Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé O Máa Ń Ṣe Eré Ìmárale Tó Bó Ṣe Yẹ?

Ṣé O Máa Ń Ṣe Eré Ìmárale Tó Bó Ṣe Yẹ?

Ṣé O Máa Ń Ṣe Eré Ìmárale Tó Bó Ṣe Yẹ?

“Kò sóògùn kankan báyìí tó lè mú kó dá èèyàn lójú pé olúwarẹ̀ ò ní ṣàìsàn, bóyá ló sì lè wà lọ́jọ́ iwájú, ohun tó lè mú kára èèyàn máa le ní gbogbo ìgbà ò kọjá kéèyàn máa ti kékeré ṣe eré ìmárale, tó bá sì dàgbà, kó máà jáwọ́ nínú ẹ̀.”

LỌ́DÚN 1982 ni Dókítà Walter Bortz II, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn ní yunifásítì, kọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yẹn. Ọdún kẹtàlélógún tó ti kọ ọ̀rọ̀ náà rèé, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ògbógi nínú ìmọ̀ ìlera, àwọn ilé iṣẹ́ àtàwọn lájọlájọ ló ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé, ìwé ìròyìn àti sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ẹ̀rí wà pé bí àmọ̀ràn Dókítà Bortz ṣe tọ̀nà tó, tó sì wúlò tó lọ́dún 1982 náà ló ṣì ṣe tọ̀nà, tó sì wúlò di bá a ṣe ń wí yìí. Nítorí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń ṣe eré ìmárale tó pọ̀ tó?’

Àwọn kan máa ń ṣàṣìṣe nípa sísọ pé àwọn ò nílò eré ìmárale nítorí pé àwọn ò tíì sanra jù? Lóòótọ́, àwọn tó bá sanra jọ̀kọ̀tọ̀ àtàwọn tó bá ki pọ́pọ́ jù á rí àǹfààní tó pọ̀ jẹ bí wọ́n bá ń ṣeré ìmárale déédéé. Àmọ́, bó ò bá tiẹ̀ sanra jù pàápàá, tó o bá túbọ̀ ń lo ara rẹ sí i, ó ṣeé ṣe kó ṣàǹfààní fún ìlera rẹ kó sì jẹ́ kára ẹ lè dènà àwọn àrùn lílágbára, tó fi mọ́ irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ kan báyìí. Bákan náà, àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ṣíṣe eré ìmárale lè dín àníyàn kù ó sì lè dènà àárẹ̀ ọkàn. Òótọ́ kan rèé, ọ̀pọ̀ àwọn tí kò sanra náà máa ń lárùn ọpọlọ, àìbalẹ̀ ọkàn, àrùn òpójẹ̀, àrùn àtọ̀gbẹ àtàwọn àrùn míì tí àìṣe eré ìmárale tó pọ̀ tó máa ń fà. Nítorí náà, yálà o sanra tàbí o kò sanra, tó o bá máa ń jókòó sójú kan, á dáa kó o fi kún àwọn nǹkan tó ò ń fara ṣe.

Ta La Lè Sọ Pé Ó Ń Jókòó Sójú Kan?

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bó o bá ń lo ara rẹ tó bó ṣe yẹ? Oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ń sọ nípa irú ẹni tá a lè sọ pé ó ń jókòó sójú kan. Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀ràn nínú ìṣègùn gbà pé ó láwọn ohun kan tí wọ́n fi lè mọ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ lọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ fún. Ìlànà kan tí ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ìlera máa ń tẹ̀ lé nìyí, wọ́n gbà pé tí ọ̀kan nínú ohun márùn-ún tó tẹ̀ lé e yìí bá bá ọ mu, a jẹ́ pé ò ń jókòó sójú kan nìyẹn. (1) o kì í ṣeré ìmárale tàbí iṣẹ́ àṣelàágùn fún, ó kéré tán, ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lójúmọ́, lẹ́ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀. (2) o kì í rìn lọ rìn bọ̀ bó o bá ń ṣeré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀, (3) o kì í rìn tó ọgọ́rùn-ún mítà tí ilẹ̀ fi máa ṣú, (4) orí ìjókòó lo máa ń wà ní gbogbo àkókò tó o bá ń ṣiṣẹ́. (5) iṣẹ́ rẹ ò fi bẹ́ẹ̀ gba agbára.

