Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Wọ́n Ṣe Ń sọ Ìtàn Di Fíìmù

Bí Wọ́n Ṣe Ń sọ Ìtàn Di Fíìmù

Bí Wọ́n Ṣe Ń sọ Ìtàn Di Fíìmù

LÁTI bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, Hollywood, níbi tí wọ́n ti ń gbé fíìmù jáde ní Amẹ́ríkà, làwọn àjáàbalẹ̀ eré tó ń pa jẹ̀jẹ̀rẹ̀ owó wọlé ti ń wá. Kárí ayé ni wọ́n sì máa ń gba tirú àwọn fíìmù bẹ́ẹ̀, nítorí pé kí wọ́n máà tíì ṣe wọ́n jáde ni, wọ́n á ti dé òkè òkun, èyí lè jẹ́ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, tàbí nígbà míì, lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí wọ́n bá ti kọ́kọ́ jáde ní Amẹ́ríkà. Àwọn fíìmù kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ọjọ́ tí wọ́n jáde náà ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí wò wọ́n jákèjádò ayé. Dan Fellman, ààrẹ Ẹgbẹ́ Warner Brothers Pictures tó jẹ́ alágbàtà fíìmù tó ń jáde ní Amẹ́ríkà, tiẹ̀ sọ pé: “Òwò tó ń búrẹ́kẹ́ sí i ni kéèyàn máa ta fíìmù sáwọn orílẹ̀-èdè míì káàkiri ayé, ó sì dùn ún ṣe gan-an. Nítorí náà, nígbà tá a bá ti ń ṣe fíìmù la ti máa ń ro tàwọn tó máa rà á káàkiri àgbáyé mọ́ ọn.” Níbi tọ́rọ̀ dé báyìí lágbo àríyá, kò sẹ́ni tó lè fọwọ́ rọ́ àwọn sinimá tí wọ́n ṣe ní Hollywood tì lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. a

Àmọ́, ó kàn lè dà bíi pé ó rọrùn láti jèrè lórí fíìmù ni, kò rọrùn rárá. Owó tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀pọ̀ fíìmù àti iye tí wọ́n ń ná láti fi polówó wọn máa ń lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là. Síbẹ̀ náà, ó dìgbà táwọn aráàlú bá wo fíìmù ọ̀hún káwọn tó ṣe é tó lè rówó wọn padà. Kò sì sẹ́ni tó lè sọ bóyá wọ́n máa wò ó tàbí wọn ò ní wò ó. David Cook, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìwádìí nípa fíìmù ní Yunifásítì Emory sọ pé: “Kò sí ìgbà kankan téèyàn lè mọ ohun tó máa dùn mọ́ àwọn aráàlú tàbí ohun tó máa dá wọn lára yá.” Nítorí náà, báwo làwọn tó ń ṣe fíìmù ṣe ń ṣe é tí wọ́n kì í fi í já sọ́lọ́pọ́n? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ díẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe fíìmù. b

Bí Wọ́n Ṣe Ń Pilẹ̀ Fíìmù

Pípilẹ̀ fíìmù ló sábà máa ń gba àkókò jù, ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú fíìmù ṣíṣe sì ni. Bí ìgbà téèyàn bá fẹ́ dáwọ́ lé iṣẹ́ ńlá kan ni, èèyàn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ múra sílẹ̀ kó bàa lè ṣàṣeyege. Àwọn tó ń ṣe fíìmù máa ń fọkàn ṣírò rẹ̀ pé gbogbo owó táwọn bá ná láti fi pilẹ̀ fíìmú yìí á dín owó táwọn máa ná kù gan-an nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí yàwòrán fíìmù náà.

Orí ìtàn kan ni fíìmù ti máa ń bẹ̀rẹ̀, èyí tó lè jẹ́ àròsọ tàbí ìrírí ayé. Akọ̀tàn kan lá á kọ́kọ́ kọ ìtàn náà àtàwọn ìlànà eré. Àkàtúnkà ni wọ́n máa ń ka ìwé eré tàbí ìtàn tí akọ̀tàn kọ yìí, títí tá á fi wà ní sẹpẹ́. Inú ìtàn tó wà ní sẹpẹ́ yìí ni wọ́n máa ń kọ gbogbo ohun tí òṣèré á máa sọ àti bí yóò ṣe máa ṣe nínú fíìmù náà sí. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé míì á tún wà níbẹ̀ tá á sọ ibi tí kámẹ́rà máa wà àti bí wọ́n á ṣe máa ti orí ìran kan bọ́ sí òmíràn.

