Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Lọ́dún Gbogbo Èèyàn La Pè!

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Lọ́dún Gbogbo Èèyàn La Pè!

Ìpàdé Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Lọ́dún Gbogbo Èèyàn La Pè!

Ní Thursday, March 24, ọdún 2005, ayẹyẹ kan tó ò ní fẹ́ kí wọ́n ròyìn ẹ̀ fún ẹ máa wáyé. Ọjọ́ yìí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà kárí ayé àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn tí wọ́n pè máa pé jọ láti ṣèrántí oúnjẹ tí Jésù bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jẹ kẹ́yìn. Gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí Jésù fún wọn, wọ́n á gbé búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa kọjá níwájú àwọn èèyàn ní gbogbo ibi tí ayẹyẹ náà bá ti wáyé, wọ́n á sì ṣàlàyé ohun tí ayẹyẹ náà túmọ̀ sí.—Máàkù 14:22-24.

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ̀pọ̀ èèyàn mọ ayẹyẹ yìí sí. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pè é ní Ìrántí Ikú Kristi. Ayẹyẹ yìí ló máa ń rán wa létí ìrúbọ tí Jésù Kristi ṣe nígbà tó kú fún àǹfààní aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀. (Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 2:2) Lẹ́yìn oúnjẹ tí Jésù jẹ kẹ́yìn yìí, wọ́n mú un, wọ́n sì kàn án mọ́ igi oró níbi tó kú sí bí ẹni pé aṣebi lásánlàsàn ni. —Jòhánù 19:17, 18.

A fi tayọ̀tayọ̀ pè ọ́ síbi ayẹyẹ àkànṣe yìí. Òun ni ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Jọ̀wọ́ lọ wádìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá sún mọ́ ọ jù lọ kó o lè mọ àkókò náà gan-an tí wọ́n á ṣe ayẹyẹ yìí àti ibi tí wọ́n á ti ṣe é.