Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Lọ́wọ́

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Lọ́wọ́

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Lọ́wọ́

INÚ ayé onílàásìgbò làwọn ọ̀dọ́ òde òní ń dàgbà sí. Ojú ọ̀pọ̀ lára wọn báyìí làwọn òbí wọn ṣe ń pín gaàrí tí wọ́n sì ń kọra wọn sílẹ̀. Àwọn míì ń rí i báwọn ọmọ ilé ìwé bíi tiwọn ṣe ń lo oògùn olóró tí wọ́n sì ń hùwà ọ̀daràn. Àwọn ojúgbà ò sì jẹ́ káwọn míì gbádùn nítorí pé ṣe ni wọ́n ń fi ìbálòpọ̀ lọ̀ wọ́n. Àwọn tó ń fi ìbálòpọ̀ lọ̀ wọ́n sì lè jẹ́ ẹ̀yà kejì tàbí ẹ̀yà kan náà bíi tiwọn. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ọ̀dọ́ tí wọn kì í ṣì lóye, tí kì í dá wà, tí kì í sì í ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kódà bó ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n.

Kí ló lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí ìṣòro ayé má bàa gbé wọn mì? Dókítà Robert Shaw sọ pé: “Ìlànà kan gbòógì gbọ́dọ̀ wà táwọn ọ̀dọ́ á máa tẹ̀ lé. Ìlànà tí ò ní máa yí padà lemọ́lemọ́, tá á sì ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti lè yan ọ̀rẹ́ tó dáa, kí wọ́n ṣe ìpinnu tó tọ́, kí wọ́n sì ní àánú àwọn ẹlòmíì lójú.” Inú Bíbélì la ti lè rí ìlànà ìwà rere tó dára jù lọ, nítorí pé èrò Ẹlẹ́dàá ló wà nínú rẹ̀. Ta ló lè mọ̀ ju Jèhófà Ọlọ́run lọ nípa ohun tó yẹ ká ṣe ká lè rọ́nà gbé e gbà nínú ayé wàhálà tá à ń gbé yìí?

Ìtọ́sọ́nà Yíyẹ Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́

Àwọn ìlànà yíyẹ tó sì lè ranni lọ́wọ́ ló wà nínú Bíbélì. Àwọn ìlànà náà wúlò gan-an fáwọn òbí àtàwọn àgbà mìíràn tí wọ́n fẹ́ láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ríbi gbé ọ̀ràn ara wọn gbà títí tí wọ́n á fi dàgbà.

Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ ojú abẹ níkòó nígbà tó sọ pé “ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí,” tàbí, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Today’s English Version, ṣe túmọ̀ rẹ̀, “ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé káwọn ọmọdé máa hùwà òmùgọ̀, kí wọ́n sì máa ṣe bí aláìnírònú.” (Òwe 22:15) Ó dà bíi pé àwọn ọ̀dọ́ kan gbọ́n tó ọjọ́ orí wọn, síbẹ̀ wọn ò ní ìrírí. Ìrírí tí wọn ò ní yìí gan-an ló máa ń fà á tí wọ́n fi máa ń ní ìṣòro bí wọ́n ṣe ń bàlágà. Lára àwọn ìṣòro náà ni ìbẹ̀rù, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìdààmú ọkàn tó máa ń wáyé téèyàn bá ń dàgbà. (2 Tímótì 2:22) Báwo la ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí lọ́wọ́?

Bíbélì gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Ó rọ àwọn òbí pé: “Kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa [àwọn ìlànà Ọlọ́run] nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Àǹfààní méjì ló wà nínú irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, á jẹ́ káwọn ọmọ rí ìtọ́ni gbà nípa bí wọ́n ṣe lè máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Aísáyà 48:17, 18) Èkejì ni pé á jẹ́ káwọn òbí àtàwọn ọmọ lè máa bára wọn sọ̀rọ̀. Èyí sì ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé àwọn ọ̀dọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà ni, ojú sì lè máa tì wọ́n tàbí kí wọ́n máa rò pé àwọn ò lálábàárò.

