Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Mọ Iṣẹ́ Ọwọ́ Ṣe?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Mọ Iṣẹ́ Ọwọ́ Ṣe?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Mọ Iṣẹ́ Ọwọ́ Ṣe?

“Mi ò rò pé mo lè bá wọn ṣiṣẹ́ ọwọ́ láyé mi. Bí mo ṣe ń fi kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ ti tẹ́ mi lọ́rùn pa.”—Nathan.

“Ojú tí ò dáa làwọn èwe kan fi máa ń wo àwa tá à ń ṣiṣẹ́ ọwọ́, lójú tiwọn ńṣe ló dà bíi pé orí wa ò pé tó láti ṣiṣẹ́ míì.”—Sarah.

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ka iṣẹ́ ọwọ́ sí iṣẹ́ tó nira, iṣẹ́ ìdọ̀tí àti iṣẹ́ tí kì í dùn mọ́ èèyàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ní ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́, ó ní: “Àwọn iṣẹ́ yẹn ò níyì tó bẹ́ẹ̀ láyé táwọn èèyàn fẹ́ máa ṣiṣẹ́ alákọ̀wé yìí.” Abájọ táwọn ọ̀dọ́ fi máa ń gbọnmú tí wọ́n bá ti gbọ́rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ sétí.

Àmọ́, nǹkan tí Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ tó gba agbára yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníwàásù 2:24) Lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, iṣẹ́ àgbẹ̀ ni olórí iṣẹ́ wọn nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, iṣẹ́ àṣelàágùn lèèyàn á ṣe tó bá ń túlẹ̀, tó bá ń kórè tàbí tó bá ń pakà lákòókò yẹn. Síbẹ̀, Sólómọ́nì sọ pé èrè púpọ̀ wà nínú iṣẹ́ tó gba agbára.

Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere.” (Éfésù 4:28) Iṣẹ́ ọwọ́ ò ṣàjèjì rárá sí Pọ́ọ̀lù alára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ka jẹ̀jẹ̀rẹ̀ ìwé, iṣẹ́ àgọ́ pípa ló ń ṣe jẹun.—Ìṣe 18:1-3.

Ǹjẹ́ ìwọ náà lè fọwọ́ ara rẹ ṣiṣẹ́? Bóyá o kò mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní lo lè rí jẹ nínú iṣẹ́ ọwọ́.

Ó Lè Kọ́ Ẹ Lẹ́kọ̀ọ́ Tó Máa Wúlò fún Ẹ Láyé Ẹ

Tó o bá ń lo ara ẹ láti ṣiṣẹ́ ọwọ́, bí iṣẹ́ tó jẹ mọ́ lílo ámà tàbí ríroko inú ọgbà, á jẹ́ kara ẹ máa mókun. Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀ ò mọ sórí pé ara ẹ á jí pépé. Ǹjẹ́ o mọ bó o ṣe lè pọ́ táyà tó jò, tàbí bó o ṣe lè jo ọ́ìlì tí ò wúlò mọ́ kúrò nínú mọ́tò? Ṣé o lè tún wíńdò tó bàjẹ́ ṣe tàbí kó o tún páìpù tó dí ṣe? Ṣé o lè gbọ́únjẹ? Ṣé o lè fọ ilé ìwẹ̀ mọ́ tónítóní téèyàn ò fi ní kárùn bó bá wẹ̀ níbẹ̀? Gbogbo ọ̀dọ́, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló yẹ kó mọ àwọn iṣẹ́ yìí ṣe nítorí pé tó o bá mọ̀ ọ́n ṣe, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́jọ́ kan nígbà tó o bá dé àyè ara rẹ.

Tún wá wò ó o, ó dà bíi pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ mọ àwọn iṣẹ́ kan ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé níbí. Ó kọ́ iṣẹ́ káfíńtà, kò sì sí iyèméjì pé Jósẹ́fù, bàbá tó gbà á tọ́, ló kọ́ ọ níṣẹ́ yẹn, òun ló jẹ́ kí wọ́n máa pè é ní káfíńtà. (Mátíù 13:55; Máàkù 6:3) Ìwọ náà lè dẹni tá a mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè wúlò fún ẹ bó o bá ń ṣiṣẹ́ ọwọ́.