Ǹjẹ́ ò ń ṣe eré ìmárale tó pọ̀ tó? Bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí wá nǹkan ṣe sí i látòní lọ. O lè sọ pé ‘Níbo ni màá ti wá ráàyè.’ Nígbà tó o bá jí láàárọ̀, ó ti máa ń rẹ̀ ọ́ jù. Látàárọ̀ lọwọ́ rẹ á ti dí, o fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè ráàyè múra ibi iṣẹ́ gan-an. Tó o bá wá tibi iṣẹ́ dé, á tún ti rẹ̀ ọ́ kọjá kó o lè ṣe eré ìmárale èyíkéyìí, ọ̀pọ̀ nǹkan láá sì wà nílẹ̀ tó yẹ kó o ṣe.

Bóyá o sì wà lára àwọn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n pa á tì lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan nítorí pé wọ́n rí i pé ó ni àwọn lára, tàbí kó fẹ́ di àìsàn sí wọn lára lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣeré ìmárale tán. Ohun tí kò sì jẹ́ káwọn míì fẹ́ máa ṣe é ni pé wọ́n rò pé dandan ni kí eré ìmárale téèyàn á máa ṣe tó sì máa ṣèèyàn láǹfààní jẹ́ èyí tó nira. Wọ́n rò pé kéèyàn máa gbé ohun tó bá wúwo sókè tàbí kó máa sáré ẹlẹ́mìí ẹṣin lọ sọ́nà jíjìn, àti eré ìmárale tá a ṣètò ẹ̀ lọ́nà tí kò ṣée yí padà ni nǹkan tó lè ṣèèyàn láǹfààní.—Wo àpótí náà “Gbígbé Ohun Tó Wúwo àti Nínara.”

Wàhálà míì tún ni ti ìnáwó àti ìdààmú tó máa ń kó èèyàn sí. Àwọn tó bá fẹ́ máa sáré kúṣẹ́kúṣẹ́ máa nílò irú aṣọ àti bàtà tó bá a mu. Àwọn tó bá sì fẹ́ máa mú kí iṣan wọn ràn nílò ohun tí wọ́n á máa gbé àtàwọn àkànṣe ẹ̀rọ kan. Ó níye owó tí wọ́n máa ń gbà kéèyàn tó lè lọ máa bá wọn ṣe eré ìmárale làwọn ibi tí wọ́n dá sílẹ̀ fún un. Àkókò téèyàn á lò gan-an kó tó dé ibi táá ti lọ ṣeré ìmárale lè jẹ́ kó sú èèyàn. Síbẹ̀, gbogbo ìyẹn ò tó nǹkan tó lè mú kó o máà nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣeré ìmárale, kó o sì jàǹfààní nínú ẹ̀.

