Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wàhálà Tó Ń Báwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Fínra

Wàhálà Tó Ń Báwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Fínra

Wàhálà Tó Ń Báwọn Ọ̀dọ́ Òde Ìwòyí Fínra

KÁ TIẸ̀ sọ pé ilé ọlá ni wọ́n bí èèyàn sí, ó dájú pé ìgbà ìbàlágà ṣì lè fì í lògbòlògbò. Báwọn ọ̀dọ́ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, èrò wọn kì í dúró sójú kan, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n sì máa ń rò lọ́kàn. Lójoojúmọ́ làwọn olùkọ́ á máa daṣẹ́ bò wọ́n, àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn á sì máa yọ wọ́n lẹ́nu. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n, sinimá àti Íńtánẹ́ẹ̀tì, àti orin tí wọ́n ń gbọ́ sì máa ń ṣe ipa tiwọn náà. Ìyẹn ni ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi ṣàpèjúwe ìgbà ìbàlágà gẹ́gẹ́ bí “àkókò tí ìyípadà máa ń wáyé, tí pákáǹleke àti àníyàn sì máa ń bá ìyípadà náà rìn.”

Ibi tọ́ràn náà wá burú sí ni pé àwọn ọ̀dọ́ ò tíì ní ìrírí tí wọ́n fi lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe bí wọ́n bá kó sí ìṣòro tí nǹkan ò fi ní bu wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 1:4) Báwọn ọ̀dọ́ ò bá rẹ́ni tọ́ wọn sọ́nà, wọ́n lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí hùwà tó lè pa wọ́n lára. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Ìwádìí ti fi hàn pé nígbà tí ọ̀pọ̀ bá wà ní ọ̀dọ́ ni wọ́n ti máa ń bẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn olóró.” Ìgbà yìí náà ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ sí hu àwọn ìwàkiwà míì bí ìwà ipá àti ìṣekúṣe.

Àṣìṣe ló sábà máa ń jẹ́ báwọn òbí kan bá rò pé láàárín àwọn “òtòṣì” nìkan nirú ẹ̀ ti lè ṣẹlẹ̀, tàbí pé ó láwọn ẹ̀yà kan tírú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kárí ayé ni ìṣòro tó ń kojú àwọn ọ̀dọ́ lóde ìwòyí. Kò yọ olówó sílẹ̀; ó kan òtòṣì, ó kan àgbà àtèwe, kò sì yọ ẹ̀yà kankan sílẹ̀. Òǹkọ̀wé Scott Walter tiẹ̀ sọ pé: “Bá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ‘ìwà ìpáǹle àwọn ọ̀dọ́,’ bó o bá rò pé ẹni tó lè ya ìpáǹle ni ọmọdékùnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó tinú ẹ̀yà míì wá, tó ń gbé níbi tí nǹkan ti le láàárín ìlú, tí ìyá ẹ̀ sì ń táwọ́ ná, a jẹ́ pé àgbọ̀nrín èṣí lo ṣì ń jẹ lọ́bẹ̀. . . . Bá a bá wo àwọn ọ̀dọ́ tó ń kó sí ìṣòro lóde òní, a lè rí òyìnbó nínú wọn, a lè rí ẹni tó ń gbé inú ilé alábọ́ọ́dé tàbí ẹni tó ń gbé nínú ilé ọlá, òmíràn sì lè máà tíì tó ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (rárá), ó sì lè jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin.”

Àmọ́, kí ló fà á tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń kó sí ìṣòro? Ṣebí àwọn ọ̀dọ́ àtijọ́ náà dojú kọ ìṣòro àtàwọn ìdẹwò mìíràn. Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni Bíbélì pe ìgbà tiwa yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Pákáǹleke àtàwọn ìṣòro míì táwọn ọ̀dọ́ ń kó sí lákòókò tá à ń gbé yìí yàtọ̀ pátápátá. Ẹ jẹ́ ká yẹ díẹ̀ wò lára wọn.

