Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Abiyamọ Tó Ti Jàjàyè

Àwọn Abiyamọ Tó Ti Jàjàyè

Àwọn Abiyamọ Tó Ti Jàjàyè

ÌṢÒRO ńlá kan tó ń kojú ọ̀pọ̀ abiyamọ lónìí ni bí wọ́n á ṣe wáṣẹ́ ṣe nítorí àtigbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Láfikún sí i, fún onírúurú ìdí, àwọn kan nínú wọn ló ń dá ọmọ tọ́.

Abiyamọ tó ń dá tọ́ ọmọ méjì ni Margarita tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ó sọ pé: “Ó ṣòro láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ilé àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Lọ́jọ́ kan báyìí, ọmọ mi ọkùnrin lọ sóde àríyá, ọtí sì ti ń pa á kó tó dé. Mo kìlọ̀ fún un pé tó bá tún ṣe irú ẹ̀, mi ò ní jẹ́ kó wọlé. Eré ló pè é, nígbà tó tún ṣe irú ẹ̀, mo tilẹ̀kùn mọ́ ọn síta, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dùn mí gan-an. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé kò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ látìgbà náà.”

Láìpẹ́ sígbà yẹn ni Margarita bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tóràn án lọ́wọ́ tó fi lè kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ ilé. Ní báyìí, àwọn ọmọ méjèèjì wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Bí Ọkọ Bá Lọ sí Ìdálẹ̀

Ọ̀pọ̀ baálé tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí ò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ ló máa ń wáṣẹ́ lọ sáwọn ilẹ̀ ọlọ́rọ̀, wọ́n á sì fi ìyàwó wọn sílé láti máa bójú tó àwọn ọmọ. Abiyamọ ni Laxmi tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Nepal, ó ní: “Ọdún keje rèé tí ọkọ mi ti lọ sí ìdálẹ̀. Àwọn ọmọ ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu bíi bàbá wọn. Ká ló máa ń wálé déédéé láti wá bójú tó àwọn ọmọ ni, nǹkan ò ní le tó bẹ́ẹ̀.”

Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí, Laxmi ò jáfara lẹ́nu iṣẹ́ ẹ̀. Nítorí pé kò kàwé púpọ̀, ó gba àwọn olùkọ́ tá á máa kọ́ àwọn tó dàgbà nínú àwọn ọmọ rẹ̀ níṣẹ́ ilé ìwé. Àmọ́, ó mú kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí ní ọ̀kúnkúndùn, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó máa ń jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pẹ̀lú wọn lójúmọ́, ó sì máa ń kó wọn lọ sípàdé Kristẹni déédéé.

Àwọn Abiyamọ Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Kàwé

Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìṣòro míì ni ti bó ṣe jẹ́ pé àwọn obìnrin ló pọ̀ jù láàárín àwọn tí kò kàwé. Ọmọ mẹ́fà ni Aurelia, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò bí, kò sì kàwé. Nígbà tó ń ṣàlàyé ìyà tí àìkàwé máa ń fi jẹ abiyamọ, ó sọ pé: “Màmá mi máa ń sọ fún mi pé kò sí nǹkan táwọn obìnrin fẹ́ fi ìwé ṣe. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí n mọ̀wé kà, torí náà, n kì í lè bá àwọn ọmọ mi ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ní kí wọ́n ṣe wá látilé. Ó máa ń dùn mí gan-an. Ṣùgbọ́n, nítorí pé mi ò fẹ́ kírú ìyà tó jẹ mí jẹ àwọn náà, mo sa gbogbo ipá mi kí n lè rí i pé wọ́n kàwé.”

Kódà, láìkàwé púpọ̀, àwọn abiyamọ ṣì lè tọ́ àwọn ọmọ wọn. Òótọ́ ni nǹkan táwọn kan máa ń sọ pé: “Bá a bá kọ́ obìnrin lẹ́kọ̀ọ́, obìnrin a sì di olùkọ́ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin.” Ìgbà kan wà tí Bishnu tó wá láti orílẹ̀-èdè Nepal kò mọ dòò, ó sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó wà lọ́kàn ẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì kó sì fi òtítọ́ yìí kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó tiraka láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń kàwé àti bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́. Ó máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ òun ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣe wá láti iléèwé, ó sì máa ń lọ sí iléèwé wọn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ láti lọ bá àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ wọn.

