Ṣé O Rò Pé Jésù Ni Ọlọ́run?
Ṣé O Rò Pé Jésù Ni Ọlọ́run?
Ngbọ́ kí lo ti rò ó sí? Ṣé o gbà gbọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan, ìyẹn ẹni mẹ́ta nínú ọ̀kan? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé “mẹ́talọ́kan” ò fara hàn nínú Bíbélì àti pé Bíbélì ò fi irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ni?
Bó o bá fẹ́ láti mọ sí i, o máa gbádùn kíka ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32, tó ní àkòrí náà, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.