Mọ̀wọ̀n Ara Rẹ

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, bó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ eré ìmárale kan, máà gbé nǹkan tó kọjá agbára ẹ síwájú ara ẹ. Díẹ̀díẹ̀ ni kó o bẹ̀rẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ síwájú wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n, wọ́n sì ń dá a lábàá pé káwọn tó ń jókòó sójú kan rọra máa fi kún ṣíṣe ohun táá máa mú wọn làágùn. Bí àpẹẹrẹ, ilé ìwé gíga University of California fi ìwé kan ṣọwọ́ síta tí wọ́n pè ní UC Berkeley Wellness Letter. Ìwé náà sọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ tó dáa fún ara, bí ara ṣe lè máa dá ṣáṣá, àti ohun téèyàn lè ṣe tí nǹkan bá ń dà á láàmú. Wọ́n sọ nínú ìwé náà pé: “Bẹ̀rẹ̀ nípa fífi ìṣẹ́jú mélòó kan ṣe eré ìmárale lójúmọ́, kó o sì jẹ́ kí àkókò náà máa gùn sí i díẹ̀díẹ̀ títí táá fi pé ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, á sì dáa tó bá jẹ́ pé ojóojúmọ́ lò ń ṣe é.” Ìwé náà ṣàlàyé pé “gbogbo ohun tó o ní láti ṣe ò kọjá àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ìrìn rírìn àti gígun àtẹ̀gùn, ẹnu kó o wulẹ̀ máa ṣe é wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ni, kó o sì jẹ́ kí àkókò tí wàá fi máa ṣe é máa gùn sí i tàbí kó o máa yára ṣe é.”

Ohun tó yẹ kó jẹ àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lógún ni bó ṣe ṣe lemọ́lemọ́ tó, kì í ṣe bó ṣe pọ̀ tó. Tó bá wá di pé agbára rẹ pọ̀ sí i tó o sì ti lè ń rọ́jú sí i, o lè jẹ́ kí èyí tó ò ń ṣe máa pọ̀ sí i. O lè ṣe èyí nípa mímú kí àkókò tó o fi ń ṣe ohun tó gba agbára máa gùn sí i, irú bẹ́ẹ̀ ni rírìn kánmọ́kánmọ́, sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, gígun àtẹ̀gùn, tàbí gígun kẹ̀kẹ́. Bó bá yá, o lè fàwọn eré ìmárale míì táá jẹ́ kára gbé kánkán kún un, ó tiẹ̀ lè jẹ́ gbígbé ohun tó wúwo àtàwọn eré míì tó lè máa jẹ́ kí ara nà dáadáa. Nígbà kan, àwọn ògbógi gbà pé eré ìmárale tó bá máa ṣèèyàn láǹfààní gbọ́dọ̀ mú ìrora dání, àmọ́ ọ̀pọ̀ nínú wọn ò sọ bẹ́ẹ̀ mọ́ báyìí. Nítorí náà, kó o má bàa ṣèṣe, kó má sì sú ẹ débi tí wàá fi fẹ́ pa á tì, máa ṣe eré ìmárale níwọ̀nba.

Máa Ṣe É Déédéé

Àwọn tó dà bíi pé wọn ò lè máa ráàyè ṣe eré ìmárale lè fara mọ́ àbá tó wà nínú ìwé UC Berkeley Wellness Letter. Ó ṣàlàyé pé “eré ìmárale téèyàn bá ń fi àkókò kúkúrú ṣe jálẹ̀ ọjọ́ kan lè ṣàǹfààní fún ìlera wa. Ìyẹn ni pé, téèyàn bá ń fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá mẹ́wàá ṣe eré ìmárale lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́, àǹfààní tó wà níbẹ̀ á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó èyí téèyàn fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣe lẹ́ẹ̀kan gbọ̀n-ọ́n.” Èyí tó fi hàn pé kò pọn dandan kó o fàkókò gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ṣe eré ìmárale kó tó lè ṣe ọ́ lóore. Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ròyìn pé àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé “eré ìmárale tí kò pọ̀ jara lọ, àti iṣẹ́ táá mú kéèyàn làágùn, wà lára ohun tó lè bá èèyàn dènà àrùn iṣan ẹ̀jẹ̀ ọkàn.”

Ṣùgbọ́n ó pọn dandan kéèyàn máa ṣe é déédéé o. O lè máa lo kàlẹ́ńdà láti ṣètò àwọn ọjọ́ àti àkókò tí wàá fẹ́ fi eré ìmárale sí. Tó bá ti di bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan tó o ti ń ṣe é, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé eré ìmárale tó ò ń ṣe wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ti mọ́ ẹ lára. Tó bá ti wá di pé o ti ń rí àǹfààní ẹ̀ nínú ara ẹ báyìí, á di pé kí ara ẹ ti máa wà lọ́nà de ìgbà tí eré ìmárale ẹ máa ń bọ́ sí.

