Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ṣé Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lè Yí Padà?”

“Ṣé Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lè Yí Padà?”

“Ṣé Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lè Yí Padà?”

Ìbéèrè tó fara hàn lẹ́yìn ìwé ìròyìn “Jí!” ti May 8, 2001 nìyẹn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kàwé wa ló sọ pé àwọn mọrírì ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yẹn. Àwọn àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba àpapọ̀ ní Atlanta, Georgia, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àyọkà díẹ̀ rèé lára àwọn lẹ́tà tá a rí gbà.

◼ “Láti ọdún mẹ́jọ tí mo ti wà lẹ́wọ̀n, mo ti kíyè sí i pé kíkọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì káàkiri ọgbà ẹ̀wọ̀n ti kẹ́sẹ járí gan-an ni. Nígbà tí mo ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Atlanta, mo bá márùn-ún lára àwọn tẹ́ ẹ mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yín ṣiṣẹ́. Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí mi àti bí wọ́n ṣe máa ń tù mí nínú dùn mọ́ mi gan-an ni. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ irú àwọn arákùnrin bí èyí, tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí àwa tá a ti ṣe àṣìṣe ṣùgbọ́n tá à ń tiraka ká lè padà bọ̀ sípò ká sì di ọmọlúwàbí èèyàn.”—R. J.

◼ “Mo wà níbi tí mo ti ń ṣẹ̀wọ̀n tí wọ́n sì ń kọ́ wa láti fìwà burúkú sílẹ̀, àwọn ará tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ládùúgbò sì ti dá ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó yanran-n-tí sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n níbí. Látàrí èyí, ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń ṣẹ̀wọ̀n ti ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti yọ mí lẹ́gbẹ́ rí nínú ìjọ Kristẹni, wọ́n ti gbà mí padà báyìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn náà sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun ìṣírí gbáà ló jẹ́ pé àwa tá a wà lẹ́wọ̀n náà ń jàǹfààní ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń lọ́ káàkiri àgbáyé. Ohun àgbàyanu mà ni pé kéèyàn máa sin Jèhófà níbi yòówù kó wà o!”—J. M.

◼ “Lọ́dún 1970 ni wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n láìmọwọ́ mẹsẹ̀. Mo ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá gbáko. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ká sọ̀rọ̀ ká bá a bẹ́ẹ̀ ni tiwọn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì, ìyẹn wú mi lórí gan-an ni. Lẹ́yìn tí mo kúrò lẹ́wọ̀n, mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nìṣó kò sì pẹ́ tí mo fi ṣèrìbọmi. Nígbà míì, ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí mi ṣì máa ń dà mí lọ́kàn rú ó sì máa ń mú kí inú bí mi. Ṣùgbọ́n mo máa ń rán ara mi létí pé láìpẹ́ láìjìnnà, Jèhófà máa fòpin sí gbogbo ìrẹ́nijẹ àti ìjìyà. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n lè yí padà bí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì. Wọ́n á tún ṣọpẹ́ pé àwọn arákùnrin wa ń fi taápọntaápọn ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń yọ̀ǹda àkókò wọn láti lè wá ran àwọn lọ́wọ́. Èmi dúpẹ́ tèmi o!”—R. S.

◼ “Kó tó di pé wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n ni mo ti ń mu sìgá, mò ń lo oògùn olóró, mo máa ń sọ̀rọ̀kọ́rọ̀, arọ́bafín sì ni mí. Mo tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgárá ọmọọ̀ta. Wọ́n sì tún ti yọ mí lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ. Wọ́n ti gbà mí padà báyìí ṣá o, mo sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Mo mọ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ti sọ mí dòmìnira!”—I. G.