Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Àǹfààní Tá À Ń Rí Lára Òkè

Àwọn Àǹfààní Tá À Ń Rí Lára Òkè

Àwọn Àǹfààní Tá À Ń Rí Lára Òkè

“Àìgorí òkè ni àìrí ẹ̀kọ́ kọ́ lára òkè. Tó o bá dórí òkè, bí ibẹ̀ ṣe tòrò minimini bí omi àfòwúrọ̀ pọn á tù ọ́ lára. Ẹ̀fúùfù á rọra máa fẹ́ atẹ́gùn tútù sí ẹ lára, ìjì á sì máa fi agbára rẹ̀ hàn ọ́, wàá gbàgbé àníyàn tó wà lọ́kàn rẹ pátápátá.”—JOHN MUIR, ARÁ ILẸ̀ AMẸ́RÍKÀ KAN TÓ JẸ́ ÒǸKỌ̀WÉ TÓ SÌ TÚN JẸ́ OLÙṢÈWÁDÌÍ NÍPA ÀWỌN OHUN ÀDÁNIDÁ LÓ SỌ̀RỌ̀ YÌÍ.

GẸ́GẸ́ bí ohun tí John Muir rí ní nǹkan tó ti ju ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí, ohun tó wà lórí òkè tóó mú ká kí Ẹlẹ́dàá kúuṣẹ́. Ṣé bí òkè ṣe rí ràgàjì ragaji tó sì lẹ́wà la fẹ́ sọ ni, àbí ti onírúurú ẹranko tó kún ibẹ̀, àbí bí ara ṣe máa ń tuni béèyàn bá wà lórí ẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló máa ń lọ sórí òkè lọ́dọọdún kí wọ́n bàa lè lọ fójú lóúnjẹ kí wọ́n sì lọ gbafẹ́ níbẹ̀. Klaus Toepfer, tó jẹ́ olùdarí àgbà fún Ètò Àbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Látìgbà láéláé ni òkè ti jẹ́ ohun àwòyanu fún gbogbo àwa ẹ̀dá, irú ẹni yòówù ká jẹ́, ibi yòówù ká sì máa gbé.”

Ṣùgbọ́n, àwọn nǹkan kan wà tó ń ṣàkóbá fún òkè o. Ohun tó ti ń fà á tí mìmì kankan ò fi tí ì mi àwọn òkè látọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ni pé wọn ò sí nítòsí àwa ọmọ èèyàn. Àmọ́, mìmì ti wá ń mì wọ́n báyìí o. Àtẹ̀jáde kan tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn sọ pé: “Nítorí iṣẹ́ àgbẹ̀, iṣẹ́ sọgbódilé-sọ̀gbẹ́dìgboro àtàwọn ìgbòkègbodò míì téèyàn ò lè tètè rí ipa wọn, àwọn igbó kìjikìji tó kù sórí àwọn òkè kan ti ń pa run.”

Àyè tí òkè gbà nínú ilẹ̀ tó wà láyé kì í ṣe kékeré. Ìlàjì àwọn ẹ̀dá tó wà láyé ló jẹ́ pé orí òkè lohun tó ń so ẹ̀mí wọn ró wà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló sì ń gbé lórí òkè. Orí òkè kì í kàn ṣe ibi ìgbafẹ́ rírẹwà téèyàn ti lè lọ gba afẹ́fẹ́ àlàáfíà sára nìkan. Ẹ̀yin ẹ jẹ́ ká wo àwọn búrùjí díẹ̀ tó wà lórí òkè, èyí tí Ọlọ́run fi jíǹkí àwa ẹ̀dá èèyàn.

Ìdí Tí Òkè Fi Ṣe Pàtàkì

Ó DÀ BÍ ÀMÙ ŃLÁ. Orí òkè làwọn ìsun tẹ́rẹ́tẹ́rẹ́ tó wá di ibú omi tó tóbi jù lọ lágbàáyé wà, ibẹ̀ sì tún ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú omi tó wà nípamọ́ láyé wà. A tiẹ̀ fẹ́ẹ̀ lè sọ pé abẹ́ àpáta Rocky Mountains ni gbogbo omi tó wà nínú alagbalúgbú Odò Colorado àti Rio Grande tó wà ní Àríwá Amẹ́ríkà ti ń wá. Nǹkan bí ìdajì èèyàn tó wà láyé ló ń gbé ní ìhà gúúsù Éṣíà àti ìhà ìlà oòrùn Éṣíà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn yìí ló dara dé omi òjò tó ń rọ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ sórí àwọn òkè ńláńlá tó tò bẹẹrẹbẹ sáwọn àgbègbè Himalaya, Karakoram, Pamirs àti Tibet.

