Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyá Ni Wúrà

Ìyá Ni Wúrà

Ìyá Ni Wúrà

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ò mọyì iṣẹ́ tí ìyá ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ìyáálé ilé, àwọn míì ò tiẹ̀ kà á kún iṣẹ́. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n tàbí ogójì ọdún sẹ́yìn, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí yẹpẹrẹ iṣẹ́ bíbójú tó àwọn ọmọ. Lójú tiwọn, iṣẹ́ yẹn ò ṣe pàtàkì tó ohun téèyàn ń kà kún iṣẹ́, kódà wọ́n ní iṣẹ́ ìyà ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan á rò pé kò yẹ ká rẹni tá á sọ báyìí, síbẹ̀, bí ẹni tí ò níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ làwọn kan ṣe máa ń wo àwọn ìyáálé ilé tó ń ṣiṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ilé àti olùtọ́jú àwọn ọmọ. Àwọn kan tiẹ̀ rò pé ó yẹ kí obìnrin wáṣẹ́ lọ síta kó lè lo tálẹ́ńtì tó ní.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ baálé ilé àtàwọn ọmọ ló ti wá rí i pé kékeré kọ́ ni iṣẹ́ ìyá nínú ilé. Carlo, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Philippines, ṣàlàyé pé: “Ẹ̀kọ́ tí màmá mi kọ́ mi ló gbé mi débi tí mo dé lónìí. Bàbá mi ò gba gbẹ̀rẹ́, bá a bá ṣe ń ṣẹ̀ báyìí ló ń fìyà ẹ̀ jẹ wá, ṣùgbọ́n Màmá mi máa ń ṣàlàyé bọ́ràn ṣe rí fún wa ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀. Mo mọyì ọ̀nà tó ń gbà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ o jàre.”

Peter tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa, jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ mẹ́fà tí ìyá kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé tọ́. Bàbá rẹ̀ ò lọ́wọ́ sọ́rọ̀ wọn mọ́. Peter sọ bí nǹkan ṣe rí fún wọn nígbà yẹn pé: “Iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ni Màmá mi ń ṣe ó sì máa ń tọ́jú ọgbà, nítorí náà, owó táṣẹ́rẹ́ ló ń rí. Ó ṣòro fún un láti san owó ilé ìwé gbogbo wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà la kì í jẹun sùn. Àtirówó ilé san gan-an di ìṣòro fún un. Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yìí, Màmá wa ò sọ̀rètí nù. Ó kọ́ wa pé a kò gbọ́dọ̀ fara wa wé àwọn ẹlòmíràn. Tí kì í bá ṣe bó ṣe forí rọ́ ọ láìmikàn ni, a kì bá tí débi tá a dé lónìí.”

Ọkọ kan ní Nàìjíríà tó ń jẹ́ Ahmed ṣàlàyé bínú ẹ̀ ṣe máa ń dùn torí bí ìyàwó ẹ̀ ṣe ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn, ó sọ pé: “Ìyàwó mi ò kẹ̀rẹ̀. Bí mi ò bá sí nílé, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé ó máa tọ́jú àwọn ọmọ wa dáadáa. Dípò kí n máa rò pé ṣe ló ń bá mi díje, mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ mo sì jẹ́ káwọn ọmọ mọ̀ pé bí wọ́n ṣe ń bọ̀wọ̀ fún mi ni kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún òun náà.”

Ọkùnrin kan nílẹ̀ Palestine máa ń yin ìyàwó ẹ̀ ni ṣáá lórí iṣẹ́ ribiribi tó ń ṣe gẹ́gẹ́ bí abiyamọ, ó ní: “Mo rọ́wọ́ Lina, ìyàwó mi lára ọmọbìnrin wa ó sì tún kópa tó jọjú nínú bí ìdílé wa ṣe nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo ti rí yìí, mo gbà pé ẹ̀sìn ẹ̀ ló jẹ́ kó ṣàṣeyọrí.” Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Lina àwọn ìlànà Bíbélì ló sì fi ń kọ́ ọmọbìnrin rẹ̀.

Àwọn ìlànà wo nìyẹn? Kí la lè sọ nípa bí Bíbélì ṣe sọ̀rọ̀ àwọn abiyamọ? Irú àpọ́nlé àti ọ̀wọ̀ wo ló wà fáwọn abiyamọ ayé àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọ wọn?

Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Abiyamọ

Nígbà tí Jèhófà ṣẹ̀dá èèyàn, iṣẹ́ tó lọ́lá ló yàn fáwọn obìnrin nínú ìdílé. Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.’” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Èyí fi hàn pé àṣekún tàbí alábàáṣiṣẹ́ ni Éfà jẹ́ fún Ádámù. Jèhófà dìídì dá a lọ́nà tá á fi lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Ádámù ni. Dídá tí Ọlọ́run dá Éfà wà lára ètò tó ṣe láti lè jẹ́ kí tọkọtaya náà máa bímọ kí wọ́n sì máa tọ́jú àwọn ọmọ wọn, ilẹ̀ ayé àtàwọn ẹranko tó wà nínú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí olórí pípé ẹ̀dá, ohun àti ọkọ rẹ̀ á máa finú wénú á sì tún máa fún ọkọ rẹ̀ níṣìírí gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́. Ẹ ò rí i bínú Ádámù á ṣe ti dùn tó nígbà tó rí ẹ̀bùn tó jíire yìí gbà látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá!—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:23.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run ṣòfin lórí bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fáwọn ìyá wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ máa tẹ́ńbẹ́lú wọn. Bí ọmọkùnrin kan láàárín wọn bá “pe ibi wá sórí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀,” pípa ni wọ́n máa pa á. Bíbélì rọ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni láti “jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí” wọn.—Léfítíkù 19:3; 20:9; Éfésù 6:1; Diutarónómì 5:16; 27:16; Òwe 30:17.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé baálé ilé ló máa ń bójú tó ilé, síbẹ̀ olùkọ́ gbogbo ọmọ wọn pátá, tọkùnrin tobìnrin làwọn abiyamọ ìgbàanì jẹ́. Ọlọ́run sì pàṣẹ fún àwọn ọmọkùnrin pé wọn ò gbọ́dọ̀ ‘ṣá òfin ìyá wọn tì.’ (Òwe 6:20) Bákan náà, Òwe orí kọkànlélọ́gbọ̀n ṣàlàyé “ìhìn iṣẹ́ wíwúwo tí ìyá [Ọba Lémúẹ́lì] fún un bí ìtọ́sọ́nà.” Ó fi ọgbọ́n tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà pé kó má mu ọtí ní ìmukúmu, ó sọ fún un pé: “Kì í ṣe fún àwọn ọba láti máa mu wáìnì tàbí fún àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga láti máa sọ pé: ‘Ọtí tí ń pani dà?’ kí ènìyàn má bàa mu, kí ó sì gbàgbé ohun tí a fàṣẹ gbé kalẹ̀, kí ó sì ṣe ìyípo ọ̀ràn ẹjọ́ èyíkéyìí lára àwọn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́.”—Òwe 31:1, 4, 5.

Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ní in lọ́kàn láti gbéyàwó lá á rọ́gbọ́n kọ́ bí wọ́n bá kíyè sí bí ìyá Ọba Lémúẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe “aya tí ó dáńgájíá,” nígbà tó sọ pé: “Ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn.” Lẹ́yìn náà ló ṣàlàyé ipa ribiribi tírú ìyàwó bẹ́ẹ̀ ń kó lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ, ìyá ọba tún fi kún un pé: “Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.” (Òwe 31:10-31) Dájúdájú, ipò ọ̀wọ̀ àti ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe pàtàkì nínú ilé ni Ẹlẹ́dàá wa to àwọn obìnrin sí.

Láàárín ìjọ Kristẹni, ẹni ọ̀wọ̀ àti ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n ka àwọn ìyàwó àtàwọn ìyá sí. Éfésù 5:25 sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín.” Ṣebí ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà ló kọ́ ọ láti fọwọ́ pàtàkì mú “ìwé mímọ́ láti kékeré.” Pọ́ọ̀lù fún un ní ìmọ̀ràn tó ní ìmísí Ọlọ́run pé: “Pàrọwà fún . . . àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá.” (2 Tímótì 3:15; 1 Tímótì 5:1, 2) Torí náà, ọkùnrin kan ní láti máa bọ̀wọ̀ fún àgbà obìnrin bíi pé ìyá náà ló bí i. A lè rí i kedere báyìí pé ojú pàtàkì ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin, ipò ọ̀wọ̀ ló sì tò wọ́n sí.

Máa Kí Wọn Kú Iṣẹ́

Ọkùnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà níbi tí wọn kò ti ka obìnrin kún sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi kọ́ mi ni pé ọkùnrin nìkan ló rílé ayé wá, mo sì ti fojú ara mi rí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe obìnrin ní ìṣekúṣe àti bí wọn kì í ṣe fọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n. Nítorí náà, ṣe ni mo tiraka kó tó di pé mo lè máa ka obìnrin sí irú ẹni tí Ẹlẹ́dàá kà wọ́n sí, ìyẹn ni àṣekún tàbí alábàárò nínú ilé, àti ẹnì kejì lẹ́nu kíkọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún mi láti máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó mi, mo mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀ ni báwọn ọmọ mi ṣe ń hùwà dáadáa.”

Dájúdájú, inú àwọn abiyamọ tí wọ́n ṣiṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọ wọn á máa dùn lórí ipa tí wọ́n ń kó. Iṣẹ́ tí ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn niṣẹ́ wọn. Ẹ̀tọ́ wa ni pé ká máa gbóríyìn fún wọn ká sì gbà pé iṣẹ́ ni wọ́n ń ṣe. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn ìyá wa kọ́ wa o. Àwọn ló kọ́ wa ní ìwà tá à ń hù ká lè jẹ́ èèyàn jálẹ̀ ìgbésí ayé wa. Àwọn náà ló kọ́ wa níwà rere tí kì í jẹ́ kéèyàn di kò-rẹ́ni-bá-rìn láwùjọ. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé àwọn ìyá ló fi ìwà ọmọlúwàbí kọ́ wọn tí wọ́n sì fọ̀nà Ọlọ́run hàn wọ́n, ẹ̀kọ́ yìí ni kò sì jẹ́ kí wọ́n ṣi ẹsẹ̀ gbé títí di báyìí. Ọjọ́ wo ni ìwọ ti dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá rẹ kẹ́yìn lórí àwọn nǹkan tó ti ṣe fún ẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ìyá Peter ló kọ́ ọ láti ní àforítì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ahmed mọyì ìrànlọ́wọ́ tí ìyàwó ẹ̀ ṣe lórí títọ́ àwọn ọmọ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lina sọ pé ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn ìyàwó òun ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin àwọn ló jẹ́ kí wọ́n máa hùwà tó dáa