Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Kí N Ṣe Bí Àwọn Míì Bá Fọ̀rọ̀ Wọn Lọ̀ Mí?

Kí Ni Kí N Ṣe Bí Àwọn Míì Bá Fọ̀rọ̀ Wọn Lọ̀ Mí?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ni Kí N Ṣe Bí Àwọn Míì Bá Fọ̀rọ̀ Wọn Lọ̀ Mí?

“Ọmọbìnrin kan wà níléèwé wa. Àwọn òbí ẹ̀ ti fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀, kò sì ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀ mọ́. Ó sábà máa ń sọ àwọn ìṣòro tó wà nínú ilé wọn fún mi.”—Jan, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. “Ọmọbìnrin kan níléèwé wa jẹ́wọ́ fún mi pé ọmọkùnrin kan bá òun lò pọ̀. Ó lóun lóyún òun sì ṣẹ́ ẹ láìjẹ́ káwọn òbí òun mọ̀.”—Mira, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

ÌWỌ àti ọ̀rẹ́ ẹ kan tàbí ọmọ iléèwé ẹ kan jọ ń sọ̀rọ̀ ni o. Òjijì ló bẹ̀rẹ̀ sí “kó” ìṣòro rẹ̀ “lé” ẹ láyà. Ó lè jẹ́ pé àwọn ọ̀ràn tó máa ń jẹ àwọn ọ̀dọ́ lógún ló ń dà á láàmú, ìyẹn àwọn ọ̀ràn bí aṣọ, owó, ìrísí, àwọn tó ń bá rìn, àti máàkì tó ń gbà nílé ìwé. Àmọ́, ó tún lè jẹ́ àwọn ìṣòro tó lágbára tí ò sì rọrùn láti yanjú ló ní.

Bí ọ̀ràn ṣe rí nílẹ̀ Amẹ́ríkà jẹ́ ká rí bí ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ ṣe le tó. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe sọ, “Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ìṣòro Tó Jẹ Mọ́ Ìrònú Ẹ̀dá ṣírò rẹ̀ pé ìdámẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ àti ìdáméjì nínú ọgọ́rùn-ún láàárín àwọn ọmọdé (táwọn míì ò ju ọmọ ọdún mẹ́rin lọ) ni wọ́n ní àmì pé àárẹ̀ ọkàn ń ṣe wọ́n.” Ìwádìí mìíràn fi hàn pé: “Bá a bá kó ẹgbẹ̀rún ọ̀dọ́bìnrin tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mọ́kàndínlógún jọ nílẹ̀ Amẹ́ríkà, a óò rí àwọn bíi mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún tó ń gboyún lọ́dún. Ìyẹn fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tọ́rọ̀ wọn rí bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà á pọ̀ tó mílíọ̀nù kan. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú oyún yìí, ìyẹn bí ìdá méjìdínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ni wọ́n rí he.” Òmíràn tún ni pé ẹgbàágbèje àwọn ọ̀dọ́ ló ń gbé nínú ilé tí ò fara rọ. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn mìíràn ni wọ́n ń fìyà jẹ tàbí kí wọ́n máa bá wọn ṣèṣekúṣe láìjẹ́ pé ó tinú wọn wá. Ó ju ìlàjì àwọn ọ̀dọ́ tó ti fẹ́ẹ̀ jáde níléèwé gíga nílẹ̀ Amẹ́ríkà tó ti mutí yó rí. Iye àwọn ọ̀dọ́ tó níṣòro àìlèjẹun bó ṣe yẹ ti ń pọ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ.

Abájọ tó fi jẹ́ pé lójú méjèèjì ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń wá ẹni tí wọ́n lè máa bá sọ̀rọ̀ tí wọ́n á sì lè fi àṣírí pamọ́ sí lọ́wọ́! Ẹni tí wọ́n sì máa ń kọ́kọ́ fẹ́ lọ gbé ọ̀rọ̀ wọn bá ni akẹgbẹ́ wọn. Kí ló yẹ kó o ṣe bó bá jẹ́ pé ìwọ ni akẹgbẹ́ ẹ kan wá fọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ̀? Bó o bá jẹ́ Kristẹni, kò yẹ kó jọ ẹ́ lójú pé wọ́n kó ọ̀rọ̀ wọn wá bá ẹ. Bíbélì pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ “àpẹẹrẹ” nínú ìwà kí wọ́n sì jẹ́ afòyebánilò. (1 Tímótì 4:12; Fílípì 4:5) Nítorí náà, àwọn ọ̀dọ́ mìíràn, tó fi mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, lè fẹ́ máa fọ̀rọ̀ pa mọ́ sí ẹ lọ́wọ́. Kí ló yẹ kó o ṣe bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀ o? Bó o bá sì wá rí i pé ìṣòro tó ń fi lọ̀ ẹ́ yìí ti kọjá èyí tó o lè bójú tó ńkọ́?

