Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tòmátì Èlò Ọbẹ̀ Tí Ìwúlò Ẹ̀ Pọ̀

Tòmátì Èlò Ọbẹ̀ Tí Ìwúlò Ẹ̀ Pọ̀

Tòmátì Èlò Ọbẹ̀ Tí Ìwúlò Ẹ̀ Pọ̀

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

NÍGBÀ tí ìyáálé ilé kan ní Ítálì ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Mi ò lè gbọ́únjẹ láìsí tòmátì.” Ohun tí àìmọye àwọn ọlọ́wọ́ ṣíbí ń sọ káàkiri orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé nìyẹn. Dájúdájú, ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri ayé ló máa ń fi tòmátì dá onírúurú àrà nínú oúnjẹ. Òun làwọn àgbẹ̀ alárojẹ máa ń gbìn jù. Àmọ́ kí ni ká pè é, ṣé èso ni àbí ewébẹ̀?

Bá a bá fojú àwọn irúgbìn tó máa ń so bíi tiẹ̀ wò ó, èso la ó pè é nítorí pé kóró wà nínú rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èlò ọbẹ̀ ni, ojú ewébẹ̀ làwọn kan fi ń wò ó. Ohun tó máa ń mú oúnjẹ dùn ni, ìtàn nípa bó ṣe di oúnjẹ sì fani mọ́ra gan-an.

Ìtàn Tó Fani Mọ́ra

Àwọn ọmọ onílẹ̀ tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò máa ń gbin tòmátì fún jíjẹ. Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn, àwọn ará Sípéènì ṣẹ́gun àwọn ará Mẹ́síkò, nígbà tí wọ́n sì ń darí lọ sí orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n mú lára tòmátì náà dání. Àwọn Nahuatl tí wọ́n jẹ́ ọmọ onílẹ̀, tí wọ́n ń gbé ní Mẹ́síkò, máa ń pè é ní tomatl. Àwọn ará Sípéènì yá èdè náà lò, wọ́n ń pè é ní tomate. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí jadùn tòmátì láwọn ìlú tó jẹ́ tàwọn ará orílẹ̀-èdè Sípéènì ní Ítálì, Àríwá Áfíríkà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn.

Lẹ́yìn nǹkan bí àádọ́ta ọdún táwọn ará Mẹ́síkò ti ń gbin tòmátì ló tó dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìhà àríwá Yúróòpù. Àwọn tiẹ̀ kọ́kọ́ rò pé iwọ ni, nítorí náà wọ́n wulẹ̀ ń gbìn ín láti fi ṣe ọgbà lọ́ṣọ̀ọ́ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irúgbìn oníwó-oníṣu tí ewé rẹ̀ máa ń ta sánsán ni, tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ rírọ̀ sì ní májèlé, èso rẹ̀ kì í ṣe ẹni tó bá jẹ ẹ́ ní nǹkan kan.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọ̀ ìyeyè ni tòmátì tí wọ́n kọ́kọ́ mú wọ Yúróòpù ní, nítorí pé pomodoro (ápù oníwúrà) làwọn ará Ítálì máa ń pè é. Àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ti kọ́kọ́ ń pè é ní tomate kí wọ́n tó wá máa pè é ni tomato, èyí tí àwa Yorùbá wá mọ̀ sí tòmátì. Àmọ́, èdè tó wọ́pọ̀ jù táwọn kan kúndùn láti máa pè é lèyí tó túmọ̀ sí “ápù ìfẹ́.” Láti iyànníyàn ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n tún mú tòmátì la agbami òkun Àtìláńtíìkì kọjá lọ sí Àríwá Amẹ́ríkà, níbi tó ti wá di èlò oúnjẹ pàtàkì ní nǹkan bí igba ọdún sẹ́yìn.

Oríṣiríṣi Tòmátì àti Bí Wọ́n Ṣe Mọ̀ Wọ́n Sí

Bó o bá béèrè pé àwọ̀ wo ni tòmátì ní, ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ fún ọ pé àwọ̀ “pupa” ni. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn oríṣi mìíràn wà tí wọ́n ní àwọ̀ ìyeyè, àwọ̀ osùn, àwọ̀ àlùkò, àwọ̀ ilẹ̀, àwọ̀ funfun, àwọ̀ ewé, táwọn míì sì jẹ́ abilà? Kì í ṣe gbogbo wọn ló rí róbótó. Àwọn kan rí pẹlẹbẹ, àwọn kan rí rógódó, àwọn míì sì pọ̀gbún bí èso ápù. Wọ́n máa ń kéré bí ẹ̀wà tàbí kí wọ́n tóbi tó ìkúùkù.

