Ibo Lọ̀rọ̀ Iṣẹ́ Ìṣègùn Máa Já sí Lọ́jọ́ Iwájú?
Ibo Lọ̀rọ̀ Iṣẹ́ Ìṣègùn Máa Já sí Lọ́jọ́ Iwájú?
LỌ́PỌ̀ ìgbà, béèyàn bá béèrè ibi tí nǹkan máa já sí fáwọn oníṣègùn lọ́jọ́ iwájú, ńṣe làwọn èèyàn máa ń méfò pé bóyá ìtẹ̀síwájú tó dé bá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lè gba àwọn oníṣègùn lọ́wọ́ ṣíṣiṣẹ́ kan náà ní àṣekúdórógbó, tí wọ́n á sì lè ráyè gbọ́ tàwọn aláìsàn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Kì í ṣe àwọn oníṣègùn nìkan lohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú máa kàn, gbogbo aráyé lápapọ̀ ló máa ṣẹlẹ̀ sí. Ìwé méjì kan wà nínú Bíbélì tó ṣàlàyé nípa ohun tá á ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, wọ́n sì tún mẹ́nu ba ìtàn Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Oníṣègùn lẹni tó kọ ìwé méjèèjì.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣàyẹ̀wò bí oníṣègùn kan ṣe pa àwọn ìtàn yìí? Báwo làwọn ìtàn náà ṣe kan ọjọ́ iwájú àwọn oníṣègùn àtàwọn agbàtọ́jú? Kí ló dé táwọn oníṣègùn kan fi ń retí ọjọ́ iwájú nígbà tá ò ní nílò iṣẹ́ wọn mọ́?
Ọ̀pọ̀ oníṣègùn máa ń kíyè sí nǹkan dáadáa. Lúùkù, ẹni tí Bíbélì pè ní “oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” ló kọ ìwé méjèèjì tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ó sì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àwọn aláìsàn tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì wò sàn. (Kólósè 4:14) Lúùkù tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Ṣé lóòótọ́ làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀? Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n ṣẹlẹ̀, kí ló túmọ̀ sí fáwọn dókítà àtàwọn agbàwòsàn lónìí?
Ẹ̀rí Àrídájú Látọ̀dọ̀ Oníṣègùn
Lúùkù láǹfààní láti jẹ́rìí sí i pé iṣẹ́ ìyanu làwọn ìwòsàn yẹn nípa fífọ̀rọ̀ wá àwọn tó ṣojú wọn lẹ́nu wò. Yàtọ̀ síyẹn, ó bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rin ìrìn-àjò púpọ̀. Ó hàn gbangba pé níṣojú Lúùkù ni Pọ́ọ̀lù ti wo àwọn èèyàn kan sàn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu. Bí a ó ṣe máa ṣàgbéyẹ̀wò àkọsílẹ̀ méjì lára irú ìwòsàn bẹ́ẹ̀ báyìí, kíyè sí bí Lúùkù ṣe ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí wọn.
Lúùkù sọ àkókò, ọjọ́, àti ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ tá a fẹ́ sọ yìí ti wáyé. Ó sọ pé ní ọ̀gànjọ́ òru ni, lọ́jọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, àti pé àwọn Kristẹni kan kóra jọ sínú yàrá Ìṣe 20:4-8) Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé: “Ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yútíkọ́sì . . . ni oorun àsùnwọra gbé lọ bí Pọ́ọ̀lù ti ń bá ọ̀rọ̀ nìṣó, àti pé, ní sísọranù lójú oorun, ó ṣubú lulẹ̀ láti àjà kẹta, a sì gbé e ní òkú.” Pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, Pọ́ọ̀lù wo àwọn ọgbẹ́ tó wà lára ọ̀dọ́kùnrin yìí sàn, ó sì jí i dìde. Lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán, “wọ́n mú ọmọdékùnrin náà lọ láàyè, a sì tù wọ́n nínú lọ́nà tí kò ṣeé díwọ̀n.”—Ìṣe 20:9-12.