Ẹni Tó Bá Ń Lo Ara Rẹ̀ Lára Rẹ̀ Máa Ń Le

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni pé fífi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré ṣe ohun tó gba agbára lójúmọ́ lè mú kára rẹ mókun sí i, síbẹ̀ àwọn tó mọ̀ nípa ọ̀ràn ìlera gbani nímọ̀ràn lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé á dáa tó bá jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n ti ń sọ báyìí pé kí ọkàn àti òpójẹ̀ èèyàn bàa lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, ó yẹ kéèyàn máa lò tó wákàtí kan lórí ohun tó gba agbára lójúmọ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, èèyàn lè rọra máa ṣe é díẹ̀díẹ̀, kó ṣáà ti pé wákàtí kan lójúmọ́ ló jà jù. Ìwé ìròyìn Canadian Family Physician ṣàlàyé pé “àwọn àbá tá a ní lọ́wọ́ báyìí sábà máa ń dá lórí pé kéèyàn máa lo wákàtí kan lójúmọ́ lórí ṣíṣe ohun tó gba agbára ṣùgbọ́n ó lè máa ṣe é díẹ̀díẹ̀. Téèyàn bá wá ń tìtorí àwọn ọ̀ràn kan tó jẹ mọ́ ìlera ṣe é, bó bá ṣe wu èèyàn ló ṣe lè pín wákàtí kan yìí.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìwádìí ti fi hàn pé téèyàn bá ń lo ara rẹ̀ tó bó ṣe yẹ, gbogbo àìsàn tó lè pa èèyàn á jìnnà sí olúwarẹ̀, síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé eré ìmárale tó mọ níwọ̀n ló dáa jù.”

Ohun tí gbogbo nǹkan tá à ń sọ yìí túmọ̀ sí ni pé, bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá ọ, ara rẹ ṣeé gbé síwá sẹ́yìn, o sì lè máa fi ṣiṣẹ́ tó gba agbára. Jíjókòó sójú kan ò dáa fún ara rẹ. Kò sì sí fítámì, egbòogi, oúnjẹ, tàbí iṣẹ́ abẹ kankan tó o lè fi rọ́pò lílo ara rẹ. Bákan náà, ọgbọ́n yòówù ká dá, eré ìmárale èyíkéyìí tá a bá yàn láti ṣe á gba àkókò. Ì báà jẹ́ eré ìmárale tó mọ níwọ̀n ni o, tàbí èyí tó nílò okun, yálà èyí tá à ń ṣe wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, tàbí èyí tá a fi àkókò gígùn ṣe, kókó tó wà níbẹ̀ ni pé á gba àkókò. Bó o ṣe ń wá àkókò láti jẹun àti láti sùn, bákan náà ló ṣe pàtàkì pé kó o wá àkókò láti máa lo ara rẹ. Èyí gba pé kó o fi nǹkan du ara rẹ kó o sì ní ètò tó dáa.

Kò sí eré ìmárale tí kò gba ìsapá. Àmọ́, tó o bá rò ti pé jíjókòó sójú kan lè la ẹ̀mí lọ, kékére ni ti gbogbo wàhálà àti ohun tó o bá fi du ara ẹ torí kára ẹ lè máa gbé kánkán. Máa fara ẹ ṣiṣẹ́, máa ṣe ohun tó máa mú ọ làágùn déédéé. Lo ara ẹ, ó lè jẹ́ kí ẹ̀mí ẹ gùn sí i, kó o sì pẹ́ láyé!

