Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Àwọn Ọ̀nì Funfun Rèé!

Ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Íńdíà náà, The Hindu sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ Ọgbà Ẹranko Ìjọba ti Bhitarkanika, ní Ìpínlẹ̀ Orissa, ti rí àwọn ọ̀nì funfun mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí irú wọn ṣọ̀wọ́n gan-an . . . nígbà tí wọ́n ń ka àwọn ọ̀nì tó wà nínú omi bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lọ́dọọdún.” Ó ṣọ̀wọ́n gidigidi kéèyàn tó lè rí ọ̀nì tó láwọ̀ funfun, kódà “kò sí ibòmíì téèyàn ti lè rí wọn lágbàáyé.” Nítorí pípa táwọn apẹran láìgbàṣẹ ń pa àwọn ọ̀nì nípakúpa, àwọn ọ̀nì tó ń gbé nínú omi oníyọ̀ lágbègbè náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1979, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ètò tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti dá ibi tí wọ́n á ti máa sin ọ̀nì sílẹ̀ nínú ọgbà ẹranko náà. Àwọn ọ̀nì náà sì ti ń gbá yìn-ìn nítorí pé igi tó pọ̀ níbẹ̀ ń ṣíji bò wọ́n, inú omi tó mọ́ tónítóní ni wọ́n ń gbé, wọ́n ń foúnjẹ tó dáa bọ́ wọn, àwọn èèyàn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ yọ wọ́n lẹ́nu mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Hindu, tún ṣe sọ, àwọn ọ̀nì tí ò láwọ̀ funfun tí wọ́n wà níbẹ̀ báyìí jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500], àwọn funfun tó ṣọ̀wọ́n yẹn náà sì tún wà níbẹ̀.

Tábà Ń Fa Òṣì àti Àìsàn

Ìwé ìròyìn èdè Spanish náà, Diario Medico, sọ pé: “Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ fáyé gbọ́ pé nǹkan bí ìdá mẹ́rìnlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn tó ń mu sìgá ló ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀, níbi tí òṣì ò ti jẹ́ kí wọ́n yé mu sìgá, tí sìgá mímu sì túbọ̀ ń sọ wọ́n di òtòṣì.” Ìyẹn nìkan wá kọ́ o, ní gbogbo orílẹ̀-èdè, “àwọn tó ń mu sìgá jù tí sìgá sì máa ń fa ìṣòro púpọ̀ fún jù làwọn tó tòṣì jù lọ láwùjọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sìgá mímu ti dín kù lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè ọlọ́làjú, ìwé ìròyìn náà tún sọ pé ó ti di “ohun tó léwu ṣìkẹrin lára àwọn nǹkan tó ń fa àìsàn” káàkiri àgbáyé. Ní Sípéènì, níbi tí iye àwọn èèyàn tó ń kú lọ́dún nítorí sìgá mímu ti pọ̀ tó ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000], sìgá mímu ti di “ohun tó ń fa àìsàn, tó ń sọni di aláàbọ̀ ara, tó sì tún ń pa àwọn èèyàn jù lọ.”

Àwọn Àgùntàn Kì Í Gbàgbé Ojú Tí Wọ́n Bá Ti Rí Rí

Nínú ìwé ìròyìn New Scientist, Keith Kendrick tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀, sọ pé: “A ti rí i pé àwọn àgùntàn ṣì lè rántí ojú àádọ́ta àgùntàn mìíràn tàbí ojú èèyàn mẹ́wàá tí wọ́n bá ti rí rí. Ọ̀gbẹ́ni Kendrick àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ rí i pé lẹ́yìn táwọn àgùntàn náà ti rí àwọn ọgọ́ta ojú yìí léraléra láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, wọ́n ṣì ń rántí gbogbo wọn “fún ọdún méjì ó kéré tán.” Kì í wá ṣe pé àwọn àgùntàn náà máa ń rántí àwọn ojú tí wọ́n bá ti rí rí nìkan o, àmọ́ bíi tàwa èèyàn, wọ́n tún lè fi bí ojú náà ṣe rí “mọ̀ bóyá inú onítọ̀hún dùn tàbí inú ẹ̀ ò dùn.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, àwọn àgùntàn “lè mọ̀ béèyàn bá ń fojú sọ̀rọ̀, bí ojú àgùntàn tí ìdààmú bá tẹ́lẹ̀ bá sì yí padà wọ́n lè mọ̀. Ó máa ń wù wọ́n kéèyàn máa rẹ́rìn-ín músẹ́ dípò kó máa bínú.” Àwọn olùṣèwádìí náà tún ti wá rí i pé “àwọn àgùntàn lè bẹ̀rẹ̀ sí fojú kan náà tí wọ́n fi ń wo àgùntàn tí wọ́n mọ̀ dunjú nínú agbo àgùntàn wo ẹni tó ń tọ́jú wọn.” Ọ̀gbẹ́ni Kendrick wá sọ pé: “Bí èèyàn kan bá níwà bí ọ̀rẹ́ sáwọn àgùntàn, kì í pẹ́ tí wọ́n fi máa ń kà á sí ọ̀kan lára wọn. Èyí fi hàn pé àwọn àgùntàn máa ń dọ̀rẹ́ ẹni tó ń tọ́jú wọn.”