Inú Ilé Ti Yàtọ̀ sí Tàtijọ́

Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìyípadà tó ti bá bí nǹkan ṣe máa ń rí nínú ilé. Ìwé ìròyìn Journal of Instructional Psychology sọ pé: “Ó ju ìdámẹ́ta lọ lára àwọn ọmọdé tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà táwọn òbí wọn máa ń kọra wọn sílẹ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún.” Bí ọ̀ràn ṣe rí náà nìyẹn láwọn orílẹ̀-èdè míì ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Gbàrà tí ìgbéyàwó àwọn òbí wọn bá sì ti tú ká báyìí, ó di káwọn ọ̀dọ́ máa fàyà rán ìdààmú ọkàn nìyẹn. Ìwé ìròyìn náà wá fi kún un pé: “Nǹkan sì sábà máa ń nira fáwọn ọmọ tí òbí wọn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọra sílẹ̀. Wọ́n lè máa jó àjórẹ̀yìn nílé ìwé kó sì ṣòro fún wọn láti bá àwọn ẹlòmíì da nǹkan pọ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kì í rí bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọ míì tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú bàbá àti ìyá wọn, tàbí àwọn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń gbé pẹ̀lú òbí kan ṣoṣo, tàbí àwọn tó ń gbé nínú ìdílé tí bàbá tàbí ìyá wọn ti fẹ́ ẹlòmíì. . . . Òmíràn sì tún ni pé báwọn òbí bá kọra wọn sílẹ̀, ó sábà máa ń mú kí ọmọ máa rò pé nǹkan ń ṣe òun ni, kò sì ní ka ara ẹ̀ sí mọ́.”

Yíyà tí ọ̀pọ̀ obìnrin ń yà lọ sídìí iṣẹ́ wà lára ohun tí ò jẹ́ kí ìdílé rí bíi tàtijọ́ mọ́. Ìwádìí kan tó dá lórí ìwà ìpáǹle àwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè Japan tún ti jẹ́ ká mọ̀ pé nínú ìdílé tí bàbá àti ìyá bá ti ń ṣiṣẹ́, ó máa ń nira gan-an láti tọ́jú àwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n nínú ìdílé tí òbí kan ti máa ń wà nílé bí èkejì bá gba ibi iṣẹ́ lọ, kì í rí bẹ́ẹ̀.

Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ìdílé ló wà tí wọ́n nílò owó oṣù ti bàbá àti ti ìyá kí awọ tó lè kájú ìlù. Owó oṣù tó ń wọlé lọ́nà méjèèjì yìí tún lè mú káyé dẹrùn sí i fáwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n ìyẹn náà ní àléébù tiẹ̀. Àléébù ọ̀hún ni pé nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé bá darí láti ilé ìwé, ńṣe ní ilé máa ń dá. Nígbà táwọn òbí bá sì dé, ó ti máa ń rẹ̀ wọ́n jù, wàhálà tibi iṣẹ́ ni wọ́n sì máa kó léyà. Kí nìyẹn wá ń yọrí sí o? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lòbí ò rójú gbọ́ tiwọn mọ́. Ọ̀rọ̀ náà dun ọ̀dọ́ kan, ó sọ pé: “Nǹkan kan kì í dà wá pọ̀ nínú ilé wa.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tó rí bí nǹkan ṣe ń lọ sí ń ronú pé bí nǹkan ṣe ń lọ yìí kò ní dáa fọ́jọ́ iwájú àwọn ọmọdé. Dókítà Robert Shaw sọ pé: “Mo gbà pé ọwọ́ táwọn òbí fi ń mú àwọn ọmọ wọn láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ti sọ wọ́n di adánìkànjẹ̀, ẹni tó máa ń wò suu, tó máa ń nira fún láti kẹ́kọ̀ọ́, tí kì í ṣì í ṣeé darí. Bí nǹkan ṣe ń lọ sí láwùjọ ló ń fipá mú káwọn èèyàn máa fẹ́ kó ohun ìní tara jọ, ohun ló sì ń mú kí wọ́n fẹ́ máa fi gọ̀gọ̀ fa ohun tọ́wọ́ wọn ò tó. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí wọ́n fi ń fi wákàtí rẹpẹtẹ ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń gbowó tó pọ̀ tí wọn ò sì wá ráyé ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe káwọn àtàwọn ọmọ bàa lè mọwọ́ ara wọn dáadáa.”

