Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìbọ̀rìṣà Àwọn Adúláwọ̀ Ṣe Wọnú Ẹ̀sìn Kátólíìkì

Bí Ìbọ̀rìṣà Àwọn Adúláwọ̀ Ṣe Wọnú Ẹ̀sìn Kátólíìkì

Bí Ìbọ̀rìṣà Àwọn Adúláwọ̀ Ṣe Wọnú Ẹ̀sìn Kátólíìkì

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní Brazil

NÍ ÌLÚ Salvador, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Bahia, lórílẹ̀-èdè Brazil, wọ́n máa ń ṣayẹyẹ kan tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ lásìkò tí wọ́n bá ń ṣọdún tuntun. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn obìnrin á tò síwájú omilẹgbẹ èrò tó ń wọ́ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti Bonfim, níbi tí wọ́n á ti lọ fi omi onílọ́fíńdà fọ àtẹ̀gùn ṣọ́ọ̀ṣì náà. Òòṣà Ńlá, táwọn Adúláwọ̀ mọ̀ sí ọlọ́run ìṣẹ̀dáyé ni wọ́n ń fi ayẹyẹ yìí júbà.

Àwọn tó máa ń lọ wòran ayẹyẹ yìí máa ń tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn. Gbogbo wọn lá á máa jó, tí wọ́n á máa yọ̀ láàárín ìgboro bí wọ́n ṣe ń lu oríṣiríṣi ṣaworo ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ó ti tó àádọ́talérúgba ọdún tí wọ́n ti ń ṣayẹyẹ yìí, ó sì jẹ́ àpẹẹrẹ kan pàtàkì lára àmúlùmálà ìgbàgbọ́ tó kún inú Ẹ̀sìn Kátólíìkì lórílẹ̀-èdè Brazil. Ó ju àádọ́rin mílíọ̀nù ọmọ ilẹ̀ Brazil tí wọ́n sọ pé ó ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀sìn Candomblé, Umbanda, Ṣàngó, àtàwọn ẹ̀sìn míì táwọn Adúláwọ̀ mú wọ orílẹ̀-èdè náà. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì.

Kí ló fa àmúlùmálà ìgbàgbọ́ yìí? Ojú wo làwọn Kátólíìkì fi ń wò ó? Ṣó yẹ kéèyàn lọ́wọ́ sí àmúlùmálà ẹ̀sìn àbí ó yẹ kéèyàn kọ̀ ọ́?

‘Ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ sí Dídi Onígbàgbọ́ Òdodo’

Ìṣirò ò dọ́gba lórí iye èèyàn tí wọ́n mú lẹ́rú láàárín ọdún 1540 sí ọdún 1888, tí wọ́n fòpin sí àṣà mímú èèyàn lẹ́rú. Síbẹ̀, á ju mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Adúláwọ̀ tí wọ́n kó re oko ẹrú lórílẹ̀-èdè Brazil látinú àwọn ẹ̀yà bíi Yorùbá, Bantu, àtàwọn ẹ̀yà míì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú látijọ́ ló da ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àwọn Adúláwọ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì lórílẹ̀-èdè Brazil.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kátólíìkì fi dandan lé e pé gbogbo àwọn ẹrú wọ̀nyẹn ló gbọ́dọ̀ di Kátólíìkì, síbẹ̀ wọ́n fọwọ́ sí dída àwọn ààtò ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àwọn Adúláwọ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì. Òpìtàn Roger Bastide sọ pé àwọn míṣọ́nnárì ọmọ ẹgbẹ́ Jesuit gbà pé ṣe ló yẹ káwọn rọra tu àwọn ọmọ Áfíríkà lójú bíi tàwọn ọmọdé kí wọ́n lè gba ẹ̀sìn Kátólíìkì. Wọ́n ní orin àti ijó ló yẹ káwọn fi mú àwọn ará Áfíríkà wọnú ẹ̀sìn náà káwọn má sì paná ìfẹ́ tí wọ́n ní fún oyè jíjẹ àti gbígbé orúkọ oyè lérí. Bastide fi kún un pé wọ́n ní kò yẹ káwọn fipá gba àṣà àbáláyé àwọn Adúláwọ̀ lọ́wọ́ wọn, dípò ìyẹn wọ́n ní ńṣe ló yẹ káwọn yẹ àṣà náà wò dáadáa káwọn sì fi èyí táwọn bá fọwọ́ sí níbẹ̀ ṣe ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ sí sísọ wọ́n di onígbàgbọ́ òdodo.

