Abiyamọ Kú Ọrọ̀ Ọmọ!
Abiyamọ Kú Ọrọ̀ Ọmọ!
“Iṣẹ́ táwọn ìyá ń ṣe lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù láwùjọ ẹ̀dá. . . . Bí ìyá ò bá ṣiṣẹ́ ẹ̀ dáadáa, ṣe ni ká má wulẹ̀ retí àwọn ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí ká kúkú máa retí àwọn ìran tọ́jọ́ iwájú wọn ti polúkúrúmuṣu.” —Theodore Roosevelt, ààrẹ kẹrìndínlọ́gbọ̀n tó jẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sọ̀rọ̀ yìí.
GBOGBO èèyàn ló mọ̀ pé ìyá ni ọlọ́kọ̀ tó wà wá wá sáyé, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìyá ò mọ sórí ọmọ bíbí. Òǹkọ̀wé kan sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ pàtàkì tí ìyá ń ṣe lápá ibi tó pọ̀ jù lọ láyé òde òní, ó ní: “Bí ara ọmọ ṣe máa dá tó, irú ìmọ̀ tọ́mọ máa ní, bí ọpọlọ ẹ̀ ṣe máa jí pépé tó, irú èèyàn tó máa yà, ìwà tá a máa hù àti bó ṣe máa lọ́kàn tó, gbogbo ẹ̀ dọwọ́ ìyá.”
Ọ̀kan lára ẹgbàágbèje iṣẹ́ ìyá ni pé kó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Ẹnu ìyá lọmọ ti sábà máa ń kọ́ ọ̀rọ̀ tó bá kọ́kọ́ máa pè àti bá á ṣe máa sọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń pe èdè téèyàn bá kọ́kọ́ gbọ́ ní èdè àbínibí. Àkókò tí ìyá máa ń lò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ sábà máa ń pọ̀ ju èyí tí bàbá máa ń lò lọ́dọ̀ wọn lọ, nítorí náà, ó lè jẹ́ ìyá lá á máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tá á sì máa bá wọn wí ju bàbá wọn lọ. Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń pa á lówe nílẹ̀ Mẹ́síkò pé: “Ẹnú ọmú lọmọ ti í kẹ́kọ̀ọ́,” láti lè sọ bí iṣẹ́ abiyamọ ti ṣe pàtàkì tó.
Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa náà ò fọ̀rọ̀ àwọn abiyamọ ṣeré. Kódà, ọ̀kan lára Òfin Mẹ́wàá tí Ọlọ́run fi ìka ara rẹ̀ kọ sára wàláà òkúta rọ àwọn ọmọ pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:12; 31:18; Diutarónómì 9:10) Bákan náà, òwe kan nínú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “òfin ìyá rẹ.” (Òwe 1:8) Káàkiri ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ báyìí pé ó ṣe pàtàkì ká kọ́ àwọn ọmọ dáadáa láàárín ọdún mẹ́ta tí wọ́n bá kọ́kọ́ lò láyé. Láàárín àkókò yìí, ìyá ló sábà máa ń pọ̀n wọ́n kiri.
Kí Ni Díẹ̀ Lára Ohun Tójú Àwọn Abiyamọ Ń Rí?
Ohun kan tó máa ń mú kó ṣòro fáwọn ìyá láti kọ́ ọmọ wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́njú ni pé ó di dandan kí wọ́n wáṣẹ́ ṣe
nítorí àtigbọ́ bùkátà ìdílé. Nínú ìṣirò tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, wọ́n rí i pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lágbàáyé, ó ju ìlàjì àwọn abiyamọ tọ́mọ wọn ò tíì pé ọdún mẹ́ta tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.Yàtọ̀ síyẹn, àwọn obìnrin míì ló máa ń nìkan ṣe wàhálà ọmọ títọ́ nítorí pé ọkọ ti filé sílẹ̀, ó ti wáṣẹ́ lọ sí ìlú míì tàbí orílẹ̀-èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, láwọn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Àméníà, ó fẹ́ẹ̀ tó ìdámẹ́ta àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti wáṣẹ́ lọ sókè òkun. Àwọn ìyá míì ò rẹ́ni bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́ nítorí pé ọkọ ti pa wọ́n tì tàbí kó ti kú.
Láwọn orílẹ̀-èdè kan, olórí ìṣòro tó ń kojú ọ̀pọ̀ abiyamọ ni pé wọn ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ẹ̀ka Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Bójú Tó Ètò Ọrọ̀ Ajé àti Ìbáṣepọ̀ Ẹ̀dá fojú bù ú pé mílíọ̀nù ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin [876,000,000] èèyàn ni ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Tá a bá sì dá gbogbo wọn sọ́nà mẹ́ta, obìnrin ló kó ìdá méjì. Kódà, gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ṣe sọ, nílẹ̀ Áfíríkà, láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń sọ èdè Lárúbáwá, àti ní Ìlà Oòrùn àti Gúúsù Éṣíà, nínú ọgọ́rùn-ún obìnrin, a óò rí iye tó lé ní ọgọ́ta tí ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Láfikún sí i, àìmọye ọkùnrin ló gbà pé kò pọn dandan kí wọ́n jẹ́ kí ọmọbìnrin kàwé, wọ́n tiẹ̀ ní ìwé tí ọmọbìnrin bá kà kò ní jẹ́ kó mọ òwò ọmọ ṣe.
Ìwé ìròyìn Outlook sọ pé ní àgbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Kerala, lórílẹ̀-èdè Íńdíà, níbi táwọn ọmọbìnrin ti máa ń sábà bímọ nígbà tí wọ́n bá wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, kò sí ọkùnrin tó fẹ́ fi ẹni tó kàwé ṣaya. Ní orílẹ̀-èdè Pakistan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè Íńdíà, àwọn ọmọkùnrin ni wọ́n sábà máa ń fojú sí lára. Wọ́n máa ń tọ́ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè ríṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé kí wọ́n bàa lè tọ́jú àwọn òbí wọn tọ́jọ́ ogbó bá dé. Ṣùgbọ́n ní tàwọn obìnrin, ohun tí ìwé Women’s Education in Developing Countries sọ ni pé: “Àwọn òbí kì í náwó púpọ̀ lé àwọn ọmọbìnrin lórí nítorí pé wọn ò retí pé káwọn ọmọbìnrin mówó wálé.”
Tá a bá tún wá ní ká sọ ti wàhálà táwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ń fà fún wọn ńkọ́? Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìyá ò gbọ́dọ̀ sọ pé òun ò gbà kí wọ́n ta ọmọbìnrin òun tó ṣì kéré fún ọkọ tó máa fẹ́ ẹ, ó sì gbọ́dọ̀ dá abẹ́ fáwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Èèwọ̀ tún ni pé kí ìyá máa kọ́ àwọn ọmọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ tàbí kó máa bá wọn wí. Ṣé dandan ni kí ìyá máa tẹ̀ lé irú àṣà báwọ̀nyí kó sì fàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹlòmíì kọ́?
Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò rí báwọn ìyá kan ṣe jàjàyè lójú irú àwọn ìṣòro yìí. A óò túbọ̀ wá mọ báwọn abiyamọ ṣe ṣe pàtàkì tó àti ipò tó yẹ ká tò wọ́n sí. A óò sì tún rí ìdí tí kò fi yẹ ká kóyán wọn kéré gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọ wọn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Tó bá dọ̀rọ̀ ká kọ́ ọmọ kí ọpọlọ ẹ̀ lè jí pépé kó sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣèwádìí kó sì tún mọ nǹkan ṣe, ìyá ni ìyá á máa jẹ́.”—Níbi Àpérò Lórí Ọ̀rọ̀ Àwọn Ọmọdé ní Orílẹ̀-Èdè Burkina Faso ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ yìí lọ́dún 1997.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Bí ara ọmọ ṣe máa dá tó, irú ìmọ̀ tọ́mọ máa ní, irú èèyàn tó máa yà àti bí ọkàn rẹ̀ á ṣe balẹ̀ tó, gbogbo ẹ̀ dọwọ́ ìyá