Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mìmì Ti Ń Mi Àwọn Òkè Báyìí O

Mìmì Ti Ń Mi Àwọn Òkè Báyìí O

Mìmì Ti Ń Mi Àwọn Òkè Báyìí O

“Gbogbo wa la máa jàǹfààní ẹ̀ tá a bá tọ́jú àwọn ibi tí òkè wà débi tí àwọn ìran tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú á fi lè gbádùn àwọn àlùmọ́ọ́nì tó wà nínú wọn.”—KOFI ANNAN, Ọ̀GÁ ÀGBÀ ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ LÓ SỌ BẸ́Ẹ̀.

TÓ O bá ń ronú nípa òkè, wàá máa ṣe tótó fùn-ún-ùn, wàá rò pé mìmì kan ò lè mì ín wàá sì máa rò pé agbara tó kọjá agbára ń bẹ lórí ẹ̀. Ǹjẹ́ ohun kan lè wu àwọn òkè yìí léwu? Àwọn kan ò lè tètè gbà gbọ́ pé ewukéwu lè máa wu àwọn òkè tó wà láyé yìí. Ṣùgbọ́n òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé mìmì ti n mi òkè báyìí o. Àwọn tó ń jà fún ààbò ohun alààyè ṣàlàyé àwọn nǹkan kan tó ń fa ìṣòro tó ń ṣàkóbá fáwọn ohun alààyè tó ń gbé lórí òkè. Gbogbo ìṣòro wọ̀nyí ló lágbára, wọ́n sì ń gogò sí i ni. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìṣòro ọ̀hún.

IṢẸ́ SỌGBÓDILÉ, SỌ̀GBẸ́DÌGBORO. Nǹkan bí ìdámẹ́rin àwọn òkè tó wà láyé ló ti wà nínú ewu báyìí nítorí ọ̀nà lílà, ìwakùsà, gbígbé páìpù gba inú ilẹ̀, gbígbẹ́ adágún síbẹ̀, àtàwọn iṣẹ́ sọgbódilé, sọ̀gbẹ́dìgboro mìíràn tí wọ́n ń gbèrò àtiṣe ní bí ọgbọ̀n ọdún sí àsìkò yìí. Bí wọ́n bá la ọ̀nà, ó lè mú kí ọ̀gbàrá máa wọ́ ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ọ̀nà tí wọ́n sì là yí lè jẹ́ kí àwọn agégẹdú ríbi dé orí òkè, tí wọ́n bá sì fi débẹ̀, itú burúkú ni wọ́n máa ń pa. Kùsà táwọn awakùsà ń wà jáde lọ́dún tó èyí tí nǹkan bíi bílíọ̀nù kan àbọ̀ mọ́tò akóyọyọ lè kó, púpọ̀ nínú ẹ̀ ni wọ́n sì ń wà jáde lórí òkè. Èyí tí wọ́n sì fi ń ṣòfò lára ẹ̀ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. a

BÍ AYÉ ṢE Ń MÓORU. Àjọ Worldwatch Institute tó ń ṣèwádìí sọ pé: “Láàárín ọdún 1990 sí ìsinsìnyí la ti rí ọdún mẹ́wàá tó wà lákọọ́lẹ̀ pé ayé tíì gbóná jù.” Àwọn tó ń gbé lórí òkè ló sì máa ń jẹ̀rán ẹ̀ jù lọ. Àwọn òkìtì yìnyín ti ń yọ́, àwọn yìnyín tó máa ń dì sórí òkè sì ti ń dín kù. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí lè mú kí omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀ pọ̀ jù, ó sì lè mú kí àwọn òkè máa ya lulẹ̀. Ọ̀pọ̀ adágún omi oníyìnyín tó wà lórí àwọn òkè Himalaya ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ya bo bèbè wọn báyìí, èyí ló sì ń fa omíyalé tó ń ṣẹlẹ̀ léraléra lẹ́nu bí ọgbọ̀n sí ogójì ọdún báyìí.

