Mo Dúpẹ́ Pé Ìrìn Mi Ò Já Sásán
Mo Dúpẹ́ Pé Ìrìn Mi Ò Já Sásán
GẸ́GẸ́ BÍ CLAIRE VAVY ṢE SỌ Ọ́
ÒKÈ àti igbó kìjikìji pọ̀ ní erékùṣù Madagascar, tó fi nǹkan bí irínwó kìlómítà jìnnà sí orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì tó wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Betoko II tó wà ní ìlà oòrùn erékùṣù yẹn ni wọ́n bí mi sí. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ọdún 1987, mo kúrò níbẹ̀ láti lọ kàwé ní ìlú Mahanoro tó wà létíkun.
Ọ̀dọ̀ bùrọ̀dá mi Celestin, tó wà ní Mahanoro, ni mò ń gbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn. Lọ́dún méjì lẹ́yìn náà ni mo di Ẹlẹ́rìí. Mo pinnu pé màá sin Jèhófà Ọlọ́run débi tí mo bá lágbára dé.
Bí Mo Ṣe Sapá Kí Ọwọ́ Mi Lè Tẹ Ohun Tí Mò Ń Lé
Ọ̀kan lára ohun tó wà lórí ẹ̀mí mi ni pé kí n ran àwọn ará ilé mi tó wà lábúlé wa ní Betoko II lọ́wọ́, mo sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé ìgbà tá a bá gbaludé ní iléèwé nìkan ni mo máa ń lè lọ síbẹ̀. Ọ̀nà ibẹ̀ jìn tó ọgọ́rùn-ún kìlómítà síbi tá a wà, kì í ṣe ibi téèyàn lè kù gìrì lọ. Kò sí mọ́tò kankan tó lè gbé èèyàn kọjá ogójì kìlómítà àkọ́kọ́. Ọgọ́ta kìlómítà tó sì kù kéèyàn fi débẹ̀ tóóró débi pé ẹsẹ̀ nìkan lèèyàn lè fi rìn ín, orí òkè sì tún ni.
Ọ̀pọ̀ òkè gogoro ni mo máa ń gùn, àwọn apá ibì kan lójú ọ̀nà ò sì ju gbórógbóró báyìí lọ. Tí mo bá kẹ́sẹ̀ sọ́nà láti ìdájí, tí mo sì rìn títí di ọjọ́rọ̀, ibi tí màá rìn lè tó ogójì kìlómítà lójúmọ́. Ẹrù mi máa ń wúwo gan-an nítorí pé màá di ẹrù sórí, dì sẹ́yìn, màá sì fa àwọn yòókù lọ́wọ́. Ohun tí mo sì máa ń dì lẹ́rù ò ju àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo máa ń pín fáwọn ará ilé mi àtàwọn yòókù tó bá nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìwé náà. Lójú ọ̀nà yẹn, ìgbà kan wà tí wọ́n máa ń pè mí ní “ìyá ẹlẹ́rù.”
Pẹ̀lú gbogbo ìtara tí mò ń lò yìí, àwọn ẹbí mi ò kọ́kọ́ fẹ́ fetí sí mi nígbà tí mò ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà yìí. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yí padà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè débi pé nígbà míì, ó máa ń tó aago méjì òru ká tó sùn.
Mi Ò Lè Gbàgbé Ìgbà Kan Báyìí Tí Mo Lọ Sílé
Ní December 24, ọdún 1990, mo lọ lo ọlidé lábúlé wa ní Betoko II. Inú àwọn
ará ilé wa dùn nígbà tí wọ́n rí mi, wọ́n rò pé mo wá bá àwọn ṣọdún Kérésì ni. Àmọ́, ó dùn wọ́n nígbà tí mo sọ fún wọn pé mi ò ní bá wọn dá sí ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì. Wọn ò mọ bí wọ́n á ṣe ṣàlàyé fáwọn yòókù lábúlé nítorí pé bí ọmọ ìyá làwọn ará abúlé wa máa ń ṣe. Bó ṣe di pé mo ní láti lọ fẹnu ara mi ṣàlàyé fáwọn ará abúlé nìyẹn o. Ṣùgbọ́n ọ̀nà wo ni mo fẹ́ gbé e gbà?Kò tiẹ̀ yé mi, pàápàá jù lọ nítorí pé mo ṣì kéré gan-an. Mò ń rò ó bóyá ó máa bójú mu kí n lọ ṣàlàyé fáwọn ará abúlé nígbà tí wọ́n bá kóra jọ sínú ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ kejì. Mo fi àkókò gígùn gbàdúrà sí Jèhófà taratara lórí ọ̀rọ̀ yìí pé kó kọ́ mi lóhun tí màá ṣe. Lẹ́yìn náà mo béèrè lọ́wọ́ bùrọ̀dá mi Paul, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì náà pé, “Ṣé ẹ rò pé kò ní dáa kí n ṣàlàyé ìdí tí n kì í fi í ṣe Kérésì fáwọn tó máa wá sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́la?” Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn tó kù, wọ́n sì gbà fún mi.