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn Eré Ìmárale Tó Túbọ̀ Gba Agbára

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé téèyàn bá ń fi kún bó ṣe ń lo ara rẹ̀ lójoojúmọ́, ó lè jẹ́ kára ẹ̀ túbọ̀ máa le, àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé téèyàn bá ń ṣe eré ìmárale tó túbọ̀ gba agbára, á tún ṣàǹfààní díẹ̀ sí i. Àwọn eré ìdárayá tí wọ́n dá lábàá nìwọ̀nyí.

Àwọn onímọ̀ nípa ìlera sọ pé kéèyàn kàn sí dókítà rẹ̀ kó tó bẹ̀rẹ̀ eré ìmárale èyíkéyìí tó gba agbára.

Rírìn Kánmọ́kánmọ́: Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó rọrùn téèyàn lè gbà máa ṣe eré ìmárale rèé. Gbogbo ohun tó o nílò ò kọjá bàtà tó dùn ún gbé àti ojú ọ̀nà. Bó o bá fẹ́ máa rin irú ìrìn yìí, máa na ẹsẹ̀ rẹ kó gùn kó o sì máa yára rìn ju tìgbà tó o bá ń rìnrìn gbẹ̀fẹ́. Gbìyànjú láti rin ìrìn tó yára tó ti ẹni tó ń rin ìrìn kìlómítà mẹ́rin sí mẹ́sàn-án láàárín wákàtí kan.

Sísáré Kúṣẹ́kúṣẹ́: Ẹlẹgbẹ́ pé ò ń sáré náà ni tó o bá ń sáré kúṣẹ́kúṣẹ́, ó kàn jẹ́ pé ṣe lo rọra ń sá a ni. Wọ́n ti sọ pé kéèyàn máa sáré kúṣẹ́kúṣẹ́ lọ̀nà tó dáa jù láti mú kí òpójẹ̀ èèyàn máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Àmọ́, nítorí bó ṣe máa ń gba pé kéèyàn máa gbé gbogbo ara, ó lè mú kí iṣan àti oríkèé ara máa dun èèyàn. Látàrí èyí, wọ́n máa ń rán àwọn tó ń sáré kúṣẹ́kúṣẹ́ létí pé wọ́n nílò bàtà tó dáa, kí wọ́n sì máa nara, àmọ́ kó jẹ́ níwọ̀nba.

Kẹ̀kẹ́ gígùn: Bó o bá ní kẹ̀kẹ́, o lè máa gbádùn eré ìmárale tó ṣàǹfààní fún ara rẹ. Kẹ̀kẹ́ gígùn lè mú kéèyàn jó ooru tó pọ̀ tó ìwọ̀n kálórì ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin dà nù nínú ara láàárín wákàtí kan. Àmọ́, bí ìrìn rírìn, ojú ọ̀nà lèèyàn ti sábà máa ń gun kẹ̀kẹ́. Fún ìdí èyí, ó yẹ kó o wà lójú fò tó o bá ń gun kẹ̀kẹ́, kó o ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kó o ṣe kó o má bàa kàgbákò jàǹbá.

Lílúwẹ̀ẹ́: Bó o bá ń lúwẹ̀ẹ́, gbogbo ibi tí iṣan pọ̀ sí lára rẹ ni wàá máa lò. Ó tún lè mú káwọn oríkèé ara rẹ rọ̀, gbogbo ohun tí sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́ máa ṣe fún òpójẹ̀ rẹ náà ni lílúwẹ̀ẹ́ lè ṣe fún ọ. Nítorí pé lílúwẹ̀ẹ́ kì í sábà ṣe ara ní wàhálà tó bẹ́ẹ̀, ohun ni eré ìmárale tí wọ́n sábà máa ń yàn fáwọn tí oríkèé bá ń ro, tẹ́yìn bá ń dùn, tàbí àwọn tíṣòro wọ́n jẹ mọ́ sísanra, wọ́n sì máa ń sọ fáwọn aláboyún náà pé kí wọ́n máa ṣe é. Ṣùgbọ́n má ṣe dá lúwẹ̀ẹ́ o.