ní àjà kẹta ilé kan ní Tíróásì, ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Róòmù ní Éṣíà. (Lúùkù ròyìn pé òun bá Pọ́ọ̀lù dé Málítà pẹ̀lú. Púbílọ́sì, tó jẹ́ “ọkùnrin sàràkí” erékùṣù yẹn ló gbà wọ́n lálejò ó sì tọ́jú wọn gan-an, ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù ti ṣiṣẹ́ ìyanu míì. Láyé ìgbà yẹn, àìsàn tó ń ṣe ẹni tí Pọ́ọ̀lù wò sàn yẹn lè pààyàn, nítorí pé kò tíì sáwọn oògùn apakòkòrò ayé ìsinsìnyí. Lúùkù ròyìn pé bàbá Púbílọ́sì ń ṣàìsàn ibà, ó sì ń yàgbẹ́ ọ̀rìn. Ó tẹ̀ síwájú pé: “Pọ́ọ̀lù sì wọlé lọ bá a, ó sì gbàdúrà, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì mú un lára dá. Lẹ́yìn tí èyí ṣẹlẹ̀, ìyókù àwọn ènìyàn erékùṣù náà tí wọ́n ní àwọn àìsàn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wò wọ́n sàn.”—Ìṣe 28:7-9.
Kí Ló Mú Kó Dá Lúùkù Oníṣègùn Lójú?
Lúùkù kọ àwọn ìtàn yìí sínú ìwé Ìṣe lásìkò táwọn tó bá kà wọ́n á lè wádìí òótọ́ tó wà níbẹ̀ lẹ́nu àwọn tí Lúùkù 1:3, 4) Ohun tí oníṣègùn yìí fojú ara ẹ̀ rí àti ìwádìí tó ṣe ló mú kó dá a lójú pé òótọ́ làwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Ìwòsàn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu wà lára àwọn ẹ̀kọ́ yẹn, èyí sì tún jẹ́ ká rí ìdí tá ó fi gba àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì gbọ́, pé Ọlọ́run á ṣẹgun àìsàn. (Aísáyà 35:5, 6) Gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn tó máa ń tọ́jú àwọn tíyà ń jẹ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, inú Lúùkù ti ní láti máa dùn nígbàkugbà tó bá ń ronú lórí ìgbà tíṣẹ́ rẹ̀ ò ní wúlò mọ́. Ǹjẹ́ irú ìrètí yẹn ń dá ìwọ náà lọ́rùn?
ọ̀rọ̀ tó kọ síbẹ̀ kàn. Àwọn ìtàn yẹn ò lè jẹ́ àròsọ. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó kọ sínú ìwé tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pè, Lúùkù sọ pé: “Mo ti tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye . . . kí ìwọ lè mọ̀ ní kíkún ìdánilójú àwọn [nǹkan náà].” (A dúpẹ́ pé bọ́jọ́ iwájú ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó fẹ́ràn Ọlọ́run nìyẹn, ibi yòówù kí wọ́n máa gbé láyé. Bíbélì ṣèlérí pé nínú Ìjọba Ọlọ́run, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ọ̀pọ̀ àwọn dókítà ayé òde òní ti wá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti gba àwọn ìlérí Bíbélì gbọ́.