Fetí Sílẹ̀ Dáadáa

Bíbélì sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. (Oníwàásù 3:7) Nígbà tẹ́nì kan bá níṣòro tó sì fẹ́ fọ̀ràn lọ̀ ẹ́, ohun tó sábà máa ń dáa jù ni pé kó o fetí sílẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì ò fọwọ́ sí i pé kéèyàn kọ etí ikún sí “igbe ìráhùn ẹni rírẹlẹ̀.” (Òwe 21:13) Ó lè ti pẹ́ díẹ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin yìí ti ń da ọ̀rọ̀ náà rò kó tó di pé ó láyà láti sọ ọ́. a Á rọrùn fún un láti sọ ọ́ tó o bá fetí sílẹ̀ sí i. Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Hiram sọ pé: “Mo sábà máa ń jẹ́ kí ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Màá jẹ́ kó sọ gbogbo ohun tó bá ń dà á láàmú, màá sì gbìyànjú láti bá a kẹ́dùn.” Vincent sọ bákan náà pé: “Nígbà míì, àwọn èèyàn ṣáà máa ń fẹ́ sọ tinú wọn ni.”

Nítorí náà ọ̀dọ́kùnrin yìí lè má retí pé kó o bá òun yanjú àwọn ìṣòro òun. Gbogbo ohun tó fẹ́ lè má ju pé kó o ṣáà fetí sí ohun tó fẹ́ bá ẹ sọ. Nítorí náà fetí sílẹ̀! Máà jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà láyìíká gbà ẹ́ lọ́kàn, má sì máa já lù ú bó bá ṣe ń sọ̀rọ̀. Pé o tiẹ̀ dúró tó ń rí ẹ bá sọ̀rọ̀ yẹn nìkan gan-an ti tó ìrànlọ́wọ́. Ó fi hàn pé o fi í sọ́kàn nìyẹn.

Ṣé ohun tí ìyẹn wá túmọ̀ sí ni pé o kò ní láti fèsì kankan sí gbogbo ohun tó bá bá ẹ sọ? Ìyẹn á dá lórí irú ìṣòro tó bá ń dà á láàmú o. Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tó o bá fèsì pẹ̀lú sùúrù àti ìyọ́nú, ó ti tó. (Òwe 25:11) Bí àpẹẹrẹ, bí ìjàǹbá bá ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan tó o mọ̀ rí, ó dáa bó o bá bá a kẹ́dùn. (Róòmù 12:15) Òwe 12:25 sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” Ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe ò ju pé kó o sọ̀rọ̀ ìyànjú fún un. Jẹ́ kó mọ̀ pé o gbà gbọ́ pé ìṣòro rẹ̀ ò ní borí rẹ̀. Tó o bá sọ àwọn gbólóhùn bíi “Mo ti wá mọ̀dí tọ́ràn náà fi rí báyẹn lára ẹ” tàbí “Ó dùn mí pé ohun tó o forí rọ́ rèé,” á mọ̀ pé tinútinú lo fi ń bá òun sọ̀rọ̀ àti pé o fẹ́ ran òun lọ́wọ́.

Síbẹ̀, Òwe 12:18 kìlọ̀ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” Máa ṣọ́ ohun tó máa jáde lẹ́nu ẹ, kó o máa lọ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ bí “Ìyẹn náà ò tí ì burú jù,” “Gbàgbé ẹ̀ jọ̀ọ́,” tàbí “Ìwọ lo tún ń ṣe báyìí.” Tún ṣọ́ra kó o má lọ máa fi ọ̀rọ̀ tó ń dun ẹlòmíì ṣàwàdà. Ẹni yẹn lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ọ̀rọ̀ òun ò ká ẹ lára.—Òwe 25:20.