IṢẸ́ ÀGBẸ̀ ALÁBỌ́DÉ. Bí èrò ṣe ń pọ̀ sí i láyé báyìí, ó ti di dandan fáwọn èèyàn láti máa lọ dáko sórí àwọn ilẹ̀ tí kò ṣeé dáko. Ìwádìí kan fi hàn pé ní Áfíríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì ilẹ̀ tó wà lórí òkè tí wọ́n fi ń dáko tàbí tí wọ́n lọ ń fi ẹran jẹko níbẹ̀. Ìdá mẹ́wàá ilẹ̀ yìí ni wọ́n gbin nǹkan sí, wọ́n sì ń daran lórí ìdá mẹ́ta ààbọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà ni wọn kì í rí èrè lórí ohun tí wọ́n gbìn nítorí pé orí òkè ò fi bẹ́ẹ̀ dáa fún dídáko. b Tí wọ́n bá ti ń daran lọ sórí òkè jù ó lè ṣàkóbá fáwọn irúgbìn tí ò rọ́kú tó ń hù níbẹ̀. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé nǹkan bí ìdá mẹ́ta péré nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ilẹ̀ tó wà lórí òkè ló ṣeé gbin nǹkan sí láìsí ìṣòro.

OGUN. Bí ogun ṣe ń jà níwá lẹ́yìn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ń ṣàkóbá ńláǹlà fún ọ̀pọ̀ òkè àti àyíká wọn. Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ máa ń fi orí òkè ṣe ibùba, níbi tí wọ́n á ti máa ṣètò gbogbo itú tí wọ́n bá fẹ́ pa. Ìṣirò kan tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe fi hàn pé tá a ba pín gbogbo òkè tó wà láyé sí ọ̀nà ọgọ́rùn-ún, ìdá mẹ́tàdínláàádọ́ta nínú wọn ni “rògbòdìyàn àárín àwọn èèyàn” ń ṣe lọ́ṣẹ́. Láfikún sí i, àwọn òkè kan wà tí wọ́n ti di ibi tí àwọn tó ń ṣe oògùn olóró ń fara pamọ́ sí, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni wọ́n máa ń fìjà pẹẹ́ta níbẹ̀, èyí sì máa ń ba àyíká ibẹ̀ jẹ́.

Kí Ló Tún Kù Ní Ṣíṣe?

Ní báyìí, aráyé ti ń mọ báwọn èèyàn ṣe ń ba àwọn òkè jẹ́ lára. Díẹ̀ nínú àwọn àmì tá a fi lè mọ̀ pé ewu ń bẹ ni omíyalé, ìyalulẹ̀ òkè, àti ọ̀dá omi tó máa ń ṣẹlẹ̀. Àwọn ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ sí fojú ara wọn rí i. Wọ́n ti ń tún igi gbìn wọ́n sì ń fòfin de igi gígé láwọn ibì kan. Ìjọba ti sọ àwọn ibì kan di ọgbà ìtura kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn ibi tó jojú ní gbèsè jù lọ láyé àti ibùgbé àwọn ẹranko tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ run tán.

Kódà, àwọn ibi tí wọ́n dáàbò bò yìí náà ò bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ òkè. (Wo àpótí náà, “Díẹ̀ Lára Àwọn Ọgbà Tí Wọ́n Ń Tọ́jú Àwọn Nǹkan Alààyè Sí.”) Báwọn ohun alààyè ṣe ń pòórá báyìí fi hàn pé ìlàkàkà àwọn èèyàn láti dáàbò bo àwọn ohun alààyè tó ń bu ẹwà kún orí òkè kò tíì bọ́ sójú ẹ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti mọ àwọn ìṣòro yìí, síbẹ̀ wọn ò tíì pawọ́ pọ̀ ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti lè dáàbò bo àwọn ibi tí kò tíì bà jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. Ìlúmọ̀ọ́ká onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kan tó mọ̀ nípa ohun alààyè, E. O. Wilson sọ pé: “Ó máa ń yá mi lórí tí mo bá rí ibi tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ wa pọ̀ dé, àmọ́ ó tún máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́ bí mo bá rí báwọn èèyàn ṣe ń ba ibi tó kù tí oríṣiríṣi àwọn ohun alààyè wà jẹ́.”

