Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹlẹ́wọ̀n Ni Wọ́n, Síbẹ̀ Wọ́n Lómìnira!

Ẹlẹ́wọ̀n Ni Wọ́n, Síbẹ̀ Wọ́n Lómìnira!

Ẹlẹ́wọ̀n Ni Wọ́n, Síbẹ̀ Wọ́n Lómìnira!

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Mẹ́síkò

ÀGBÁRÍJỌ àwọn erékùṣù kan tó ń jẹ́ Islas Marías wà ní àádọ́rùn-ún kìlómítà sí etíkun tó wà ní ìwọ̀ oòrùn àárín gbùngbùn Mẹ́síkò. a Ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Òkun Pàsífíìkì tó ń jẹ́ Islas Marías yìí ni María Madre. Ibẹ̀ ni ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Mẹ́síkò máa ń kó àwọn ọ̀daràn sí látọdún 1905 wá. Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé àjẹkún ìyà làwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá kó lọ síbẹ̀ máa ń jẹ. Àmọ́ àwọn tí kì í ṣe ajìhànrín ẹlẹ́wọ̀n tiẹ̀ lè sọ báyìí pé kí wọ́n kó àwọn náà lọ síbẹ̀!

Ìdí kan tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan kó ẹbí wọn wá síbẹ̀. Dípò tí wọn ì bá fi ti àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ mọ́ inú àhámọ́ onírin, inú ilé kéékèèké ni wọ́n máa ń gbé. Gbogbo nǹkan téèyàn lè rí nínú ìlú kékeré èyíkéyìí ló wà ní erékùṣù náà. Tẹlifóònù ni o, ibi téèyàn ti lè tẹ wáyà ni o, tó fi mọ́ tẹlifíṣọ̀n àti ilé ìfìwéránṣẹ́, gbogbo ẹ̀ ló pé síbẹ̀, ìyẹn ló sì ń jẹ́ káwọn ẹlẹ́wọ̀n mọ ohun tó ń lọ lẹ́yìn òde erékùṣù náà. Àwọn ọmọ lè lọ sílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n bá fẹ́ kàwé sí i, wọ́n gbọ́dọ̀ padà sínú ìlú lẹ́yìn òde erékùṣù náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sáyè fáwọn èèyàn láti máa dà wọnú erékùṣù náà, ọkọ̀ àwọn ọmọ ogun ojú omi máa ń lọ síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, á sì kó àwọn ohun èlò àtàwọn àlejò lọ síbẹ̀.

Báwo ni wọ́n ṣe ń tún ayé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀ ṣe? Àtìpó làwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní erékùṣù náà máa ń pe ara wọn. Wọ́n máa ń kó wọn ṣiṣẹ́ fún wákàtí bí mélòó kan lójúmọ́. Kì í wulẹ̀ ṣe pé èyí á jẹ́ kí ìta mọ́ wọn lára bí wọ́n bá kúrò lẹ́wọ̀n nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà rówó sanwó ilé tí wọ́n ń gbé. Àwọn àtìpó náà tún lómìnira láti máa ṣe iṣẹ́ tó bá wù wọ́n, bíi kí wọ́n máa dáko tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ ọwọ́ láti lè rí tọ́rọ́ kọ́bọ̀ tù jọ. Èyí ò túmọ̀ sí pé kò sí òfin kankan tó ká wọn lọ́wọ́ kò gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n o. Bí àpẹẹrẹ, ó di dandan káwọn ẹlẹ́wọ̀n pé jọ ní ìdájí, wọ́n sì ti gbọ́dọ̀ wà nílè lẹ́yìn ìséde tó máa ń wáyé ní agogo mẹ́sàn-án alẹ́.

Òmìnira Tẹ̀mí Dé sí Erékùṣù Islas Marías

Ní nǹkan bí ọdún 1985, àtìpó kan táwọn ẹbí ẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní kí wọ́n wá ran òun lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ. Nígbà tó ṣe, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kóra jọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpàdé Kristẹni. Lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ti gbàṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí erékùṣù náà déédéé. Bí wọ́n bá ti gbéra láti ìlú Mazatlán, tó wà lódì kejì erékùṣù náà ní alẹ́ á gbà wọ́n tó wákàtí mẹ́tàlá kí wọ́n tó débẹ̀ lọ́jọ́ kejì. Látìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́kọ́ fi ẹsẹ̀ tẹ ibẹ̀ lọ́dún 1985, ó ti tó ogójì ẹlẹ́wọ̀n tó ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì ti ṣèrìbọmi. Nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dá fún wọn lẹ́wọ̀n sì pé, wọ́n ti dá wọn sílẹ̀. Nígbà tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́fà tó ti ṣèrìbọmi ló wà ní erékùṣù náà, nǹkan bí èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló sì ń ṣèpàdé Kristẹni níbẹ̀.