‘Ó Fà Mí Lọ́kàn Mọ́ra Gan-an Ni’
Dókítà Jon Schiller tó jẹ́ oníṣègùn ìdílé ní Àríwá Amẹ́ríkà sọ pé: “Ohun tó ń gbé ọ̀pọ̀ èèyàn dé ìdí iṣẹ́ ìṣègùn ló gbé èmi náà dé ìdí ẹ̀. Èmí náà fẹ́ máa ran àwọn tí àìsàn ń jẹ níyà lọ́wọ́. Ìrètí ìgbà tí ò ní sí àìsàn mọ́ láyé fà mí lọ́kàn mọ́ra gan-an ni. Mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn tí mo ti kọ́ nípa bí ọ̀làjú ṣe bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù nílé ẹ̀kọ́ gíga kan. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ jẹ́ kí n mọ̀ pé ìsìn ló wà nídìí ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń dààmú aráyé, àti pé lójú tèmi, ó dà bíi pé ńṣe ni wọ́n ń fi Bíbélì tan àwọn èèyàn jẹ. Ìyẹn ni
mo ṣe ń bi ara mi lọ́pọ̀ ìgbà pé, ‘Kí tiẹ̀ ni Bíbélì sọ gan-an?’“Nígbà tí mo dé Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ráwọn èèyàn tó dùn ún mú lọ́rẹ̀ẹ́, àwọn tó yááyì tí wọn ò dà bí àwọn tí mo ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ọkùnrin kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí wá bá mi ó sì sọ fún mi pé òun á fẹ́ láti máa bá mi jíròrò Bíbélì. Ohun tó jọ mí lójú ni pé kò sí ohun tí mo béèrè tí kì í fi ìdáhùn rẹ̀ hàn mí nínú Bíbélì.
“Bí mo ṣe ń dàgbà sí i ni mò ń rí àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà téèyàn bá ṣì kéré nídìí iṣẹ́ dókítà, olúwa rẹ̀ á máa rétí ìgbà tóun máa rọ́wọ́ mú nídìí ẹ̀. Ṣùgbọ́n mo sábà máa ń ráwọn èèyàn tí wọ́n ń rí i pé òfo ni gbogbo ohun tí àwọn ń rò já sí, tí wọ́n sì ń rí i pé àwọn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ rí nǹkan gidi gbé ṣe. Lójú tèmi o, ọ̀kan lára àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù táwa ń jẹ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé a nírètí ọjọ́ iwájú, ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀. À báà jẹ́ dókítà tàbí mẹkáníìkì, kódà ká jẹ́ aṣọ́gbà, a mọ̀ pé ohun tá à ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe pàtàkì nítorí pé Jèhófà là ń ṣe é fún. Ìyẹn sì ń mú ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.”
“Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Mú Kí Àlàáfíà Jọbá Nínú Ìdílé Wa”
Oníṣègùn ni Dókítà Krister Renvall lórílẹ̀-èdè Finland, ó sì fẹ́ràn kó máa bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, mo bá ọmọ ọdún méjìlá kan tó lárùn jẹjẹrẹ tí ò gbóògùn sọ̀rọ̀. Ó fún mi ní ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Alafia ati Ãbo Tõtọ—Lati Orisun Wo? a Ìgbàgbọ́ tó ní nígbà tó ń ṣàìsàn tó pa á yẹn wú mi lórí púpọ̀, ṣùgbọ́n mi ò ráyè ka ìwé náà. Kódà, nígbà yẹn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní ilé ìwòsàn tó wà nílùú Helsinki mú kọ́wọ́ mi dí débi pé ó ti fẹ́ máa kó bá ìdílé mi.
“Àmọ́, nígbà tó yá ìyàwó mi rí ìwé náà níbi tá à ń kówèé sí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Lójú ẹsẹ̀ ló gbà pé òtítọ́ ni nǹkan tóun ń kà yìí. Obìnrin kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bá a ó sì bẹ́rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákọ̀ọ́kọ́, ìyàwó mi ń bẹ̀rù díẹ̀díẹ̀ láti sọ fún mi. Ṣùgbọ́n nígbà tó sọ fún mi, mo sọ pé, ‘Mo fara mọ́ ohunkóhun tó bá lè ṣe ìdílé wa láǹfààní.’ Mo bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún. Títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì mú kí àlàáfíà jọba nínú ìdílé wa ó sì jẹ́ ká lè térò wa pa nípa ìgbésí ayé. Inú mi dùn nígbà tí mo mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú, kò ní sí àìsàn mọ́; ó bá ohun témi náà ń rò mu pé irú nǹkan tó yẹ kí Ọlọ́run ṣe fún ìran èèyàn nìyẹn. Láìpẹ́ sígbà náà, èmi àti ìyàwó mi ṣèrìbọmi, àwọn ọmọ wa sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà. Ọmọbìnrin tó bá mi sọ̀rọ̀ yẹn kú o, ṣùgbọ́n a lè sọ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò kú.”