Nígbà tí Silash, ọmọkùnrin Bishnu ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ tẹ̀mí àti ẹ̀kọ́ ilé tí ìyá wọn kọ́ wọn, ó ṣàlàyé pé: “Ohun tó wù mí jù nípa bí ìyá mi ṣe kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni pé bá a bá ṣàṣìṣe, àpẹẹrẹ kan láti inú Bíbélì lá á fi bá wa wí. Ọgbọ́n tó ń dá yìí ló jẹ́ kó rọrùn fún mi láti gba ìbáwí.” Bishnu kẹ́sẹ járí nínú kíkọ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run.

Antonia tó ń gbé ní Mẹ́síkò jẹ́ abiyamọ tó ń tọ́ ọmọ méjì lọ́wọ́, ó sọ pé: “Mi ò kà ju ìwé mẹ́fà péré lọ. Abúlé àdádó kan báyìí là ń gbé nígbà yẹn, ilé ìwé girama tó sún mọ́ wa jù sì jìnnà síbẹ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n, mo fẹ́ káwọn ọmọ mi kàwé débi tí mi ò kà á dé, nítorí náà mo dìídì wáyè fún wọn. Mo máa ń kọ́ wọn ní a, b, d àti oókan, eéjì, ẹẹ́ta. Ọmọbìnrin mi ti lè sípẹ́lì àwọn lẹ́tà tó wà nínú orúkọ rẹ̀ ó sì ti lè kọ a, b, d títí dé y, kó tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé. Látìgbà tí ọmọkùnrin mi ti wà nílé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi ló ti ń kàwé.”

Nígbà tí wọ́n bi í léèrè bó ṣe ṣe é tó fi kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ ilé, Antonia ṣàlàyé pé: “Mo máa ń kọ́ wọn láwọn ìtàn Bíbélì. Kó tó di pé ọmọbìnrin mi lè sọ̀rọ̀, ó ti lè sọ àwọn ìtàn Bíbélì nípa fífara ṣàpèjúwe. Ọmọ ọdún mẹ́rin ni ọmọkùnrin mi nígbà tó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ Bíbélì kíkà ní ìpàdé Kristẹni.” A lè rí i báyìí pé ọ̀pọ̀ abiyamọ tí ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé ló ń ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọ wọn.

Bí Wọ́n Ṣe Kọ Àwọn Àṣà Tó Léwu

Láàárín àwọn ẹ̀yà Tzotzil lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, àṣà wọn ni pé kí wọ́n máa ta àwọn ọmọbìnrin wọn sílé ọkọ lọ́mọ ọdún méjìlá tàbí mẹ́tàlá. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹni tá á fẹ́ẹ̀ tó ọmọbìnrin náà bí lọ́mọ, tó sì ń wá ìyàwó kejì tàbí ìkẹta ni wọ́n máa tà á fún. Bí ọmọbìnrin náà ò bá sì tẹ́ ọkùnrin tí wọ́n tà á fún lọ́rùn mọ́, ó lè dá a padà kó sì gbowó ẹ̀. Ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe fún Petrona náà nìyẹn. Nígbà tí ìyá rẹ̀ fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, wọ́n ti tà á sílé ọkọ, ó ti bímọ síbẹ̀, ọkọ tó fẹ́ ẹ sì ti kọ̀ ọ́! Ọmọ tó kọ́kọ́ bí yẹn kú, wọ́n sì tún tà á fún àwọn ọkọ míì nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Gbogbo ọmọ tí ìyá Petrona bí ṣáà jẹ́ mẹ́jọ lápapọ̀.

Petrona ò fẹ́ káyé tòun rí báyìí, ó ṣàlàyé bó ṣe ṣe é, ó ní: “Nígbà tí mo jáde nílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, mo sọ fún Màámi pé mi ò tíì fẹ́ relé ọkọ́, ńṣe ni mo fẹ́ kàwé sí i. Màámi sọ fún mi pé kò sí nǹkan tóun lè ṣe nípa ẹ̀, kí n lọ bá bàbá mi sọ ọ́.”

Bàbá mi sọ fún mi pé: “Mo máa wá ọkọ fún ẹ ni. O ti mọ èdè Spanish sọ. O ti mọ̀wé kà. Kí lo tún ń wá? Tó o bá ló o fẹ́ kàwé sí i ṣá o, ìwọ fúnra ẹ lo máa tọ́ ara ẹ.”

