Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Tẹlifóònù Alágbèéká Dára àbí Kò Dára?

Ṣé Tẹlifóònù Alágbèéká Dára àbí Kò Dára?

Ṣé Tẹlifóònù Alágbèéká Dára àbí Kò Dára?

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ

NÍ ỌDÚN mélòó kan sẹ́yìn, téèyàn bá sọ̀rọ̀ nípa tẹlifóònù alágbèéká, kò lè nítumọ̀ létí àwọn tó bá gbọ́ ọ. Nítorí pé béèyàn bá fẹ́ máa gbé tẹlifóònù káàkiri àfi kó jẹ́ ẹni tó taagun, tàbí kó gbé e sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, nítorí pé gìdìgbì gidigbi báyìí làwọn bátìrì tó ń lò. Fóònù nìkan sì tóbi ju páálí bàtà lọ, àti pé ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ dọ́là ni wọ́n ń tà wọ́n.

Lóde ìwòyí, tẹlifóònù alágbèéká tó wà tó bílíọ̀nù kan àti àádọ́ta lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù. Ó ju ìdajì lọ lára àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ní in lọ́wọ́. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn fóònù náà ò ju nǹkan téèyàn lè mú dání lọ, àwọn ilé iṣẹ́ kan sì máa ń fún èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ nígbà míì. a Ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ Ọsirélíà, The Bulletin, sọ pé: “Gbogbo tẹlifóònù alágbèéká táwọn èèyàn ń lò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iye tẹlifíṣọ̀n àti kọ̀ǹpútà [tó wà].” Láwọn orílẹ̀-èdè tó ju ogún lọ, iye tẹlifóònù alágbèéká táwọn èèyàn ní pọ̀ ju iye tẹlifóònù oníwáyà tí wọ́n gbà sínú ilé. Ọ̀gá kan nílé iṣẹ́ tẹlifóònù sọ pé tẹlifóònù alágbèéká kọjá ohun àgbàyanu kan lásán, “ohun tó gbayì láwùjọ ni.”

Ipa wo làwọn tẹlifóònù alágbèéká ń ní lórí àwọn èèyàn láwùjọ? Ṣé wọ́n dára àbí wọn ò dára?

Ó Ń Mú Kí Ọjà Tà Sí I

Tẹlifóònù alágbèéká ń mú kí àwọn èèyàn máa rí ọjà tà sí i nítorí pé ńṣe lòun fúnra ẹ̀ ń tà wàràwàrà. Ìròyìn láti ilé iṣẹ́ ńlá kan sọ pé: “Tẹlifóònù alágbèéká làwọn èèyàn ń rà jù lọ lára àwọn ohun èlò oníná tàbí oníbátìrì.” Lédè mìíràn, iye táwọn èèyàn ń ná sórí tẹlifóònù alágbèéká lóde òní pọ̀ ju iye tí wọ́n máa ń ná sórí àwọn ohun èlò oníná tàbí oníbátìrì látijọ́ lọ.

Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Ọsirélíà, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára ogún mílíọ̀nù èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ tí wọ́n ní tẹlifóònù alágbèéká. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, lára àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifóònù tó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn, àwọn oníbàárà ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn fi tẹlifóònù pe àwọn èèyàn nígbà bílíọ̀nù méje àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù. Ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé, tẹlifóònù alágbèéká máa ń ká kòkó àìmọye dọ́là wọlé lọ́dún fáwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀. Èyí lè jẹ́ ká rí ìdí tí àwọn tó ti rí tajé ṣe nídìí òwò á fi gbà pé tẹlifóònù alágbèéká dára.

Èdè Tuntun Dóde

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìgbà làwọn èèyàn máa ń fi fóònù yìí kọ lẹ́tà síra wọn dípò kí wọ́n fi bára wọn sọ̀rọ̀. Èyí tí wọn ì bá fi sọ̀rọ̀ ní tààràtà sínú tẹlifóònù ọwọ́ wọn, ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń lò ó, pàápàá àwọn ọ̀dọ́, máa ń fi kọ lẹ́tà ṣókí síra wọn. Lílò tí wọ́n ń lò ó láti kọ lẹ́tà ṣókí yìí máa ń dín owó tí wọ́n á ná kù, ẹnu kí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ náà sínú fóònù kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ara wọn ni. Nítorí pé kíkọ lẹ́tà ránṣẹ́ lọ́nà yìí máa ń gba pé kéèyàn máa tẹ bọ́tìnì kéékèèké lórí fóònù náà láti tẹ ohun tó fẹ́ sọ, álífábẹ́ẹ̀tì àti nọ́ńbà làwọn tó kúndùn àtimáa kọ irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ fi máa ń kọ ọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó dà bí ẹnà ni wọ́n sì máa ń lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fífi fóònù kọ lẹ́tà báyìí ò rọrùn bíi kéèyàn bá ẹni tọ̀hún sọ̀rọ̀, síbẹ̀ lóṣooṣù làwọn èèyàn ń fi fóònù kọ nǹkan bí ọgbọ̀n bílíọ̀nù lẹ́tà síra wọn lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé.