Toepfer ṣàlàyé pé: “Ńṣe làwọn òkè dà bí àmù gíga gogoro tó ń gbómi pa mọ́ fún ayé. Wọ́n wúlò púpọ̀ fún àwọn ohun alààyè àtàwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé.” Ó wá fi kún un pé: “Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí òkè téńté ń bọ̀ wá kan àwọn ohun alààyè tó ń gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nínú omi, kódà nínú òkun oníyọ̀.” Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn yìnyín tó bá wọ̀ sórí òkè kì í tètè yọ́, bí wọ́n sì ṣe ń yọ́ díẹ̀díẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ojú ilẹ̀ gbẹ táútáú níbẹ̀ tòjò, tẹ̀ẹ̀rùn. Láwọn ibi tí ilẹ̀ ti máa ń gbẹ táútáú láyé, omi tó ń ṣàn wá láti ara yìnyín tó ń yọ́ láwọn orí òkè tó jìnnà réré ni wọ́n fi máa ń bomi rin oko. Ọ̀pọ̀ òkè ni igbó hù sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọn, àwọn igbó yìí dà bíi kànrìnkàn tó ń fa omi mu tó sì ń jẹ́ kí wọ́n máa rọra ṣàn lọ sínú àwọn odò, ìyẹn ni ò sì jẹ́ káwọn odò kún àkúnya.

IBÙGBÉ ÀWỌN ẸRANKO ÀTÀWỌN OHUN ALÀÀYÈ LỌ́LỌ́KAN-Ò-JỌ̀KAN. Nítorí pé òkè kì í sábà sí láàárín ìlú àti pé kò fi bẹ́ẹ̀ dáa fún iṣẹ́ àgbẹ̀, àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ lò síbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé orí òkè ló kù tá a ti lè rí àwọn ẹranko àti ohun ọ̀gbìn tó ṣeé ṣe kí wọ́n máà sí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọgbà Ìtura Kinabalu, tó wà lórí òkè, lórílẹ̀-èdè Malaysia kéré ju ìlú New York City nìkan lọ. Síbẹ̀, onírúurú ewéko tó wà níbẹ̀ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé lẹ́gbàajì [4,500], èyí tó ju ìdámẹ́rin onírúurú ewéko tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ. Orí òkè làwọn ẹranko panda tó dà bíi béárì, tí wọ́n máa ń rí ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà lè gbé, bákan náà sì ni àwọn igún kan tó wà láwọn òkè ìlú California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó fi mọ́ àmọ̀tẹ́kùn funfun tó wà ní àárín gbùngbùn Éṣíà, àti àìmọye onírúurú ẹranko míì tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán nígbó.

Ìwé ìròyìn National Geographic sọ pé àwọn kan tó kọ́ nípa ìbágbépọ̀ àwọn ohun alààyè ti ṣírò rẹ̀ pé, “ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn irúgbìn àtàwọn ẹranko tó léegun ẹ̀yìn ló wà níbi tí kò ju ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ tó wà láyé.” Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹranko la lè rí lórí àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá táwọn èèyàn ò tíì bà jẹ́, irú ilẹ̀ báyìí làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń pè ní ilẹ̀ ààbò fáwọn ohun alààyè. Onírúurú ohun alààyè tó lè ṣe wá láǹfààní ló kún àwọn ibi tí wọ́n pè ní ilẹ̀ ààbò yìí tí ọ̀pọ̀ wọn wà lórí òkè. Àwọn kan tó ṣe pàtàkì jù lára irúgbìn tẹ́nu ń jẹ la ṣì ń rí lórí òkè. Díẹ̀ lára wọn ni àgbàdo tó ń hù láwọn òkè tó wà nílẹ̀ Mẹ́síkò, ọ̀dùnkún àti tòmátì tó ń hù láwọn òkè tó tò jọ lórílẹ̀-èdè Peru, àti àlìkámà tó wà láwọn òkè Caucasus lórílẹ̀ èdè Soviet Union àtijọ́.

IBI ÌGBAFẸ́ ÀTI IBI ẸLẸ́WÀ. Ẹwà tún pọ̀ gan-an lórí àwọn òkè. Orí àwọn àpáta tí omi ti máa ń ya wálẹ̀ bí òkìtì la fẹ́ sọ ni, àbí tàwọn adágún omi tó dùn ún wò, àbí àwọn ohun àwòtúnwò míì tó wà láyé. Ìdí nìyẹn tí kò fi yẹ kó yani lẹ́nu pé ìdámẹ́ta àwọn ibi tí wọ́n ráyè dáàbò bò wà níbi òkè. Irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀ ló sì máa ń wu àwọn tó bá fẹ́ rìnrìn àjò afẹ́ láti lọ.