Àmọ́ ṣá o, ìgbà míì wà tó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ bíi pé ńṣe ni wọ́n dá wà. Àwọn kan sì wá wà tí wọ́n máa ń ní ìṣòro ìdánìkanwà tó le gan-an. A ṣèwádìí nínú ìwé kan, ìwé náà sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ yìí sọ pé ó ṣòro fáwọn láti lọ́rẹ̀ẹ́ nílé ìwé, àti pé kò sẹ́ni táwọn lè fọ̀rọ̀ lọ̀, àwọn ò lẹ́nì kan, ó máa ń ṣòro fáwọn láti rójúure àwọn ọmọ míì, ó sì máa ń ṣe àwọn bíi pé kò sẹ́ni táwọn lè tọ̀ lọ báwọn bá nílò ìrànlọ́wọ́.” a

Àwọn òbí àtàwọn àgbà tí ò fẹ́ dágunlá sọ́rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìṣòro wọn. Lọ́nà wo? Olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn kan tó wà fáwọn ọ̀dọ́ kọ̀wé pé: “Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a fi lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ ni pé ká bi wọ́n léèrè.” Dájúdájú, ó máa ná èèyàn ní àkókò, èèyàn sì gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù kó tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tó bá gbà ló yẹ kéèyàn ṣe nítorí pé èrè ibẹ̀ pọ̀.—Òwe 20:5.

Ìdí Tó Fi Yẹ Káwọn Òbí Máa Fòye Tọ́ Àwọn Ọmọ Sọ́nà

Yàtọ̀ sí káwọn òbí máa bá àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀, àwọn ọ̀dọ́ fúnra wọn mọ̀ lódò ikùn wọn lọ́hùn-ún pé àwọn ń fẹ́ ẹni tí yóò má fòye tọ́ àwọn sọ́nà. Bíbélì sọ pé “ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” (Òwe 29:15) Àwọn ògbógi gbà pé ohun tó ń sọ àwọn ọ̀dọ́ di ìpáǹle ni pé àwọn òbí kì í dá gbèdéke lé ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Dókítà Shaw, tá a ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Bá a bá ń kẹ́ ọmọ lákẹ̀ẹ́bàjẹ́, tá ò sì sọ fún un rí pé ‘bẹ́ẹ̀ kọ́’ tàbí pé ‘ṣe tibí má ṣe tọ̀hún,’ a jẹ́ pé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ máa rò pé òun nìkan ni Ọlọ́run dá ayé fun ni, kò ní mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹlòmíì, kò ní mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́, kò ní mọ ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn. Báwọn òbí ò bá kọ́ ọ láti ní ìgbatẹnirò, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ò ní mọ béèyàn ṣeé nífẹ̀ẹ́ ẹlòmíì.”

Ohun tí Ọ̀mọ̀wé Stanton Samenow náà sọ ò yàtọ̀ síyẹn. Ọ̀mọ̀wé yìí ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tó kó sí ìṣòro. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn òbí kan gbà pé ńṣe ló yẹ káwọn ọmọdé náà wà láyè ara wọn. Wọ́n gbà láìronújinlẹ̀ pé kò dáa kéèyàn máa sọ fọ́mọ pé ‘ṣe tibí, má ṣe tọ̀hún’ nítorí pé ìyẹn á ti pọ̀ jù fún un, kò sì ní gbádùn ìgbà ọmọdé rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí wọn ò bá tètè jẹ́ káwọn ọmọ mọ̀wọ̀n ara wọn, ìṣòro ló máa fà lọ́jọ́ iwájú. Ohun táwọn òbí yìí ò sì mọ̀ ni pé ó lè ṣòro fún ọmọdékùnrin tàbí ọmọdébìnrin táwọn òbí kì í bá bá wí láti máa hùwà ọmọlúwàbí.”

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ńṣe ló yẹ káwọn òbí máa fọwọ́ líle koko mú àwọn ọmọ? Ó tì o. Apá kan ṣoṣo péré ni dídá gbèdéke lé ohun táwọn ọmọ gbọ́dọ̀ ṣe jẹ́ nínú ọ̀ràn àbójútó àwọn ọmọ. Báwọn òbí bá tún fọwọ́ tó le koko jù mú ọ̀ràn ìbáwí, tí wọ́n ń sì ń ká àwọn ọmọ lọ́wọ́ kò jù, ìyẹn lè jẹ́ kínú ilé máa gbóná mọ́ wọn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21; Éfésù 6:4.

