Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kéèyàn Máa Lo Ère Nínú Ìjọsìn?

Ṣó Yẹ Kéèyàn Máa Lo Ère Nínú Ìjọsìn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Kéèyàn Máa Lo Ère Nínú Ìjọsìn?

AYẸYẸ ìsìn ńlá kan máa ń wáyé ní gbogbo àyájọ́ ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹjọ ní erékùṣù ilẹ̀ Gíríìsì tó ń jẹ́ Tínos. Omilẹgbẹ èèyàn tí wọ́n gbà gbọ́ pé Màríà, ìyá Jésù, láwọn agbára àràmàǹdà máa ń kóra jọ láti lọ jọ́sìn òun àti ère rẹ̀. a Ìwé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìsì kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé: “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ àti ìfọkànsìn tí kò lábùlà làwa ń bọlá fún Theotokos, Ẹni Mímọ́ Jù Lọ, Ìyá Olúwa wa, tá à ń tọrọ ààbò rẹ̀, tá a sì ń ké pè é kó yára wá ràdọ̀ bò wá kó sì wá ràn wá ṣe. Àwa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn Ẹni Mímọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin, tí wọ́n ń ṣe ìyanu, pé kí wọ́n wá gbọ́ tiwa nípa tara àti nípa tẹ̀mí . . . Tọkàntọkàn làwa fi ń fi ìfẹnukonu mímọ́ ṣèbà fún àwòrán àwọn ẹni mímọ́ àtàwọn ère mímọ́ wọn.”

Ọ̀pọ̀ àwọn míì náà tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni ni wọ́n ń jọ́sìn ère àwọn ẹni mímọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ Bíbélì fi kọ́ni pé ká máa lo ère nínú ìjọsìn?

Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀

Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí àádọ́ta-dín-lẹ́gbàá [1,950] ọdún sẹ́yìn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ sí Áténì, ìlú tí wọ́n ti fẹ́ràn kí wọ́n máà lo ère nínú ìjọsìn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé fáwọn ará Áténì pé Ọlọ́run “kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn ṣe ìránṣẹ́ fún un bí ẹni pé ó ṣe aláìní nǹkan kan . . . Nítorí náà, . . . kò yẹ kí a lérò pé Olù-Wà Ọ̀run rí bí wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a gbẹ́ lére nípasẹ̀ ọnà àti ìdọ́gbọ́nhùmọ̀ ènìyàn.”Ìṣe 17:24, 25, 29.

Dájúdájú, àwọn ìkìlọ̀ náà pé kéèyàn má ṣe lo ère pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tí wọ́n tún ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Jòhánù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà?” (2 Kọ́ríńtì 6:16) Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ náà ti lo àwọn ère rí nínú ìjọsìn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà, ó rán wọn létí pé: “[Ẹ] yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run kúrò nínú òrìṣà yín láti sìnrú fún Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè.” (1 Tẹsalóníkà 1:9) Láìsí àníàní, ojú tí Jòhánù àti Pọ́ọ̀lù fi wo lílo ère tàbí àwòrán nínú ìjọsìn làwọn Kristẹni wọ̀nyẹn náà fi wò ó.

Bí Lílo Ère Nínú Ìjọsìn Ṣe Wọnú Ẹ̀sìn “Kristẹni”

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé “láàárín ọ̀ọ́dúnrún ọdún àkọ́kọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni dáyé, . . . kò sí ohun tó ń jẹ́ àwòrán tàbí ère Kristẹni, nítorí pé gbogbo ara làwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì fi ta kò ó. Bí àpẹẹrẹ, Clement ará Alẹkisáńdíríà ta ko lílo àwòrán (tàwọn abọ̀rìṣà) nínú ìjọsìn nítorí pé ó máa ń mú káwọn èèyàn jọ́sìn ìṣẹ̀dá dípò Ẹlẹ́dàá.”