Petrona sọ pé: “Ohun tí mo kúkú ṣe nìyẹn. Ńṣe ni mò ń báwọn èèyàn kóṣẹ́ sí aṣọ lára kí n tó lè rówó.” Ohun tí ò jẹ́ káwọn òbí ẹ̀ tà á sílé ọkọ nìyẹn. Nígbà tí Petrona dàgbà, màmá ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí ló sì fún ìyá Petrona nígboyà láti gbin òtítọ́ Bíbélì sí àwọn àbúrò Petrona tó jẹ́ obìnrin lọ́kàn. Látinú ohun tójú ìyá yìí rí, ó ṣàlàyé fáwọn ọmọ ẹ̀ nípa àwọn nǹkan búburú tó máa ń tẹ̀yìn títa ọmọ fọ́kọ láti kékeré yọ.

Àṣà míì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé ni pé bàbá nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti bá àwọn ọmọkùnrin wí. Petrona ṣàlàyé pé: “Ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn obìnrin Tzotzil ni pé àwọn ọkùnrin kì í ṣẹgbẹ́ wọn. Àwọn ọkùnrin ti máa ń jẹ gàba jù níbẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin kéékèèké máa ń ṣe bí àwọn bàbá wọn, wọ́n sì máa ń sọ fáwọn ìyá wọn pé: ‘Ẹ ò lè kọ́ mi ní nǹkan tó yẹ kí n ṣe o. Tí bàbá mi ò bá ti sọ fún mi, mi ò lè ṣe ohun tẹ́ ẹ sọ yẹn.’ Torí ìyẹn, àwọn abiyamọ ò lè kọ́ àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bí nínú wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí màmá mi ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun fúnra rẹ̀ ti kọ́ àwọn àbúrò mi ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì gbẹ̀kọ́. Wọ́n ti fi ohun tó wà nínú Éfésù 6:1, 2 sọ́kàn. Ibẹ̀ kà pé: ‘Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín. . . . Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.’”

Mary, abiyamọ kan tó ń gbé Nàìjíríà sọ pé: “Níbi tí mo dàgbà sí, àṣà àwọn èèyàn ò fàyè gba ìyá láti máa kọ́ àwọn ọmọkùnrin tàbí kó máa bá wọn wí. Ṣùgbọ́n ní títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Lọ́ìsì, màmá Tímótì àgbà àti ti Yùníìsì màmá Tímótì, mo pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ dí mi lọ́wọ́ kíkọ́ àwọn ọmọ tèmi lẹ́kọ̀ọ́.”—2 Tímótì 1:5.

Àṣà míì tí wọ́n sábà máa ń tẹ̀ lé láwọn orílẹ̀-èdè kan ni “kíkọ obìnrin nílà,” èyí tí wọ́n ń pè ní dídábẹ́ fún obìnrin. Bí wọ́n ṣe ń ṣe eléyìí ni pé wọ́n á gé nǹkan kan kúrò lára ẹ̀yà ìbímọ ọmọbìnrin. Waris Dirie, ìlúmọ̀ọ́ká agbógelárugẹ tó tún jẹ́ aṣojú pàtàkì fún àjọ tó ń bójú tó ìnáwó lórí ìkànìyàn lábẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló sọ̀rọ̀ nípa àṣà yìí fáyé gbọ́. Ìyá Waris Dirie gbé e sílẹ̀ kí wọ́n dá abẹ́ fún un ní kékeré, gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn lórílẹ̀-èdè Sòmálíà. Ìròyìn kan sọ pé á tó mílíọ̀nù mẹ́jọ sí mílíọ̀nù mẹ́wàá àwọn obìnrin, lágbà lọ́mọdé, ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé àti nílẹ̀ Áfíríkà tó ṣeé ṣe kí wọ́n dá abẹ́ fún. Kódà, àwọn ọmọbìnrin tó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe irú ẹ̀ fún nílẹ̀ Amẹ́ríkà á tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.

