“Ṣé Mo Lè Rẹ́ni Fẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?”
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
“Ṣé Mo Lè Rẹ́ni Fẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?”
“Lójoojúmọ́ la máa ń kọ̀wé síra wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. A ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ibi tá a ó máa gbé àti ibi tá a ó ti máa ṣiṣẹ́. Èmi ló yẹ kí n fi òrùka ìgbéyàwó sílẹ̀. Kò tíì tó oṣù kan tá a mọra wa o, a ò sì tíì pàdé ara wa lójúkojú rí.”—Monika, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Austria. a
BÓYÁ ó ń wù ẹ́ bíi kó o tiẹ̀ rí ẹnì kan, ẹni tí wàá lè máa bá rìn, tí wàá lè fẹ́. Ṣùgbọ́n títí di báyìí, o ò tíì rí ẹnì kankan, pàbó ni gbogbo ìgbìyànjú ẹ ń já sí. Gbogbo báwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí ẹ tó fẹ́ ọ fẹ́re ṣe ń gbìyànjú láti fojú ìwọ àti ẹnì kan mọra, òfo ló ń já sí, dípò tíyẹn ì bá fi ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìtìjú ló ń kó bá ẹ ó sì ń mú kó dùn ẹ́ kọjá sísọ. Lo bá ń rò pé níbi tí ètò ìbánisọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti rìn jìnnà dé yìí, ó yẹ kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rẹ́ni fẹ́.
Láyé tó dayé kọ̀ǹpútà yìí, ó lè dà bíi pé àtirẹ́ni fẹ́ ò ṣòro, ẹnu kéèyàn kàn fi kọ̀ǹpútà rẹ̀ yẹ ibi mélòó kan wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni. Àwọn kan sọ pé gbogbo ohun tó o máa ṣe ò ju pé kó o tẹ àdírẹ́sì ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan sórí kọ̀ǹpútà kó o sì gbabẹ̀ wọlé síbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ táwọn àpọ́n ti ń wá olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà oṣù kan wà tí mílíọ̀nù márùndínláàádọ́ta èèyàn yẹ ìkànnì tí wọ́n ti ń wá olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì wò. Ilé iṣẹ́ kan tó ń bá àwọn èèyàn wọ́kọ-wáya lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé àwọn tó ń wo ìkànnì tàwọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ju mílíọ̀nù mẹ́sàn-án lọ, wọ́n sì ń wò ó ní òjìlérúgba [240] orílẹ̀-èdè.
Ohun Tó Ń Mú Kí Wọ́n Máa Wá Olólùfẹ́ Lọ Sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì
Ṣé ojú máa ń tì ẹ́, àbí ṣe ló máa ń ṣòro fún ẹ láti bá èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú? Ṣé ẹ̀rù kí ẹnì kan kọ̀ fún ẹ ló ń bà ẹ́? Àbí nǹkan tó o kàn ń rò ni pé kò sí irú ẹni tó o lè fẹ́ ládùúgbò ibi tó ò ń gbé? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè wù ẹ́ pé kó o wá ẹni tí wàá fẹ́ lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ohun kan tó ń mú kó máa wu èèyàn ni pé àwọn tó ń bá èèyàn
wá ọkọ tàbí aya lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì á máa sọ fún ẹ pé wàá lè darí “ìfẹ́” tó wà láàárín ìwọ àtẹni tó o bá rí. Tó o bá ti dé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wàá rí àpótí tí wọ́n to àwọn ìsọfúnni kan sí lójú kọ̀ǹpútà rẹ. Tó o bá ti yẹ ibẹ̀ wò báyìí, wàá rí ọjọ́ orí àwọn èèyàn, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, irú ẹni tí wọ́n jẹ́, fọ́tò wọn àti orúkọ tí wọ́n ń lò láti wọlé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà tó o bá ti rí gbogbo ohun tó yẹ kó o mọ̀ tí wàá fi lè yan ẹni tó wù ẹ́ báyìí, ó lè dà bíi pé rírí ẹni fẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló dáa jù, ó sì rọrùn ju kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé lójúkojú lọ.Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́? Ṣé ìfẹ́ tó bá wà láàárín àwọn tó rí ara wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń mú ayọ̀ tó ń bani kalẹ́ wá? Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná: Láàárín ọdún mẹ́fà kan báyìí, àwọn èèyàn tó lọ sí iléeṣẹ́ tó ń báni wá olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kànlá. Àmọ́, iye ìgbéyàwó tó wáyé kò ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [1,475] lọ. Láàárín mílíọ̀nù kan èèyàn míì tí wọ́n wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ lọ sí ìkànnì iléeṣẹ́ kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, èèyàn márùndínlọ́gọ́rin péré ló rẹ́ni fẹ́! Kí ló fa ìṣòro tó wà nídìí ọ̀ràn yìí?
