Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 14. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Bí Pétérù ṣe sọ, kí nìdí tí Ọlọ́run fi yan Ísírẹ́lì tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀yà àyànfẹ́” rẹ̀? (1 Pétérù 2:9)
2. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù kọ́kọ́ ṣe, ibo ló sì ti ṣe é? (Jòhánù 2:1-11)
3. Kí ni Ọlọ́run fi dá Éfà tí í ṣe ẹnì kejì Ádámù? (Jẹ́nẹ́sísì 2:22)
4. Gbajúmọ̀ ọkùnrin wo nílẹ̀ Ísírẹ́lì làwọn èèyàn mọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sí “aláìdára fún ohunkóhun”? (1 Sámúẹ́lì 2:12)
5. Òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun gbígbẹ wo, tí wọ́n ń lò nígbàanì, ló ṣe wẹ́kú pẹ̀lú òṣùwọ̀n hómérì tó sì jẹ́ báàfù mẹ́wàá? (Lúùkù 16:7)
6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí mọ bí wọ́n ṣe lè túmọ̀ ìrísí sánmà, kí ni Jésù sọ pé wọn ò lè túmọ̀? (Mátíù 16:3)
7. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, ta ló gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n ń gbé láìléwu tí wọ́n sì láásìkí? (Ìsíkíẹ́lì 38:14-16; 39:11)
8. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé asán ni ìjọsìn tí àwọn aṣáájú ìsìn ń “fi ètè” wọn ṣe? (Máàkù 7:6, 7)
9. Èwo nínú àwọn ọmọ Nóà ló ṣe ohun tó mú kí Kénáánì ọmọ tiẹ̀ forí gba ègún Nóà? (Jẹ́nẹ́sísì 9:22-25)
10. Ilẹ̀ tó jẹ́ ti ẹ̀yà wo ní Ísírẹ́lì làwọn èèyàn máa ń pè ní ìpẹ̀kun àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì? (Àwọn Onídàájọ́ 20:1)
11. Kí ni Bíbélì pe òwú gígùn tí wọ́n fi ń hun aṣọ òfì? (Aísáyà 38:12)
12. Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé kí Dáfídì yan ọ̀kan lára ìjìyà mẹ́ta lẹ́yìn tó ti ṣe àìgbọ́ràn nípa kíka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjìyà wo ni Dáfídì fọwọ́ ara ẹ̀ yàn? (2 Sámúẹ́lì 24:12-15)
13. Àwọn ìwé Bíbélì mẹ́ta wo ni Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà Júù kọ?
14. Àgbègbè ìpínlẹ̀ wo ni Gómìnà Fẹlíìsì rí i dájú pé Pọ́ọ̀lù ti wá? (Ìṣe 23:34)
15. Ta ni olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ábúsálómù nígbà tó fi dìtẹ̀ mọ́ Dáfídì tó sì tún jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun fún Dáfídì lẹ́yìn ikú Ábúsálómù? (2 Sámúẹ́lì 17:25; 19:13)
16. Ta ni Ọ̀gágun Jóábù yàn pé kó túfọ̀ fún Dáfídì Ọba pé ọmọkùnrin rẹ̀, Ábúsálómù ti kú? (2 Sámúẹ́lì 18:21, 32)
17. Kí ló mú kí Jákọ́bù gbà pé ẹranko ẹhànnà ti pa Jósẹ́fù ọmọkùnrin òun jẹ? (Jẹ́nẹ́sísì 37:31-33)
18. Kí lorúkọ áńgẹ́lì tó sọ fún Màríà pé Ọlọ́run ti yàn án láti bí Jésù? (Lúùkù 1:26-31)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Kí wọ́n bàa lè “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá” Ọlọ́run
2. Ó sọ omi di ọtí wáìnì; Kánà
3. Egungun ìhà kan tí ó mú láti ara Ádámù
4. Élì
5. Òṣùwọ̀n kọ́ọ̀
6. “Àwọn àmì àkókò”
7. Gọ́ọ̀gù àti “ogunlọ́gọ̀” rẹ̀
8. Nítorí pé ‘ọkàn wọn jìnnà réré sí i’
9. Hámù
10. Dánì
11. Fọ́nrán òwú títa
12. Àjàkálẹ̀ àrùn
13. Kíróníkà Kìíní, Kíróníkà Kejì, Ẹ́sírà
14. Sìlíṣíà
15. Ámásà
16. Ọmọ Kúṣì kan tí Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀
17. Wọ́n fi ẹ̀wù gígùn abilà ti Jósẹ́fù, tí wọ́n ti kì bọnú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ hàn án
18. Gébúrẹ́lì