Àmọ́, nígbà tí wọ́n bá ṣì ń múra fíìmù sílẹ̀ ni wọ́n ti máa ń wá alágbàṣe fíìmù tó máa ra eré náà tá á sì gbé e jáde. c Irú fíìmù tàbí eré wo ló máa ń wu alágbàṣe láti rà? Ná, ohun tó máa tẹ́ àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ àtàwọn ọ̀dọ́ lọ́rùn ló sábà máa ń wà nínú àwọn fíìmù tí wọ́n bá gbé jáde lákòókò ìsinmi. Ẹnì kan tó máa ń ṣe lámèyítọ́ eré sinimá tiẹ̀ pe irú àwọn ògowẹẹrẹ àti ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ní “àwọn ajẹgbúgbúrú,” nítorí pé rírún ni wọ́n máa ń rún gbúgbúrú lẹ́nu tí wọ́n bá fẹ́ lọ wo eré àti nígbà tí wọ́n bá ń wòran eré lọ́wọ́. Nítorí náà, alágbàṣe fíìmù lè tètè bẹ́ mọ́ eré táwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyẹn bá máa gba tiẹ̀.

Bí ìtàn náà bá wá jẹ́ èyí tí tàgbà tèwe á nífẹ̀ẹ́ sí, ìyẹn gan-an lá á túbọ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, bí fíìmù kan bá dá lórí akọni kan nínú eré bèbí táwọn ọmọdé máa ń wò tàbí tí wọ́n máa ń rí nínú ìwé, ó dájú pé ó máa fa àwọn ògo wẹẹrẹ tí wọ́n bá ti mọ akọni náà tẹ́lẹ̀ mọ́ra. Ó sì dájú pé àwọn òbí wọn náà á tẹ̀ lé wọn lọ wò ó. Àmọ́, báwo làwọn tó ń ṣe fíìmù ṣe máa ń ṣe eré táwọn tí ò tíì pọ́mọ ogún ọdún àtàwọn ọ̀dọ́ míì á fẹ́ láti wò? Ìyáàfin Liza Mundy dáhùn nínú ìwé ìròyìn The Washington Post Magazine pé: “Àwọn eré tó bá ní nǹkan àrà ọ̀tọ̀ nínú” ni wọ́n máa ń gbé jáde. Bí fíìmù bá lọ́rọ̀ àlùfààṣá nínú, tí wọ́n ń pààyàn nípakúpa nínú ẹ̀, tí wọ́n sì ń bára wọn ṣèṣekúṣe fàlàlà, ọ̀nà kan tún nìyẹn “tí wọ́n fi máa ń jẹ́ kó túbọ̀ mówó rẹpẹtẹ wọlé nítorí pé wọ́n ti ro ti tàgbà tèwe mọ́ ọn kò sì sẹ́ni tí ò ní fẹ́ wò ó.”

Bí alágbàṣe fíìmù bá rí i pé eré tí ìwé rẹ̀ wà lọ́wọ́ òun máa wọ́ èrò gan-an, ó lè rà á kó sì bẹ olùdarí eré tó lóókọ àti gbajúgbajà òṣèré lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin lọ́wẹ̀. Báwọn èèyàn bá mọ̀ pé olùdarí tó lóókọ àti èèkàn nínú àwọn òṣèré máa kópa nínú fíìmù náà, gìrọ́gìrọ́ lèrò á máa wọ́ níbi tí wọ́n ti ń ta tíkẹ́ẹ̀tì bí eré náà bá jáde. Kódà, bí akitiyan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ báyìí, orúkọ àwọn ògbóǹtarìgì lágbo eré táwọn olùdókòwò bá gbọ́ lè mú kí wọ́n náwó wọn sórí irú fíìmù bẹ́ẹ̀.

Ohun mìíràn tí wọ́n tún máa ń ṣe bí wọ́n bá ń pilẹ̀ fíìmù ni yíyàwòrán bí eré náà ṣe máa rí. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé wọ́n á máa ya onírúurú àwòrán tó ń ṣàpèjúwe ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó máa wà nínú fíìmù náà, pàápàá jù lọ, àwọn ibi tí òṣèré tí ṣe àwọn nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn àwòrán àfọwọ́yà yẹn làwọn tá á ya eré náà á máa tẹ̀ lé, ó sì máa ń dín àkókò tí wọ́n á fi ya fíìmù kù gan-an. Bí ọ̀gbẹ́ni Frank Darabont, tó jẹ́ olùdarí àti akọ̀tàn ṣe sọ, “kò sóhun tó burú bíi kéèyàn dé ibi tó ti fẹ́ ya eré kó wá fi gbogbo ọjọ́ ṣòfò níbi tó ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá ibi tó máa gbé kámẹ́rà sí.”