Ṣé kò yẹ kó ká wa lára bí ẹranko àti oríṣiríṣi irúgbìn ṣe ń dàwátì báyìí ni? Ọ̀pọ̀ onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tó mọ̀ nípa ohun alààyè ló sọ pé ọmọ aráyé á jàǹfààní gan-an tá a bá lè bójú tó oríṣiríṣi ohun alààyè tó wà láyé. Wọ́n tọ́ka sí òdòdó rosy periwinkle tó wà láwọn ilẹ̀ olókè ní orílẹ̀-èdè Madagascar, níbi tí oríṣiríṣi ewéko àti ẹranko pọ̀ sí. Wọ́n máa ń fi irúgbìn yìí ṣe oògùn pàtàkì kan tí wọ́n ń lò sí àrùn sẹ̀jẹ̀ domi. Yàtọ̀ síyẹn, àìmọye ọdún ni wọ́n ti ń lo igi cinchona, tó wà lórí àwọn òkè Àríwá Amẹ́ríkà láti ṣe oríṣiríṣi oògùn ibà. Ọ̀pọ̀ àwọn irúgbìn míì tó ń hù lórí àwọn òkè ló ti gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn là. A mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti gbin àwọn kan nínú irúgbìn yìí sáwọn ibi tí kò sí òkè, tá á sì hù dáadáa o. Àmọ́, ohun tó ń kọni lóminú ni pé báwọn èèyàn ṣe ń ba irúgbìn tó wà lórí òkè jẹ́ yìí, wọ́n lè ṣèèṣì pa àwọn èyí tí wọn ò tíì mọ̀ pé ó lè wúlò fún oògùn àti oúnjẹ run.

Ǹjẹ́ a lè dáwọ́ àwọn nǹkan tó ń ba orí òkè jẹ́ dúró? Ṣé àwọn ohun tí wọ́n ti bà jẹ́ níbẹ̀ lè ṣeé tún ṣe? Ṣé a ó ṣì máa rí oríṣiríṣi òdòdó àti irúgbìn tó rẹwà, tí ò sì wọ́pọ̀ mọ́, lórí òkè báyìí?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kí wọ́n tó lè ṣe òrùka góòlù kan, wọ́n sábà máa ń fi kùsà tó pọ̀ tó ìlàjì ọkọ̀ akóyọyọ ṣòfò.

b Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn tó ń gbé orí òkè ti mọ ọgbọ́n tí wọ́n fi ń dáko níbẹ̀ láìba àyíká ibẹ̀ jẹ́.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn Ẹranko Tó Ń Gbé Lórí Òkè

Orí òkè ni wọ́n ti sábà máa ń rí kìnnìún orí òkè, tí wọ́n ń pè ní puma, àfi bíi pé orúkọ ń rò ó. Orí àwọn òkè tó tò lọ bẹẹrẹbẹ ní Gúúsù Amẹ́ríkà ló pọ̀ sí. Bí ọ̀pọ̀ ẹranko apẹranjẹ ńlá míì, àwọn náà ti ń fara pamọ́ síbi tí ò ṣeé dé nítorí báwọn èèyàn ṣe ń dọdẹ wọn.

Orí àwọn òkè Himalaya nìkan ni ẹranko panda pupa tó dà bí ológbò ń gbé (kódà a lè rí i ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Everest, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òkè Himalaya). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tó ń gbé jìnnà sáwọn èèyàn, síbẹ̀ ayé ò rọrùn fún ẹranko yìí látàrí bí wọ́n ṣe ń run àwọn igi ọparun, nítorí pé ewé igi ọparun ló máa ń jẹ.

[Credit Line]

Cortesía del Zoo de la Casa de Campo, Madrid

Ìgbà kan wà tí béárì aláwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú máa ń jẹ̀ dé apá ibi tó pọ̀ jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù, Éṣíà, àti Àríwá Amẹ́ríkà. Báyìí nílẹ̀ Yúróòpù, àwọn ibi tá a ti lè rí i ò ju orí àwọn òkè tó jìnnà sí ibi táwọn èèyàn ń lò sí. Àmọ́ ṣá, ó ṣì pọ̀ díẹ̀ láwọn òkè tó wà ní Kánádà, Alaska, àti Siberia. Iye wọn tó kù sílẹ̀ Amẹ́ríkà báyìí ò ju ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún iye wọn tó wà ní ọ̀rúndún tó kọjá.