Lọ́jọ́ kejì wọ́n ní kẹ́nì kan lọ pè mí wá nígbà tí wọ́n parí ìsìn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mélòó kan dání. Lẹ́yìn tí mo kí wọn, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún ipa tí wọ́n kó nínú bí mo ṣe dẹni tó ti kékeré fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì. Mo ṣàlàyé fún wọn pé nígbà tí mo dé ìlú Mahanoro, mo tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Mo sọ pé ọ̀pọ̀ òtítọ́ tí wọn ò tíì kọ́ wa rí ni mo rí nínú Bíbélì.
Mo lo àǹfààní náà láti fi Bíbélì ṣàlàyé fún wọn nípa ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé (Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4), ìdí tó fi jẹ́ pé àwọn olóòótọ́ díẹ̀ láti ayé ló máa lọ sọ́run (Jòhánù 14:2, 3; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3), àti ohun tí Bíbélì kọ́ wa pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, bí ẹni pé wọ́n ń sùn ni nítorí náà wọn ò sí níbi tí wọ́n ti ń jìyà (Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 11:11-14, 38-44). Mo tún fi hàn wọ́n nínú Bíbélì pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò ṣe Kérésìmesì, àti pé ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀.
Nígbà tí mo parí ọ̀rọ̀ mi, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni mo sọ. Àwọn kan tiẹ̀ bi mí ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè míì. Lẹ́yìn náà ni mo wá fi àwọn ìwé tí mo kó dání hàn wọ́n, mo sì ṣàlàyé fún wọn pé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn ìwé náà àti pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe wọ́n. Mo fi kún un pé bí ẹni kẹ́ni nínú wọn bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì màá ràn án lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gbà lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn.
Mo Bá Ẹnì Kan Tí Mi Ò Rò Tì Pàdé
Obìnrin kan tí mi ò rí rí dédé wá bá mi ó sì sọ fún mi pé: “Àbúrò mi obìnrin tó ń gbé lábúlé míì wà lára yín.” Ó yà mí lẹ́nu, mo ní, “Lábúlé ibo?”
Ó dáhùn pé, “Lábúlé Andranomafana.” Abúlé yẹn fi bí ọgbọ̀n kìlómítà jìnnà sí abúlé Betoko II.
Mo sọ fún obìnrin náà pé ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀sìn míì ni àbúrò rẹ̀ ń ṣe nítorí pé gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí tá a wà lágbègbè yẹn mọ ara wa. Àmọ́, obìnrin náà tẹnu mọ́ ọn pé, àbúrò òun ti kọ́ òun láwọn nǹkan kan náà tí mo ṣàlàyé nígbà tí mò ń sọ̀rọ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Mo béèrè orúkọ àbúrò obìnrin yìí àti ibi tó ń gbé, ńṣe ló sì dà bíi pé kí n kọrí sọ́nà abúlé náà lójú ẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n, màmá mi ní kí n dúró bí ọjọ́ kan kí n tó kẹ́sẹ̀ sọ́nà torí pé ìrìn kékeré kọ́ ni màá rìn débẹ̀. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, èmi àti bùrọ̀dá mi Charles forí lé ọ̀nà abúlé Andranomafana.
Bá a ṣe débẹ̀ báyìí, a béèrè lọ́wọ́ àwọn ará abúlé pé: “Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níbí?” Ọkàn mi bà jẹ́ nígbà tí wọ́n dáhùn pé: “Àwọn
ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, àwọn Gba-Jésù àti àgbáríjọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló wà lábúlé wa níbí.”Àfi bí obìnrin kan ṣe sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ̀ ń wá, ó ní láti jẹ́ pé Marceline àtàwọn ará ilé ẹ̀ lẹ̀ ń wá yẹn.” Orúkọ ẹni tí wọ́n ní kí n béèrè gan-an nìyẹn!
Ẹnì kan lọ bá mi pe Marceline wá. Kò pẹ́ tó fi dé ṣùgbọ́n ó dà bíi pé ẹ̀rù ń bà á díẹ̀díẹ̀. Gbogbo àwọn ará abúlé pé lé wa lórí, torí wọ́n rò pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wá wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹ̀ ni wá. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni mo wá rí i pé ohun tó ń mú un ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ti ṣenúnibíni sí òun àtàwọn ará ilé ẹ̀ lábúlé yẹn nítorí àwọn ará abúlé sọ pé aládàmọ̀dì ẹ̀sìn ni wọ́n.