Nítorí náà, léraléra ló yẹ káwọn òbí máa ṣàyẹ̀wò irú ìtọ́ni àti ìbáwí tí wọ́n ń fáwọn ọmọ, pàápàá báwọn ọmọ wọn ṣe ń bàlágà tí wọ́n sì ń gbọ́n sí i. Bóyá á dáa kẹ́ ẹ dẹwọ́ àwọn òfin kan tàbí kẹ́ ẹ mú àwọn ìkálọ́wọ́kò kan kúrò, tàbí kẹ́ tiẹ̀ yí wọn padà, kí wọ́n má bàa kọjá ohun táwọn ọmọ á lè pa mọ́.—Fílípì 4:5.

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Fà Wọ́n Mọ́ra

Bá a ṣe sọ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé kó tó di pé Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn aráyé tá á sì mú gbogbo ìwà ibi kúrò, ayé wa yìí á bá ara rẹ̀ nínú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Ẹ̀rí fi hàn pé àkókò tí Bíbélì sọ yẹn gan-an là ń gbé yìí, ìyẹn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí. Báwọn àgbà ṣe ń fara dà á nínú ayé táwọn èèyàn ti jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá” àti “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu” yìí, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọ̀dọ́ ṣe gbọ́dọ̀ máa fara dà á.—2 Tímótì 3:1-5. b

Àwọn òbí tí wọ́n bá rí i pé àwọn àtàwọn ọmọ wọn kì í bára sọ̀rọ̀ lè wá bí wọ́n á ṣe máa fà á mọ́ra díẹ̀díẹ̀ nípa níní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ó yẹ ká gbóríyìn fún àwọn òbí tí wọ́n ń ṣakitiyan láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ọmọ tí ìsapá wọn lórí àwọn ọmọ náà ò sì kéré.

Bíbélì ni irin iṣẹ́ tó wúlò jù lọ táwọn òbí lè lò láti máa bá àwọn ọmọ jíròrò. Ó ti ran ọ̀pọ̀ òbí lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wọn ó sì ti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe kó sínú ìṣòro tó lè gbẹ̀mí wọn. (Diutarónómì 6:6-9; Sáàmù 119:9) Nítorí pé látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ni Bíbélì ti wá, ó yẹ kó dá wa lójú pé ìrànlọ́wọ́ tó dáa jù lọ ló máa ṣe fáwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí. c

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé yìí tún sọ pé lóòótọ́ làwọn ọ̀dọ́ kan wà tí wọ́n máa ń ní ìṣòro dídá wà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, nígbà gbogbo ló máa ń ṣe àwọn tí ìṣòro ìnìkanwà tiwọn le gan-an bíi pé àwọn dá wà fún àkókò gígùn. Bí ọ̀ràn ọkùnrin kan tàbí ọ̀ràn obìnrin kan bá ti rí báyìí ńṣe ló máa “gbà gbọ́ pé béèyàn ò bá ti lọ́rẹ̀ẹ́ kò lè lọ́rẹ̀ẹ́ nìyẹn, kò sí ohun téèyàn lè ṣe sí i, àléébù ti olúwarẹ̀ sì ni” àti pé ọ̀ràn náà “ò lè yí padà, kò sì ní yí padà.”

c Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé ìrànlọ́wọ́ tí ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ ń ṣe kúrò ní kékeré. Gbogbo orí mọ́kàndínlógójì tó wà nínú ẹ̀ ló ní àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn àkòrí tó wà nínú ẹ̀ nìyí: “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Ní Awọn Ọ̀rẹ́ Tootọ?” “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Koju Ìkìmọ́lẹ̀ Ojúgbà?” “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ki Ìdánìkanwà Mi Lọ?” “Mo Ha Ti Ṣetan Lati Dá Ọjọ Àjọròde Bi?” “Ki Nidi fun Sisọ Pe Bẹẹ Kọ si Oogun Lile?” “Ki Ni Nipa Ti Ibalopọ Takọtabo Ṣaaju Igbeyawo?”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jíròrò ohun tó bá ń dùn ọ́ lọ́kàn pẹ̀lú àgbàlagbà tá á fara balẹ̀ tẹ́tí gbọ́ ẹ