Ǹjẹ́ Wọ́n Lè Mọra Wọn Dáadáa?
Ìwé ìròyìn kan sọ pé: “Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, olúkúlùkù ló máa ń dà bí èèyàn gidi, gbogbo èèyàn ló máa ń dà bí olóòótọ́ àti ẹni tó ti rọ́wọ́ mú.” Ṣùgbọ́n ṣé èèyàn lè ka gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá sọ nípa ara wọn sí ògidì òótọ́? Ìròyìn míì sọ pé: “A mọ̀ pé gbogbo èèyàn ló máa ń parọ́ díẹ̀díẹ̀.” Obìnrin kan tó jẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn gbajúgbajà kan tó wà fáwọn ọ̀dọ́ ṣe ìwádìí fúnra rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó forúkọ ara rẹ̀ sílẹ̀ ní ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì mẹ́ta táwọn èèyàn ti máa ń wá ẹni tí wọ́n á fẹ́, nígbà tó fi máa dọjọ́ kejì, àwọn bíi mélòó kan ti láwọn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Bó ṣe di pé àwọn ọkùnrin mélòó kan fẹ́ máa fẹ́ ẹ nìyẹn. Kí ló tẹ̀yìn ẹ̀ wá? Òfo pondoro! Irọ́ gbuu ni nǹkan táwọn ọkùnrin yẹn sọ nípa ara wọn. Ó wá kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé: “Látàrí ohun tí mo ti rí o, àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń purọ́.”
Ó lè máà já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn láti purọ́ nípa bí wọ́n ṣe ga tó tàbí bí wọ́n ṣe tẹ̀wọ̀n tó. Àwọn kan lè sọ pé, ‘Béèyàn ṣe rí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì.’ Òótọ́ ni, Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé “òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán.” (Òwe 31:30) Ṣùgbọ́n, ṣó dáa káwọn méjì tó bá fẹ́ fẹ́ra wọn fi píparọ́ lórí ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ wọn? (Lúùkù 16:10) Ṣé wàá lè gba àwọn nǹkan míì tẹ́ni náà bá sọ fún ẹ gbọ́ nípa àwọn ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì bí ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” (Sekaráyà 8:16) Òdodo ọ̀rọ̀ ni, orí òótọ́ ni ìfẹ́ tó bá máa jinlẹ̀ máa ń dúró lé.