Kí làwọn èèyàn ń rí bára wọn sọ tó bẹ́ẹ̀? Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti fi hàn pé bá a bá kó ọgọ́rùn-ún ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún sí mẹ́rìnlélógún jọ, a óò rí méjìlélógójì nínú wọn tó ń lò ó láti bára wọn tage, tí ogún lára wọn á máa lo ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tó gbòde yìí láti sọ pé kí ẹnì kan máa bá àwọn ròde, mẹ́tàlá á sì máa lò ó láti já ara wọn sílẹ̀.

Àwọn kan tó ń kíyè sí ohun tó ń lọ láwùjọ ti ń kọminú sí bí wọ́n ṣe ń ba ọ̀rọ̀ àti èdè jẹ́ bí wọ́n bá ń fi fóònù kọ lẹ́tà, wọ́n sọ pé kò ní jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ ní òye èdè tó já gaara. Àwọn míì sọ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, pé àǹfààní àtikọ lẹ́tà ṣókí yẹn á wulẹ̀ “jẹ́ kí ojú àwọn ọmọdé túbọ̀ là sí ìwé kíkọ ni.” Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ tó ṣe ìwé atúmọ̀ èdè kan tí wọ́n ń lò nílẹ̀ Ọsirélíà sọ fún aṣojú ìwé ìròyìn Sun-Herald pé: “Ó ṣọ̀wọ́n kéèyàn tó lè dá èdè tuntun sílẹ̀ . . . ṣùgbọ́n bí a bá pa gbogbo lẹ́tà táwọn ọ̀dọ́ ń fi fóònù àti Íńtánẹ́ẹ̀tì kọ pọ̀, ńṣe ló fi hàn pé wọ́n ti ń kọ̀wé sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. [Wọ́n] gbọ́dọ̀ ní òye èdè tó já gaara kí wọ́n tó lè mọ ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà fi fóònù kọ lẹ́tà kí wọ́n sì dẹni tó mọ àpadé àludé . . . ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ lẹ́tà yìí.”

Ibi Díẹ̀ Tí Lílo Tẹlifóònù Alágbèéká Kù Díẹ̀ Káàtó Sí

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irin iṣẹ́ tó wúlò ni tẹlifóònù alágbèéká bá a bá fẹ́ bá àwọn ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ ajé, láwọn ìgbà míì, ohun tó ń kan ìdí ẹni mọ́lẹ̀ lọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ kà á sí, nítorí pé kì í jẹ́ kí wọ́n lè kúrò ní ọ́fíìsì. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òṣìṣẹ́ tó ń polówó ọjà àti ìdá ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òṣìṣẹ́ kọ́lékọ́lé ló máa ń dà bíi pé kí wọ́n já ara wọn sí méjì nítorí pé báwọn ọ̀gá iṣẹ́ ṣe ń pè wọ́n náà làwọn oníbàárà á máa ké sí wọn ní gbogbo ìgbà ṣáá. Nítorí pé ibi yòówù káwọn èèyàn wà tàbí ohun yòówù kí wọ́n máa ṣe àfi kí wọ́n dá ẹni tó bá pè wọ́n lórí tẹlifóònù alágbèéká lóhùn, wọ́n máa ń kó sí pákáǹleke tí olùṣèwádìí kan pè ní “àṣà ká máa díni lọ́wọ́.” Nítorí àtikòòré èyí, àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti ṣe àwọn ohun èlò ìkọ́lé kan sáwọn ilé ìtajà oúnjẹ àti àwọn gbọ̀ngàn ńlá. Tẹlifóònù alágbèéká kì í ṣiṣẹ́ nínú ilé tí wọ́n bá fi àwọn ohun èlò náà kọ́.—Wo àpótí tó ní àkọlé náà, “Àwọn Àbá Nípa Bó O Ṣe Lè Lo Tẹlifóònù Alágbèéká.”

Yàtọ̀ sí pé tẹlifóònù yìí máa ń jẹ́ kí wọ́n já lu ohun téèyàn bá ń ṣe, wọ́n tún lè dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ ní pópó nítorí rírí téèyàn máa ń rí wọn yẹyẹ̀ẹ̀yẹ. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Kánádà fi hàn pé bó ṣe léwu kéèyàn máa wakọ̀ lẹ́yìn tó bá ti mutí yó náà ló léwu kéèyàn máa lo tẹlifóònù alágbèéká bó bá ń wakọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Mark Stevenson, ti Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Àwọn Tó Fara Pa ní Yunifásítì Ìwọ̀ Oòrùn Ọsirélíà, ṣàlàyé pé bíbá èèyàn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù ṣòro púpọ̀ ju kéèyàn wulẹ̀ máa bá èèyàn sọ̀rọ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Ó léwu débi pé láwọn ibì kan, àwọn ọlọ́pàá máa ń gbowó ìtanràn lọ́wọ́ dírẹ́bà tó bá ń lò ó nígbà tó ń wakọ̀. Síbẹ̀, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe jákèjádò ilẹ̀ Ọsirélíà láìpẹ́ yìí fi hàn pé nínú dírẹ́bà márùn-ún, dírẹ́bà kan máa ń fi fóònù kọ lẹ́tà. Nínú dírẹ́bà mẹ́tà, dírẹ́bà kan máa ń fi tẹlifóònù alágbèéká pe àwọn èèyàn tàbí kí wọ́n fi pè wọ́n bí wọ́n bá ń wakọ̀ lọ́wọ́.

Ewu tún wà nínú àṣìlò tẹlifóònù alágbèéká béèyàn bá ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òfuurufú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtànṣán tó ń gbé ọ̀rọ̀ kọjá sínú tẹlifóònù alágbèéká ò lè wọnú àwọn wáyà ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe, a rí lára àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n ṣì fi ń gbé èrò tí ìtànṣán náà lè ta jàǹbá fún. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nínú àwọn ọkọ̀ òfuurufú méjì kan, Ilé Iṣẹ́ Ọkọ̀ Òfuurufú Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìtànṣán tó ń wọnú tẹlifóònù alágbèéká máa ń ṣàkóbá fún irin iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ń gbé ọkọ̀ òfuurufú fò láìséwu.” Nígbà tí agbẹnusọ fún Ilé Iṣẹ́ Ọkọ̀ Òfuurufú náà ń sọ̀rọ̀ lórí irú ewu pàtó kan bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Bí tẹlifóònù alágbèéká bá ṣe ń jìnnà sí ibi tí wọ́n rí òpó rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni ìtànṣán tó ń jáde lára ẹ̀ ṣe máa ń pọ̀ tó. Nítorí náà bí ọkọ̀ òfuurufú bá ṣe ń ròkè lẹ́yìn tó bá ti gbéra, bẹ́ẹ̀ ni agbára ìtànṣán tí fóònù alágbèéká ń lò á máa pọ̀ sí i, èyí tá á mú kí jàǹbá tó lè ta fún ẹ̀rọ tó ń gbé ọkọ̀ òfuurufú fò máa pọ̀ sí i.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Ọsirélíà ti fi hàn pé àwọn ohun èlò tó ń bá iná tàbí ìtànṣán ṣiṣẹ́, tó fi mọ́ tẹlifóònù alágbèéká, ti dá ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú akérò nítorí pé àwọn èrò ọkọ̀ kọtí ikún sí ìkìlọ̀ pé kí wọ́n pa tẹlifóònù wọn bí wọ́n bá ti ń wọnú ọkọ̀ òfuurufú.

Ṣé Tẹlifóònù Alágbèéká Ń Fa Àrùn Jẹjẹrẹ?

Awuyewuye ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí bóyá agbára ìtànṣán tí tẹlifóònù alágbèékà àti òpó tẹlifóònù máa ń ta látaré lè fa àrùn jẹjẹrẹ fáwọn èèyàn. Nítorí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń lo àwọn ohun èlò tó ń bá iná tàbí ìtànṣán ṣiṣẹ́ wọ̀nyí, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára wọn ló ń ṣèpalára fún, ẹ wo bí lílò wọ́n á ṣe léwu tó. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ìwádìí làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń ṣe láti wá fìn-ín ìdí kókò nípa ọṣẹ́ tó ṣeé ṣe kí ìtànṣán tó ń jáde lára tẹlifóònù máa ṣe fún ara ẹ̀dá alààyè. Ibo ni wọ́n ti wá bá ìwádìí wọn dé báyìí o?