Wọ́n máa ń gbin tòmátì táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó yìí ní ìkángun àríwá ayé ní ilẹ̀ Iceland àti ní ìkángun gúúsù ayé lórílẹ̀-èdè New Zealand. Àwọn tó ń ṣọ̀gbìn ẹ̀ jù làwọn ará Amẹ́ríkà àti àwọn ará ìhà gúúsù ilẹ̀ Yúróòpù. Láwọn ilẹ̀ olótùútù, ilé ọ̀gbìn tí wọ́n ń mú móoru ni wọ́n máa ń gbìn ín sí ní tiwọn. Àmọ́, láwọn àgbègbè ibi tí ilẹ̀ ti gbẹ inú èròjà ajílẹ̀ ni wọ́n máa ń gbìn ín sí.

Àgbẹ̀ kúẹ́kúẹ́ gan-an á gbádùn àtimáa ṣọ̀gbìn tòmátì. Kò ṣòro láti gbìn, tòmátì téèyàn sì máa rí lórí gaga mélòó kan ti tó láti bọ́ ìdílé tí ò lérò púpọ̀. Bó ò bá ráyè tó tó gbìn ín sí, ìwọ ṣáà wá irú èyí tó ṣeé gbìn sínú ìkòkò lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ògiri àti nínú àwọn àpótí tí wọ́n kó iyẹ̀pẹ̀ sí tó máa ń wà níbi fèrèsé.

Bó O Ṣe Lè Máa Lò Ó àti Iṣẹ́ Tó Ń Ṣe Lára

Bí otútù bá pọ̀ jù ó máa ń jẹ́ kí tòmátì tẹ́ lẹ́nu, nítorí náà má ṣe tọ́jú wọn sínú ẹ̀rọ amú-nǹkan-tutù. Bó o bá fẹ́ kí tòmátì tètè pọ́n, o lè tò ó sójú fèrèsé níbi tí oòrùn á ti máa ta yẹ́ẹ́ sí i, tàbí kí o kó o sínú abọ́ àdému kan tí ò ní dá ooru púpọ̀ mú un tàbí àpòòwé tó ki tó jẹ́ aláwọ̀ kakí, kó o wá fi tòmátì kan tàbí ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ kan tó ti pọ́n sínú abọ́ tàbí àpòòwé náà. Lẹ́yìn náà, dé abọ́ àdému náà pa, tàbí kó o di ẹnu àpòòwé náà, kó o sì gbé e sínú ilé fún ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀.

Ó níṣẹ́ tí tòmátì ń ṣe lára. Ó ní oríṣiríṣi fítámì nínú, ó sì tún ní àwọn èròjà tó ń mú kí ọkàn ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èròjà tó ń mú kí eegun gbó keke, àti àwọn èròjà oníyọ̀. Àwọn olùṣèwádìí tún ti bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé tòmátì ní èròjà kan nínú tí kì í jẹ́ kí nǹkan tètè bà jẹ́, wọ́n sì ní kì í jẹ́ kí àrùn bíi jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn tètè ṣeni. Omi ló pọ̀ jù nínú tòmátì, ìròyìn ayọ̀ sì nìyẹn jẹ́ fáwọn tí kò fẹ́ sanra nítorí pé kò ní ọ̀rá nínú.