Àwọn tó ń rí olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sábà máa ń lá àlá ọ̀sán gangan ni. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Ọ̀rọ̀ dídùndídùn làwọn tó ń lọ sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì sábà máa ń lò nínú àwọn lẹ́tà tí wọ́n ń kọ ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, wọ́n sì máa ń pọ́n ara wọn lé ju bó ṣe yẹ lọ. . . . Ìyẹn ló máa jẹ́ kẹ́ni tó bá ka àwọn lẹ́tà bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí wọn kó sì fèsì: wọ́n máa ń dà bí èèyàn gidi tó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ, ìwọ náà á sì fẹ́ fi hàn pé èèyàn gidi ni ẹ àti pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nílé ìwé gbogboǹṣe Rensselaer Polytechnic Institute ní New York ṣèwádìí nípa fífẹ́ra ẹni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sọ pé bọ́rọ̀ bá rí bó ṣe rí yìí, ìfẹ́ ẹnì kan máa ń tètè kó sí ẹlòmíì lọ́kàn. Síbẹ̀, bó ṣe sábà máa ń rí, èèyàn ò lè retí pé kí irú ìfẹ́rasọ́nà báyìí yọrí sí ìgbéyàwó aláyọ̀. Ọkùnrin kan kọ̀wé nípa ohun tójú ẹ̀ rí nídìí wíwá olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sọ pé: “Ẹ̀tàn ló wà nídìí ẹ̀. Wàá máa ronú pé bó ṣe yẹ kí nǹkan tó ò tíì mọ̀ nípa ẹ̀ rí náà ló ṣe rí.”
Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Tójú Bá Kojú
Àwọn kan gbà pé ó láwọn àǹfààní pàtó kan tó wà nínú káwọn má fojú kanra. Wọ́n lè rò pé tí wọ́n bá ń fẹ́ra wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn méjèèjì á lè máa ronú nípa ohun tẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ sọ́nà jẹ́ nínú láìfi ti ẹwà rẹ̀ pè. Lóòótọ́, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ronú lórí àwọn ànímọ́ inú táwọn èèyàn ní. (1 Pétérù ) Àmọ́, ìṣòro ibẹ̀ yẹn ni pé o ò lè ráyè kíyè sẹ́ni tó ò ń fẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì dáadáa débi tí wàá fi lè mọ ìṣesí ẹ̀, bó ṣe máa ń rẹ́rìn-ín àti irú ẹni tó fojú jọ. O ò lè rí bó ṣe máa ń ṣe sáwọn ẹlòmíì tàbí bó ṣe máa ń hùwà bí nǹkan kan bá ń dà á láàmú. Ó sì ṣe pàtàkì kó o mọ nǹkan wọ̀nyẹn kó o tó pinnu bóyá ẹni tó o máa lè fọkàn tán tí wàá sì lè nífẹ̀ẹ́ ni. Ìwọ ka ohun tí Bíbélì sọ pé ìfẹ́ jẹ́ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú 3:41 Kọ́ríńtì 13:4, 5. Kíyè sí i pé ìwà ni Bíbélì fi júwe ìfẹ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀. Nítorí náà, á dáa kó o wáyè láti kíyè sí ẹnì kan dáadáa kó o lè rí i bóyá ìwà rẹ̀ bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mu.
Àwọn míì ò ní tíì mọ ẹni tí wọ́n ń fẹ́ lọ́nà yìí tí wọ́n á fi máa sọ ohun tó wà lọ́kàn ara wọn fúnra wọn nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra wọn. Láìronú jinlẹ̀, àwọn kan tó ń fẹ́ra wọn ti fi wàdùwàdù ṣèlérí pé àwọn á fẹ́ra, láìtíì mọra wọn dáadáa. Nínú àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n pe àkọlé ẹ̀ ní “Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, Ìfẹ́ Fọ́jú Lóòótọ́,” wọ́n sọ ìtàn àwọn méjì tí wọ́n ń fẹ́ra wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n sì ń gbé níbi tó jìn tó nǹkan bí ẹgbàá mẹ́fà àbọ̀ [12,500] kìlómítà síra wọn. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ti ń fẹ́ra, wọ́n fojú kanra. Ọkùnrin náà sọ pé: “Ńṣe ló lẹ tìróò mọ́ gbogbo ojú. Èmi ò sì lè fẹ́ obìnrin tó bá ń tọ́ tíròó ní tèmí.” Bọ́rọ̀ wọn ṣe dà rú nìyẹn. Nígbà táwọn méjì míì tí wọ́n ń fẹ́ra wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fojú kanra, inú èyí ọkùnrin bà jẹ́ nítorí ohun tó ń retí kọ́ ló rí. Ó dùn ún débi pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti sanwó ọkọ̀ òfuurufú tàlọtàbọ, ó gba owó ọkọ̀ àbọ̀ padà lọ́wọ́ àwọn olọ́kọ̀ òfuurufú!
