Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Kí Ọkùnrin Àti Ọkùnrin Máa Fẹ́ra?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Kí Ọkùnrin Àti Ọkùnrin Máa Fẹ́ra?
BÍ ÌSÌN ṣe ń lọ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin méjì fọwọ́ kọ́ ara wọn lọ́wọ́ níwájú gbajúgbajà àlùfáà Ìjọ Oníbíṣọ́ọ̀bù. Wọ́n bá ara wọn “dá májẹ̀mú . . . níwájú Ọlọ́run àti níwájú ìjọ.” Bíṣọ́ọ̀bù ìjọ náà, tó wọ aṣọ àlùfáà tó láwọ̀ wúrà àti funfun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì, tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí ìgbéyàwó wọn lójú gbogbo ìjọ. Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin tó ń ṣègbéyàwó yìí gbára wọn mọ́ra, wọ́n fẹnu kora wọn lẹ́nu, àwọn èèyàn sì dìde dúró kí wọ́n lè yẹ́ wọn sí. Bíṣọ́ọ̀bù náà wá sọ pé bí ọkùnrin bá fẹ́ ọkùnrin bí wọ́n ti ṣe yẹn, ó “jẹ́ àjọṣe mímọ́ tó yẹ kéèyàn tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí ẹ̀, . . . tó sì yẹ kéèyàn pè lórúkọ tó jẹ́ gan-an, ìyẹn ni àjọṣe mímọ́.”
Àmọ́ ṣá o, àwọn aṣáájú ìsìn míì wà tí wọ́n ń sọ pé àwọn ò fara mọ́ kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin. Cynthia Brust, agbẹnusọ fún Ìgbìmọ̀ Áńgílíkà Ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn àwùjọ àwọn ọmọ Ìjọ Oníbíṣọ́ọ̀bù tí wọ́n dúró sórí ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ́ṣì náà bó ṣe wà láti ìpìlẹ̀, sọ pé: “Ohun tí bíṣọ́ọ̀bù yìí ṣe bà wá lọ́kàn jẹ́ gan-an ni. Kéèyàn máa tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí ọkùnrin tó ń gbé ọkùnrin níyàwó ta ko ẹ̀kọ́ ṣíṣe kedere tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀,” ó wá fi kún un pé, “ìbálòpọ̀ . . . gbọ́dọ̀ mọ sáàárín ọkùnrin àti obìnrin tí a so pọ̀ nínú ìdè ìgbéyàwó mímọ́.”
Àríyànjiyàn gbígbóná janjan tó ń lọ lórí ọ̀rọ̀ kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin yìí ò wá mọ sáàárín àwọn onísìn nìkan o. Káàkiri àgbáyé ni arukutu ṣì ti ń sọ lórí ọ̀ràn náà lágbo òṣèlú. Ìdí ni pé
wàhálà tó máa ń tìdí ẹ̀ yọ láwùjọ, lágbo òṣèlú àti nínú ètò owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́, tó fi mọ́ ètò nípa ìtọ́jú ọkọ lórúkọ aya àti owó orí máa ń pọ̀ gan-an ni.
Ọ̀ràn tó bá jẹ mọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ibi tí òfin to àwọn èèyàn sí sábà máa ń díjú gan-an ni, èrò àwọn aráàlú kì í sì í ṣọ̀kan lórí ẹ̀. Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí tọ̀tún tòsì, nítorí náà wọn kì í lọ́wọ́ sí àríyànjiyàn lórí ọ̀ràn ìṣèlú. (Jòhánù 17:16) a Síbẹ̀, àwọn kan wà tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì ṣùgbọ́n tí wọn ò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe gan-an lórí ọ̀ràn kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Ngbọ́, ojú wo lo fi ń wo ọ̀ràn náà? Ìlànà wo ni Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó? Kí ni ìhà tó o kọ sí ọ̀ràn náà ní í ṣe pẹ̀lú àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run?
Ẹlẹ́dàá Ti Ṣòfin Lórí Ẹ̀
Kó tó di pé ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí ṣòfin lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó ni Ẹlẹ́dàá wa ti gbé òfin tí yóò máa ṣàkóso ìgbéyàwó kalẹ̀. Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Vine’s Expository Dictionary of Biblical Words, ṣe sọ, béèyàn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù náà “aya,” “obìnrin tàbí ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ abo, ló máa wá séèyàn lọ́kàn.” Jésù náà jẹ́rìí sí i pé “akọ àti abo” ló yẹ káwọn tó bá máa gbéra wọn níyàwó jẹ́.—Mátíù 19:4.