Oríṣiríṣi ẹ̀sìn àwọn ará Áfíríkà tí wọ́n yí padà ni wọ́n wá mú wọnú ẹ̀sìn “Kristẹni.” Irú bẹ́ẹ̀ ni ti ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe fún Benedict, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “Ẹni Mímọ́” Kátólíìkì àti Wúńdíá Onílẹ̀kẹ̀ Àdúrà. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, lọ́jọ́ tí wọ́n bá ń ṣàjọ̀dún ẹgbẹ́ Benedict “Mímọ́,” àwọn ọmọ irú ẹgbẹ́ báwọ̀nyẹn máa ń yan ọba àti ayaba láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn. Lára àṣà bí wọ́n ṣe máa ń yan ọba tó máa rọ́pò ọba nílẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti káṣà yìí.

“Àwọn Ẹni Mímọ́” Ni Wọ́n Ń Bọ àbí Àwọn Òrìṣà?

Bí ọ̀pọ̀ alárinà ṣe wà láàárín Ọlọ́run àti ènìyàn nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì náà ló wà nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àwọn Adúláwọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Yorùbá ní ìgbàgbọ́ nínú òrìṣà. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé àwọn jagunjagun àtàwọn ọba tí wọ́n jẹ́ irúnmọlẹ̀ làwọn òrìṣà yìí. Wọ́n láwọn irúnmọlẹ̀ yìí lágbára lórí àrá, omi àtàwọn nǹkan míì, àti pé àwọn ni alárinà láàárín ọmọnìyàn àti olódùmarè, ìyẹn Ọlọ́run. Àwọn Kátólíìkì gbà pé “àwọn ẹni mímọ́” ló máa ń gbẹnu sọ fáwọn èèyàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bí wọ́n bá sì ń fẹ́ ààbò lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí, ó ní “ẹni mímọ́” tí wọ́n máa ké pè.

Dípò káwọn ẹrú wọ̀nyí pa àwọn òrìṣà wọn tì, ọ̀pọ̀ nínú wọn wulẹ̀ ń fi jíjúbà “àwọn ẹni mímọ” tí ìtàn wọn jọ tàwọn òrìṣà náà ṣe bojúbojú ni, òrìṣà wọn gan-an ni wọ́n ń bọ. Bó ṣe di pé wọ́n fi Ògún, táwọn Yorùbá mọ̀ sí ọlọ́run ogun wé Anthony tàbí George nìyí, ìyẹn “àwọn ẹni mímọ́” Kátólíìkì tí wọ́n jẹ́ jagunjagun àti akọni nínú ìsìn Kirisẹ́ńdọ́mù nígbà ayé wọn.

Bákan náà, Yemọja tí wọ́n kà sí ìyá gbogbo òrìṣà àti olúwẹri àwọn òrìṣà inú odò ni wọ́n sọ pé ó bá oríṣiríṣi àǹjọ̀ọ̀nú Màríà Wúńdíá tí wọ́n ti rí mu. Olúwa Bonfim, “ẹni mímọ́” tó gbayì jù ní ìlú Salvador ni wọ́n fi sípò Òòṣà Ńlá, tó jẹ́ àgbà òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá. Títí dòní nígbà tí wọ́n bá lọ ń fọ àtẹ̀gùn ṣọ́ọ̀ṣì lọ́dọọdún, wọ́n ṣì máa ń ṣayẹyẹ òrìṣà yìí, lórúkọ Olúwa Bonfim. a

Olórí ẹ̀sìn Kátólíìkì kan láti ìlú Salvador sọ pé: “Ọkàn kan làwọn ará ibí yìí fi gba Jésù, àwọn ẹni mímọ́ àtàwọn òrìṣà gbọ́. Wọn ò sì gbé ọ̀kan ga ju èkejì lọ.” Ọmọ ilẹ̀ Brazil kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìran èèyàn wá fi kún un pé: “Ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn ń tìdí ẹ̀sìn kan dédìí òmíràn. Bí wọ́n bá ṣe ń kúrò níbi ìsìn Máàsì ní ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ni wọ́n á tún forí lé ilé ìjọsìn candomblé [ọkàn lára ẹ̀sìn àwọn Adúláwọ̀].”