Àwọn Ilé Ọ̀gbìn Ilẹ̀ Ọsirélíà Ń Ba Àyíká Jẹ́

Àjọ kan nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tó ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, àwọn ilé ọ̀gbìn ti ilẹ̀ Ọsirélíà ló ń tú ohun tó ń ba àyíká jẹ́ sáfẹ́fẹ́ jù. Tá a bá fojú wò ó pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tó ń gbé níbẹ̀ ló ń tú gáàsì yìí dà sáfẹ́fẹ́.” Ó lé díẹ̀ ní tọ́ọ̀nù gáàsí carbon dioxide mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àti afẹ́fẹ́ ilé ọ̀gbìn tí wọ́n ń mú móoru tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tó ń gbé ní Ọsirélíà tú sí afẹ́fẹ́ lọ́dún 2001. Ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ àjọ ilẹ̀ Ọsirélíà náà sọ pé ohun tó fà á tí gáàsì náà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rọ tó ń lo èédú làwọn ará Ọsirélíà fi ń pèsè iná mànàmáná, òun làwọn ohun ìrìnnà wọn ń lò, òun náà ni wọ́n tún ń lò nílé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe ayọ́. Orílẹ̀-èdè tó pọwọ́ lé ti ilẹ̀ Ọsirélíà, níbi tẹ́nì kọ̀ọ̀kan tí ń tú gáàsì tí wọ́n ń rí ní ilé ọ̀gbìn tí wọ́n ń mú móoru dà sáfẹ́fẹ́ ni Kánádà (tọ́ọ̀nù gáàsì méjìlélógún). Lẹ́yìn náà ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (tọ́ọ̀nù gáàsì mọ́kànlélógún ó lé díẹ̀). Orílẹ̀-èdè Latvia ló tú gáàsì tó kéré jù lọ dà sáfẹ́fẹ́ lọ́dún 2001, iye gáàsì tẹ́nì kọ̀ọ̀kan tó ń gbébẹ̀ tú sáfẹ́fẹ́ kò tó tọ́ọ̀nù kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ń gbé ní ilẹ̀ Ọsirélíà ò pọ̀, àpapọ̀ gáàsì táwọn ilé ọ̀gbìn tó wà lórílẹ̀-èdè náà ń tú dà sáfẹ́fẹ́ “tayọ táwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ògúnnágbòǹgbò onílé-iṣẹ́ okòwò nílẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn àwọn orílẹ̀-èdè bíi Faransé àti Ítálì (tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n tóbi ju ilẹ̀ Ọsirélíà lọ nígbà mẹ́tà),” gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ.

Ariwo Ojú Pópó Ń Mú Kí Ohùn Orin Ẹyẹ Nightingale Ròkè Sí I

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, Berliner Zeitung, sọ pé: “Bí ariwo bá ròkè, ńṣe ni ohùn orin ẹyẹ nightingale náà á ròkè sí i. Ìwádìí kan tí Henrik Brumm, láti ilé ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè ní Free University ní ìlú Berlin ṣe fi hàn pé orin tí ẹyẹ yìí máa ń kọ làwọn ẹyẹ míì fi máa ń mọ ibi tó ń gbé, orin náà ló sì tún fi máa ń ké sí abo. Ṣùgbọ́n wọ́n tí ṣàkíyèsí pé nígbà tí ariwo tó wà láyìíká pọ̀ sí i, ohùn ẹyẹ náà fi ìwọ̀n mẹ́rìnlá ròkè sí i. Brumm sọ pé, “èèyàn lè má fi bẹ́ẹ̀ kà á sí pé ohùn yìí ròkè tó bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ṣe ló dà bí ìgbà tí ẹyẹ náà bá pariwo, tí ohùn rẹ̀ sì kẹ̀ rìrì ní ìlọ́po márùn-ún. Èyí tó túmọ̀ sí pé ẹ̀dọ̀fóró ẹyẹ náà gbọ́dọ̀ fẹ̀ sí i ní ìlọ́po márùn-ún.” Láwọn ibi tí ìgboro bá ti pa rọ́rọ́, ohùn ẹyẹ náà kì í ròkè tó báyìí. Àmọ́, láwọn ibi tí ariwo bá ti pọ̀ nígboro, ohùn ẹyẹ náà máa ń ròkè gan-an ni. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ohun tó tiẹ̀ wá ya àwọn olùṣèwádìí náà lẹ́nu ni pé ńṣe ló dà pé bíi bí ariwo bá ṣe pọ̀ sí lójú pópó lọ́jọ́ èyíkéyìí ni ẹyẹ náà ṣe máa gbé ohùn rẹ̀ sókè tó. Lópin ọ̀sẹ̀, tí kò bá sí àwọn ọkọ̀ akérò lójú pópó, ohùn jẹ́jẹ́ làwọn ẹyẹ náà sábà máa ń fi kọrin, èyí tí kì í rí bẹ́ẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ táwọn mọ́tò bá pọ̀ lójú pópó.”

