Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Burú Kéèyàn Máa Wá Ipò Ọlá Ni?

Ṣó Burú Kéèyàn Máa Wá Ipò Ọlá Ni?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Burú Kéèyàn Máa Wá Ipò Ọlá Ni?

“Ẹ GBỌ́ ná, kí ló burú nínú kéèyàn di olókìkí, ọlọ́là àti alágbára?” Inú ìròyìn àwọn ẹlẹ́sìn kan la ti rí ìbéèrè yìí. Ó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Àìfohùnṣọ̀kan Lórí Ìlànà.” Ìròyìn náà mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù sọ, tó kà pé: “Èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ, èmi yóò sì mú kí orúkọ rẹ di ńlá.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí i kà nínú ìròyìn náà pé “èèyàn ò gbọ́dọ̀ máa wá ipò ọlá débi táá fi kó bá àwọn ẹlòmíì,” síbẹ̀ ìròyìn náà mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ tí gbajúgbajà olùkọ́ ẹ̀sìn Júù kan sọ ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Bí mi ò bá fọwọ́ ara mi gbé ara mi dépò, ta ló máa gbé mi débẹ̀?” ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bá ò bá ṣiṣẹ́ kára láti dé gbogbo ibi tó ṣeé ṣe fúnni láti dé, kò sẹ́ni tó máa gbéni débẹ̀.” Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ohùn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àtimáa sin Ọlọ́run ò ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ wíwá ipò ọlá? Àwọn nǹkan wo ló rọ̀ mọ́ kéèyàn máa ṣiṣẹ́ kára láti dé gbogbo ibi tó bá lè dé? Ṣó burú kéèyàn máa wá ipò ọlá ni? Ojú wo ni Bíbélì fi wo ọ̀ràn náà?

Ǹjẹ́ Ábúráhámù Wá Ipò Ọlá?

Bíbélì fi hàn pé Ábúráhámù jẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tayọ. (Hébérù 11:8, 17) Nígbà tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára Ábúráhámù àti pé òun yóò sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá, kì í ṣe pé ó fẹ́ kí Ábúráhámù máa wá ipò ọlá. Ńṣe ni Ọlọ́run wulẹ̀ ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ nípa bí òun á ṣe bù kún gbogbo aráyé nípasẹ̀ Ábúráhámù, bẹ́ẹ̀ ìlérí yìí ṣe pàtàkì fíìfíì ju ipò ọlá yòówù téèyàn kan lásán lè máa wá.—Gálátíà 3:14.

Nítorí pé Ábúráhámù sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ló fi gbà láti yááfì ìgbé ayé tó tura ní ìlú Úrì níbi tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù. (Jẹ́nẹ́sísì 11:31) Nígbà tó ṣe, Ábúráhámù yọ̀ǹda tinútinú pé kí Lọ́ọ̀tì tẹ̀ dó sí ilẹ̀ tó dára ju tiẹ̀ lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára àti àṣẹ lórí Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 13:8, 9) Kò sí ibikíbi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ Ábúráhámù bí ẹni tó ń wá ipò ọlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́, ìgbọràn àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ ló mú kó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run, tó sì wá di “ọ̀rẹ́” rẹ̀ gidi.—Aísáyà 41:8.

Ojú Tó Yẹ Ká Fi Máa Wo Ipò, Òkìkí àti Agbára

Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé àwọn tó ń wá ipò ọlá máa ń fẹ́ láti ní “ipò, òkìkí, tàbí agbára ní gbogbo ọ̀nà.” Ní ìgbàanì, Sólómọ́nì Ọba ní ipò, òkìkí àti agbára, ó sì tún ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ. (Oníwàásù 2:3-9) Àmọ́, kì í ṣe pé ó ń wá wọn ní gbogbo ọ̀nà kó tó di pé wọ́n tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ o. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé nígbà tí Sólómọ́nì gorí ìtẹ́ baba rẹ̀, Ọlọ́run sọ fún un pé kó béèrè ohunkóhun tó bá fẹ́. Sólómọ́nì fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti jẹ́ onígbọràn kó sì fún òun ní ìfòyemọ̀ tí yóò fi lè máa ṣàkóso àwọn èèyàn tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 3:5-9) Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì fẹnu ara rẹ̀ ṣàlàyé bí ọrọ̀ àti agbára tí òun ní ṣe pọ̀ tó, ó wá polongo pé “asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 2:11.

