Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run wà?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run wà?
BÉÈYÀN bá pe Ọlọ́run ní alágbára gbogbo àti arínúróde, òótọ́ ló sọ. Síbẹ̀, nígbà táwọn kan ń ṣàpèjúwe ọlá ńlá Ọlọ́run síwájú sí i, wọ́n fi kún un pé kò sí ibi tí Ọlọ́run ò sí. Wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa ń wà níbi gbogbo, nígbà kan náà.
Dájúdájú, Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni lóòótọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ alágbára gbogbo, ó sì tún jẹ́ arínúróde. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Hébérù 4:13; Ìṣípayá 11:17) Ìyẹn sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run. Àmọ́, ṣé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà, ṣé kò ní ibì kan pàtó tó fi ṣe ibùgbé ni?
Níbo Ni Ọlọ́run Wà?
Àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan mẹ́nu kan “ọ̀run” gẹ́gẹ́ bí ‘ibi àfìdímúlẹ̀ tí Ọlọ́run ń gbé.’ (1 Ọba 8:39, 43, 49; 2 Kíróníkà 6:33, 39) Àmọ́ ṣá o, nígbà tí àkọsílẹ̀ kan nínú Bíbélì ń ṣàpèjúwe ọlá ńlá Jèhófà Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ọlọ́run yóò ha máa bá aráyé gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí? Wò ó! Ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́.”—2 Kíróníkà 6:18.
Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Nítorí náà, ilẹ̀ ọba ẹ̀mí tí kì í ṣe ayé wa níbí ló ń gbé. Nígbà tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọ̀run” gẹ́gẹ́ bí ibùgbé Ọlọ́run, ńṣe ló ń sọ bí ibi tí Ọlọ́run ń gbé ṣe ga fíofío ju orí ilẹ̀ ayé rírẹlẹ̀ táwa ń gbé níbí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ ṣá, Bíbélì kọ́ wa pé ibi tí Ọlọ́run ń gbé yàtọ̀ pátápátá sí àgbáálá ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n ó ṣáà dájú pé ó ń gbé níbì kan pàtó.—Jóòbù 2:1-2.
Ọlọ́run Jẹ́ Ẹni Gidi Kan
Jésù mẹ́nu ba ibi tí Jèhófà ń gbé nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ní ń bẹ. . . . mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 14:2) Ibo ni Jésù bá ọ̀nà rẹ̀ lọ? Ó “wọlé sí . . . ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.” (Hébérù 9:24) Ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì la lè rí kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run nínú àkọsílẹ̀ yìí. Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ni pé ó ní ibi kan ní ti gidi tó ń gbé. Ẹ̀kọ́ kejì ni pé ó jẹ́ ẹni gidi, kì í wulẹ̀ ṣe agbára kàǹkà kan tí ò ṣeé ṣàpèjúwe tó wà níbi gbogbo.
Mátíù 6:9; 12:50) Ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yìí kò yàtọ̀ sí bá a ṣe kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kí wọ́n máa gbàdúrà láti nǹkan tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún ṣaájú. Nínú ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ tó sì ní ìmísí Ọlọ́run, ni àdúrà yìí wà, ó kà pé: “Bojú wolẹ̀ ní ti gidi láti ibùgbé rẹ mímọ́, ọ̀run, kí o sì bù kún àwọn ènìyàn rẹ.”—Diutarónómì 26:15.
Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” Gbígbàdúrà lọ́nà yìí ń fi hàn pé Jèhófà, tó jẹ́ ẹni gidi kan, tó ń gbé ní ibi pàtó kan, ìyẹn ilẹ̀ ẹ̀mí tí Bíbélì pè ní “ọ̀run” ni wọ́n ń gbàdúrà sí. (Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run Tó Ń Ṣiṣẹ́ Débi Gbogbo
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sábà máa ń sọ pé Ọlọ́run ní ibi kan pàtó tó ń gbé, ó sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́ bíi pé ó wà níbi gbogbo. Onísáàmù náà Dáfídì, béèrè pé: “Ibo ni mo lè lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ, ibo sì ni mo lè fẹsẹ̀ fẹ lọ kúrò ní ojú rẹ?” (Sáàmù 139:7) Àwọn kan ti lè ṣi irú àwọn ẹsẹ Bíbélì bí èyí lóye kí wọ́n sì máa sọ pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà. Síbẹ̀, bá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì bá dé ẹsẹ yìí, àtàwọn ẹsẹ mìíràn nínú Bíbélì, a óò rí i kedere pé Jèhófà lè rán ẹ̀mí mímọ́, tàbí agbára tó fi ń ṣiṣẹ́, jáde láti ibi tí òun fúnra rẹ̀ wà lọ sí apá ibikíbi lágbàáyé.
Bí ìgbà tí bàbá kan bá na ọwọ́ jáde, tó fi gbá ọmọ ẹ̀ mọ́ra, kó bàa lè tù ú nínú kó sì fi hàn án pé òun wà lẹ́yìn ẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ọwọ́ Jèhófà, tó dúró fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe lè nà dé ibikíbi ní ilẹ̀ ọba ẹ̀mí àti ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé kó bàa lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi lè sọ pé: “Bí mo bá mú ìyẹ́ apá tí ó jẹ́ ti ọ̀yẹ̀, kí n lè máa gbé nínú òkun jíjìnnàréré jù lọ, ibẹ̀, pẹ̀lú, ni ọwọ́ rẹ yóò ti ṣamọ̀nà mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbá mi mú.”—Sáàmù 139:9, 10.
O Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà ló mú kó yọ̀ọ̀da fún àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì láti fi èdè ẹ̀dá èèyàn ṣàpèjúwe Òun àti ibi tóun ń gbé lọ́nà tá ó fi lóye irú ẹni tó jẹ́ àti bí ibùgbé rẹ̀ ṣe rí. Lọ́nà yìí àti ní àwọn ọ̀nà mìíràn, ńṣe ló dà bíi pé ó “rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 113:6) Síbẹ̀, kò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti mọ ohun gbogbo nípa Ọlọ́run.
Jèhófà tayọ nínú ọlá, gíga rẹ̀ ò láfiwé, ó sì jẹ́ ẹni àgbàyanu, èyí kọjá ohun tí èèyàn lè ṣàpèjúwe. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa ibùgbé rẹ̀ lókè ọ̀run bí ibi pàtó kan, kò lè ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn rárá láti ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye nípa ohun tí ilẹ̀ ọba ẹ̀mí yẹn túmọ̀ sí.—Sáàmù 139:6.
Síbẹ̀, ìwọ̀nba òye tá a ní nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ ní ti gidi fi wá lọ́kàn balẹ̀. A ti wá mọ̀ pé kì í wulẹ̀ ṣe agbára kàǹkà kan ṣáá, tí ò ṣeé ṣàlàyé, tó wà nínú gbogbo nǹkan láyé àti lọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ẹni gidi kan, ó ní ibi kan pàtó tó ń gbé, ó sì ní àwọn ànímọ́ tá a lè fi mọ̀ ọ́n yàtọ̀, irú bí ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ló ṣílẹ̀kùn àǹfààní àgbàyanu jù lọ sílẹ̀ fún ẹ̀dá èyíkéyìí, ìyẹn ni àǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Olódùmarè, ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, títí láé.—Jákọ́bù 4:8.