Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sún Mọ́ Ẹlẹ́dàá

Sún Mọ́ Ẹlẹ́dàá

Sún Mọ́ Ẹlẹ́dàá

Lẹ́yìn tí obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, ó kọ̀wé ránṣẹ́. Ó sọ nínú ìwé náà pé: “Mo ní kí n sọ fún yín bí ìgbésí ayé mi ṣe lárinrin tó àti bí mo ṣe túbọ̀ sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run lẹ́yìn tí mo ka ìwé yìí tí mo sì ṣàṣàrò lórí ohun tí mo kà nínú rẹ̀. Ìsinsìnyí gan-an ni mo tó lè sọ pé ọ̀rẹ́ mi ni Jèhófà. Ìwé àkọ́kọ́ rèé tó mú kí n rẹ́rìn-ín ayọ̀, tó mú kí omijé yọ lójú mi, tó mú kí n máa ronú lórí ohun tí mo kà tìyanutìyanu, kí n sì gbàdúrà sí Jèhófà lójú ẹsẹ̀ tí mo kà á tán. Mo wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an báyìí, mo sì mọ̀ pé ìwé yìí wà lára ohun tó jẹ́ kí ìfẹ́ Jèhófà wọ̀ mí lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀.”

Ó dá wa lójú pé bí ìwọ náà bá ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, olójú ewé 320 yìí yóò ṣe ọ́ láǹfààní. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lókè yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.