Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀dọ́ Ń wá Ìdáhùn Sí Ìbéèrè Wọn

Àwọn Ọ̀dọ́ Ń wá Ìdáhùn Sí Ìbéèrè Wọn

Àwọn Ọ̀dọ́ Ń wá Ìdáhùn Sí Ìbéèrè Wọn

Nígbà tí àpéjọ ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínlógún ti Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Ìjọ Kátólíìkì Lágbàáyé wáyé nílùú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà lọ́dún 2002, ọ̀pọ̀ èèyàn láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé ló rọ́ lọ síbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sí lára àwọn tó lọ síbi àpéjọ yìí, síbẹ̀ wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa rọ́ wá sínú ìlú náà. Báwo ni wọ́n ṣe gbára dì fún àpéjọ àwọn ọ̀dọ́ náà? Wọ́n ṣe bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ni, wọ́n lo àǹfààní yìí láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́.—Ìṣe 16:12, 13.

Àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́kọ́ gbóríyìn fáwọn ọ̀dọ́ náà nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bó ṣe di pé wọ́n gbà káwọn Ẹlẹ́rìí máa jíròrò ọ̀pọ̀ nǹkan látinú Bíbélì pẹ̀lú wọn nìyẹn o. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà bi ọ̀dọ́bìnrin kan bóyá bí wọ́n ṣe ròyìn Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Lágbàáyé ló ṣe bá a, ó dáhùn pé: “Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé látìgbà tá a ti dé la ti ń kọrin tá a sì ń jó, ṣùgbọ́n kò tíì sí ohun tó fún ìgbàgbọ́ mi lókun sí i.”

Lẹ́yìn náà ni Ẹlẹ́rìí yìí fún ọmọbìnrin náà ní ìwé pẹlẹbẹ tó ní àkòrí náà Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ó sì ṣàlàyé fún un pé ìwé náà dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè táwọn èèyàn ti ń béèrè nípa Bíbélì, ìyẹn àwọn ìbéèrè bíi, “Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ní tòótọ́?” àti “Báwo la ṣe lè mọ̀ pé kò tíì yàtọ̀ sí bó ṣe rí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́?”

Ọmọbìnrin náà dáhùn pé: “Àwọn ìbéèrè tó ń jà gùdù lọ́kàn mi gan-an nìyẹn níbi tí mo bá ìgbésí ayé mi dé báyìí. Á wù mí kí n rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi. Màá fẹ́ láti kàwé yìí lójú ẹsẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ohun tó máa ṣe mí láǹfààní jù lọ nínú ìrìn àjò yìí nìyẹn.”

Ọ̀kan péré nìyẹn lára ọ̀pọ̀ ìjíròrò tó wáyé láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn tó wá sí àpéjọ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Ìjọ Kátólíìkì Lágbàáyé. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́ mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.