Kódà, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé ló máa ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ibùdó ìgbafẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré. Bí àpẹẹrẹ, láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé làwọn èèyàn ti máa ń rìnrìn àjò lọ sí Ibùdó Ìgbafẹ́ Denali, tó wà ní ìpínlẹ̀ Alaska lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ wo Òkè McKinley tó tóbi jù lọ ní Àríwá Amẹ́ríkà. Ọ̀pọ̀ sì máa ń lọ fójú lóúnjẹ ní Àfonífojì Great Rift nígbà tí wọ́n bá lọ wo bí Òkè Ńlá Kilimanjaro àti òkè Meru ṣe ga tó. Wọ́n tún máa ń lọ wo oríṣiríṣi ẹranko ìgbẹ́ tó ń gbé ní àfonífojì tó wà láàárín àwọn òkè gàgàrà méjèèjì yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé orí òkè yìí ló ń jàǹfààní nínú báwọn èèyàn ṣe ń rọ́ wá wo ibẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé tí wọn ò bá fètò sí báwọn èèyàn ṣe ń wá ṣe àbẹ̀wò sáwọn orí òkè yìí, ó lè ṣàkóbá fáwọn ohun alààyè tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ èyí tó wà níbẹ̀.

Ìmọ̀ Kún Agbárí Àwọn Tó Ń Gbé Lórí Òkè

Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn tó ń gbé lórí òkè ti jágbọ́n bí wọ́n á ṣe máa gbádùn ayé wọn láyìíká ibi tí nǹkan bá ti nira. Wọ́n ti tún ojú ilẹ̀ tó wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè ṣe, ó ti tẹ́jú, àwọn èèyàn sì ti ń lè dáko níbẹ̀ láti bí ẹgbàá ọdún títí di báyìí. Wọ́n ti tu àwọn ẹranko tó wà níbẹ̀ lójú, wọ́n sì ti sọ wọ́n di ẹran ọ̀sìn. Irú àwọn ẹranko bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko tó lè fara da ìnira òkè gíga bíi llama, tó dà bíi ràkúnmí àti yak, tó nírun lára tó sì jọ màlúù tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. Ìmọ̀ táwọn tó ń gbé orí òkè yìí ti kó jọ látọdúnmọdún lè wúlò fún dídáàbò bo orí òkè tó jẹ́ kò-ṣeé-máà-ní fún gbogbo wa.

Alan Thein Durning ti ilé iṣẹ́ Worldwatch Institute ṣàlàyé pé: “Àwọn tó lè dáàbò bo àwọn ibi tó lọ salalu, táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ dà láàmú, lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé ni àwọn tí wọ́n bí síbẹ̀.” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Wọ́n mọ oríṣiríṣi nǹkan nípa àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ju èyí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní kọ sílẹ̀.” Bó ṣe yẹ ká dáàbò bo àwọn ohun mìíràn tá a lè rí lórí òkè, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká tọ́jú ìmọ̀ tó wà lágbárí wọn.

Ètò Àbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè ṣayẹyẹ Ọdún Orí Òkè Jákèjádò Ayé ti Ọdún 2002. Láti lè jẹ́ kó túbọ̀ di mímọ̀ pé ọmọ èèyàn ò lè wà láìsí òkè, àwọn tó ṣètò ayẹyẹ yìí hùmọ̀ ọ̀rọ̀ kan pé, “Ará Orí Òkè Ni Gbogbo Wa.” Èròǹgbà wọn ni láti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ìṣòro tó bá àwọn òkè tó wà láyé kí wọ́n sì wá bí wọ́n á ṣe máa dáàbò bò wọ́n.

Ó dájú pé ọ̀ràn yìí ń fẹ́ àbójútó. Olùbánisọ̀rọ̀ pàtàkì kan níbi Ìpàdé Àpérò Kárí Ayé Lórí Ọ̀ràn Òkè ti Ọdún 2002, èyí tí wọ́n ṣe ní ìlú Bishkek, lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń wo òkè bí ibi táwọn ti lè rí ọ̀pọ̀ àlùmọ́ọ́nì, àmọ́ wọn ò kíyè sí àwọn ìṣòro táwọn tó ń gbébẹ̀ ń dojú kọ àti báwọn nǹkan alààyè tó wà níbẹ̀ ò ṣe ní run tán.”

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn òkè tó wà láyé àtàwọn tó ń gbé ibẹ̀? Báwo làwọn ìṣòro wọ̀nyí ṣe kàn gbogbo wa?