Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọmọdé Tó Ń Wo Ìwòkuwò

Àwọn Ọmọdé Tó Ń Wo Ìwòkuwò

Àwọn Ọmọdé Tó Ń Wo Ìwòkuwò

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ FINLAND

FÍÌMÙ, tẹlifíṣọ̀n, fídíò, eré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà àti Íńtánẹ́ẹ̀tì kò ṣàjèjì sí ọ̀pọ̀ ọmọdé. Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Ṣàyẹ̀wò Fíìmù Tí Wọ́n Ń Gbé Jáde Lórílẹ̀-Èdè Finland sọ pé, “gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣirò kan ṣe fi hàn, ìgbà ogún sí ìgbà ọgbọ̀n ni àkókò táwọn ọmọdé ń lò nídìí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán àtàwọn nǹkan ìgbàlódé míì fi pọ̀ ju àkókò tí wọ́n ń lò pẹ̀lú àwọn ìdílé wọn lọ.” a Ó mà ṣe o, ńṣe lèyí ń mú káwọn ọmọdé máa wo ọ̀pọ̀ nǹkan tó léwu.

Láwọn orílẹ̀-èdè kan ìjọba ń gbìyànjú láti dáàbò bo àwọn ọmọdé, nítorí náà wọ́n sọ bí ọmọ ṣe gbọ́dọ̀ dàgbà tó kó tó lè wo àwọn ètò kan lórí afẹ́fẹ́, wọ́n sì tún sọ irú ètò orí afẹ́fẹ́ àti fíìmù tó yẹ káwọn ọmọdé wò. Àmọ́, bí ìròyìn tá a sọ lẹ́ẹ̀kan yẹn ṣe fi hàn, ìsọ̀rí tí wọ́n pín àwọn fídíò yẹn sì kì í sábà yé àwọn ọmọ àtàwọn òbí wọn. Wọ́n tiẹ̀ lè máa sọ pé bí wọ́n ṣe pín wọn ò dáa. Láfikún sí i, wọ́n ti rí ọ̀pọ̀ ilé sinimá àtàwọn tó ń fi kásẹ́ẹ̀tì fídíò rẹ́ǹtì tí wọn kì í tẹ̀ lé òfin tó sọ bó ṣe yẹ kéèyàn dàgbà tó kó tó lè wo àwọn fídíò kan. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò tiẹ̀ pín àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù kan sí ìsọ̀rí èyíkéyìí.

Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ tí wọ́n wádìí èrò wọn sọ pé: “Ó dà bíi pé tí nǹkan táwọn ọmọ ilé ìwé ń wò kò bá ti ní ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú, wọn kì í sábà kà á sí oníwà ipá.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ fídíò àti eré orí kọ̀ǹpútà, tó fi mọ́ àwọn eré bèbí tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọdé pàápàá, ló láwọn nǹkan tó lè ṣèpalára fáwọn tó ń wò wọ́n nínú.

Ìròyìn náà sọ pé àwọn ará ilé ló ní “iṣẹ́ tó pọ̀ jù láti ṣe lórí irú fíìmù àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n táwọn ọmọ ń wò.” Wọ́n wá fi ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ parí ìròyìn náà pé: “Ǹjẹ́ àwa àgbààgbà fẹ́ láti gba àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ ewu tó lè wu wọ́n látàrí ohun tí wọ́n ń fojú rí nínú àwọn ètò orí afẹ́fẹ́, ṣé a lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé a sì mọ ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é?”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lẹ́yìn tí wọ́n ti wádìí èrò òjìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún [340] àwọn ọmọ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àtàwọn òbí wọn tó fi mọ́ àwọn olùkọ́ wọn, wọ́n wá gbé ìròyìn kan jáde tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Báwọn Ọmọ Ṣe Gbọ́dọ̀ Dàgbà Tó Kí Wọ́n Tó Lè Wo Àwọn Ètò Kan Lórí Afẹ́fẹ́ àti Ààbò fún Ọmọdé.”