Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Máa Gba Àwọn Òkè Lọ́wọ́ Ewu?

Ta Ló Máa Gba Àwọn Òkè Lọ́wọ́ Ewu?

Ta Ló Máa Gba Àwọn Òkè Lọ́wọ́ Ewu?

FÚN ọjọ́ mẹ́rin gbáko ni ìlú Bishkek lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan (ní àárín gbùngbùn Éṣíà) fi gbàlejò àwọn tó wá ṣe Ìpàdé Àpérò Kárí Ayé Lórí Ọ̀ràn Òkè lọ́dún 2002. Ìpàdé yìí ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí wọ́n á fi jíròrò àwọn ọ̀ràn tó kan òkè. Àwọn tó ṣagbátẹrù ìpàdé náà nírètí pé ọdún 2002 ló máa jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀ sáà tuntun nínú èyí tí wọ́n á ti máa kíyè sáwọn àǹfààní tá a lè rí lórí òkè.”

Àwọn tó wá síbi ìpàdé pàtàkì yìí fìmọ̀ ṣọ̀kan láti fọwọ́ sí ohun tí wọ́n pè ní “Ìlànà Orí Òkè Ti Ìlú Bishkek,” ìyẹn òfin tó sọ bí gbogbo èèyàn á ṣe máa ṣètọ́jú òkè. Èròǹgbà wọn ni láti “mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ rọrùn fáwọn tó ń gbé orí òkè, láti dáàbò bo àwọn ohun alààyè tó wà níbẹ̀ àti láti lo àwọn àlùmọ́ọ́nì tó wà lórí òkè bó ṣe yẹ kí wọ́n lò ó.”

Wọ́n ti báṣẹ́ débì kan lórí ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọgbà ìtura tí wọ́n dá sílẹ̀ kárí ayé ń dáàbò bo àwọn àgbègbè tó lẹ́wà tí onírúurú irúgbìn àtàwọn ẹranko sì wà níbẹ̀. Lápá ibi tó pọ̀ láyé, àwọn ẹgbẹ́ tó ń jà fún dídáàbò bo àyíká ti jà fitafita láti mú káwọn èèyàn dẹ́kun bíba àyíká jẹ́, a sì lè rí i pé iṣẹ́ wọn ń yọ díẹ̀díẹ̀. Ọ̀kan lára àbájáde ìpàdé àpérò kárí ayé, lórí ọ̀ràn òkè èyí tí wọ́n ṣe ní ìlú Bishkek ni àdéhùn tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí wọ́n ṣe láti rí sí i pé àwọn á palẹ̀ gbogbo ìtànṣán olóró tí wọ́n ti tú dà sórí àwọn òkè lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan mọ́. Èròjà onímájèlé tí wọ́n tú síbẹ̀ yẹn lè ṣàkóbá fún omi tí ìdá márùn-ún àwọn tó ń gbé ní ìhà àárín gbùngbùn Éṣíà ń lò.

Síbẹ̀, àwọn ìṣòro tó wà nídìí dídáàbò bo orí òkè ṣì kọjá ohun téèyàn lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1995, ìjọba orílẹ̀-èdè Kánádà gbé “Ìlànà Lórí Igi Gígé” kalẹ̀ láti dáàbò bo àwọn igbó tó kù ní àgbègbè British Columbia. Síbẹ̀, ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé àwọn ilé iṣẹ́ agégẹdú ò tẹ̀ lé ìlànà yìí, ṣe ni wọ́n ń gégi lọ bẹẹrẹbẹ ní tiwọn, kódà wọ́n ń gé igi láwọn ibi tó ṣe gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ jù lọ lórí òkè. Wọ́n tiẹ̀ dẹwọ́ òfin náà díẹ̀ lọ́dún 1997 nítorí pé àwọn iléeṣẹ́ agégẹdú sọ pé ó ti le jù.

Ọ̀rọ̀ ìṣòwò nìkan kọ́ ló wà nídìí ìṣòro yìí o. Kókó tó gbẹ̀yìn ìpinnu tí wọ́n ṣe nínú ìpàdé tó wáyé ní ìlú Bishkek fi hàn pé ogun, ìṣẹ́, àti ebi wà lára àwọn nǹkan tó ń fa àrágbáyamúyamù ìṣòro tó ń rọ́ lu àwọn ohun alààyè tó wà lórí òkè wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Ó dìgbà táwọn ohun tó ń kó àwọn ìṣòro yìí bá àyíká kò bá sí mọ́ kí orí òkè àti apá yòókù láyé tó bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú yìí.

Ọlọ́run Ò Kúkú Gbàgbé Iṣẹ́ Ọwọ́ Rẹ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí yìí kò fini lọ́kàn balẹ̀, a ní ìdí láti máa retí pé nǹkan ṣì máa dáa lọ́jọ́ iwájú. Ọlọ́run Olódùmarè ò ṣàì rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Bíbélì pè é ní Ẹni “tí àwọn téńté òkè ńláńlá jẹ́ tirẹ̀.” (Sáàmù 95:4) Ó sì tún fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹranko tó ń gbé láwọn orí òkè náà sọ́kàn. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 50:10, 11 ṣe sọ, Jèhófà sọ pé: “Tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó, àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá. Èmi mọ olúkúlùkù ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń bẹ lórí àwọn òkè ńlá ní àmọ̀dunjú, ògídímèje àwọn ẹran pápá gbalasa sì ń bẹ pẹ̀lú mi.”

Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ mọ̀nà tó máa gbà yanjú àwọn ìṣòro tó ń dààmú àyíká? Bẹ̀ẹ́ ni, ó mọ̀ ọ́n! Bíbélì sọ pé ó ti “gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Jèsú Kristi, ẹni tí Jèhófà ti yàn láti jẹ́ Alákòóso Ìjọba ọ̀run yìí nífẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ayé púpọ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn tá a wà nínú rẹ̀ gan-an ni. (Òwe 8:31) Ìjọba rẹ̀ yóò mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ ayé yóò sì fòpin sí gbogbo bíbà táwọn èèyàn ń ba ayé jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa tún gbogbo ohun tó ti bà jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ṣe.—Ìṣípayá 11:18.

Tó o bá fẹ́ fojú rẹ rí ìgbà tí ọ̀ràn máa rí báyìí, ó dájú pé wàá máa gbàdúrà níṣò pé kí ‘ìjọba Ọlọ́run dé.’ (Mátíù 6:9, 10) Ọlọ́run ò sì ní ṣaláì gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo àìṣedéédéé tó wà láyé yìí yóò sì tún gbogbo ohun tó bà jẹ́ láyé ṣe. Nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ńṣe lá á dà bíi pé àwọn òkè ńlá lápapọ̀ ń “fi ìdùnnú ké jáde.”—Sáàmù 98:8.