Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Fàyè Gba Èrò Òdì?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Fàyè Gba Èrò Òdì?
“Orí mi máa ń gbóná nígbà míì débi pé máà sọ àwọn nǹkan tí mi ò fẹ́ sọ sáwọn òbí mi. Mi ò ní dá sí wọn títí inú mi á fi rọ̀.”—Kate, ọmọ ọdún mẹ́tàlá.
“Olórí ìṣòro tí mo ní ni àìbalẹ̀ ọkàn. Nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé mò ń kú lọ, tí mi ò sí ní lè sọ fẹ́nì kan.”—Ivan, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.
OHUN tó ń dunni ló ń pọ̀ lọ́ràn ẹni. Ohun tó bá wà lọ́kàn ẹ lá máa darí ìrònú àti ìṣe rẹ. Ó lè mú kó o hùwà tó dáa, ó sì lè sún ẹ hùwà tí ò dáa. Nígbà míì, ohun tó wà lọ́kàn ẹ lè ru bò ẹ́ lójú. Jacob tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Gbogbo ìgbà ló sábà máa ń dà bíi pé mi ò ṣe dáadáa tó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kì í lè ṣe tó bí mo ṣe rò pé ó yẹ kí n ṣe. Nígbà míì, màá kàn máa sunkún ni tàbí kí n bínú débi pé màá máa fìkanra mọ́ àwọn tó wà nítòsí mi. Èrò inú mi ṣòro darí.”
Síbẹ̀, ara nǹkan tá a fi lè mọ̀ pé ẹnì kan ti dàgbà tẹ́ni tí wọ́n ń fi nǹkan pàtàkì lé lọ́wọ́ ni pé kó ní àmúmọ́ra. Àwọn ògbógi kan ti gbà báyìí pé bí ọpọlọ èèyàn ṣe pé tó kò ṣe pàtàkì bíi kéèyàn ní àmúmọ́ra kó sì mọ bó ṣe lè máa bá àwọn ẹlòmíì lò. Tá ò bá tiẹ̀ wo tìyẹn, Bíbélì sọ pé ó ṣe pàtàkì gan-an ni pé ká máa ní àmúmọ́ra. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 25:28 sọ pé: “Bó ò bá lè pa ìbínú rẹ mọ́ra, wàá dà bí ìlú tí kò ní odi, tí ẹnikẹ́ni lè kọ lù.” (Today’s English Version) Kí ló máa ń mú kó ṣòro fún èèyàn láti ní ìpamọ́ra?
Ìṣòro Ni Fáwọn Ọ̀dọ́
Gbogbo èèyàn pátá, àtàgbà àtọmọdé ló ń tiraka láti máa kóra wọn níjàánu nítorí bí nǹkan ṣe máa ń rí lọ́kàn wọn. Àmọ́, ìgbà téèyàn bá ń gòkè àgbà lẹ́yìn tó ti bàlágà ló máa ń ṣòro jù. Ìwé náà Changing Bodies, Changing Lives, látọwọ́ Ruth Bell sọ pé: “Àwọn èrò tó máa ń wá sí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́kàn kì í yé wọn, nítorí pé nígbà míì inú wọn lè máa dùn kí ẹ̀rù sì tún máa bà wọ́n. Oríṣiríṣi èrò tó ta kora ló máa ń wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn nípa nǹkan kan náà. . . . Nígbà míì inú èèyàn lè máa dùn báyìí ò, lójú ẹsẹ̀ kí nǹkan yí padà kí inú ẹ̀ sì máa bà jẹ́.”