Àwọn nǹkan míì ṣì tún wà tí wọ́n gbọ́dọ̀ wá ojútùú sí nígbà tí wọ́n bá ń pilẹ̀ eré. Bí àpẹẹrẹ, ibo ni wọ́n a ti lọ ya eré náà? Ṣó máa la ìrìn àjò lọ? Báwo ni wọ́n á ṣe máa to ìtàgé? Ṣé wọ́n máa nílò àwọn aṣọ eré? Ta ló má bójú tó títan iná, ṣíṣe ara lóge àti ṣíṣe irun lọ́ṣọ̀ọ́? Ta ni yóò máa rí sí gbígba ohùn eré sílẹ̀, ta lá á máa gbé onírúuru ohùn àti idán jáde. Ta lá á sì máa ṣe ibi tó ṣòroó ṣe? Díẹ̀ péré nìwọ̀nyí lára ọ̀pọ̀ apá tí ṣíṣe fíìmù pín sí tó sì yẹ kí wọ́n gbé yẹ̀ wò dáadáa kí wọ́n tó ya ohunkóhun lára eré náà. Bó o bá wo orúkọ àwọn tó kópa nínú fíìmù kan tí wọ́n fowó iyebíye ṣe lẹ́yìn tó bá parí, wàá rí i pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ló kópa nínú ẹ̀ ṣùgbọ́n tí a kò rójú wọn! Amojú ẹ̀rọ kan tó ti kópa nínú yíya ọ̀pọ̀ fíìmù sọ pé: “Èèyàn máa nílò ìrànlọ́wọ́ ọ̀pọ̀ èrò láti ṣe fíìmù kan tó fa kíki.”

Yíya Eré

Yíya eré máa ń gba àkókò gan-an, ó máa ń nira, ó sì máa ń náni lówó. Kódà, ìṣẹ́jú kan ṣoṣo téèyàn bá fi ṣòfò lè náni ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là. Nígbà míì, wọ́n ní láti gbé àwọn òṣèré, àwọn tó ń bá wọn ṣiṣẹ́, àtàwọn irin iṣẹ́ lọ sọ́nà jíjìn. Àmọ́, ibi yòówù kí wọ́n ti lọ ya eré náà, owó gọbọi ni wọ́n ń ná lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.

Lára àwọn tó kọ́kọ́ máa ń dé síbi tí wọ́n á ti ya eré ni àwọn olùtanná, àwọn aṣerunlóge, àtàwọn aṣaralóge. Lójoojúmọ́ tí wọ́n bá lọ ya eré ni wọ́n máa ń lo àkókò tó pọ̀ láti múra fáwọn òṣèré. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí ya àwọn òṣèré náà látàárọ̀ ṣúlẹ̀.

Gbágbáágbá ni olùdarí eré máa dúró ti àwọn tó ń ya àwọn òṣèré kó lè máa bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ. Kódà, ìran kan téèyàn lè rò pé kò ṣòro rárá lè gba odindi ọjọ́ kan mọ́ wọn lọ́wọ́. Kámẹ́rà kan ṣoṣo ni wọ́n fi máa ń ya èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìran tó wà nínú eré, nítorí náà, àṣetúnṣe ni wọ́n máa ṣe àwọn ìràn náà kí wọ́n lè yà á lápátùn-ún, lápásì, níwá àti lẹ́yìn. Ìyẹn nìkan wá kọ́, ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń ya àwọn òṣèré náà léraléra láti lè rí ibi tí wọ́n ti ṣe dáadáa jù tàbí láti lè ṣe àtúnṣe tó jẹ mọ́ bí wọ́n ṣe to ìtàgé tàbí bí wọ́n ṣe dúró, tó fi mọ́ àtúnṣe tó bá jẹ́ ti ẹ̀rọ. Bí wọ́n bá ya apá kan tán nínú eré náà láìdá kámẹ́rà dúró, apá yẹn ti délẹ̀ nìyẹn. Bó bá jẹ́ àwọn ìràn tó gùn ni, apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n á yà lè tó àádọ́ta! Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ya ìran tọjọ́ yẹn tán, olùdarí eré á wo gbogbo àwòrán tí wọ́n ti yà níkọ̀ọ̀kan á sì sọ èyí tí wọ́n á fi pa mọ́ fún lílò bó bá yá. Látìbẹ̀rẹ̀ dópin, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ oṣù nígbà míì kí wọ́n tó ya eré kan tán.