Ó Lè Kọ́ Ẹ Lọ́gbọ́n Tí Wàá Fi Máa Gbé Ìgbé Ayé Ẹ

Iṣẹ́ tó gba agbára tún lè jẹ́ kó o mọ irú ojú tó yẹ kó o máa fi wo ara rẹ. Nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Fred Provenzano ń kọ̀wé tó fi ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń bójú tó ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìrònú èèyàn nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ó sọ pé téèyàn bá mọ iṣẹ́ ọwọ́, ó túbọ̀ máa ń mú kí ọkàn “èèyàn balẹ̀ pé àtẹlẹwọ́ ẹni kì í tanni jẹ” ó sì “lè jẹ́ kéèyàn mọ bá a ti í fi nǹkan kọ́ra àti bá a ti í wà létòlétò. Àwọn nǹkan báwọ̀nyí sì ṣe pàtàkì fẹ́ni tó bá fẹ́ rí iṣẹ́ tó dáa tí iṣẹ́ náà ò sì ní bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́.” Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ John sọ pé: “Iṣẹ́ ọwọ́ máa ń kọ́ èèyàn ní sùúrù. Ó lè kọ́ ẹ bí wàá ṣe borí ìṣòro tó bá yọjú.”

Sarah tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣàlàyé pé: “Ṣíṣiṣẹ́ ọwọ́ ti kọ́ mi láti dẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára. Mo ti mọ bí mo ṣe lè máa kó ara àti ọkàn mi níjàánu.” Ṣé tí iṣẹ́ kan bá ti jẹ́ iṣẹ́ tó gba agbára, ó ní láti jẹ́ iṣẹ́ ìnira ni? Nathan sọ pé: “Mo máa ń gbádùn ohun tí mo bá fọwọ́ ara mi ṣe. Bí mo bá sì ṣe ń ṣe é sí, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ń dára sí i. Èyí ló túbọ̀ jẹ́ kó dá mi lójú pé n kì í ṣe ọ̀lẹ.”

Ìwọ náà á rí i pé bó o bá ṣe iṣẹ́ kan tó gba agbára láṣeyọrí, wàá láyọ̀. Ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ James sọ nípa ìyẹn rèé: “Mo gbádùn iṣẹ́ káfíńtà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè rẹ̀ mí láwọn ìgbà míì, bí mo bá ti ń rí ohun tí mo kàn báyìí, ńṣe ni inú mi máa ń dùn pé mo ti ṣe bẹbẹ. Ó máa ń dùn mọ́ èèyàn nínú gan-an ni.” Brian náà sọ ohun tó fẹ́ jọ bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Mo kúndùn kí n máa ṣiṣẹ́ lára mọ́tò. Mímọ̀ tí mo tiẹ̀ mọ̀ pé mo lè tún ohun tó bàjẹ́ ṣe tá á fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bíi tuntun máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń mú kí n ní ìtẹ́lọ́rùn.”

Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́

Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tó bá mọṣẹ́ ọwọ́ lè jàǹfààní ẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run. Nígbà tí Jèhófà gbé iṣẹ́ kíkọ́ arabaríbí tẹ́ńpìlì fún Ọba Sólómọ́nì, Sólómọ́nì mọ̀ pé òun nílò àwọn akíkanjú èèyàn tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú iṣẹ́ ọwọ́ kóun tó lè ṣiṣẹ́ yẹn. Bíbélì sọ pé: “Sólómọ́nì Ọba sì tẹ̀ síwájú láti ránṣẹ́ lọ wá Hírámù wá láti Tírè. Ó jẹ́ ọmọkùnrin obìnrin opó kan láti inú ẹ̀yà Náfútálì, baba rẹ̀ sì jẹ́ ọkùnrin ará Tírè, oníṣẹ́ bàbà; ó sì kún fún ọgbọ́n àti òye àti ìmọ̀ fún ṣíṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́ bàbà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wá sọ́dọ̀ Sólómọ́nì Ọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 7:13, 14.

Àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ fún Hírámù o, pé ó lè fi ọwọ́ ara ẹ̀ ṣiṣẹ́ fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn Jèhófà! Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hírámù yẹn jẹ́ ká túbọ̀ rí òótọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nínú Òwe 22:29 pé: “Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí; kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn yẹpẹrẹ.”

