́wọ́ tó máa ń ṣe fún ìlera. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ lórí jíjẹ́ òbí sọ pé: “Bó o bá ń lo díẹ̀ lára àkókò tí ò tó lò àti okun rẹ láti bójú tó ọ̀ràn ara rẹ̀, ńṣe lá dà bí ìgbà tó ń pọnmi sílẹ̀ de òùngbẹ. . . . Béèyàn bá sì ń wáyè gbọ́ tara ẹ̀ déédéé, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun ń wá àyè fún ara nísinmi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọkàn rẹ̀ lè máà lélẹ̀ tàbí kó kúkú tán ara rẹ̀ lókun pátápátá.”
Ní àfikún sí i, Bíbélì máa ń ranni lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ tí ò ní mú kí ṣíṣàníyàn dáni lágara, irú bí “inú tútù,” sùúrù àti inú rere. (Gálátíà 5:22, 23; 1 Tímótì 6:11) Kò mọ síbẹ̀ yẹn nìkan, Bíbélì tún fi hàn pé a ní ìrètí, ìyẹn ni ìrètí nípa ayé tuntun kan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, nínú èyí tí gbogbo nǹkan tó ń fa wàhálà bá ẹ̀dá ò ti ní sí mọ́! (Ìṣípayá 21:1-4) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ ọ́ dàṣà láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Bó o bá fẹ́ mọ bí wà á ṣe máa ṣe é àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè wá máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, inú wọ́n á dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́, lọ́fẹ̀ẹ́, láìgba kọ́bọ̀.
A ò sọ pé ẹní bá jẹ́ Kristẹni kì í ṣàníyàn o. Ṣùgbọ́n Jésù sọ pé èèyàn lè ṣe é tí kò fi ní di ẹni tí “a dẹrù pa pẹ̀lú . . . àwọn àníyàn ìgbésí ayé.” (Lúùkù 21:34, 35) Bákan náà, bó o bá mọ Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ, ó lè jẹ́ ibi ààbò fún ìwọ náà! (Sáàmù 62:8) Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó o máa ṣe nípa àwọn àníyàn ìgbésí ayé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà “Bí Wọ́n Bá Dájú Sọ Ọ́ Níbi Iṣẹ́—Kí Lo Lè Ṣe?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti May 8, 2004.
b Bó o bá ń fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo orí 3 nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Nígbà tí mo wà léwe, kò sí ohun tí mi ò lè ṣe tán. Àmọ́, nísinsìnyí tí mo ti dàgbà, ó wá túbọ̀ nira fún mi. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ń mọ ìgbésí ayé oní-ságbà-súlà tí mo ti gbé lára ni”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Béèyàn Ṣe Lè Dín Ṣíṣàníyàn Kù
◼ Máa fún ara rẹ ní ìsinmi tó pọ̀ tó lójoojúmọ́
◼ Máa jẹ oúnjẹ tó dáa síkùn ẹ. Má máa jẹ àjẹkì
◼ Máa ṣeré ìdárayá tara bá nílò déédéé, irú bíi rírìn kánmọ́kánmọ́
◼ Bí ohun kan bá ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́, sọ ọ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ
◼ Máa lo àkókò tó pọ̀ sí i pẹ̀lú ìdílé rẹ
◼ Máa yan iṣẹ́ ilé fún àwọn míì nínú ìdílé tàbí kẹ́ ẹ máa pín in ṣe
◼ Mọ ibi tí agbára rẹ mọ àti ìwọ̀nba ohun tó o lè gbé sọ́kàn
◼ Má máa ṣe jura ẹ lọ; má sì máa rò pé o gbọ́dọ̀ mọ gbogbo nǹkan ṣe
◼ Wà létòletò; sì ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó mọ níwọ̀n tó sì bọ́gbọ́n mu
◼ Kọ́ bó o ṣe lè ní àwọn ànímọ́ Kristẹni bí ìwà tútù àti sùúrù
◼ Máa wá àkókò gbọ́ tara ẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bó o bá ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá ọ̀gá rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro rẹ, ó lè dín ṣíṣàníyàn lẹ́nu iṣẹ́ kù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn òbí lè bá àwọn ọmọ wọn jíròrò lórí bí wọ́n á ṣe máa ṣọ́ owó ná
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, jẹ́ kí ẹni tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ mọ̀ nípa ohun tó ò ń ṣàníyàn lé lórí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ẹ lè ran ara yín lọ́wọ́ nínú ìdílé