Títọ Pọ́únpọ́ún: Ohun téèyàn nílò láti máa ṣe irú eré ìmárale yìí, ìyẹn ọ̀kan táá máa mú kéèyàn máa mí dáadáa, kò ju ohun kan téèyàn lè gbé sílẹ̀, táá wá máa tọ lórí ẹ̀, táá sì máa ta olúwarẹ̀ sókè. Àwọn tó ń ṣagbátẹrù eré ìmárale yìí máa ń sọ pé títọ pọ́únpọ́ún máa ń mú kí ẹ̀jẹ̀ àti omi ara lè máa ṣàn dáadáa ó sì máa ń mú kí ọkàn àti ẹ̀dọ̀fóró lágbára. Bakan náà, ó máa ń mú kí ara tò dáadáa kó sì lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Gbígbé Ohun Tó Wúwo àti Nínara

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé èèyàn gbọ́dọ̀ fi gbígbé ohun tó bá wúwo kún eré ìmárale téèyàn bá fẹ́ máa ṣe kára ẹ̀ tó lè máa gbé kánkán. Béèyàn bá ṣe é bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, gbígbé ohun tó bá wúwo máa ń mú kéèyàn níṣu lára, ó sì máa ń mú kí eegun èèyàn lágbára, kì í sì í jẹ́ kí ọ̀rà pọ̀ jù lára.

Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìlera tún ń sọ pé ó dáa kéèyàn máa nara kí ara lè rọ̀ kí ẹ̀jẹ̀ sì lè máa ṣàn dáadáa nínú ara. Nínara tún lè mú káwọn oríkèé ara rẹ ṣeé gbé dáadáa.

Àmọ́ ṣá, kó o má bàa ṣèṣe, ó yẹ kó o kíyè sí bí wàá ṣe máa gbé ohun tó bá wúwo àti bí wàá ṣe máa nara. Á dáa tó o bá mọ àwọn ìlànà tó wà lórí eré ìmárale wọ̀nyí nípa kíka àwọn ìwé tí wọ́n kọ lórí rẹ̀ tàbí kó o kàn sí dókítà rẹ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àǹfààní Tí Eré Ìmárale Ń Ṣe fún Ọkàn Rẹ

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti rí i pé téèyàn bá ń lo ara rẹ̀, ó lè mú káwọn èròjà inú ọpọlọ tó máa ń jẹ́ kí ìṣesí èèyàn yí padà máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Irú àwọn èròjà bẹ́ẹ̀ ni dopamine, norepinephrine, àti serotonin. Ó lè jẹ́ ìyẹn ló fà á tọ́pọ̀ èèyàn fi máa ń sọ pé ọkàn àwọn máa ń balẹ̀ táwọn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe eré ìmárale tán. Àwọn ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé àárẹ̀ ọkàn kì í sábàá ṣe àwọn tó bá ń ṣe eré ìmárale déédéé bí àwọn tó bá ń jókòó sójú kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì lè mú nǹkan gbòógì jáde lórí àwọn ìwádìí yìí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ dókítà ló máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe eré ìmárale láti lè dín àníyàn àti àìbalẹ̀ ọkàn kù.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Ìgbòkègbodò Ojoojúmọ́ Tó Ń Mú Kára Le

Ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn tó máa ń jókòó sójú kan lè jàǹfààní bí wọ́n bá túbọ̀ ń fi kún àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ tó gba agbára. O lè fẹ́ dán díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí wò.

● Tó o bá fẹ́ lọ sókè, gun àtẹ̀gùn dípò tí wàá fi máa lo ẹ̀rọ agbéniròkè, o sì lè kúrò nínú ẹ̀rọ agbéniròkè náà kó tó gbé ọ dé ibi tó ò ń lọ kó o bàa lè gun àtẹ̀gùn débẹ̀.

