‘Ìwé Ìròyìn Tó Ní Àtìlẹ́yìn Ọlọ́run’
‘Ìwé Ìròyìn Tó Ní Àtìlẹ́yìn Ọlọ́run’
ỌKÙNRIN kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Nàìjíríà lọ síbi àpérò kan tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Àtàwọn Ọmọdé Jákèjádò Ilẹ̀ Áfíríkà ṣe. Ó kó ìwé ìròyìn Jí! méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ.
Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ àpérò náà, ọkùnrin náà kíyè sí i pé inú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn tóun mú lọ ni olùbánisọ̀rọ̀ náà ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìwé ìròyìn náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn táyé ti sú tí wọ́n sì ń fọwọ́ ara wọn gbẹ̀mí ara wọn. (November 8, 2001, ojú ìwé 13 sí 22) Fàrà ló fa ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ yọ, ló bá kúkú ń fojú bá a lọ.
Nígbà tí àpérò ti ọjọ́ yẹn parí, amòfin kan tó máa bá àwọn tó wá síbi àpérò sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ kejì rí àkòrí tó wà lẹ́yìn ìtẹ̀jáde Jí! kejì tó wà lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, èyí tó dá lórí ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ìrànwọ́ fún Àwọn Obìnrin Tọ́kọ Wọn Ń Lù.” Amòfin náà ní kó yá òun. Ní òru mọ́jú, ó fa ìwé tó kọ ohun tó fẹ́ sọ tẹ́lẹ̀ sí ya, ó sì lo àpilẹ̀kọ inú Jí! yẹn láti kọ òmíràn. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, bí amòfin náà ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, obìnrin kan tó jókòó sí ìlà ibi tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wà mú ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! tiẹ̀ jáde ó sì ń fojú bá a lọ.
Ọkùnrin tó ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wúlò gan-an níbi àpérò yẹn nítorí pé òun náà ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Jí! ọ̀hún. Ó wá sọ pé, ‘kò sí àníàní pé ìwé ìròyìn náà ní àtìlẹ́yìn Ọlọ́run.’
Ṣé wàá fẹ́ kí wọ́n máa mú ìwé ìròyìn náà wá sílé rẹ déédéé? A rọ̀ ọ́ pé kó o sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kó máa mú un wá fún ọ.