Ìwà Ọ̀daràn Pọ̀ Láwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Lórílẹ̀-Èdè Poland

Ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Poland, Zwierciadciadło, sọ pé: “Ìgbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ni wọ́n ja àwọn èèyàn lólè láwọn ilé ẹ̀kọ́ [lórílẹ̀-èdè Poland] lọ́dún 2003.” Ìwé ìròyìn náà tún wá fi kún un pé, “ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọléèwé [lórílẹ̀-èdè Poland] ni ilé ìwé ò wù mọ́ nítorí pé wọ́n máa ń dá wà, ó sì máa ń ṣòro fún wọn láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú olùkọ́ àtàwọn akẹgbẹ́ wọn nílé ìwé.” Ìṣòro ọ̀hún ṣe wá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Wojciech Eichelberger, tó mọ̀ nípa ìtọ́jú ọpọlọ sọ pé: “Iléèwé nìkan kọ́ ni wọ́n ti ń hùwàkiwà. Ohun tó ń lọ láwùjọ là ń rí tó ń ṣẹlẹ̀ nílé ìwé. Ìwà táwọn ọmọ sì bá lọ́wọ́ wa ni wọ́n ń hù bí wọ́n bá délé ìwé.” Ìyáàfin Eichelberger wá dá a lábàá pé káwọn òbí dín ìṣòro náà kù nípa títúbọ̀ wáyè gbọ́ tàwọn ọmọ. Ìyẹn á sì mú káwọn ọmọ wọn lóye pé ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú àwọn.

Báwọn Kan Ṣe Rí Ò Tẹ́ Wọn Lọ́rùn

Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Kánádà, Globe and Mail, sọ pé: “Látìgbà kékeré ni bí ara àwọn ọ̀dọ́ ṣe rí kì í ti í tẹ́ wọn lọ́rùn, ìyẹn sì lè di àìsàn sí wọn lára. Àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ náà sì ti ń ṣe bíi tàwọn ọ̀dọ́.” Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọbìnrin tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí mẹ́rìnlá nípa bí wọ́n ṣe ń jẹun sí, àwọn tó rí nǹkan sọ lé ní ẹgbọ̀kànlá [2,200]. Ìwé ìròyìn Globe ròyìn pé: “Lára àwọn ọmọbìnrin náà, kò tó ìdá méje nínú ọgọ́rùn-ún, tó ki pọ́pọ́ jù, ṣùgbọ́n ó ju ìdá mọ́kànlélọ́gbọ̀n lọ tí wọ́n sọ pé àwọn ti ‘sanra jù,’ tí ìdá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sì sọ pé ńṣe làwọn ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ ní tàwọn báyìí.” Kí ló fà á táwọn ọmọbìnrin tára wọ́n dá ṣáṣá fi ń fẹ́ káwọn jò? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ṣe sọ, àwọn àgbà tí wọ́n ń wò bí àpẹẹrẹ ló lẹ̀bi ọ̀ràn náà. Ńṣe làwọn àgbà wọ̀nyẹn máa ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ ní gbogbo ìgbà ṣáá, tí wọ́n sì máa ń dá yẹ̀yẹ́ ẹni tó bá sanra jù. Ìwé ìròyìn Globe sọ pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde náà máa ń ṣe ipa tiwọn. Wọ́n ń mú káwọn ọ̀dọ́ máa ronú lọ́nà tó yàtọ̀, nítorí pé lemọ́lemọ́ ni wọ́n máa ń gbé àwọn tó ń fi ìmúra polówó ọjà sáfẹ́fẹ́, àwọn èèyàn tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n sì máa ń lò.” Ọ̀mọ̀wé Gail McVey, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó máa ń ṣe ìwádìí ní Ọsibítù Àwọn Ọmọdé Tó Ń Ṣàìsàn ní Ìlú Toronto ṣàlàyé pé ó yẹ káwọn ọmọdé, àwọn òbí àtàwọn olùkọ́ mọ̀ pé “kò sí ohun tó burú nínú kí àwọn ọmọdé lómi lára sí i nígbà ìbàlágà, apá kan ìdàgbàsókè ni.”