Ńṣe ni ìdáàmú àwọn dókítà lẹ́nu iṣẹ́ ń pọ̀ sí i ní gbogbo ìgbà báyé yìí ṣe ń yí padà. Ó yẹ ká torí èyí lù wọ́n lọ́gọ ẹnu látàrí bí wọ́n ṣe ń tọ́jú aláìsàn. Ṣùgbọ́n ṣíún báyìí ló kù, nǹkan ò ní pẹ́ yí padà fún gbogbo aráyé lápapọ̀. Ọ̀pọ̀ oníṣègùn ló ń fi ìdánilójú dúró de ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí nípa ọjọ́ iwájú, ìyẹn ayé tí a ò ti ní máa ṣàìsàn! (Ìṣípayá 21:1-4) Ó yẹ kó o ṣèwádìí fúnra rẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
“MO MỌ̀ PÉ Ó NÍDÌÍ TÍ ỌLỌ́RUN FI DÁ WA SÁYÉ”
“Nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ níléèwé àwọn ọmọ àláàbọ̀ ara, mo rí i bí tàwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yàtọ̀. Ó dà bíi pé àwọn mọ bí wọ́n ṣe lè bójú tó ọmọ tó bá jẹ́ aláàbọ̀ ara ju àwọn òbí tó kù lọ. Mo tún rí i pé òye yé wọn kọjá béèyàn á ṣe rò bó bá fojú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe wò wọ́n. Mo kan sárá sí wọn fún ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní. Àwọn tó ń kọ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ti fẹ́ẹ̀ ba ìgbàgbọ́ mi jẹ́ tán. Síbẹ̀, ohun tí mo kọ́ nínú ìmọ̀ nípa ìṣègùn ṣe mí ní kàyéfì nípa bọ́rọ̀ ayé yìí ṣe rí.
“Bákan náà, mo wá ń rí i pé mi ò mọ bó ṣe yẹ kí n tọ́ àwọn ọmọ mi. Kí ló yẹ kí n kà léèwọ̀ fún wọn? Kí ló yẹ kí n gbà wọ́n láyè láti máa ṣe? Kí ló yẹ kí ń fi hàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìdí tí wọ́n fi wà láyé? Ìgbésí ayé tèmi gan-an ò nítumọ̀ mọ́. Mo tiẹ̀ bẹ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́.
“Ìgbà yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ìwé ìròyìn kan wá fún mi tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ sọ́nà bí wọ́n bá ṣàṣìṣe àti béèyàn ṣe lè fìfẹ́ bá wọn wí. Mo rí i pé àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n jíròrò nínú ẹ̀ wúlò gan-an, nítorí náà mo ní kí wọ́n wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe ń kọ́ nípa ìdí tí Jèhófà fi dá wa àti ìdí tí Jésù fi kú, mo rí i pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:12, 18, 19) Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti yí mi lórí pátápátá. Inú mi dùn jọjọ nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé àìsàn àti ikú ò sí lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé níbẹ̀rẹ̀! Báyìí, mo ṣì ń láyọ̀ bí mo ṣe ń kọ́ àwọn olóòótọ́ èèyàn nípa bí Ọlọ́run yóò ṣe wo gbogbo àìsàn sàn.”
[Àwọn àwòrán]
Helena Bouwhuis ti ṣiṣẹ́ oníṣègùn àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tó ń relé ìwé rí lórílẹ̀-èdè Netherlands
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Lúùkù oníṣègùn tó tún jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn-àjò nígbà tí Pọ́ọ̀lù wo bàbá Púbílọ́sì sàn tó sì jí Yútíkọ́sì tó kú dìde
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Dókítà Jon Schiller, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Dókítà Krister Renvall, láti orílẹ̀-èdè Finland