Ṣíṣe Àtúntò Àwòrán

Bí wọ́n bá ń ṣe àtúntò àwòrán, wọ́n á yẹ apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n yà wò, wọ́n á mú èyí tó dáa jù lọ, wọ́n á sì tún wọn tò di sinimá tó já geere. Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n á gbé orin tó máa wà nínú fíìmù náà sí i. Lẹ́yìn ìyẹn ni olóòtú eré á to àwọn àwòrán náà pọ̀ sínú ẹ̀dà àkọ́kọ́ fíìmù náà.

Ohun tó kàn báyìí ni kí wọ́n fi oríṣiríṣi ohùn àti idán kún un. Fífi idán, ìró àti ohùn síbi tó yẹ nínú eré jẹ́ ọ̀kan lára àwọn apá tó díjú jù lọ fáwọn tó ń ṣe fíìmù, wọ́n sì ní láti lo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà nígbà míì kí wọ́n tó lè rí i ṣe. Àmọ́ bí wọ́n bá ṣe é tán báyìí, gbogbo rẹ̀ á ṣe wẹ́kú, ṣe ló máa dà bíi pé ohun téèyàn ń wò ń ṣẹlẹ̀ lójú ayé ni.

Àsìkò yìí ni wọ́n tún máa ń fi orin kún un. Ọwọ́ pàtàkì sì làwọn fíìmù tí wọ́n ń ṣe lóde ìwòyí fi mú ọ̀rọ̀ olórin dé yìí. Ọ̀gbẹ́ni Edwin Black sọ nínú ìwé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ Film Score Monthly pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbé sinimá jáde ti wá ń béèrè báyìí pé àwọn ń fẹ́ orin púpọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kí wọ́n má kàn máa fún àwọn ní èyí tí wọ́n fẹ́ lò lára orin náà nìkan, ṣùgbọ́n odindi orin làwọn fẹ́.”

Nígbà míì, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tún fíìmù kan tò tán, wọ́n máa ń pe àwọn èèyàn kí wọ́n wá bá àwọn wò ó wò, ìyẹn àwọn ọ̀rẹ́ olùdarí eré tàbí àwọn tó ń bá wọn ṣiṣẹ́ tí wọn ò sí níbi tí wọ́n ti lọ yàwòrán eré náà. Ohun tí wọ́n bá sọ á ran olùdarí lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá òun á tún àwọn ìran kan nínú eré náà yà tàbí kí òun kúkú yọ́ wọn kúrò pátápátá. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n tún gbogbo ìparí eré yà nítorí pé ibi tí eré náà parí sí kò tẹ́ àwọn tó wá bá wọn wò ó lọ́rùn.

Nígbà tí wọ́n bá wá ṣe tán pátápátá, ó di kí wọ́n gbé fíìmù náà jáde fún wíwò láwọn ilé sinimá. Ìgbà yẹn gan-an sì ni wọ́n tó lè sọ bóyá ó máa pawó wọlé tàbí ó máa kùtà, tàbí kó kàn tà níwọ̀nba tiẹ̀ ṣá. Ṣùgbọ́n díẹ̀ ni towó téèyàn á rí lórí fíìmù yìí o. Nítorí, bó bá di pé ó ń di wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tí òṣèré kan ò ṣe dáadáa nínú eré, ó lè máà rẹ́ni pè é sí eré mọ́ kó sì tún ba orúkọ olùdarí eré náà jẹ́. Olùdarí eré ni ọ̀gbẹ́ni John Boorman. Nígbà tó ń sọ bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fi kámẹ́rà ya eré, ó sọ pé: “Mo mọ àwọn mélòó kan lára àwọn tá a jọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí tí wọ́n fiṣẹ́ náà sílẹ̀ lẹ́yìn táwọn eré mélòó kan tí wọ́n yà ti kùtà. Ibi tọ́rọ̀ sinimá le sí jù ni pé bó ò bá pawó wọlé fáwọn tó pè ẹ́ séré, ẹnu kí wọ́n lé ẹ dànù ni.”