● Bó o bá wọkọ̀ èrò, bọ́ sílẹ̀ tó bá ku bí ibùdókọ̀ mélòó kan kó o dé ibi tó ò ń lọ kó o wá fẹsẹ̀ rin ìyókù.

● Bó bá jẹ́ pé mọ́tò ara rẹ lo gbé jáde, fi kọ́ra láti máa gbé e síbi tó jìnnà díẹ̀ sí ibi tó ò ń lọ. Bó bá jẹ́ pé ibi ìgbọ́kọ̀sí tó ní ìpele lo fẹ́ gbé ọkọ̀ rẹ sí, gbé e sí ìpele tó wà ní ìsàlẹ̀ kó o bàa lè gun àtẹ̀gùn.

● Máa sọ̀rọ̀ lórí ìrìn. Kò pọn dandan pé kó o máa jókòó ní gbogbo ìgbà tó o bá ń bá ọ̀rẹ́ ẹ tàbí ara ilé ẹ sọ ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ lè sọ lórí ìrìn tàbí lórí ìdúró.

● Bó bá jẹ́ pé iṣẹ́ ìjókòó lò ń ṣe, wáàyè láti máa ṣe é lórí ìdúró, kó o sì máa rìn ká tó bá ṣeé ṣe nígbà tó o bá ń ṣiṣẹ́.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣé Ò Ń Mu Omi Tó Pọ̀ Tó?

Ó léwu tí o kì í bá mu omi tó pọ̀ tó lásìkò tó o bá ń ṣeré ìmárale. Ó lè mú kára wó ẹ, káwọn ẹ̀yà ara rẹ má ṣiṣẹ́ dáadáa tàbí kó fa pajápajá fún ọ. Nígbà tó o bá ń ṣeré ìmárale, wàá làágùn púpọ̀, èyí sì lè mú kí ẹ̀jẹ̀ tó wà lára rẹ dín kù. Bó ò bá wá mu omi tó pọ̀ tó láti fi dípò omi ara tó ti bá òógùn jáde, ọkàn rẹ lè ní láti máa ṣiṣẹ́ agbára kó tó lè mú kí ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn káàkiri nínú ara rẹ. Àbá kan ni pé kó má bàa di pé omi ara rẹ gbẹ tán, ó yẹ kó o máa mu omi kó o tó ṣeré ìmárale àti nígbà tó o bá ń ṣe é lọ́wọ́ àti nígbà tó o bá ṣe é tán.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Tọ́jú Ara Rẹ—Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni

Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa fọwọ́ pàtàkì mú ara wa àti ẹ̀bùn ìwàláàyè tá a ní. Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.” (Sáàmù 139:14) Bíi ti Dáfídì, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọrírí ẹ̀bùn ìwàláàyè. Àwọn pẹ̀lú sì máa ń ka ìtọ̀jú ara wọn sí iṣẹ́ pàtàkì.

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì ṣẹ́yìn, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀; ṣùgbọ́n fífọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” (1 Tímótì 4:8) Ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ yìí fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àǹfààní gidi ló wà nínú ṣíṣeré ìmárale, síbẹ̀ àwọn àǹfààní náà ò ṣe pàtàkì bíi kéèyàn jèrè ojú rere Ọlọ́run. Ìdí rèé tó fi yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ gbìyànjú láti máà jẹ́ kí wíwá tí wọ́n ń wá bí ara wọn á ṣe le, ìyẹn “ara títọ́,” gborí lọ́wọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.

Àwọn Kristẹni mọ̀ pé bí ara àwọn bá ṣe le tó làwọn ṣe máa lè fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn hàn tó. Láfikún sí kéèyàn máa jẹ oúnjẹ tó dáa kó sì máa sinmi, ó tún yẹ kéèyàn máa lo ara rẹ̀ kó bàa lè ní ìlera tó dáa. Nítorí pé wọ́n mọ̀ pé ẹ̀bùn pàtàkì ni ara wọn jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbìyànjú láti máa tọ́jú ara wọn dáadáa.