Àṣá aláwọ̀ wúrà ni ọba gbogbo àwọn ẹyẹ orí òkè tó wà jákèjádò Àríwá Ìlàjì Ayé. Àmọ́ ṣá, kò dùn ún gbọ́ sétí pé iye takọtabo wọn tó kù sílẹ̀ Yúróòpù kò tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún mọ́ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan táwọn èèyàn ń kà á sí ‘ẹyẹkẹ́yẹ àti àsọ̀kòpa.’

Ẹranko panda ńlá tó dà bíi béárì “ò lè wà láàyè láìsí ohun pàtàkì mẹ́ta kan,” bí Tang Xiyang, ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà tó jẹ́ olùṣèwádìí nípa àwọn ohun àdánidá ṣe sọ. Àwọn nǹkan mẹ́ta ọ̀hún ni “òkè gàgàrà òun àfonífojì jìndunjìndun, igbó ọparun, àti odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́.” Ìṣirò kan fi hàn pé iye ẹranko yìí tó kù sínú aginjù ò tó ẹgbẹ̀jọ [1,600].

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Díẹ̀ Lára Àwọn Ọgbà Tí Wọ́n Ń Tọ́jú Àwọn Nǹkan Alààyè Sí

Ọgbà Ìtura Yosemite (tó wà ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà) jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Ọdún 1890 ni John Muir, olùṣèwádìí nípa àwọn ohun àdánidá forí ṣe fọrùn ṣe láti kọ́ ọgbà ìtura yìí. Mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn ló máa ń ṣèbẹ̀wò síbi ìgbafẹ́ rírẹwà yìí lọ́dún. Àmọ́ àwọn alábòójútó ibi ìgbafẹ́ náà ní láti múra dáadáa kó máa bàa di pé bí ibẹ̀ ṣe jẹ́ ibi ìgbafẹ́ fáwọn tó fẹ́ fójú lóúnjẹ á ṣàkóbá fún ọgbà tí wọ́n láwọn ń dáàbò bò.

Ọgbà Ìtura Podocarpus (tó wà lórílẹ̀-èdè Ecuador) tún jẹ́ òmíràn. Igbó kan wà tí wọ́n dáàbò bò lórí òkè gíga fíofío nínú ọgbà yìí. Oríṣiríṣi ẹran ìgbẹ́ àtàwọn ewéko ló wà nínú igbó yìí. Oríṣiríṣi ẹyẹ tó wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀ta [600], nǹkan bí ẹgbàajì irúgbìn [4,000] ló sì wà níbẹ̀. Ibí yìí ni wọ́n ti kọ́kọ́ rí oògùn quinine tó ti gba ẹ̀mí ẹgbàágbèje èèyàn là. Bí ọ̀pọ̀ ọgbà ìtura míì, ńṣe ni wọ́n ń gégi níbẹ̀ ní àgéèdábọ̀, tí wọ́n ń pẹran, tí wọ́n sì tún ń dẹdò níbẹ̀ láìgbàṣẹ.

Òkè Kilimanjaro (tó wà lórílẹ̀-èdè Tanzania) wà lára àwọn òkè ayọnáyèéfín tó gbilẹ̀ jù lọ, òun náà ló sì ga jù nílẹ̀ Áfíríkà. Awọn erin máa ń jẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè yìí táwọn òdòdó ńlá bíi lobelia àti groundsel sì máa ń hù ní téńté orí òkè níbẹ̀. Dídẹ̀gbẹ́ láìgbàṣẹ, pípagbórun, àti dídaran níbẹ̀ ni olórí ohun tó ń dá wàhálà sílẹ̀ níbẹ̀.