Ọ̀ràn ẹlẹgẹ́ ni bí wọ́n ṣe ń da ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àwọn Adúláwọ̀ yìí o. Lucas Moreira, tó jẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀ nínú Àjọ Bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Kátólíìkì ní Orílẹ̀-Èdè Brazil, la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ pé: “Ṣe ló yẹ kí olúkúlùkù gbájú mọ́ ẹ̀sìn tiẹ̀, èwo ni ti àmúlùmálà?” Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì míì sọ pé: “Àmúlúmálà ẹ̀sìn ti deegun ẹja sí ṣọ́ọ̀sì lọ́rùn.”

Ọ̀rọ̀ ti wá di méjì báyìí. Àwọn aṣáájú ìjọ tó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ìpìlẹ̀ ò fẹ́ fàyè gba ohun tí wọ́n kà sí àṣà kèfèrí àti ìjọsìn ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀wẹ̀, àwọn míì sọ pé ó yẹ kí wọ́n fi ìgbàgbọ́ àti ijó àwọn Adúláwọ̀ kún ààtò ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Kí Ni Jésù Sọ?

Jésù Kristi tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ ìsìn Kristẹni wàásù fáwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn tí wọ́n sì jẹ́ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́ kò bá èèyàn fi ọ̀ràn ìjọsìn dọ́rẹ̀ẹ́, ohun tó sọ ni pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Láfikún sí i, Jésu ṣàlàyé pé nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì ni Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Bàbá gbà ń fi òtítọ́ hàn wá.—Jòhánù 17:17.

Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa kọ́ ‘àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè láti máa pa gbogbo ohun tó pa láṣẹ mọ́. (Mátíù 28:19, 20) Kò fìgbà kan sọ fún wọn pé kí wọ́n fi kún ẹ̀kọ́ òun tàbí kí wọ́n yọ kúrò nínú ẹ̀ kó bàa lè wu àwọn èèyàn tó ní oríṣiríṣi àṣà àti ìgbàgbọ́. Nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, àwọn kan gbìyànjú láti mú àwọn èrò àtì àṣà látinú àwọn ìsìn míì wọnú ìsìn Kristẹni. Àmọ́, wọn ò gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láyè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, . . . [Ọlọ́run] yóò sì gbà yín wọlé.”—2 Kọ́ríńtì 6:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Dicionário de Cultos Afro-Brasileiros (Àtúpalẹ̀ Àwọn Ìsìn Áfíríkà Tó Wọ Orílẹ̀-Èdè Brazil) sọ pé bí wọ́n ṣe ń fọ àwọn àtẹ̀gùn ṣọ́ọ̀ṣì Bonfim yìí jọ ààtò kan táwọn Yorùbá máa ń ṣe. Ìwé míì tún wá fi kún un pé ààtò yìí máa ń wáyé nígbà tí wọ́n bá ń fọ àwẹ̀ (orù ńlá) Òòṣà Ńlá.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn yèyé òrìṣà nínú ẹ̀sìn tó tilẹ̀ Adúláwọ̀ wọ ilẹ̀ Brazil rèé tí wọ́n ń fọ àtẹ̀gùn ṣọ́ọ̀ṣì

Àwọn èrò tó pé jọ síbi àtẹ̀gùn ṣọ́ọ̀ṣì Bonfim, lórílẹ̀-èdè Brazil

[Àwọn Credit Line]

Ti òkè: De: A Tarde—Wilson da Rocha Besnosik; ti ìsàlẹ̀: De: A Tarde—Antônio Queirós