Ká wá ní o kò tíì lè ronú ohun tó yẹ kó o sọ báyìí ńkọ́ o? Ṣáà má parọ́. Jẹ́wọ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ pé o ò tíì mọ ohun tí wàá sọ báyìí, ṣùgbọ́n wàá ṣì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́. Béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé, “Kí ni mo lè ṣe láti ràn ẹ́ lọ́wọ?” Àwọn nǹkan kan á wà ni ṣáá tó o lè fi ràn án lọ́wọ́ tí ọ̀ràn rẹ̀ a fi fúyẹ́.—Gálátíà 6:2.

Bó O Ṣe Lè Fún Un Nímọ̀ràn bí Ọ̀rẹ́

Tó o bá sì wá rí i pé ọ̀rẹ́ ẹ nílò ìmọ̀ràn ńkọ́? Ṣó o rántí pé ọ̀dọ́ ni ìwọ náà, ìwọ̀nba ni ìrírí ayé tíwọ náà tíì ní. (Òwe 1:4) Nítorí náà, o lè má lè dá fún èèyàn nímọ̀ràn lórí gbogbo ìṣòro. Àmọ́ ṣá, Sáàmù 19:7 sọ pé: “Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” Bó ṣe rí nìyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé “aláìní ìrírí” ni ẹ́, o lè ní ìmọ̀ Bíbélì tó pọ̀ débi tí wàá fi lè ran akẹgbẹ́ ẹ kan tó níṣòro lọ́wọ́. (Òwe 27:9) Láìṣe bí ẹni tó ń là lé e lọ́wọ́, o lè fi àwọn kókó kan hàn án nínú Bíbélì. Tó ò bá mọ èyí tó o lè lò nínú àwọn ìlànà Bíbélì, ṣèwádìí. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni abala “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn yìí ti jíròrò ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn Bíbélì lórí onírúurú ọ̀ràn. Ìwé míì tó tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ni ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń BéèrèAwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. b

Bóyá o tún lè ràn án lọ́wọ́ nípa sísọ àwọn ohun tó o ti rí rí fún un. O tiẹ̀ lè láwọn àbá bíi mélòó kan tó lè ràn án lọ́wọ́ tó bá tẹ̀ lé wọn. Láìṣe bí ẹni tó ń sọ pé tìẹ nìkan ló tọ́, o lè ṣàlàyé ohun tó ràn ẹ́ lọ́wọ́ fún un. (Òwe 27:17) Àmọ́ o, má gbàgbé pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí yín yàtọ̀ síra o. Ohun tó ṣiṣẹ́ fún ẹ lè má ṣiṣẹ́ fún gbogbo èèyàn.

Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ O

Má máa pẹ́ níbi tó o ti ń fetí sí ìṣòro àwọn tí ò bẹ̀rù Jèhófà tàbí tí wọn ò ka àwọn ìlànà rẹ̀ sí. Ó lè jẹ́ pé ìgbésí ayé tí kò bá Bíbélì mu tí wọ́n ń gbé ló fa èyí tó pọ̀ nínú ìṣòro wọn. Tó o bá ń gbìyànjú láti ran àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì lọ́wọ́, wàá kàn rí i pé ńṣe lò ń da ara rẹ láàmú, tó o sì ń yọ onítọ̀hún lẹ́nu. (Òwe 9:7) Bákan náà, o tún lè rí i pé wàá kàn máa fetí ara ẹ gbọ́ oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ játijàti tàbí ìgbọ́kúgbọ̀ọ́ pàápàá. (Éfésù 5:3) Nítorí náà, tó o bá ti rí i pé ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún ẹ ò fẹ́ bá ẹ lára mu, má bẹ̀rù àtisọ fún un pé o kò lè ràn án lọ́wọ́ tàbí pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò wù ẹ́ gbọ́.

Ṣọrá bó bá jẹ́ obìnrin lẹni tó fẹ́ máa fọ̀rọ̀ tó ń gbé e lọ́kàn lọ̀ ẹ́. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ọkàn wa lè tàn wá jẹ. (Jeremáyà 17:9) Tẹ́ ẹ bá ti sún mọ́ ara yín jù, ọkàn yín lè máa fà síra yín kódà ó lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe.