Ohun mìíràn wà tó tún máa ń fa ìṣòro fáwọn ọ̀dọ́. Ìyẹn ni pé bí àwọn òbí bá ń ṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ wọn sábà máa ń wà láyè ara wọn, láìsí ẹni tó ń yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò. Bí ọmọ ò bá sì ní oníbàáwí, ìjàngbọ̀n ń bọ̀ nìyẹn.

Ìyàtọ̀ Ti Bá Ojú Táwọn Èèyàn Fi Ń Wo Ìbáwí

Ìyàtọ̀ tó ń bá ojú táwọn èèyàn fi ń wo báwọn òbí ṣe ń bá ọmọ wí náà tún wà lára ohun tó ń fa ìṣòro fáwọn ọ̀dọ́ òdé ìwòyí. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé Ron Taffel ṣe sọ láìṣẹ́nupo, ọ̀pọ̀ òbí ló ti “gbé àṣẹ tí wọ́n ní gẹ́gẹ́ bí òbí tà.” Bọ́rọ̀ bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ìlànà díẹ̀ ló kù tá a máa darí báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń hùwà, tàbí kó tiẹ̀ máà sí ìlànà kankan tó ń darí ohun tí wọ́n ń ṣe.

Nígbà míì sì rèé, ó máa ń dà bíi pé ńṣe làwọn òbí ò fẹ́ káwọn ọmọ wọn jẹ irú ìyà tí wọ́n jẹ nígbà tí wọ́n wà ní kékeré. Wọ́n á kàn fẹ́ láti máa fọwọ́ pa àwọn ọmọ wọn lórí ni, wọ́n ò ní fẹ́ máa bá wọn wí. Ìyá kan sọ pé: “Mo kẹ́ ọmọ mi lákẹ̀ẹ́bàjẹ́. Àwọn òbí mi ò gbàgbàkugbà ní tiwọn; ṣùgbọ́n mí ò fẹ́ le mọ́ ọmọ mi. Ibi tí mo sì ti kùnà gan-an nìyẹn.”

Ibo làwọn òbí kan ba àwọn ọmọ wọn jẹ́ dé nítorí pé wọn ò fẹ́ máa bá wọn wí? Ìwé ìròyìn USA Today, sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kan ń gba ìtọ́jú ní ìpínlẹ̀ New York, Texas, Florida àti California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nítorí pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má lo oògùn olóró. Ìwádìí tí wọ́n ṣe láàárín nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] nínú wọn fi hàn pé nǹkan bí ọgọ́fà lára wọn làwọn àtàwọn òbí wọn jọ máa ń lo oògùn olóró. Nígbà tó jẹ́ pé nǹkan bí ọgbọ̀n lára wọn ni màmá tàbí bàbá wọn kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa lo oògùn olóró, pàápàá igbó.” Kí ni ì báà sún òbí láti máa hu irú ìwà pálapàla bẹ́ẹ̀? Òbí kan jẹ́wọ́, ó sọ pé: “Mo sọ fún un pé kó kúkú máa lo oògun olóró nínú ilé níbi tí ojú mi á ti tó o.” Ó dà bíi pé àwọn kan rò pé lílo oògùn olóró jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà “di ọ̀rẹ́” ọmọ wọn.

Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ń Dá Kún Ìṣòro Àwọn Ọ̀dọ́

A ò tún ní ṣàì mẹ́nu ba ọṣẹ́ táwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń ṣe fáwọn ọ̀dọ́. Gẹ́gẹ́ bí olùṣèwádìí, Marita Moll, ṣe sọ ìwádìí kan fi hàn pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ó tó wákàtí mẹ́rin àti ìṣẹ́jú méjìdínláàádọ́ta lójúmọ́ táwọn ọ̀dọ́ máa ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n tàbí kọ̀ǹpútà.