Nípa báyìí, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tímọ́tímọ́, tó máa wà pẹ́ títí, láàárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin pé kí wọ́n jẹ́ àṣekún ara wọn, kí wọ́n bàa lè jọ máa gba ti ara wọn rò, kí wọ́n jọ máa sin Ọlọ́run, kí wọ́n sì jọ máa ní ìbálòpọ̀.
Àkọsílẹ̀ Bíbélì tá a mọ̀ bí ẹní mowó nípa ìlú Sódómù àti Gòmórà jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run nípa bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Igbe ìráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà, bẹ́ẹ̀ ni, ó ń dún kíkankíkan, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ó rinlẹ̀ gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20) Àwọn méjì tó dé bá Lọ́ọ̀tì olódodo lálejò ló tú àṣírí bí wọ́n ṣe ya oníṣekúṣe tó nígbà yẹn. “Àwọn ọkùnrin . . . Sódómù yí ilé náà ká, láti orí ọmọdékùnrin dórí àgbà ọkùnrin, gbogbo àwọn ènìyàn náà ní ìwọ́jọpọ̀ kan. Wọ́n sì ń bá a nìṣó láti nahùn pe Lọ́ọ̀tì, ní wíwí fún un pé: ‘Ibo ni àwọn ọkùnrin tí wọ́n wọlé wá bá ọ ní alẹ́ yìí wà? Mú wọn jáde fún wa kí a lè ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú wọn.’” (Jẹ́nẹ́sísì 19:4, 5) Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọkùnrin Sódómù sì burú, wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku sí Jèhófà.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:13.
Àwọn ọkùnrin yẹn “di ẹni tí a mú ara wọn gbiná lọ́nà lílenípá nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin.” (Róòmù 1:27) Wọ́n ti “jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá.” (Júúdà 7) Láwọn orílẹ̀-èdè tó ti wọ́pọ̀ pé káwọn èèyàn máa jà fún ẹ̀tọ́ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, àwọn kan lè sọ pé àwọn ò gbà kí wọ́n máa sọ pé bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ “lòdì sí ti ẹ̀dá.” Báwọn kan bá tiẹ̀ ń sọ bẹ́ẹ̀, ṣebí Ọlọ́run ló yẹ kó sọ ohun tó bá ìwà ẹ̀dá mu àtèyí tí kò bá a mu? Àṣẹ tó pa fáwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sùn ti ọkùnrin bí ìwọ yóò ṣe sùn ti obìnrin. Ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni.”—Léfítíkù 18:22.
Ọlọ́run Ni Wà Á Jíhìn Fún
Ohun tí Bíbélì ń sọ lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere, ìyẹn ni pé: Ọlọ́run ò fọwọ́ sí bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, kò sì gba ẹnikẹ́ni láyè pé kó máa lọ́wọ́ nínú ẹ̀. Ọlọ́run ò tún nífẹ̀ẹ́ sáwọn èèyàn tó bá “fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn tí ń fi wọ́n ṣe ìwà hù.” (Róòmù 1:32) Kódà, ìgbéyàwó ò sọ kí ọkùnrin àti ọkùnrin máa fẹ́ra di nǹkan iyì. Kí ọkùnrin àti ọkùnrin máa fẹ́ra kò sí lára ìtọ́ni Ọlọ́run tó sọ pé kí “ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn,” nítorí pé ohun ẹ̀gbin gbáà ló kà á sí.—Hébérù 13:4.
Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, kò sẹ́ni tí ò lè kọ́ béèyàn ṣeé “ta kété sí àgbèrè,” tó fi mọ́ bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, kó sì “mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:3, 4) Òótọ́ ni pé èyí kì í sábà rọrùn. Nathan b, tó ti jẹ́ abẹ́yà kan náà lò pọ̀ rí, sọ pé: “Mo rò pé mi ò ní lé jáwọ́ nínú ẹ̀ ni.” Ṣùgbọ́n, ìrànlọ́wọ́ tó rí gbà nípasẹ̀ “ẹ̀mí Ọlọ́run wa” mú kó yí padà. (1 Kọ́ríńtì 6:11) Nathan ti wá rí i pé kò sí ìṣòro tí apá Jèhófà ò ká, òun lẹni tó lè fún wa lókun tó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti dójú ìlà àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀ ká sì rí ìbùkún Rẹ̀ gbà.—Sáàmù 46:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kódà, bí òfin orílẹ̀-èdè táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé bá ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n ti fi Bíbélì kọ́, wọn kì í lọ́wọ́ nínú fífi ẹ̀hónú hàn, wọn kì í sì í báwọn olóṣèlú yíde kiri lọ́nà èyíkéyìí nítorí àtiyí irú òfin bẹ́ẹ̀ padà.
b Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Fọ́tò tí Chris Hondros/Getty Images yà