Tòmátì Dá A Nínú Oúnjẹ

Bó o bá fẹ́ ra tòmátì, irú èwo lo máa rà? Oríṣi èyíkéyìí nínú pupa tó wọ́pọ̀ yẹn dùn ún jẹ àsán ewébẹ̀, ó sì tún máa ń dùn nínú ọbẹ̀ àsèpọ̀ tàbí omi ọbẹ̀ lásán. Bó o bá sì jẹ àsán tòmátì róbóróbó pupa, tàbí aláwọ̀ ìyeyè, tó máa ń dùn gan-an yẹn, wàá gbádùn rẹ̀ nítorí pé ó ní èròjà ṣúgà tó pọ̀. Bó o bá fẹ́ yan búrẹ́dì tí wọ́n fi ẹran há nínú tàbí oúnjẹ rírò, bóyá ì bá kúkú dáa kó o lo tòmátì dídán bọ̀rọ́bọ̀rọ́ tó pọ̀gbún nítorí pé ara rẹ̀ yi dáadáa. Tòmátì ńlá tó níṣu lára, tó sì yó bọ̀kíbọ̀kí máa ń dáa téèyàn bá kì í bọ àárín àwọn nǹkan bíi búrẹ́dì tàbí nǹkan téèyàn bá fẹ́ yan. Àjẹpọ́nnulá ni oúnjẹ téèyàn bá fi tòmátì abilà, aláwọ̀ ewé sí. Kò sírọ́ níbẹ̀, tòmátì tó pọ́n fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ máa ń mú kí oríṣiríṣi oúnjẹ àjẹpọ́nnulá bí ẹ̀fọ́, ẹyin, oúnjẹ rírò, ọbẹ̀ ẹran àti ọbẹ̀ ẹja dùn sí i. Bó ò bá rí tòmátì eléso rà, ó dájú pé bó o bá lọ sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta tòmátì alágolo ládùúgbò rẹ, wàá rí èyí tó o fẹ́ lára ọ̀pọ̀ àwọn tòmátì alágolo tó wà níbẹ̀.

Gbogbo ọlọ́wọ́ ṣíbí, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ní bó ṣe ń lo tòmátì, àmọ́ àwọn àbá díẹ̀ nìyí tó o lè fi dán ọwọ́ wò.

1. Bó o bá fẹ́ wá ohun ìpanu tí ò ní gbàkókò, síbẹ̀ tá á fani lójú mọ́ra, to ègé tòmátì sínú àwo, fi ègé wàràkàṣì há a láàárín, wá to ègé píà sí i. Ta òróró ólífì sí i kó o sì fọ́n ata dúdú lílọ̀ lé e lórí fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, kó o wá kéwé efinrin lé e lórí.

2. Tó o bá ń fẹ́ àsán ewébẹ̀ irú èyí tí wọ́n máa ń jẹ nílẹ̀ Gíríìsì, gé tòmátì, apálá, wàràkàṣì àti èso ólífì tí ò tíì pọ́n, kó wọn sínú àwo, kó o wá rẹ́ àlùbọ́sà pupa lé e lórí. Wọ́n iyọ̀ àti ata sí i. Lẹ́yìn náà, ta òróró ólífì àti omi òroǹbó kíkan sí i, ó di jíjẹ nìyẹn.

3. Bó o bá fẹ́ jẹ́ oúnjẹ aláta bíi tàwọn ara Mẹ́síkò, gé tòmátì wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, rẹ́ àlùbọ́sà sí i, fi ata wẹ́wẹ́ sí i, da ewéko kọriáńdà gbígbẹ mọ́ ọn, kó o wá da omi òroǹbó wẹ́wẹ́ sí i, ó di jíjẹ nìyẹn.

4. Bó o bá fẹ́ se ọbẹ̀ tòmátì aládùn tí ò ní ná ọ ní wàhálà púpọ̀, tá á sì ṣeé jẹ oúnjẹ rírò, da ẹ̀kún agolo tòmátì tó o ti gé sí wẹ́wẹ́ sínú abọ́ ìdáná, kó o sì fi ṣúgà sí i bó o bá ṣe fẹ́ kó dùn tó. Àwọn nǹkan míì tí wàá tún fi sí i ni òróró ólífì, aáyù tó o ti gé sí wẹ́wẹ́, ewé díẹ̀ bí efinrin àti ata pẹ̀lú iyọ̀. Wá gbé e kaná, kó o sì jẹ́ kí omi hó mọ́ ọn lára fún nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú títí tí ọbẹ̀ náà á fi ki. Bù ú sórí oúnjẹ rírò tó ti fẹ́ri náà.

Àpẹẹrẹ kan lásán ni tòmátì tó ṣeé lò ní onírúurú ọ̀nà yìí jẹ́ lára oríṣiríṣi àgbàyanu oúnjẹ tí Ọlọ́run ti dá fún lílò wa.