Ṣó ò gbàgbé pé ìrírí ẹ ò tíì pọ̀ nítorí pé o ṣì kéré. (Òwe 1:4) Nítorí náà, bó o bá dédé pàdé ohun tó ò rí rí, ẹ̀rú á ṣe bí ẹni bà ẹ́ díẹ̀, ọkàn rẹ tiẹ̀ lè dà rú. Fọkàn balẹ̀ pé Ẹlẹ́dàá rẹ lóye nǹkan tó wà lọ́kàn rẹ dáadáa. Kódà ó mọ ‘àwọn ìrònú tí ń gbé ọ lọ́kàn sókè.’ (Sáàmù 139:23) Ó ti fi àwọn ìlànà kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lélẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ohun Pàtàkì Tá Á Mú Kó O Lè Fira Ẹ Lọ́kàn Balẹ̀
Ohun pàtàkì kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi lè máa fira ẹ lọ́kàn balẹ̀ ni pé kó o mọ ohun tí wàá máa gbé sọ́kàn. Tó o bá fàyè gba èrò òdì, o ò ní lágbára láti ṣe ohun tó yẹ kó o ṣe. (Òwe 24:10) Báwo lo ṣe lè kọ́ bí wàá ṣe máa lérò tó dáa tí ìrẹ̀wẹ̀sì ò fi ní jọba lọ́kàn ẹ?
Ọ̀nà kan ni pé kó o má ṣe máa ronú nípa àwọn nǹkan tí ò dáa tó lè mú kó o rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí ọkàn ẹ má balẹ̀. Ṣùgbọ́n tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé kó o máa ronú lórí àwọn nǹkan “ṣíṣe pàtàkì” àtàwọn nǹkan tó jẹ́ “òdodo,” wàá lè fi èrò tó tọ́ rọ́pò èrò òdì. (Fílípì 4:8) Ó lè máà rọrùn láti ṣe ohun tá a sọ yìí o, ṣùgbọ́n tó o bá sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i ṣe.
Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jasmine. Nígbà kan, ó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde pé: “Gbogbo ohun tó dojú kọ mí kà mí láyà. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe níbi tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ríṣẹ́ sí yàtọ̀. Mi ò rọ́kàn gbé e. Mi ò rímú mí.” Kò yani lẹ́nu pé ó máa ń ṣe àwọn ọ̀dọ́ báyìí láwọn ìgbà míì, ó sì lè jẹ́ kó máa ṣe wọ́n bíi pé ọkàn wọn ò balẹ̀, tí wọn ò sì ní dára wọn lójú. Bíbélì sọ fún wa pé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Tímótì dáńgájíá láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé e lọ́wọ́. Síbẹ̀, ó dà bíi pé ó fìgbà kan ń ronú pé bóyá lòun máa lè dá iṣẹ́ náà ṣe.—1 Tímótì 4:11-16; 2 Tímótì 1: 6, 7.
Bóyá nígbà tí ìwọ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ kan tàbí èyí tó ò ṣe rí, ọkàn rẹ ò balẹ̀ pé iṣẹ́ yẹn á jẹ́ ọ ṣe. O tiẹ̀ lè ti sọ lọ́kàn ara rẹ pé ‘láé, mi ò lè dá eléyìí ṣe.’ Ṣùgbọ́n o lè borí irú èrò tí ò fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ bẹ́ẹ̀ bó o bá ní in lọ́kàn pé wàá lè ṣe é. Máa ronú lórí bí wàá ṣe mọṣẹ́ náà ṣe dáadáa. Béèrè ohun tí ò bá yé ẹ, kó o sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n bá fún ẹ.—Òwe 1:5, 7.
Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ iṣẹ́ kan sí i, bẹ́ẹ̀ lọkàn rẹ á ṣe máa balẹ̀ nídìí ẹ̀. Má máa ronú púpọ̀ lórí ibi tó o kù díẹ̀ káàtó sí, ìyẹn á jẹ́ kí agbára rẹ pin kò sì ní jẹ́ kó o lè gbìyànjú láti tẹ̀ síwájú. Nígbà kan báyìí táwọn kan ń ta ko àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ohun tó fi dá wọn lóhùn ni pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 10:10; 11:6) Bákan náà, o lè nígboyà tó o bá ń wo apá ibi tó o dáa sí tó o sì ń bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ lápá ibi tó o kù sí. Ó dájú pé Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran àwọn ará àtijọ́ lọ́wọ́.—Ẹ́kísódù 4:10.