Bákan náà, máà jẹ́ kọ́rọ̀ débi tí wàá ti ṣèlérí pé o kò ní sọ fẹ́nì kankan. Mọ̀ pé o lè má lè ran ẹni tó ń fọ̀rọ̀ lọ̀ ẹ́ lọ́wọ́ débi tó nílò ìrànlọ́wọ́ dé, ó lè nílò ìránlọ́wọ́ mìíràn tó kọjá agbára rẹ.—Òwe 11:2.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Tó O Bá Nílò Ìrànlọ́wọ́ Àwọn Ẹlòmíì

Lọ́pọ̀ ìgbà ohun tó máa dáa jù ni pé kó o wá ẹni tá á kọ́ ẹ bó o ṣe máa ran ọ̀rẹ́ rẹ lọ́wọ́. Mira, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ mọ bí màá ṣe ran ọmọbìnrin tó sọ àṣírí ẹ̀ fún mi yìí lọ́wọ́. Mo bá alàgbà kan nínú ìjọ wa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó sì fún mi láwọn ìmọ̀ràn kan tó lọ́gbọ́n nínú nípa bí màá ṣe ràn án lọ́wọ́.” Bó ṣe rí nìyẹn, àwọn ọkùnrin onírìírí wà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Éfésù 4:11, 12) Alàgbà yẹn dábàá fún Mira pé kó rọ ọmọ iléèwé wọn yẹn pé kó sọ fáwọn òbí ẹ̀. Ọmọbìnrin yẹn tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Mira. Mira sọ pé: “Ìṣòro ẹ̀ ti ń yanjú. Ní báyìí, ó fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì.”

Ká wá sọ pé Kristẹni kan fọ̀rọ̀ àṣírí pa mọ́ sí ẹ lọ́wọ́ ńkọ́ o? A mọ̀ pé wàá fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kó o ṣe kó o bà a lè ràn án lọ́wọ́. (Gálátíà 6:10) Àmọ́, tó o bá ń wòye pé ó ti ń kúrò lórí ìlànà tí Jèhófà là sílẹ̀ nípa ìwà híhù, má bẹ̀rù láti “sọ òtítọ́” fún un. (Éfésù 4:25) Má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ ṣùgbọ́n má ṣe bíi pé o jẹ́ olódodo lójú ara ẹ. Pé o lè bá a sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ló fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni ẹ́.—Sáàmù 141:5; Òwe 27:6.

Bọ́rọ̀ bá rí báyẹn, ó tún yẹ kó o rọ̀ ọ́ pé kó lọ bá àwọn òbí ẹ̀ tàbí alàgbà kan tàbí Kristẹni míì tó dàgbà dáadáa tó sì bọ̀wọ̀ fún pé kí wọ́n ràn án lọwọ. Tó o bá rí i pé ó ti tó bí ọjọ́ mẹ́ta kan tí ò sì tíì sọ̀rọ̀ náà fẹ́nikẹ́ni, ó lè jẹ́ pé ìwọ lo ní láti lọ bá a sọ fẹ́nì kan. (Jákọ́bù 5:13-15) Ó lè gba ìgboyà kó o tó ṣe irú ẹ̀ o, ṣùgbọ́n ìyẹn ló máa fi ẹ́ hàn bí ọ̀rẹ́ tó ń fi ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹ̀ sọ́kàn tó sì ń fẹ́re fún un.

Kì í kúkú ṣe pé Jèhófà retí pé kó o yanjú gbogbo ìṣòro táwọn èèyàn bá ti gbé wá síwájú ẹ. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan bá fọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ̀ ẹ́, má rò pé kò sí nǹkan tó o lè ṣe. Lo àwọn nǹkan tó o ti kọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kó o sì fi hàn pé “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́” ni ẹ́.—Òwe 17:17.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹ kíyè sí i pé tọkùnrin tobìnrin ni ohun tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí kàn.

b Àwa Ẹlérìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Láwọn ìgbà míì, ó lè gba pé kó o bá ọ̀rẹ́ ẹ tó wà nínú ìṣòro wá ìrànlọ́wọ́