Ṣé bẹ́ẹ̀ ló burú tó ni? Àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n gbé jáde nínú ìwé ìròyìn Science sọ pé “ajọ ètò ẹ̀kọ́ ńláńlá mẹ́fà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà,” tó fi mọ́ Ẹgbẹ́ Oníṣègùn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ti gbà pé ìwàkiwà táwọn ọmọ kan ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ń mú kí wọ́n ya garawa. Ìwé ìròyìn Science sọ pé: “Bó tilẹ jẹ́ pé àwọn ògbógi gbà pé bọ́ràn ṣe rí nìyí, ó dà bíi pé kò tíì yé àwọn aráàlú, láìka ohun tí wọ́n ń rí gbọ́ nínú ìròyìn sí, pé ìwàkiwà táwọn ọmọ ń wò lórí tẹlifiṣọ̀n ló sábà máa ń mú kí ìwà ipá pọ̀ sí i láwùjọ.”

Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo fídíò orin. Ńṣe lara àwọn òbí máa ń bù máṣọ bí wọ́n bá rí bí wọ́n ṣe ń fàwòrán ìṣekúṣe hàn níbẹ̀. Ṣé irú àwòrán bẹ́ẹ̀ lè mú káwọn ọ̀dọ́ máa hùwàkiwà? Ìwádìí kan tó dá lórí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àwọn ọmọ kọ́lẹ́ẹ̀jì fi hàn pé, “títẹ́tí sí ọ̀rọ̀ òrin oníwà ipá máa ń mú kéèyàn rèròkerò kó sì máa ṣe onítọ̀hún bíi kó hùwà ipá.” Ìwádìí míì tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí tún sọ pé, “àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń lo àkókò tó pọ̀ láti wòran ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá lórí fídíò orin onílù dídún kíkankíkan, èyí táwọn ọmọ ìta máa ń kọ. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lè hùwà ìbálòpọ̀ tàbí ìwà ipá bí àyè ẹ̀ bá yọ.” Ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọmọdébìnrin yìí fi hàn pé irú àwọn tó ń fàkókò gígùn wo fídíò orin àwọn ọmọọ̀ta yìí ló lè tètè yá lára pé kí wọ́n lu olùkọ́, irú wọn ló ṣeé ṣe kí ọlọ́pàá mú, irú wọn náà ló sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa níbàálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn.

Kí Ni Kọ̀ǹpútà Ń Ṣe Fáwọn Ọ̀dọ́?

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, kọ̀ǹpútà náà ti di ọ̀kan pàtàkì lára nǹkan tó ń darí ọkàn àwọn ọ̀dọ́. Ìwé ìròyìn Pediatrics sọ pé: “Kọ̀ǹpútà táwọn èèyàn ń rà sílé kàn ń pọ̀ sí i ni ṣáá lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Jákèjádò [ilẹ̀ Amẹ́ríkà], ní gbogbo ilé mẹ́tà táwọn ọmọ tó ń relé ìwé wà (ìyẹn àwọn ọmọ ọdún mẹ́fà sí mẹ́tàdìnlógún), ilé méjì ni wọ́n ti ní kọ̀ǹpútà. . . . Iye àwọn ọmọdé tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ta sí mẹ́tàdínlógún lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n sì ń gbé nínú ilé tí kọ̀ǹpútà wà ti pọ̀ sí i láti ìdá márùndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 1998 sí ìdá márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 2000.” Àwọn tó ń lo kọ̀ǹpútà lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè míì náà ti pọ̀ sí i.

Àmọ́, kò dìgbà tí ọ̀dọ́ kan bá ní kọ̀ǹpútà tiẹ̀ kó tó lè rí kọ̀ǹpútà lò o. Ìyẹn ni olùṣèwádìí kan fi sọ pé “nǹkan bí ìdá àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún márùn-ún sí mẹ́tàdínlógún ló ń lo kọ̀ǹpútà, tí ìdá mọ́kàndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún sì ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.” Èyí ti wá fún àwọn ọ̀dọ́ ní àǹfààní tí wọn ò ní tẹ́lẹ̀ láti máa fa ìsọfúnni mu bí omi. Kì bá ti sí ohun tó burú nínú ìyẹn bí wọ́n bá ń lo kọ̀ǹpútà bó ṣe tọ́, táwọn àgbà sì ń tọ́ wọn sọ́nà. Ṣùgbọ́n ibi tọ́rọ̀ náà burú sí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn òbí ti fàwọn ọ̀dọ́ sílẹ̀ láti máa lo kọ̀ǹpútà bí wọ́n ṣe fẹ́.