Bó o tún ṣe lè fira ẹ lọ́kàn balẹ̀ ni pé kó o má máa lé ohun tó o mọ̀ pé o kò lè bá. Kó o sì mọ̀ pé ó ní ibi tágbára rẹ mọ. Bákan náà, má máa fara ẹ wé àwọn ẹlòmíì láìrí bí nǹkan ṣe rí dáadáa. Nínú Gálátíà 6:4, Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn àtàtà yìí pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”
Bó O Ṣe Lè Dẹwọ́ Ìbínú
Kíkóra ẹni níjàánu bọ́ràn ìbínú bá délẹ̀ tún lè jẹ́ ìṣòro líle míì. Bíi ti Kate tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè yẹn, ìbínú lè mú káwọn ọ̀dọ́ ṣe ohun kan tàbí kí wọ́n sọ ohun kan tó lè bí ẹlòmíì nínú tàbí tó lè dá wàhálà sílẹ̀.
Lóòótọ́, kò sẹ́ni tó rínú tí kì í bí. Ṣùgbọ́n má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ Kéènì, apààyàn àkọ́kọ́. Nígbà tí “ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi,” Ọlọ́run kì í nílọ̀ pé inú burúkú tó ń bí i yẹn lè sún un débi tó ti máa dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Ó béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Ìwọ yóò ha sì kápá [ẹ̀ṣẹ̀] bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 4:5-7) Kéènì ò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ìwọ ní tìẹ lè kápá ìbínú rẹ, tó ò sì ní dẹ́ṣẹ̀!
Bá a sọ ọ́ lọ sọ ọ́ bọ̀, orí pé kó o darí èrò ọkàn ẹ la máa fàbọ̀ sí. Nínú Òwe 19:11, Bíbélì sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Nígbà tẹ́nì kan bá ṣe nǹkan tó bí ẹ nínú, gbìyànjú láti lóye ìdí tó fi ṣe nǹkan tó ṣe yẹn. Ṣé onítọ̀hún mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ tọ́ ẹ níjà ni? Ṣé kò lè jẹ́ pé ṣe ló kàn ń hùwà láìronú jinlẹ̀ tàbí láìmọ̀ pé ohun tóun ń ṣe ò dáa? Tó o bá ń fara mọ́ àṣìṣe àwọn ẹlòmíì, ò ń fi hàn pé o mọ àánú Ọlọ́run nìyẹn, ìyẹn á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dẹwọ́ ìbínú ẹ.
Ká tiẹ̀ ní ohun tó ṣe tó nǹkan tó lè múnú bí èèyàn ńkọ́? Rántí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, pé: ‘Fi ìrunú hàn, síbẹ̀ má ṣẹ̀.’ (Éfésù 4:26) Tó bá pọn dandan bá ẹni yẹn sọ ọ́. (Mátíù 5:23, 24) Ó sì lè jẹ́ pé ohun tá á dáa jù ni pé kó o gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, kó o yé bínú, kó o sì máa bá ìgbésí ayé ẹ lọ.
Tún wá wò ó o, irú àwọn ọ̀rẹ́ tó o ní lè kọ́ ẹ bí wàá ṣe máa ṣe tínú bá ń bí ẹ. Ó bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé, kí ìwọ má bàa mọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ dunjú, kí o sì gba ìdẹkùn fún ọkàn rẹ dájúdájú.”—Òwe 22:24, 25.