Lónìí, àní àwọn ọ̀dọ́ tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọsẹ́ ọwọ́ kan gbòógì tàbí àwọn tí ò tiẹ̀ mọṣẹ́ ọwọ́ kankan rárá ti láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nítorí pé wọ́n bá wọn dá sí irú iṣẹ́ ilé kíkọ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn ti mọ àwọn iṣẹ́ ọwọ́ bí iṣẹ́ mànàmáná, iṣẹ́ àwọn tó ń fa omi sílé, iṣẹ́ bíríkìlà àti iṣẹ́ káfíńtà. Ìwọ náà lè bá àwọn alàgbà ìjọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, bóyá á ṣeé ṣe fún ẹ láti kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

James, tó ti bá wọn lọ́wọ́ sí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba bíi mélòó kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ará ìjọ yín lè máà ráyè tàbí kó máa ṣeé ṣe fún wọn. Nítorí náà tí ìwọ bá yọ̀ǹda ara rẹ, gbogbo ìjọ lápapọ̀ lò ń ràn lọ́wọ́ yẹn.” Nathan, tó kọ́ bí wọ́n ṣe ń po kankéré, rí i pé iṣẹ́ ọwọ́ tó kọ́ yẹn ṣílẹ̀kùn àǹfààní míì fún un nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí orílẹ̀-èdè Zimbabwe mo láǹfààní láti lọ ṣe iṣẹ́ ọwọ́ tí mo kọ́ níbẹ̀. Oṣù mẹ́ta ni mo fi ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ìrírí tí mo gbádùn jù lọ láyé mi sì nìyẹn.” Ohun tó mú káwọn ọ̀dọ́ míì kọ̀wé láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀nda ara ẹni ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn ni pé wọn ò kọ̀ láti ṣiṣẹ́ tó gba agbára.

Bó o bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ kan, ìyẹn á tún jẹ́ kó o ní “itẹlọrùn” dé ibì kan. (1 Tímótì 6:6, Bíbélì Mímọ́) Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn ajíhìnrere alákòókò kíkún. Iṣẹ́ táwọn míì kọ́ ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn láìsí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi owóbówó àti ọ̀pọ̀ àkókò kàwé.

Bó O Ṣe Lè Kọ́ṣẹ́ Ọwọ́

Ó ṣe kedere pé o lè jàǹfààní bó o bá mọṣẹ́ ọwọ́, ì báà jẹ́ láti lè máa rówó mú wálé nídìí ẹ̀ lo ṣe fẹ́ kọ́ ọ ni o tàbí kó o bàa lè mọ iṣẹ́ ilé ṣe. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n máa ń kọ́ yín láwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ọwọ́ níléèwé yín. Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé yín náà lo tí máa kọ́ àwọn iṣẹ́ kan. Báwo lo ṣe lè kọ́ṣẹ́ ọwọ́ nínú ilé ná? O lè kọ́ ọ nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé. Ọ̀mọ̀wé Provenzano tá a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì fáwọn ọ̀dọ́ láti máa ṣiṣẹ́ ilé nítorí pé àwọn iṣẹ́ tí wọ́n bá kọ́ nínú ilé ló máa jẹ́ kí wọ́n lè máa ‘rí nǹkan pawọ́ dà’ nígbà tí wọ́n bá kúrò lábẹ́ òbí wọn, táwọn náà á sì fi lè wà láàyè ara wọn láìwo ọwọ́ ẹnì kankan kí wọ́n tó jẹun.” Nítorí náà máa fojú wá àwọn nǹkan tó bá yẹ ní ṣíṣe nínú ilé. Ṣé oko inú ọgbà ló ti tó ro àbí kọ́ńbọ́ọ̀dù ló bàjẹ́?

Iṣẹ́ ọwọ́ kì í ṣe iṣẹ́ àbùkù rárá àti rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ tó lè ṣe ẹ́ láǹfààní rẹ́kẹrẹ̀kẹ ni. Má máa sá fún iṣẹ́ ọwọ́! Dípò ìyẹn, gbìyànjú kó o bàa lè “rí ohun rere” nínú iṣẹ́ tó o bá fi ọwọ́ ara rẹ ṣe nítorí pé “ẹ̀bùn Ọlọ́run ni,” gẹ́gẹ́ bí Oníwàásù 3:13 ṣe sọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]

Kíkọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ti mú kí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lè ṣe iṣẹ́ ìsìn tó pọ̀ sí i fún Ọlọ́run

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ ló wà táwọn òbí ẹ lè kọ́ ẹ