Marceline rọra mú wa kúrò láàárín èrò lọ síbi tá a ti lè sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo bí i bóyá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ó sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Ló bá lọ mú ẹ̀dà kan ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye wá, àtàwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tọ́jọ́ wọn ti pẹ́. Ìwé tó lọ mú wá yìí làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀. Gbogbo wọn ti gbó táútáú wọ́n sì ti ya. Mo béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Ìwé ìròyìn wo lẹ kà lọ́jọ́ Sunday tó kọjá?”
Ó fèsì pé: “Gbogbo èyí tá a ní ò jù báyìí lọ, àwọn náà la sì máa ń kà lákàtúnkà.” Ìgbà yẹn ni mo tó wá sọ fún Marceline pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi náà. Inú ẹ̀ dún dẹ́yìn! Nígbà tí mo sọ fún un pé mo fẹ́ rí arákùnrin tó ń darí ìpàdé wọn, ó sọ fún mi pé ọ̀nà ẹ̀ jìn síbi tá a wà.
Mo Tún Pàdé Ẹlòmíì Tí Mi Ò Rò Tì
Lọ́jọ́ kejì, èmi àti Marceline bọ́ sójú ọ̀nà, ó dilé ọkùnrin náà. Nígbà tá a débẹ̀, ó lanu ó fẹ́ẹ̀ má lè pa á dé bó ṣe rí wa, inú ẹ̀ dùn gan-an ni. Ẹlẹ́rìí ni lóòótọ́, ìlú Toamasina tó wà létíkun ní ìlà oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè yìí tó fi bí igba kìlómítà jìnnà ló sì ti kó wá síbẹ̀ yẹn. Nígbà tíṣẹ́ ṣàdédé bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn ló di dandan pé kóun àti ìdílé ẹ̀ padà sábúlé yìí. Bó ṣe padà síbẹ̀, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí wàásù, tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ń darí ìpàdé.
Inú arákùnrin yìí àtàwọn ará ilé ẹ̀ dùn gan-an ni nígbà tí wọ́n rí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, tí mo mú dání. Mo tún fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye hàn wọ́n, ìwé yìí là ń lò nígbà yẹn láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa rí i nìyẹn. Nígbà tó di ọjọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, mo padà wá bá wọn ṣèpàdé lábúlé Andranomafana. Mo gbà
wọ́n níyànjú pé kí wọ́n kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Antananarivo tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè Madagascar nítorí pé wọn ò mọ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì pé àwọn Ẹlẹ́rìí wà níbẹ̀.Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù January ọdún 1991, ó fẹ́ẹ̀ máà sí oṣù tí mi ò rìnrìn àjò láti ìlú Mahanoro lọ sí abúlé Andranomafana, tí màá lọ máa kó àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé àtàwọn ìtẹ̀jáde mìíràn fún wọn. Ìrìn-àjò ọ̀tàlénígba [260] kìlómítà ni ibẹ̀ yẹn ní tàlọtàbọ̀, ó sì ju kìlómítà mẹ́tàdínlọ́gọ́sàn-án [177] lọ tí mo máa ń fẹsẹ̀ rìn nínú ẹ̀. Bí mo bá ṣe ń pọ́n òkè ni màá máa sọ̀ kalẹ̀ lójú ọ̀nà tó rí gbágun gbàgun, nígbà míì nínú igbó kìjikìji. Tí òjò bá sì fi rọ̀, ó di kí n máa dura rìn nínú ẹrọ̀fọ̀ tó lè yọ èèyàn ṣubú.
Ńṣe lẹrù mi máa ń wúwo sí i bí mo bá ṣe ń padà lọ síbẹ̀, ìdí ni pé ṣe làwọn tó nílò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n, ohun tí kì í jẹ́ kí n mọ̀ ọ́n lára bó ṣe máa ń rẹ̀ mí àti bára ṣe máa ń ro mí nígbà tí mo bá padà délé ni ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí mo máa ń rí. Inú mi máa ń dùn nígbà tí mo bá rí i báwọn ará wa yìí ṣe máa ń fi tayọ̀tayọ̀ gba àwọn ìtẹ̀jáde tuntun àti bí wọ́n ṣe máa ń yọ̀ látàrí òtítọ́ tí wọ́n ń kọ́ látinú Bíbélì!