Àwùjọ Àwọn Ògbógi Tí Wọ́n Ń Dá Ìwádìí Ṣe Lórí Tẹlifóònù Alágbèéká ti gbé àbájáde ìwádìí wọn jáde, wọ́n sọ pé: “Àwùjọ Ògbógi yìí gbà gbọ́ pé, látàrí ẹ̀rí tó ṣì wà lọ́wọ́, kò sí ìdí táwọn èèyàn tó ń lo tẹlifóònù alágbèéká á fi máa kó ara wọn lọ́kàn sókè.” Ìwé ìròyìn New Scientist tún sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti ń gbé àwọn ìròyìn tó lè bani lẹ́rù jáde láti bí ọdún mélòó kan báyìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó di báa ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé kò sí jàǹbá kankan tí ìtànṣán tó ń jáde látinú tẹlifóònù alágbèéká ń ṣe fún ìlera ara. Àwọn tó sì sọ nínú ìwádìí tiwọn pé ó ń ṣe ìpalára ò tíì lè fi ẹ̀rí kankan ti ìwádìí náà lẹ́yìn.”

Àmọ́ ṣá o, nítorí pé àwọn èèyàn ò yé ṣiyèméjì nípa jàǹbá tó ṣeé ṣe kí tẹlifóònù alágbèéká máa ṣe fún ara, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń da àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là sórí ìwádìí síwájú sí i. Títí tá ó fi rí ìdáhùn tó ṣe gúnmọ́, àwọn àbá tí àwọn ògbógi yìí dá nìyí: “Má máa pẹ́ lórí tẹlifóònù alágbèéká. Tẹlifóònù tí ìtànṣán tó ń jáde lára ẹ̀ kò pọ̀ ni kó o máa lò. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí ìtànṣán tó ń wọ agbárí ẹ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Máa lo gbohùngbohùn àkìbọtí àtàwọn ohun èlò mìíràn nítorí pé wọ́n máa ń dín ìtànṣán téèyàn ń gbà sára kù.” Àwùjọ Ògbógi náà tún dámọ̀ràn pé kí “àwọn ọmọdé tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún má ṣe lo tẹlifóònù alágbèéká,” níwọ̀n bí iṣan ara àwọn ọmọdé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà kò ti gbó nítorí náà “ohun téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀ lè tètè ṣèpalára fún wọn.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé awuyewuye ṣì wà síbẹ̀ lórí ìlò tẹlifóònù alágbèéká, igi owó ló ṣì jẹ́, tèwe tàgbà ló sì ń lò ó láwùjọ. Bíi tàwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ míì bíi tẹlifíṣọ̀n àti kọ̀ǹpútà, tẹlifóònù alágbèéká lè jẹ́ ohun èlò wíwúlò téèyàn ń darí tàbí èyí tó ń darí ẹni nídàkudà. Nítorí náà, yálà ó máa jẹ́ ohun èlò tó dára tàbí èyí tí kò dára, ó kù sọ́wọ́ ẹni tó bá ń lò ó.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà míì, báwọn kan bá kọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú ilé iṣẹ́ tó ń ta tẹlifóònù pé láàárín àkókò kan àwọn á máa ná iye kan pàtó láti fi ké sí àwọn èèyàn lórí tẹlifóònù, wọ́n lè fún wọn ní fóònù lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

ÀWỌN ÀBÁ NÍPA BÓ O ṢE LÈ LO TẸLIFÓÒNÙ ALÁGBÈÉKÁ

1. Má ṣe pariwo jù bó o bá ń lo tẹlifóònù rẹ níbi tí èrò pọ̀ sí. Ó ṣe tán makirofóònù tí wọ́n ṣe mọ́ ọn lágbára gan-an, kò sì dà bíi pé àwọn tó wà nítòsí rẹ á fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ.

2. Bó o bá wà níbi ìjọsìn, níbi ìpàdé ìṣòwò, nílé sinimá tàbí níbi ayẹyẹ míì tí èrò pọ̀ sí, tàbí nílé oúnjẹ, pa fóònù rẹ tàbí kó o yí i sí ibi tá á ti gbọ̀n rìrì láìpariwo bí wọ́n bá ké sí ọ.

3. Má ṣe lo tẹlifóònù tí wàá fọwọ́ gbé sétí bó o bá ń wakọ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, nǹkan bí ọgbọ̀n bílíọ̀nù lẹ́tà làwọn èèyàn ń fi tẹlifóònù alágbèéká kọ ránṣẹ́ síra lóṣooṣù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Bí ewu ṣe wà nínú kéèyàn máa wakọ̀ lẹ́yìn tó bá ti mutí yó náà lewu ṣe wà nínú kéèyàn máa lo tẹlifóònù alágbèéká bó bá ń wakọ̀