Ẹ̀rí kan rèé tó ti ohun tá à ń sọ lẹ́yìn. Olùṣèwádìí ni Moll, ó sì sọ nínú ìwé ìròyìn Phi Delta Kappan pé nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2001, nípa báwọn èèyàn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì sí, “ìdá mọ́kànléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òbí ni wọ́n rò pé àwọn mọ ‘ohun tó pọ̀, tàbí ohun díẹ̀’ nípa báwọn ọmọ àwọn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì sí. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n bi àwọn ọmọ wọn bóyá àwọn òbí wọn mọ bí wọ́n ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì sí, ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé báwọn òbí àwọn bá tiẹ̀ mọ ‘ohunkóhun’ nípa nǹkan táwọn ń dán wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ‘díẹ̀’ báyìí ni.” Ìwádìí yìí tún fi hàn pé, “ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ ọdún mẹ́sàn-án sí mẹ́wàá sọ pé àwọn máa ń lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ àdáni tàbí tó wà fáwọn àgbà nìkan. Pabanbarì ìṣòro náà wá ni pé àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn kére gan-an ni wọ́n ń lọ síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yìí. Bá a bá sì fi gbogbo wọn dá ọgọ́rùn-ún, àwọn ọmọ ọdún mọ́kànlá sí méjìlá tí wọ́n ń lọ síbẹ̀ jẹ́ ìdá méjìdínlọ́gọ́ta, àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́rìnlá tí wọ́n ń lọ síbẹ̀ jẹ́ ìdá àádọ́rin, àwọn ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́tàdínlógún tí wọ́n ń lọ síbẹ̀ sì jẹ́ ìdá méjìléláàádọ́rin. . . . Nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nípa báwọn èèyàn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì sí nínú ilé, òbí kan nínú méje ló gbà pé àwọn ò mọ ohun táwọn ọmọ àwọn ń dán wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”

Báwọn ọmọ ò bá rẹ́ni yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò, Íńtánẹ́ẹ̀tì lè sọ wọ́n dẹni tó ń wo àwòrán oníhòòhò. Ewu yẹn ò wá mọ síbẹ̀ nìkan o. Ọ̀rọ̀ náà ba Ọ̀mọ̀wé Taffel, tá a fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ lókè àpilẹ̀kọ yìí nínú jẹ́, ó sọ pé: “Àwọn ọmọ wa ń báwọn èèyàn sọ̀rẹ́ nílé ìwé àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nípa báyìí, àwọn ọmọ wa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ táwa òbí gan-an kì í rí sójú.”

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé àwọn ọ̀dọ́ àtijọ́ ò mọ̀ nípa pákáǹleke àti ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí ń dojú kọ. Abájọ nígbà náà tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń hùwà tó ń kọni lóminú! Ǹjẹ́ ohun kan wà tá a lè ṣe láti ran àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí lọ́wọ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Mo gbà pé ọwọ́ táwọn òbí fi ń mú àwọn ọmọ wọn láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ti sọ wọ́n di adánìkànjẹ̀, ẹni tó máa ń wò suu, tó máa ń nira fún láti kẹ́kọ̀ọ́, tí kì í ṣì í ṣeé darí.”—DÓKÍTÀ ROBERT SHAW LÓ SỌ̀RỌ̀ YÌÍ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Yíyà tí ọ̀pọ̀ obìnrin ń yà lọ sídìí iṣẹ́ wà lára ohun tí ò jẹ́ kí ìdílé rí bíi tàtijọ́ mọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Báwọn ọ̀dọ́ ò bá ní oníbàáwí kò ní pẹ́ tí wọ́n á fi kó sí ìṣòro

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé fídíò orin máa ń mú káwọn ọ̀dọ́ hùwà ìpáǹle

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ǹjẹ́ o mọ ohun táwọn ọmọ rẹ ń wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?