Inú àwọn aláṣẹ máa ń dùn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí ìsapá wọn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó di Ẹlẹ́rìí lára wọn. Láìpẹ́ yìí, igbá kejì ọ̀gá wọ́dà tó wà ní erékùṣù yìí, sọ fún Ẹlẹ́rìí kan tó wá síbẹ̀ pé: “Ó mà dáa gan-an o tí èrò tiyín àti tiwa dọ́gba! A jọ ń fẹ́ àlàáfíà ara fáwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ni, ó sì jọ wù wá pé kí wọ́n di ọmọlúwàbí èèyàn ni, ẹ sì tún wá ń ṣe wàhálà torí wọn. A wà lẹ́yìn yín gbágbáágbá.” Ó sọ pé òun á tún àwọn ilé tí wọ́n ti ní káwọn ará ti máa ṣèpàdé ṣe.

Ẹlẹ́rìí kan tó ti ṣèrìbọmi, tó ti wà lẹ́wọ̀n fún ọdún mẹ́wàá, sọ pé: “Nígbà tí arákùnrin tó wá bẹ̀ wá wò bi mí bóyá màá fẹ́ láti kúrò níbẹ̀, mo sọ fún un pé á wù mí kí n máa sìn nìṣó níbí; mo ti ka ibí yìí sí ìpínlẹ̀ ìwàásù tèmi, nítorí pé àwọn tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ pọ̀. Àmọ́ ṣá o, á wù mí kí n lè máa lọ sí àwọn àpéjọ kí n sì máa gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni.” Ọdún tó ń bọ̀ ni wọ́n máa dá a sílẹ̀ nítorí pé ó níwà rere.

Àwọn èèyàn máa ń sọ pé ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbi àgbáríjọ erékùṣù Islas Marías ti tún ayé wọn ṣe gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti fún wọn ní òmìnira tòótọ́ ó sì ti tún ayé wọn ṣe nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé ó ti mú “ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè” àti ‘ìlajúsílẹ̀ rekete [wá] fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.’—Lúùkù 4:18; Aísáyà 61:1.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àkọsílẹ̀ ìjọba, mẹ́rin ni àwọn erékùṣù yìí, mẹ́tà nínú wọn ni kò ní olùgbé kankan.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ajoògùnyó Ni Tẹ́lẹ̀, àmọ́ Ó Ti Di Alàgbà Ìjọ Kristẹni

Nítorí pé Guillermo ń ta oògùn olóró tó sì tún ń lò ó ni wọ́n ṣe jù ú sẹ́wọ̀n. Kódà, lẹ́yìn tí wọ́n mú un lọ síbi àgbáríjọ erékùṣù náà, ńṣe ló ṣáà ń lo oògùn olóró lọ ràì. Ṣùgbọ́n ó kíyè sí i pé àwọn kan tí wọ́n dá ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún nítorí ẹ̀sùn tó jẹ mọ́ ṣíṣòwò oògùn máa ń múra dáadáa, ojú wọn máa ń fani mọ́ra, wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Nígbà tó wá mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun náà bá wọn lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Guillermo ṣe ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé ẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi dá a sílẹ̀. Kíá ló wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí kó bàa lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó. Ní báyìí, ó ti di alàgbà nínú ìjọ Kristẹni, àwọn mẹ́tàdínlógún nínú ìdílé rẹ̀ sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣàlàyé pé: “Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ fún mi pé mo mọ Jèhófà tí mo sì jáwọ́ nínú gbogbo ìwà pálapàla tí mò ń hù yẹn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ ni wọ́n ti kú nítorí pé wọ́n ń lo oògùn olóró. Oògùn olóró ti ra mí níyè, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti rántí nǹkan. Ṣùgbọ́n ọ̀nà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ kí iyè mí ṣí. Èyí ya àwọn dókítà lẹ́nu nítorí pé wọ́n ti rò pé kò lè sàn fún mi mọ́. Ohun tí òtítọ́ Bíbélì ti ṣe fún èmi àti ìdílé mi kọjá sísọ. A kì í rí ara wa sójú tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo wa ti wà ní ìṣọ̀kan báyìí.”

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Mazatlán

Islas Marías

María Madre

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn àjèjì àtàwọn ẹbí wọn máa ń lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní María Madre