Tó o bá ń bá àwọn tó ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu nígbà tí inú bá ń bí wọn rìn, wàá lè mọ bí wàá ṣe máa kó ara ẹ níjàánu. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sì wà káàkiri àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn àwọn tí wọ́n dàgbà dénú dáadáa, tí wọ́n jù ẹ́ lọ tí wọ́n sì ní ìrírí jù ẹ́ lọ. Sún mọ́ wọn dáadáa. Máa kíyèsí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tí wọ́n bá níṣòro. Wọ́n sì tún lè fún ẹ ní “ìdarí jíjáfáfá” tí ìṣòro bá dé. (Òwe 24:6) Jacob, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tó wúwo lọ́wọ́ mi lọ̀rẹ́ tó dàgbà dénú tó lè máa rán mi létí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí mo bá rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi láìka bí ọkàn mi ṣe máa ń mì sí, mo máa ń rí i pé ọkàn mi máa ń balẹ̀ mo sì máa ń fara balẹ̀.”
Àwọn Nǹkan Míì Tó O Lè Ṣe
Ìwé kan tó gbajúmọ̀ lórí ọ̀rọ̀ eré ìdárayá sọ pé: “Àìmọye ìwádìí táwọn èèyàn ti ṣe ló fi hàn pé àwọn èròja kan wà nínú ara tó máa ń sọ bí inú ẹni ṣe máa dùn tó tàbí bó ṣe máa bà jẹ́ tó. Àmọ́ ìyẹn sinmi lórí béèyàn bá ṣe ń lo ara ẹ̀ sí. Kódà, àwọn èròjà inú ara yìí lè pọ̀ sí i, wọ́n sì lè dín kù sí i nígbà míì.” Láìsí àníàní, eré ìmárale lóore tó ń ṣe fún ara. Bíbélì sọ fún wa pé: “Èrè díẹ̀ wà nínú ṣíṣeré ìmárale.” (1 Tímótì 4:8, Today’s English Version) Ìwọ náà ò ṣe kúkú máa wá eré ìmáralé kan tó mọ níwọ̀n ṣe kó o sì máa ṣe é wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́? Ó lè nípa lórí irú èrò tá máa sọ sí ẹ lọ́kàn. Bákan náà tó o bá ń jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, á ṣe ẹ́ láǹfààní.
Tún kíyè sí eré ìnàjú àti orin tó ò ń gbọ́. Ìwádìí tí wọ́n tẹ̀ jáde sínú ìwé kan tí wọ́n pè ní The Harvard Mental Health Letter sọ pé: “Ó dà bíi pé wíwòran ìwà ipá . . . lè mú kéèyàn máa bínú kó sì máa ṣe gànràngànràn. . . . Àwọn tó ń wo ìwà ipá lórí fídíò sábà máa ń lèrò jàgídíjàgan lọ́kàn, ẹ̀jẹ̀ wọn sì máa ń ru.” Torí náà tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí wàá máa tẹ́tí sí tàbí ohun tó o fẹ́ wò, fọgbọ́n hùwà.—Sáàmù 1:1-3; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
Ọ̀nà pàtàkì tó o fi lè mọ bí wàá ṣe máa fira ẹ lọ́kàn balẹ̀ bí ohun kan bá dà ọ́ lọ́kàn rú ni pé kó o fi Ẹlẹ́dàá rẹ ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ó sọ pé kí olúkúlùkù wa máa bá òun sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà, ká sọ gbogbo ohun tó bá wà lọ́kàn wà àti bí nǹkan ṣe rí lára wa fóun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun . . . kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.” Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ní okun inú tí wàá fi lè gbé ohunkóhun tó bá ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ nínú ìgbésí ayé ẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:6, 7, 13.
Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Malika sọ pé: “Mo ti rí i pé mi ò gbọ́dọ̀ fàdúrà ṣeré. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Jèhófà ò pa mí tì jẹ́ kí n lè máa fira mi lọ́kàn balẹ̀ kí n sì lè máa kó ara mi níjàánu.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ìwọ náà á lè mọ bó ò ṣe ní máa fàyè gba èrò òdì.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Ohun kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti darí bọ́ràn ṣe máa ń rí lára ẹ ni pé kó o máa ṣọ́ bó o ṣe ń ronú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Tó o bá ń bá àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ rìn, wàá mọ bó ò ṣe ní fàyè gba èrò òdì