Kí ló wá fà á tí lílo àwọn ère nínú ẹ̀sìn fi di ohun tó wọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ní nǹkan bí àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀sán [1,750] ọdún sẹ́yìn ni àwòrán àti ère gbígbẹ́ yọ́ wọnú ẹ̀sìn àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lò wọ́n nínú ìjọsìn. Síbẹ̀, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan wà tí wọn ò ti gbojú bọ̀rọ̀ lórí ọ̀ràn lílo ère nínú ìjọsìn. Àmọ́, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrin, nígbà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni di ẹ̀sìn tí ilẹ̀ ọba Róòmù fọwọ́ sí, Constantine tí í ṣe Olú Ọba di aṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni. Ìgbà yẹn gan-an ni lílo àwòrán tàbí ère nínú ìjọsìn wá bẹ̀rẹ̀ sí rídìí jókòó nínú ẹ̀sìn Kristẹni.”

Ó wọ́pọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n sọ pé àwọn di Kristẹni nígbà náà pé kí wọ́n máa jọ́sìn àwòrán àwọn olú ọba. Nínú ìwé Icon Painting, tí John Taylor kọ, ó ṣàlàyé pé: “Nínú ààtò ìjọsìn olú ọba, ńṣe làwọn èèyàn máa ń jọ́sìn àwòrán rẹ̀ tí wọ́n yà sára aṣọ tàbí igi. Ìyẹn ló sì bá wọn dé ìdí jíjọ́sìn àwọn ère.” Bó ṣe di pé wọ́n fi jíjọ́sìn àwọn àwòrán tàbí ère Jésù, ti Màríà, tàwọn áńgẹ́lì, àtàwọn “ẹni mímọ́,” rọ́pò ère táwọn abọ̀rìṣà máa ń bọ nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn àwòrán tàbí ère táwọn èèyàn ń jọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì di ohun tí àìmọye èèyàn ń gbé sílé, tí wọ́n sì ń júbà fún nínú ilé wọn pẹ̀lú.

Bá A Ṣe Lè Máa Sin Ọlọ́runní Ẹ̀mí àti Òtítọ́

Jésù sọ fún àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa sìn Ín “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Nítorí náà, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lẹnì kan fẹ́ mọ bọ́rọ̀ lílo ère nínú ìjọsìn ṣe jẹ́, àfi kó yáa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìlàlóye lórí ọ̀ràn náà.

Bí àpẹẹrẹ, bá a bá wo inú Bíbélì, a óò rí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run kan ni ó wà, àti alárinà kan láàárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn, ọkùnrin kan, Kristi Jésù,” àti pé “Kristi . . . ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa.” (1 Tímótì 2:5; Róòmù 8:34) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa Jésù túbọ̀ ṣe kedere níbi tó ti sọ pé Kristi lè “gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.” (Hébérù 7:25) Nítorí náà, lórúkọ Jésù Kristi ló yẹ ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run. Kò tún sẹ́lòmíì tá a lè fi dípò Jésù, ká má tiẹ̀ wá sọ ti èrè ìsìn lásán làsàn. Mímọ̀ tá a bá mọ èyí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ran ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ lóye òtítọ́ lọ́wọ́ láti mọ bóun ṣe lè máa “jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́” kóun sì wà lára àwọn tí Ọlọ́run fojú ẹ̀ mọ ọ̀nà ìjọsìn gíga jù lọ yìí. Dájúdájú, bí Jésù ṣe sọ, “irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.”—Jòhánù 4:23.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun tí wọ́n sábà máa ń pè ní ère ìsìn ni àwòrán tàbí àmì kan táwọn ẹlẹ́sìn kan máa ń jọ́sìn. Bí àpẹẹrẹ, ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlà Oòrùn, wọ́n ní àwọn àwòrán tàbí àmì tó dúró fún Kristi; àwọn míì sì wà tó dúró fún Mẹ́talọ́kan, àwọn “ẹni mímọ́,” tàbí àwọn áńgẹ́lì, tó fi mọ́ àwòrán tàbí àmì tó dúró fún Màríà, ìyá Jésù, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lókè. Ọ̀wọ̀ tí àìmọye èèyàn ní fún irú àwòrán tàbí àmì bẹ́ẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo àwọn ère tàbí àwòrán tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn. Àwọn ìsìn kan tí wọn kò pe ara wọn ní Kristẹni náà ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nínú ère àti àwòrán àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwòrán tí Boris Subacic/AFP/Getty Images yà