Ọgbà Ìtura Teide (tó wà ní Erékùṣù Canary). Tí kì í bá ṣe ti irúgbìn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó ṣì ń bu ẹwà kún àwọn òkè ayọnáyèéfín tó wà nínú ọgbà yìí, ibẹ̀ ì bá ti dahoro. Àwọn ohun abẹ̀mí tó wà lórí àwọn òkè ayọnáyèéfín tó bá dá dúró kì í sábà lágbára tó bẹ́ẹ̀, débi pé tí wọ́n bá mú oríṣi àwọn irúgbìn míì débẹ̀, ó lè kó bá àwọn tó ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Àwọn ọgbà ìtura Pyrenees àti Ordesa (tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Faransé àti Sípéènì) ń dààbò bo àwọn ohun mèremère tó fi mọ́ àwọn irúgbìn àti ẹran ìgbẹ́ lórí àwọn òkè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Ohun tójú àwọn òkè míì tó wà nílẹ̀ Yúróòpù ń rí lojú tiẹ̀ náà ń rí. Ńṣe làwọn tó máa ń ṣeré yíyọ̀ tẹ̀rẹ́ lórí yìnyín sọ ibí di pápá ìṣeré wọn, bákan náà sì ni tàwọn tó ń wá wòran níbẹ̀. Ohun míì tó tún ń kó bá àgbègbè yẹn ni báwọn èèyàn ò ṣe ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ báwọn aṣáájú wọn ṣe ṣe é mọ́.

Ọgbà Ìtura Sǒraksan ló gbajúmọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè Korea. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn akọ òkúta tó wà níbẹ̀ àti igbó tó hù sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń dùn ún wò gan-an ni. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé bó bá ti ń di òpin ọ̀sẹ̀ báyìí, ńṣe làwọn èèyàn á máa wọ́ lọ wọ́ bọ̀ níbẹ̀. Kódà àwọn ojú ọ̀nà kan nínú ọgbà yìí máa ń kún bí ojú ọ̀nà àárín ìgboro ni.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn Irúgbìn Tó Wà Lórí Òkè

Òdòdó tower of jewels. Láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, òdòdó ẹlẹ́wà yìí máa ń ga tó èèyàn. Èèyàn lè rí i níbi tó ga bí ẹgbẹ̀sán [1,800] mítà, tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà, láwọn òkè ayọnọ́yèèfín méjì péré ní Erékùṣù Canary. Ọ̀pọ̀ ìrú òdòdó yìí míì wà tó lójú irú àwọn òkè tí wọ́n ti lè hù.

Òṣùṣú carline máa ń hù lórí òkè tó wà láàárín ilẹ̀ Faransé àti Ítálì àti orí òkè tó wà láàárín ilẹ̀ Faransé àti ilẹ̀ Sípéènì. Bó ṣe máa ń tàn yanranyanran máa ń bu ẹwà kún àwọn koríko pápá nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, èyí sì ń mú kí ọbẹ̀ sọ̀ fáwọn kòkòrò.

Òdòdó English iris. Bí wọ́n bá gbin oríṣiríṣi òdòdó igbó rírẹwà yìí pọ̀, ńṣe ló máa ń hù bí igi tó wà nínú ọgbà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn òdòdó tí wọ́n máa ń gbìn sínú ọgbà ni wọ́n ń rí látinú igbó orí òkè.

Òdòdó houseleek orí òkè wà lára àwọn irúgbìn tó lè hù sáàárín àpáta tó bá sán lórí òkè. Orí àwọn òkè tó wà ní gúúsù Yúróòpù ló ti ń hù, wọ́n sì tún máa ń pè é ní gbékúdè nítorí bó ṣe rọ́kú tó sì máa ń pẹ́ láyé.

Òdòdó bromeliad. Oríṣiríṣi àwọn òdòdó bromeliad àti orchid ló ń hù láwọn òkè gíga fíofío tó wà láwọn Ilẹ̀ Olóoru, ní agbedeméjì ayé. Wọ́n máa ń hù níbi tó ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àbọ̀ mítà, ìyẹn ẹgbẹ̀rún-ún mẹ́rìnlá àbọ̀ ẹsẹ̀ bàtà.

Orí òkè Er Rif tó wà lórílẹ̀-èdè Mòrókò àtàwọn òkè Atlas tó wà ní ìhà àríwá Áfíríkà ni òdòdó kan tó ń jẹ́ algerian iris ti máa ń hù. Ibí yìí ni wọ́n gbà pé àwọn irúgbìn tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ run tán ní àgbègbè Mẹditaréníà kù sí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Bí wọ́n ṣe ń wa bàbà àti góòlù lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Òkè Maoke, lórílẹ̀-èdè Indonesia

[Credit Line]

© Àwòrán tí Rob Huibers/Panos yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Òdòdó “Rosy periwinkle”