Àmọ́ o, bá a bá fi dá tàwọn èèyàn tó ń dúró wo orúkọ àwọn òṣèré nílé sinimá, kò sí ohun tó kàn wọ́n kan ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ẹni tó ń ṣe fíìmù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó jà jù lọ́rọ̀ tiwọn làwọn nǹkan bíi: ‘Ṣé màá gbádùn fíìmù yìí? Ṣé mi ò ní fowó mi jóná báyìí? Ṣé kì í ṣe nǹkan tí ò wọ̀ tàbí àwọn nǹkan jágbajàgba ló wà nínú fíìmù ọ̀hún? Ṣó dáa káwọn ọmọ mi wò ó?’ Bó o bá ń pinnu irú fíìmù tí wàá wò, báwo lo ṣe lè dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí Anita Elberse, olùkọ́ kan nílé ẹ̀kọ́ gíga Harvard Business School ṣe sọ, “bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó tí wọ́n ń pa lórí fíìmù nílẹ̀ òkèèrè pọ̀ ju owó tí wọ́n ń pa lórí ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ, síbẹ̀ bí fíìmù bá ṣe tà tó lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló jà jù, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká mọ bó ṣe máa tà sí lókèèrè.”

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń ṣe fíìmù yàtọ̀ síra, ohun tá a sọ̀rọ̀ lé lórí níbí jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ń ṣe é.

c Nígbà míì, ògédé ìtàn ni wọ́n á gbé fún alágbàṣe fíìmù pé kó kà, dípò ìtàn tí wọ́n ti sọ di eré. Bí ìtàn náà bá wù ú, ó lè rà á, ẹ̀tọ́ òfin láti gbé eré náà jáde á sì di tiẹ̀. Lẹ́yìn náà lá á wá ṣètò bó ṣe máa di fíìmù.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Kò sí béèyàn ṣe lè mọ ohun tó máa yá àwọn aráàlú lára tàbí ohun tó máa gbádùn mọ́ wọn.”—David Cook, olùkọ́ àgbà nínú ẹ̀kọ́ nípa fíìmù ló sọ̀rọ̀ yìí

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

ỌGBỌ́N TÍ WỌ́N FI Ń RÍ FÍÌMÙ TÀ WÀRÀWÀRÀ

Wọ́n ti parí fíìmù náà báyìí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn sì ti ṣe tán láti wò ó. Ṣó máa tà? Àwọn ọ̀nà díẹ̀ rèé táwọn tó ń ṣe fíìmù ń gbà polówó rẹ̀ tó fi máa ń pawó rẹpẹtẹ wọlé.

Ọ̀RỌ̀ ÀSỌGBÀ: Ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tí wọ́n fi ń mú káwọn èèyàn máa retí fíìmù tó ń bọ̀ lọ́nà ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ lásọgbà nípa ẹ̀. Nígbà míì, ọ̀pọ̀ oṣù ni wọ́n ti máa ń sọ̀rọ̀ lásọgbà nípa fíìmù kan kó tó di pé ó jáde. Nígbà míì sì rèé, wọ́n wulẹ̀ lè sọ pé wọ́n á ṣe apá kejì fíìmù kan tí wọ́n ti ṣe rí. Ṣé àwọn àgbà òṣèré tó wà nínú apá kìíní máa wà níbẹ̀? Ṣó máa dáa bíi tàkọ́kọ́, àbí ṣé bí tàkọ́kọ́ ṣe burú lòun náà máa burú?

Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ohun kan táwọn èèyàn ò fẹ́ nínú fíìmù náà ni wọ́n á máa sọ̀rọ̀ lé lórí. Bóyá ó lè jẹ́ bí wọ́n ṣe ń bára wọn ṣèṣekúṣe, ò sì lè jẹ́ tàwọn àwòrán oníhòòhò tí wọ́n ń gbé jáde jù níbẹ̀. Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣekúṣe ọ̀hún burú tó ni? Ṣé àṣejù ti wọ fíìmù náà ni? Bí oníkálùkù ṣe ń sọ ohun tó rí lásọgbà yìí máa ń dùn mọ́ àwọn tó ń ṣe fíìmù nínú torí pé bí ẹni bá wọn polówó fíìmù wọn lọ́fẹ̀ẹ́ ni. Kódà ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àròyé tí wọ́n ń ṣe yìí gan-an lá á jẹ́ káwọn èèyàn wọ́ lọ wo fíìmù náà bó bá jáde.

ÀWỌN AGBÉRÒYÌNJÁDE: Lára àwọn nǹkan míì tí wọ́n fi ń polówó fíìmù ni àwọn pátákó tí wọ́n máa ń lẹ ìwé mọ́, ìwé ìròyìn, tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn àwòrán tí wọ́n fi máa ń tọ́ àwọn èèyàn lẹ́nu wò nílé sinimá tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n kó tó di pé fíìmù gidi bẹ̀rẹ̀, tó fi mọ́ àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò níbi táwọn àgbà òṣèré á ti ríbi dán ẹnu mọ́ fíìmù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe. Ní báyìí ṣá, àràbà Íńtánẹ́ẹ̀tì ti wá di baba lára àwọn ohun tí wọ́n fi ń polówó fíìmù.

FÍFÚN ÀWỌN ÈÈYÀN LẸ́BÙN: Àwọn ẹ̀bùn kan wà tí wọ́n fi ń fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè wo fíìmù tó bá jáde. Bí àpẹẹrẹ, fíìmù kan wà tó dá lórí akọni kan nínú eré bèbí. Wọ́n ta àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ eré náà fáwọn èèyàn, ìyẹn àwọn nǹkan bí ike ìjẹun, ife ìmumi, àwọn ohun ọ̀ṣọ́, aṣọ, ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń so kọ́kọ́rọ́ mọ́, agogo, àtùpà àti ayò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀gbẹ́ni Joe Sisto, sọ nínú ìwé àtìgbàdégbà kan tó jẹ́ ti Ẹgbẹ́ Àwọn Amòfin ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà èyí tó ń sọ nípa ohun tó ń lọ lágbo àríyá, pe: “Wọ́n sábà máa ń tà tó ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ń ṣe nítorí fíìmù kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n gbé fíìmù náà jáde.”

FÍDÍÒ ÀGBÉLÉWÒ: Báwọn èèyàn ò bá fi bẹ́ẹ̀ lọ wo fíìmù kan, àwọn tó ṣe fíìmù náà lè rówó tí wọ́n fi ṣe é padà bí wọ́n bá sọ ọ́ di fídíò àgbéléwò, tí wọ́n sì tà á. Ọ̀gbẹ́ni Bruce Nash tó mọ̀ nípa bí fíìmù ṣe ń mówó wọlé sí, sọ pé “bá a bá fowó tó ń wọlé lórí fíìmù dá ọgọ́rùn-ún, ìdá ogójì sí àádọ́ta nínú ẹ̀ là ń rí látinú fídíò àgbéléwò.”

PÍPÍN FÍÌMÙ SÍ ÌSỌ̀RÍ: Àwọn tó ń ṣe fíìmù máa ń lo bí wọ́n ṣe máa ń pín fíìmù sí ìsọ̀rí fún àǹfààní ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kàn lè ṣàdéédéé fi ohun kan kún fíìmù kan kó bàa lè wọ ìsọ̀rí fíìmù tó yẹ káwọn tó ti dàgbà wò. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n á wulẹ̀ yọ àwọn ohun kan kúrò nínú fíìmù kó bàa lè kúrò ní ìsọ̀rí tàwọn àgbà kí wọ́n lè rí i tà fáwọn ọmọdé. Nígbà tí Liza Mundy ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn The Washington Post Magazine, ó sọ pé pípín fíìmù sí ìsọ̀rí tàwọn ọmọdé “tún ti di ọ̀nà tí wọ́n ń gbà polówó ọjà: Àwọn ilé iṣẹ́ sinimá ń lò ó láti sọ fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ògo wẹẹrẹ tó wù káwọn náà dàgbà pé wọ́n á rí ohun tó máa dùn mọ́ wọn wò nínú fíìmù náà.” Mundy tún wá sọ pé bí wọ́n ṣe ń pín fíìmù sí ìsọ̀rí yìí “kì í jẹ́ kí àárín òbí àtọmọ dán mọ́rán. Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn òbí, ẹ̀tàn ló sì jẹ́ fáwọn ọmọ.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

BÍ WỌ́N ṢE Ń ṢE FÍÌMÙ

ÌWÉ ERÉ

ÀWÒRÁN ERÉ

IBI TÍ WỌ́N TI Ń YA ERÉ

AṢỌ ERÉ

ÌṢARALÓGE

TÍTÚN ÀWÒRÁN TÒ

FÍFI IDÁN SÍ I

GBÍGBA ORIN SÍLẸ̀

PÍPO OHÙN PỌ̀

IDÁN TÍ WỌ́N FI KỌ̀ǸPÚTÀ PA