Fíìmù Wo Ni Wọ́n Máa Gbé Jáde Lọ́tẹ̀ Yìí?
Fíìmù Wo Ni Wọ́n Máa Gbé Jáde Lọ́tẹ̀ Yìí?
KÍ LÓ máa ń wù ọ́ ṣe lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn? Bí ojú ọjọ́ bá yí padà tí ooru sì mú nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ó lè ṣe ọ́ bíi pé kó o gba ibi tó o ti máa gbádùn ara ẹ lọ, bíi kó o rìnrìn àjò lọ sí etíkun tàbí kó o ṣeré lọ sí ọgbà ẹranko.
Àmọ́ ńṣe làwọn tó ń ṣe fíìmù máa ń retí pé kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa rọ́ lọ lo ọ̀pọ̀ lára àkókò tí wọ́n fẹ́ fi gbádùn ara wọn nínú ilé sinimá. Ó kéré tán a ò rírú ẹ̀ rí, ibi téèyàn ti lè rí fíìmù wò ní Amẹ́ríkà nìkan tó ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [35,000]. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bá a bá fi èrè tí wọ́n rí lórílẹ̀-èdè náà láìpẹ́ yìí lórí fíìmù dá ọgọ́rùn-ún, látinú owó ìwọlé tí wọ́n pa nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ni wọ́n ti rí ìdá ogójì lára rẹ̀. a Ọ̀gbẹ́ni Heidi Parker tó jẹ́ olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn Movieline, sọ pé, “ńṣe ló jọ báwọn alágbàtà ṣe máa ń jèrè gọbọi nígbà Kérésìmesì.”
Fíìmù kì í mówó wọlé bẹ́ẹ̀ yẹn tẹ́lẹ̀ rí ṣá o. Ìgbà kan wà táwọn ilé sinimá lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń dín àwọn fíìmù tí wọ́n ń fi hàn kù tàbí kí wọ́n kógbá sílé nígbà ẹ̀ẹ̀rùn nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í lọ síbẹ̀ lọ wòran. Àmọ́ láàárín ọdún 1973 sí ọdún 1978, wọ́n ń fọgbọ́n tan àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kúrò nínú ooru ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn nípa kíkọ́ àwọn gbọ̀ngàn ìwòran tó ní ẹ̀rọ amúlétutù. Àwọn tó ń ṣe fíìmù tún máa ń fojú sun àwọn ọmọdé pé bí wọ́n bá gbaludé nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn á rí tọwọ́ wọn gbà. Fún ìdí èyí, kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn fíìmù tó ń pa jẹ̀jẹ̀rẹ̀ owó wọlé nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. Bí a ó sì ṣe rí i, ìyẹn ti mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe fíìmù àti bí wọ́n ṣe ń tà á yí padà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, oṣù May ni àkókò táwọn èèyàn máa ń lọ wo fíìmù nígbà ẹ̀ẹ̀rùn máa ń bẹ̀rẹ̀, á sì máa bá a nìṣó títí wọ oṣù September.