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Edda sọ ohun tójú ẹ̀ rí nídìí à-ń-fẹ́ra ẹni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ tó wà láàárín wa dùn kọjá sísọ. A ti ń múra ìgbéyàwó.” Ṣùgbọ́n nígbà táwọn méjèèjì fojú kanra wọn, ńṣe lọ̀rọ̀ dà rú. Edda sọ pé: “Kì í ṣerú ẹni tí mò ń retí nìyẹn, kò sí nǹkan tó ń tẹ́ ẹ lọ́rùn, gbogbo nǹkan ló ń rojọ́ lé lórí. Èmi pẹ̀lú rẹ̀ ò tiẹ̀ lè jọ gbé láéláé.” Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ àárín wọn dà rú, ọ̀rọ̀ ìgbèsí ayé Edda sì sú Edda pátápátá.
Nígbà táwọn méjì bá ń fẹ́ra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, á máa dà bíi pé gbogbo ẹ̀ ń dùn yùngbà, ìfẹ́ sì máa ń tètè kó séèyàn lórí ju bó ṣe yẹ lọ. Ìṣòro téyìí máa ń fà ni pé bọ́rọ̀ ò bá wá rí bó o ṣe rò ó, á bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́ kọjá àlà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í já síbi tó dáa. Òun ló jẹ́ kí Òwe 28:26 ṣèkìlọ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, ìwà arìndìn ni kéèyàn máa ṣèpinnu pàtàkì látàrí ìrònú asán nípa ohun tí ò dá èèyàn lójú. Abájọ tí òwe yẹn fi parí ọ̀rọ̀ náà pé: “Ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.”
Ó Léwu Láti Máa Tètè Bá Èèyàn Ṣàdéhùn Fífẹ́ra
Kò bọ́gbọ́n mu láti máa kánjú ṣàdéhùn fífẹ́ra ẹni láìtíì mọ púpọ̀ nípa ẹnì kejì. Wọ́n ní òǹkọ̀wé èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, Shakespeare sọ pé: “Ìgbéyàwó tá a bá ṣe lórí eré sábà máa ń tú ká gbẹ̀yìn ni.” Ìmọ̀ràn Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere lórí ìyẹn, ó sọ pé: “Ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.”—Òwe 21:5.
Ó mà ṣe o, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti wá olólùfẹ́ lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan ati Monika tá a fọ̀rọ̀ ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ti ń kọ̀wé síra fún bí oṣù kan, Monika rò pé àdúrà òun ti gbà nìyẹn, pé òun ti rẹ́ni tóun máa fẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ń múra ìgbéyàwó tí wọ́n tiẹ̀ ti ń wá òruka ìgbéyàwó, “ìbànújẹ́ ńlá” ló gbẹ̀yìn ìfẹ́ àpàpàǹdodo tó wà láàárín wọn.
O ò ní kó sínú ìrora ọkàn bí irú èyí, tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Àmọ́, kì í ṣe ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn nìkan ni ìṣòro tó o lè bá pàdé tó o bá ń fẹ́ èèyàn lórí Íńtánẹ́ètì. Àpilẹ̀kọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà á sọ̀rọ̀ nípa àwọn ewu míì tó tún wà nínú ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn èèyàn sábà máa ń gbéra wọn lárugẹ tàbí kí wọ́n parọ́ nípa ara wọn tí wọ́n bá wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìfẹ́ táwọn èèyàn ti kọ síra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, lọ́jọ́ tí wọ́n bá fojú kojú báyìí, ohun tí wọn ò retí ni wọ́n sábà máa ń rí