Bí Mo Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
Ní September 1, ọdún 1992, wọ́n sọ mí di ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn oníwàásù alákòókò kíkún láàárín àwa Ẹlẹ́rìí. Ìlú Mahanoro ni mo ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ṣùgbọ́n mo máa ń kọ lẹ́tà sáwọn ẹbí mi tí wọ́n wà lábúlé Betoko II. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa kíkọ lẹ́tà, wọ́n sì bi mí bóyá màá wá sábúlé láti wá ran àwọn lọ́wọ́. Mo fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣùgbọ́n mo fẹ́ rí i dájú pé lóòótọ́ ni wọ́n ti pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Nítorí náà mo dúró díẹ̀ sí ìlú Mahanoro láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi lọ.
Lápá ìparí ọdún 1993, mo láǹfààní láti lọ sí ìlú Antananarivo fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ méjì tí wọ́n ṣe fáwọn aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí n kọ̀wé pé mo fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, èyí tó lè gba pé kí wọ́n gbé mi lọ sìn níbikíbi lórílẹ̀-èdè Madagascar. Àmọ́, mi ò fẹ́ ṣe é torí pé mo fẹ́ ran àwọn ìbátan mi lọ́wọ́ lábúlé Betoko II, ìdí ni pé ibi tí wọ́n wà jìnnà sí ìjọ tó sún mọ́ tòsí. Torí náà mo pinnu láti padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi ní ìlú Mahanoro.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí alábòójútó arìnrìn-àjò wa bẹ̀ wá wò, mo béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ nípa tàwọn ẹbí mi tí mo fẹ́ padà lọ ràn lọ́wọ́. Lákòókò yẹn, wọ́n ti dá ìjọ kan sílẹ̀ ní Andranomafana. Alábòójútó arìnrìn-àjò náà sì dá a lábàá pé kí n lọ síbẹ̀ kí n lọ ran àwọn ará ìjọ náà lọ́wọ́ kí n sì fi abúlé Betoko II ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù. Ní September 1, ọdún 1994 ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tó sọ yẹn. Lóṣù kan náà yẹn ni bùrọ̀dá mi Paul tó ti di olùkọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì wọn tẹ̀ lé mi lọ sí àpéjọ àgbègbè. Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn tó ń wàásù lábúlé Andranomafana fi pé ọgbọ̀n, táwọn tó ń wá sípàdé níbẹ̀ lọ́jọọjọ́ Sunday fi ń tó márùndínláàádọ́rin.
Mo Ṣì Ń Rìnrìn Tó Jìn Lọ Sáwọn Abúlé Títí Di Báyìí
Láìpẹ́ sígbà tí mo padà sí abúlé Betoko II, àwọn ọmọ ìyá mi mẹ́rin ti dẹni tó lè máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ sígbà náà tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn tí mo padà sí abúlé Betoko II, mo máa ń lọ sí ìlú Anosibe An’ala déédéé láti lọ kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ìwé ìròyìn, ìyẹn sì tó ìrìn ọgọ́rùn-ún kìlómítà ní tàlọtàbọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí gan-an lẹ́yìn ìrìn yìí, bí mo ṣe máa ń láyọ̀ nígbà tí mo bá rí báwọn èèyàn ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí lágbègbè yẹn jẹ́ kí n gbà pé ìrìn mi ò já sásán.
Lónìí, ìjọ kan ti wà lábúlé Betoko II, àwọn tó ń lọ sípàdé níbẹ̀ lọ́jọọjọ́ Sunday sì tó márùndínláàádọ́ta. Níbẹ̀, màmá mi àti gbogbo àwọn ọmọ ìyá mi ló ti di Ẹlẹ́rìí báyìí àwọn tó pọ̀ jù nínú wọn ló sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ni àbúrò mi kan tó jẹ́ ọkùnrin. Ní November 1, ọdún 2001, wọ́n sọ èmi náà di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì gbé mi lọ sí abúlé Antanambao-Manampotsy. Ṣùgbọ́n inú dídùn ni mo fi kúrò lábúlé Betoko II.
Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1987, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní erékùṣù Madagascar ò tó ẹgbẹ̀rùn mẹ́ta. Ṣùgbọ́n báyìí, a ti ju ẹgbẹ̀rùn mẹ́rìnlá lọ. Bíi ti ọ̀pọ̀ nínú wọn, inú mi dùn pé mo láǹfààní láti fi agbára mi rìn débi tí mo fi lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fìbùkún sórí ìsapá mi láti ṣe bẹ́ẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo máa ń gbé ẹrù tó wúwo, màá di ẹrù sórí màá sì fa ìyókù lọ́wọ́ tí mo bá ń rìnrìn àjò ọgọ́ta kìlómítà lọ sábúlé wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bùrọ̀dá mi Paul
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bùrọ̀dá mi Charles
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Èmi àtàwọn ará ilé mi kan rèé. Gbogbo wọn ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí