Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú Fíìmù Wo Ni Wàá Máa Wò?

Irú Fíìmù Wo Ni Wàá Máa Wò?

Irú Fíìmù Wo Ni Wàá Máa Wò?

LÁTI ọdún mélòó kan sẹ́yìn, oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ń sọ lórí bí ìbálòpọ̀, ìwà ipá àti ọ̀rọ̀ àlùfààṣá ṣe ń pọ̀ sí i nínú sinimá, fíìmù àti lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn kan ń sọ pé ìbálòpọ̀ tó ń wáyé nínú fíìmù ń kóni nírìíra, nígbà táwọn kan ń sọ pé wọ́n fi ń mú kí eré dùn ni. Àwọn kan gbà pé ìwà ipá táwọn ń rí nínú fíìmù ò bójú mu, nígbà táwọn míì sì sọ pé kò sóhun tó burú nínú ẹ̀. Lójú àwọn kan, ọ̀rọ̀ àlùfààṣá tó máa ń pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ wọn ò yẹ ọmọlúwàbí, àwọn míì sì ń sọ pé wọ́n wulẹ̀ ń jẹ́ kéèyàn mọ bí nǹkan ṣe rí ni. Ohun tẹ́nì kan pè ní ọ̀rọ̀ rírùn, ni ẹlòmíì ń pè ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Béèyàn bá ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ yìí, ṣe lá wulẹ̀ dà bí ìgbà téèyàn ń jiyàn láìnídìí lórí ohun tó yẹ ká pe àwọn ohun tá à ń rí nínú fíìmù wọ̀nyìí.

Àmọ́, ohun tá à ń rí nínú fíìmù kì í wulẹ̀ ṣe nǹkan téèyàn lè pè ní iyàn jíjà. Ó tó ohun téèyàn ń ṣàníyàn lé lórí o. Àwọn òbí nìkan sì kọ́ lọ̀ràn yìí kàn, kódà ó kan gbogbo ẹni tó bá fọwọ́ pàtàkì mú ìwà ọmọlúwàbí. Ọ̀rọ̀ náà dun ọ̀dọ́bìnrin kan, ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí ọkàn mi bá sọ fún mi pé eré yẹn ò dáa síbẹ̀ tí mo mọ̀ọ́mọ̀ lọ wò ó, bí mo bá wò ó tán báyìí n kì í fẹ́ràn ara mi rárá ni. Ojú máa ń gbà mí tì fáwọn tó ṣe irú eré jágbajàgba bẹ́ẹ̀, ojú sì máa ń ti èmi náà tí mo lọ wò ó. Ńṣe ló máa ń dà bíi pé wíwò tí mo lọ wo eré tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wò tán yẹn tàbùkù sí irú ẹni tí mo jẹ́.”

Àwọn Òfin Tí Wọ́n Gbé Kalẹ̀ Lórí Fíìmù Ṣíṣe

Àwọn èèyàn ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣàníyàn nípa irú fíìmù tí wọ́n ń gbé jáde. Ní ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe fíìmù, inú àwọn èèyàn kì í dún sí i bí wọ́n bá rí ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ tàbí ìwà ọ̀daràn nínú ẹ̀. Nígbà tó ṣe, láàárín ọdún 1930 sí 1939, wọ́n ṣòfin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti fi dá gbèdéke lé irú àwòrán tí wọ́n á máa gbé jáde nínú fíìmù.

Bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica, ṣe sọ, òfin tuntun tí wọ́n ṣe lórí fíìmù yìí “ká àwọn èèyàn lọ́wọ́ kò pátápátá, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àjọṣe tímọ́tímọ́ tó máa ń wáyé láàárín àwọn ọkùnrin àti obìnrin lòfin náà ò fẹ́ kí wọ́n máa gbé jáde nínú fíìmù. Lára àwọn nǹkan tí òfin náà ò fẹ́ kí wọ́n máa gbé jáde nínú fíìmù ni ‘bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń fi ìfẹ́ hàn síra wọn,’ àgbèrè, ìṣekúṣe àti títanni sí ìbálòpọ̀. Kò tún gbọdọ̀ sohun tó jẹ mọ́ fífipá báni lòpọ̀ àyàfi bí eré náà ò bá ní kún tó láìsí i, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹni tó fipá báni lò pọ̀ náà gidigidi ní ìparí fíìmù náà.”

Ìwà ipá wá ńkọ́ o? “Òfin tún de fífi àwọn ohun ìjà tó wà lóde hàn tàbí jíjíròrò wọn. Òfin náà ò fàyè gba kí wọ́n fi báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ọ̀daràn ṣeré, tàbí káwọn ọ̀daràn pa agbófinró nínú eré, wọn ò gbọ́dọ̀ hùwà ìkà tàbí kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀mí ẹnikẹ́ni tàbí kí wọ́n jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbẹ̀mí ara ẹ̀ àyàfi bó bá jẹ́ ohun tí eré náà dá lé nìyẹn. . . . Ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ dáre fún ìwà ọ̀daràn yòówù tí ì báà wáyé nínú eré.” Ní kúkúrú, òfin náà sọ pé “kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ṣe fíìmù èyíkéyìí tí ò ní jẹ́ kí ìwà mímọ́ jọ àwọn tó bá wò ó lójú mọ́.”

Bí Wọ́n Ṣe Fi Pípín Fíìmù sí Ìsọ̀rí Rọ́pò Òfin Tó Wà Nílẹ̀

Láàárín ọdún 1950 sí 1959, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣe fíìmù ní Hollywood ti bẹ̀rẹ̀ sí tẹ òfin tí wọ́n ṣe náà lójú nítorí pé lójú tiwọn, àwọn òfin náà ò bágbà mu mọ́. Nítorí náà, wọ́n fagi lé òfin náà lọ́dún 1968 wọ́n sì fi pípín fíìmù sí ìsọ̀rí rọ́pò rẹ̀. a Lábẹ́ òfin tuntun yìí, fíìmù lè ní àwọn àwòrán tó ń mára tini nínú, ṣùgbọ́n wọ́n á fi àmì kan sí i lára tá á máa ki gbogbo èèyàn nílọ̀ pé àwọn nǹkan “tí ò yẹ kí ọmọdé máa rí” wà nínú ẹ̀. Bí ọ̀gbẹ́ni Jack Valenti, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Fíìmù ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fún nǹkan bí ogójì ọdún ṣe sọ, ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni “kí wọ́n lè kìlọ̀ tẹ́lẹ̀ fáwọn òbí, kí wọ́n bàa lè pinnu irú fíìmù tí wọ́n á jẹ́ káwọn ọmọ wọn wò àtèyí tí wọn ò ní jẹ́ kí wọ́n wò.”

Gbàrà tí wọ́n ṣòfin pípín fíìmù sí ìsọ̀rí báyìí, ńṣe ni àáyá àwọn onífíìmù bẹ́ sílẹ̀, tó bẹ́ séré, nígbà tí kò sóhun tó ń dí wọn lọ́wọ́ mọ́. Kálukú bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò àwọn ìtàn tó ní ìbálòpọ̀, ìwà ipá àti ọ̀rọ̀ àlùfààṣá ṣọwọ́ sí Hollywood láti fi ṣe fíìmù. Òmìnira tí wọ́n fún àwọn tó ń ṣe fíìmù ò wá jẹ́ kí wọ́n kóra wọn níjàánu mọ́, kò sì sẹ́ni tó lè dá wọn lẹ́kun. Ìkìlọ̀ ni bí wọ́n ṣe ń pín fíìmù sí ìsọ̀rí yìí pàápàá jẹ́ fún aráàlù. Àmọ́ ṣé bí wọ́n bá ṣáà ti pín fíìmù sí ìsọ̀rí, o lè mọ gbogbo nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa ẹ̀ nìyẹn?

Ohun Tí Ìsọ̀rí Tí Wọ́n Pín Fíìmù sí Ò Lè Sọ fún Ọ

Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí fura pé ó dà bíi pé ní báyìí tí ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí wọ́n ṣòfin yìí, òfin ọ̀hún ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára mọ́. Ìwádìí kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Ìlera Gbogbo Gbòò ní Harvard ṣe náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ìdí ni pé ìwádìí náà fi hàn pé ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ tó wà nínú fíìmù tí wọ́n sọ pé ó dáa fáwọn ọmọdé láti wò báyìí pọ̀ ju bó ṣe rí lọ́dún mẹ́wàá péré sẹ́yìn. Ibi tí ìwádìí náà parí ọ̀rọ̀ sí ni pé “iye àwọn nǹkan tí ò ṣeé rí sójú àtàwọn nǹkan tó léwu tó wà nínú àwọn fíìmù tí wọ́n pín sí ìsọ̀rí kan náà ń yàtọ̀ síra gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ.” Bí wọ́n bá sì “pín fíìmù sí ìsọ̀rí ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí, ìyẹn nìkan ò tó láti jẹ́ kéèyàn mọ ohun tó pọ̀ tó nípa ìwà ipá, ìbálòpọ̀, ọ̀rọ̀ àlùfààṣá àtàwọn nǹkan míì tó wà nínú ẹ̀.” b

Àwọn òbí tí wọ́n kàn máa ń jẹ́ káwọn ọmọ wọn lọ sílé sinimá bí wọ́n bá ṣe fẹ́ lè má mọ ohun tó wà nínú fíìmú tí wọ́n ló dáa fáwọn ọ̀dọ́ lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó máa ń ṣe lámèyítọ́ fíìmù ṣàpèjúwe olú ìtàn inú fíìmù kan tí wọ́n sọ pé kò burú fáwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé, “bó ṣe wu ọmọbìnrin, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún náà ló máa ń ṣe. Lójoojúmọ́ ló ń mutí yó kẹ́ri, ó máa ń lo oògùn olóró bó ṣe fẹ́, ó máa ń lọ síbi aríyá tí wọ́n ti ń hùwà ẹhànnà, ọmọkùnrin tó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bá pàdé máa ń bá a lòpọ̀ bí ajá ni.” Àwọn fíìmù bí irú èyí ò ṣàì wọ́pọ̀. Kódà, ìwé ìròyìn The Washington Post Magazine sọ pé báwọn òṣèré bá tiẹ̀ ń fẹnu pa ẹ̀yà ìbímọ ara wọn nínú fíìmù kan tí wọ́n pín sí ìsọ̀rí èyí táwọn ọ̀dọ́ lè wò, ó dà bíi pé wọn kì í rí ohun tó burú nínú ẹ̀ mọ́. Dájúdájú, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìsọ̀rí tí wọ́n pín fíìmù sí nìkan lèèyàn á fi máa díwọ̀n ohun tó wà nínú ẹ̀. Ṣé ohun mìíràn wà tó sàn jù téèyàn lè fi mọ bí fíìmù kan ṣe rí?

“Ẹ Kórìíra Ohun Búburú”

Pípín fíìmù sí ìsọ̀rí ò lè dípò ẹ̀rí ọkàn tá a ti fi Bíbélì kọ́. Nítorí náà, nínú gbogbo ìpinnu táwọn Kristẹni bá ń ṣe, tó fi mọ́ èyí tó bá jẹ mọ́ gbígbádùn ara ẹni, wọ́n gbọ́dọ̀ máa sapá láti fi ọ̀rọ̀ ìyànjú Bíbélì tó wà nínú Sáàmù 97:10 sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú.” Ẹní bá kórìíra ohun búburú á rí i pé kò dára kéèyàn máa fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra ṣe ìgbádùn.

Ó yẹ káwọn òbí ní pàtàkì máa ṣọ́ra gidigidi nípa irú fíìmù tí wọ́n ń jẹ́ káwọn ọmọ wọn wò. Ìwà àìka nǹkan sí gbáà ló máa jẹ́ fáwọn òbí bí wọ́n bá kàn ń wo ìsọ̀rí tí wọ́n pín fíìmù sí fẹ̀rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí fíìmù tí wọ́n sọ pé ẹni tó jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ rẹ lè wò máa kọ́ wọn ní ìwà kan tí ìwọ fúnra ẹ gẹ́gẹ́ bí òbí ò fọwọ́ sí. Èyí kò ya àwọn Kristẹni lẹ́nu nítorí pé báwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà kò bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. cÉfésù 4:17, 18; 1 Jòhánù 2:15-17.

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo fíìmù ni ò dáa o. Síbẹ̀, ó yẹ kéèyàn máa ṣọ́ra. Ìyẹn ni ìwé ìròyìn Jí! ti May 22, 1997 fi ṣàlàyé pé: “Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbé ọ̀ràn yẹ̀ wò tìṣọ́ratìṣọ́ra, kí ó sì ṣe àwọn ìpinnu tí yóò mú kí ó ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́ níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn.”—1 Kọ́ríńtì 10:31-33.

Béèyàn Ṣe Lè Dá Eré Ìnàjú Tó Bójú Mu Mọ̀

Báwo làwọn òbí ṣe lè máa yan irú fíìmù tó yẹ kí ìdílé wọn máa wò? Gbọ́ ohun táwọn òbí káàkiri orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé ń sọ. Ohun tí wọ́n sọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè wá eré ìtura tó gbámúṣé fún ìdílé rẹ.—Tún wo àpótí tá a pè ní “Irú Eré Ìtura Mìíràn,” tó wà ní ojú ìwé 14.

Juan, tó ń gbé ní Sípéènì sọ pé: “Èmi tàbí ìyàwó mi sábà máa ń tẹ̀ lé àwọn ọmọ wa lọ wo fíìmù nígbà tí wọ́n wà ní kékeré. Wọn ò dá lọ rí, wọn kì í sì í bá àwọn ọ̀dọ́ míì lọ. Nísinsìnyí tí wọ́n ti di ọ̀dọ́langba, wọn kì í lọ wo fíìmù tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde; kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń wù wá pé kí wọ́n dúró títí tá a ó fi mọ kókó inú fíìmù náà tàbí tá a ó fi gbọ́ ohun táwọn míì tá a gbẹ̀rí wọn jẹ́ á sọ nípa fíìmù náà. Lẹ́yìn náà, la óò tó wá pinnu gẹ́gẹ́ bí ìdílé bóyá a ó lọ wò ó tàbí a ò ní lọ wò ó.”

Mark, láti South Africa máa ń bá ọmọkùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa irú fíìmù tí wọ́n ń fi hàn láwọn gbọ̀ngàn ìwòran. Mark sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi la kọ́kọ́ máa ń dá ìjíròrò náà sílẹ̀, a óò wá béèrè òun tó rò nípa fíìmù náà. Èyí máa ń jẹ́ ká lè tẹ́tí sí i, ká mọ èrò rẹ̀, ká sì bá a fọ̀rọ̀ wérọ̀. Lọ́nà yìí, ó ti ṣeé ṣe fún wa láti yan fíìmù tí gbogbo wa á jùmọ̀ gbádùn.”

Rogerio, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Brazil, náà máa ń pe àwọn ọmọ ẹ̀ mọ́ra, wọ́n á sì jọ ṣe àrúnkúnná irú fíìmù tí wọ́n fẹ́ wò. Ó sọ pé: “A jọ máa ń ka ohun táwọn olùṣelámèyítọ́ bá sọ nípa fíìmù náà. Mo máa ń bá wọn lọ sí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta kásẹ́ẹ̀tì fídíò, màá sì kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè tara ohun tí wọ́n kọ sára páálí fídíò náà mọ̀ bóyá fíìmù náà bójú mu tàbí kò bójú mu.”

Matthew, tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, rí i pé ó máa ń ṣàǹfààní kóhun bá àwọn ọmọ òun sọ̀rọ̀ nípa irú fíìmù tí wọ́n bá fẹ́ wò. Ó sọ pé: “Látìgbà táwọn ọmọ wa ti wà ní kékeré la ti jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa irú fíìmù tí ìdílé wa gbádùn láti máa wò. Bá a bá pinnu pé a ò ní wo fíìmù kan, èmi àti ìyàwó mi á ṣàlàyé ìdí ẹ̀ fún wọn dípò ká wulẹ̀ sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe wò ó.”

Ìyẹn nìkan wá kọ́ o, àwọn òbí kan ti rí i pé ó máa ń dáa káwọn wádìí nípa fíìmù tó wà lóde lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀pọ̀ ìkànnì ló wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi téèyàn ti lè kà nípa àwọn ohun tó wà nínú fíìmù. A lè lo irú ìkànnì bẹ́ẹ̀ láti ní òye tó ṣe kedere nípa irú ẹ̀kọ́ tí eré sinimá kan fẹ́ fi kọ́ni.

Oore Tí Ẹ̀rí Ọkàn Tá A Ti Kọ́ Lè Ṣe Fúnni

Bíbélì sọ nípa àwọn tí wọ́n ti “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Nípa báyìí, ohun táwọn òbí gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn ni bí wọ́n á ṣe máa gbin ẹ̀kọ́ tó dára sọ́kàn àwọn ọmọ wọn, kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání bí wọ́n bá fẹ́ yan eré ìtura tó wù wọ́n.

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láàárín ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó jíire lórí ọ̀ràn yìí, látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bill àti Cherie, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, fẹ́ràn àtimáa lọ wo fíìmù pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ọkùnrin méjì. Bill sọ pé: “Lẹ́yìn tá a bá ti wo eré tán, a sábà máa ń jíròrò nípa fíìmù náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé. A máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ tí fíìmù náà fi ń kọ́ni àti bóyá a fara mọ́ ọn tàbí a kò fara mọ́ ọn.” Àmọ́ ṣá o, Bill àti Cherie rí i pé ó pọn dandan kéèyàn máa ṣa fíìmù wò. Bill tún fi kún un pé: “A sábà máa ń kà nípa fíìmù náà ká tó lọ wò ó, ojú kì í sì í tì wá láti jáde bá a bá rí i pé ohun tó kù díẹ̀ káàtó, tí a kò sì rò pé ó wà nínú fíìmù náà ló wà nínú ẹ̀.” Bill àti Cherie rí i pé àwọn ti ran àwọn ọmọ àwọn lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ nítorí pé àwọn máa ń jẹ́ kí wọ́n wà níbẹ̀ báwọn bá ń ṣèpinnu tó ṣe kókó nípa fíìmù. Ó tún wá sọ síwájú sí i pé: “Wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó túbọ̀ mọ́gbọ́n dání bó bá di pé kí wọ́n yan irú fíìmù tí wọ́n á wò.”

Bíi ti Bill àti Cherie, ọ̀pọ̀ òbí ló ti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti kọ́ agbára ìwòye wọn kí wọn bàa lè mọ àwọn nǹkan tí wọ́n á máa fi ṣeré ìnàjú. Ohun kan ni pe ọ̀pọ̀ fíìmù tí wọ́n ń gbé jáde láwọn ilé sinimá ò bójú mu. Òmíràn sì tún ni pé, báwọn Kristẹni bá jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì máa tọ́ àwọn sọ́nà, wọ́n lè gbádùn eré ìnàjú tó gbámúṣé tó sì ń tuni lára.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé ló ti ń tẹ̀ lé irú ìlànà kan náà. Ó ní ohun tí wọ́n máa ń kọ sára fíìmù tá á jẹ́ kéèyàn mọ ọjọ́ orí àwọn tó yẹ kó wo irú fíìmù bẹ́ẹ̀.

b Òmíràn sì tún ni pé ìlànà tí wọ́n fi ń pín fíìmù sí ìsọ̀rí máa ń yàtọ̀ síra láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Wọ́n lè sọ pé fíìmù kan ò dáa fáwọn ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè kan, ṣùgbọ́n kí wọ́n rí i pé kò sóun tó fi bẹ́ẹ̀ burú nínú ẹ̀ lórílẹ̀-èdè míì.

c Kò tún yẹ káwọn Kristẹni gbàgbé pé ó ṣeé ṣe kí fíìmù tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ tí ò tíì pé ọmọ ogún ọdún ní ọ̀ràn àjẹ́, ìbẹ́mìílò, tàbí àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ẹ̀mí èṣù nínú.—1 Kọ́ríńtì 10:21.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

“GBOGBO WA LA JỌ MÁA Ń ṢÈPINNU”

“Nígbà tí mo ṣì kéré, àwọn òbí wa máa ń mú wa lọ wo fíìmù. Ṣùgbọ́n mo ti dàgbà sí i báyìí, nítorí náà, wọ́n máa ń jẹ́ kí n dá lọ. Àmọ́ ṣá o, káwọn òbí mi tó jẹ́ kí n lọ, wọ́n á kọ́kọ́ fẹ́ láti mọ àkọlé fíìmù náà àti ohun tó dá lé lórí. Bí wọn ò bá tíì gbọ́ nípa fíìmù náà rí, wọ́n á ka ohun tí ìwé ìròyìn sọ nípa rẹ̀ tàbí kí wọ́n wo bí wọ́n ṣe polówó rẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n. Wọ́n á tún wádìí nípa fíìmù náà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí wọ́n bá rò pé fíìmù náà ò dáa, wọ́n á ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Wọ́n á sì jẹ́ kí èmi náà sọ tinú mi. Kálukú á sọ bọ́rọ̀ bá ṣe rí lọ́kàn rẹ̀, gbogbo wa la jọ máa ń ṣèpinnu.”—Héloïse, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún láti ilẹ̀ Faransé ló sọ̀rọ̀ yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ẹ JỌ JÍRÒRÒ!

“Bí àwọn òbí bá ní káwọn ọmọ má ṣe ohun kan tí wọn ò sì fi ohun míì tó gbámúṣé dípò rẹ̀, àwọn ọmọ lè wọ́nà tí wọ́n á fi mú ìfẹ́ inú ara wọn ṣẹ ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, báwọn ọmọ bá ń fẹ́ láti wo eré kan tí kò yẹ kí ọmọlúwàbí wò, àwọn òbí kan wà tí wọn kì í tètè fọwọ́ lalẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe wò ó, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ní sọ pé kí wọ́n wò ó. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á jẹ́ kí ara kálukú silé díẹ̀. Lẹ́yìn náà, láìbínú, wọ́n á fi ọjọ́ mélòó kan jíròrò ọ̀ràn náà, wọ́n á sì béèrè ohun táwọn ọmọ rí tí wọ́n fi rò pé irú eré yẹn á dáa fáwọn láti wò. Báwọn òbí bá jíròrò ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ báyìí, wọ́n sábà máa ń gbà pẹ̀lú àwọn òbí wọn, wọ́n á sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, àwọn òbí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yan eré ìtura míì tí wọ́n á jùmọ̀ gbádùn.”—Masaaki, tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè Japan ló sọ̀rọ̀ yìí.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

IRÚ ERÉ ÌTURA MÌÍRÀN

◼ “Ó sábà máa ń wu àwọn ọmọdé pé kí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́gbẹ́, nítorí náà, a máa ń bá ọmọbìnrin wa wá ẹni tó dáa tó lè bá ṣọ̀rẹ́. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ti pọ̀ nínú ìjọ wa, á máa ń gba ọmọbìnrin wa níyànjú pé kó bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́.”—Elisa, láti Ítálì.

◼ “A kì í fọ̀ràn eré ìtura àwọn ọmọ wa ṣeré. A máa ń ṣètò àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé fún wọn, irú bíi nínajú lọ síbi tó lẹ́wà, pípe àpèjẹ ráńpẹ́, ṣíṣeré lọ sáwọn ibi pàtàkì, àti kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra. Lọ́nà yìí, àwọn ọmọ wa kì í wo eré ìtura bí ohun kan táwọn lè gbádùn pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ nìkan.”—John, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

◼ “Bá a bá pé jọ pẹ̀lú àwọn ará tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ó máa ń gbádùn mọ́ wa gan-an ni. Àwọn ọmọ mi tún fẹ́ràn kí wọ́n máa gbá bọ́ọ̀lù, nítorí náà, látìgbàdégbà la máa ń ṣe eré ìdárayá yìí pẹ̀lú àwọn míì.”—Juan, láti Sípéènì.

◼ “A máa ń gba àwọn ọmọ níyànjú pé kí wọ́n máa fi àwọn èlò orin ṣeré. Ọ̀pọ̀ eré àfipawọ́ la tún jọ máa ń ṣe, bíi gbígbá ẹyin orí tábìlì, gbígbá bọ́ọ̀lù gba orí àwọ̀n, gígun kẹ̀kẹ́, kíkàwé àti bíbá àwọn ọ̀rẹ́ wa ṣeré.”—Mark, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

◼ “Gbogbo wa máa ń lọ ṣeré ìdárayá pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa. A ó to nǹkan sílẹ̀, a óò wá máa ju ohun mìíràn sí i kó lè wó. A tún máa ń ṣètò àwọn nǹkan pàtàkì míì tá a lè jọ máa ṣe lẹ́ẹ̀kan lóṣù. Báwọn òbí ṣe lè kòòré ìṣòro ni pé kí wọ́n máa fiyè sí ohun táwọn ọmọ wọn bá ń ṣe.”—Danilo, láti orílẹ̀-èdè Philippines.

◼ “Lílọ fojú ara wá rí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ níbi tí onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń wáyé sábà máa ń gbádùn mọ́ni ju kéèyàn wulẹ̀ jókòó kalẹ̀ kó sì máa wo fíìmù. A máa ń fojú sọ́nà ká lè mọ ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíi ṣíṣe àfihàn àwòrán aláfọwọ́yà, àfihàn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, tàbí eré orín kíkọ máa wáyé lágbègbè ibi tá à ń gbé. A máa ń lè bára wa sọ̀rọ̀ níbi irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí. A sì máa ń kíyè sára kí eré ìnàjú wa má pọ̀ jù. Kì í ṣe nítorí pé àkókò lè máà tó nìkan ni, àmọ́, bí eré ìtura bá tún pọ̀ jù ó lè jẹ́ kó ṣá, kó má sì gbádùn mọ́ni mọ́.”—Judith, láti orílẹ̀-èdè South Africa ló sọ̀rọ̀ yìí.

◼ “Kì í ṣe gbogbo nǹkan táwọn ọmọ míì ń ṣe ló bójú mu fáwọn ọmọ tèmi, mo sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, èmi àti ọkọ mi máa ń ṣètò eré ìnàjú tó dáa fún wọn. À ń sa gbogbo ipá wa kí wọ́n má bàa máa sọ pé, ‘A kì í ríbi lọ ní tiwa. A kì í kúrò nílé.’ Gbogbo wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé, jọ máa ń lọ sáwọn ọgbà ẹlẹ́wà a sì máa ń pe àwọn míì tá a jọ wà nínú ìjọ pé kí wọ́n wá jẹun nílé wa.” d—Maria, láti Brazil.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

d Bó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa pípe àpèjẹ, wo ìwé ìròyìn wa kejì, ìyẹn Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1992, ojú ìwé 15 sí 20.

[Credit Line]

Ilé àkójọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé James Hall Museum of Transport, nílùú Johannesburg, lórílẹ̀-èdè South Africa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Kọ́kọ́ gbọ́ kókó inú fíìmù kan KÓ o tó pinnu bóyá wàá wò ó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Ẹ̀yin òbí, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè yan fíìmù tó tọ́