Kí ni wọ́n rò débi àṣà yìí ná? Àwọn kan gbà pé àmì Èṣù ni nǹkan tí wọ́n máa ń gé kúrò lára ẹ̀yà ìbímọ obìnrin yìí àti pé ó lè sọ obìnrin di aláìmọ́ tí ẹnikẹ́ni ò sì ní lè gbé níyàwó. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún gbà pé gígé tí wọ́n bá gé nǹkan yìí kúrò, á jẹ́ kí ọmọbìnrin lè wà ní wúńdíá títí tá á fi wọlé ọkọ, tó bá sì wọlé ọkọ tán kò ní ṣèṣekúṣe. Abiyamọ tí ò bá jẹ́ kí wọ́n dá abẹ́ fún ọmọbìnrin rẹ̀ fẹ́ rí ìbínú ọkọ rẹ̀ àtàwọn ará ìlú nìyẹn.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ abiyamọ ló ti wá mọ̀ pé kò sí ìdí kankan tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ẹnikẹ́ni á fi máa tẹ̀ lé àṣà burúkú tó máa ń fa ìrora yìí. Kò sí ẹ̀sìn tó lè fipá mú èèyàn ṣe é, kò bá ìmọ̀ ìṣègùn mu, kò sì bá òfin ìmọ́tótó mu. Ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ ní Nàìjíríà, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Repudiating Repugnant Customs (Kíkórìíra Àwọn Àṣàkaṣà) jẹ́ ká rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn ìyálọ́mọ ló ti yarí kanlẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe dábẹ́ fáwọn ọmọbìnrin wọn.

Ká sòótọ́, àwọn abiyamọ káàkiri àgbáyé ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, wọ́n ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń ṣe é ní àṣeyege láìka gbogbo wàhálà tí wọ́n ń bá pàdé sí. Ǹjẹ́ kò yẹ́ ká kan sáárá sí wọn lórí iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe yìí?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

“Ọ̀pọ̀ ìwádìí ló ń fi hàn pé kò sí ètò tá a gbé kalẹ̀ tó lè kẹ́sẹ járí tá ò bá fi tàwọn obìnrin ṣe. Ṣùgbọ́n tá a bá fi tàwọn obìnrin ṣe, lójú ẹsẹ̀ la ó ti máa rí àǹfààní wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀: ara gbogbo ẹbí á le, wọ́n á jẹun tó dáa síkùn; owó tá á máa wọlé àtèyí tí wọ́n á rí fi pamọ́ àtèyí tí wọn á máa rí lò á túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Bó bá sì ṣe rí láàárín ẹbí náà ló máa rí ládùúgbò, bẹ́ẹ̀ náà ló máa rí káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè nígbà tó bá yá.”—Kofi Annan tó jẹ́ Ọ̀gá Àgbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló sọ bẹ́ẹ̀ ní March 8, ọdún 2003.

[Credit Line]

Fọ́tò àjọ UN/DPI tí Milton Grant yà

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìyá Wa Yááfì Ohun Tó Pọ̀ Torí Wa

Ọ̀dọ́kùnrin ará Brazil kan tó ń jẹ́ Juliano sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, iṣẹ́ téèyàn lè tètè là nídìí ẹ̀ ni màmá mi ń ṣe. Àmọ́ nígbà tó bí àbúrò mi obìnrin, ó pinnu láti fiṣẹ́ yẹn sílẹ̀ kó bàa lè ráyè bójú tó wa. Àwọn agbaninímọ̀ràn níbi iṣẹ́ wọn rọ̀ ọ́ pé kó má fiṣẹ́ yẹn sílẹ̀. Wọ́n ní táwọn ọmọ ẹ̀ bá ti ṣègbéyàwó tí wọ́n sì ti filé sílẹ̀, gbogbo ohun tó ti ṣe fún wọn á di àṣedànù. Wọ́n ní kò sí èrè kankan nídìí ohun tó fẹ́ rawọ́ lé. Ṣùgbọ́n èmi lè sọ pé wọ́n ṣì í; mi ò ní gbàgbé ìfẹ́ tí ìyá wa fi bá wa lò láé.”

[Àwọn àwòrán]

Fọ́tò ìyá Juliano àtàwọn ọmọ ẹ̀ rèé; Juliano ló wà nínú àwòrán àkámọ́ lápá òsì, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Bishnu kọ́ ìwé kíkà àti ìwé kíkọ, lẹ́yìn náà ló ran àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ lọ́wọ́ láti kàwé tó múná dóko

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Fọ́tò ọmọkùnrin Antonia nígbà tó ń ka Bíbélì lórí pèpéle nínú ìpàdé Kristẹni

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ olúyọ̀nda ara ẹni ní ẹ̀ká ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni Petrona. Ìyá ẹ̀ tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn kọ́ àwọn àbúrò Petrona lẹ́kọ̀ọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Fọ́tò Waris Dirie, tó jẹ èèkàn lára àwọn obìnrin tó ń ṣe ìpolongo lòdì sí dídábẹ́ fún obìnrin

[Credit Line]

Fọ́tò tí ilé iṣẹ́ Sean Gallup/ Getty Images yà