Ǹjẹ́ Sólómọ́nì tiẹ̀ sọ ohunkóhun nípa kéèyàn máa ṣiṣẹ́ kára láti dé gbogbo ibi tó bá lè dé? Kò ṣaláì sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó ti ronú síwá sẹ́yìn lórí àwọn ohun tójú rẹ̀ ti rí, ibi tó parí ọ̀rọ̀ sí ni pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:13) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gan-an nìyẹn, ẹ̀dá lè ṣiṣẹ́ kára kó sì dé ibi tó bá lè dé tó bá ṣáà ti jẹ́ pé torí àtiṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni tí kì í ṣe nítorí àtiwá ipò, ọrọ̀, òkìkí, tàbí agbára.

Ìwà Ìrẹ̀lẹ̀ Ní Í Gbéni Lékè

Lóòótọ́, kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bíbélì tiẹ̀ pàṣẹ fún wa pé ká fẹ́ràn aládùúgbò wa bí ara wa. (Mátíù 22:39) Kò sí ẹ̀dá tí kì í wù kí ara tù tàbí kó láyọ̀. Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ tún rọ̀ wá pé ká jẹ́ òṣìṣẹ́kára, onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. (Òwe 15:33; Oníwàásù 3:13; Míkà 6:8) Àwọn èèyàn sábà máa ń kíyè sí ẹni tí kì í ṣàbòsí, tó ṣeé fọkàn tán, tó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára, irú wọn máa ń ríṣẹ́ tó dáa, àwọn èèyàn sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Dájúdájú, ó sàn kéèyàn rí báyìí ju kó máa ṣe èrú nítorí àpò ara tiẹ̀ tàbí kó máa du ipò mọ́ àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.

Jésù kìlọ̀ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe máa wá ibi tó lọ́la jù lọ fún ara wọn bí wọ́n bá pè wọ́n síbi àsè ìgbéyàwó. Ó fún wọn nímọ̀ràn pé kí wọ́n lọ síbi tó rẹlẹ̀ jù lọ, bóyá ẹni tó pè wọ́n lè wá ní kí wọ́n lọ jókòó síbi tó lọ́lá jù. Kedere ni Jésù mẹ́nu kan ìlànà tó wé mọ́ èyí nígbà tó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ àti ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”—Lúùkù 14:7-11.

Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Wá Ipò Ọlá

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbéraga tó ń mú kéèyàn máa wá ipò ọlá kò ṣẹ̀yìn àìpé ẹ̀dá. (Jákọ́bù 4:5, 6) Àpọ́sítélì Jòhánù náà ti wá ipò ọlá rí. Gbogbo ọ̀nà ni òun àti arákùnrin rẹ̀ fi ń wá ipò, débi tó fi sọ fún Jésù pé kó fáwọn ní ipò gíga nínú Ìjọba ọ̀run. (Máàkù 10:37) Nígbà tó ṣe Jòhánù yí ojú tó fi ń wo nǹkan padà. Kódà, nínú lẹ́tà rẹ̀ kẹta, ó bá Dìótíréfè wí kíkankíkan, nítorí pé gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, Dìótíréfè “ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́.” (3 Jòhánù 9, 10) Àwọn Kristẹni tòde òní fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn wọ́n sì rẹ ara wọn sílẹ̀, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Jòhánù, tó kọ́ láti jáwọ́ nínú ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú wíwá ipò ọlá.

Bá a bá sì ní ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kì í ṣe ẹ̀bùn àbínibí, ohun téèyàn lágbára àtiṣe, iṣẹ́ rere ẹni, tàbí béèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ kára tó ló máa ń sọni di gbajúmọ̀. Bákan méjì ni, àwọn ẹlòmíràn lè torí èyí kani sí, àwọn ìgbà míì sì wà tí wọn ò ní já a kúnra. (Òwe 22:29; Oníwàásù 10:7) Nígbà míì, wọ́n lè gbé àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kúnjú ìwọ̀n sípò, nígbà táwọn tó kúnjú ìwọ̀n dáadáa á wà nílẹ̀ tí ò sẹ́ni tó rí wọn. Nínú ayé tí nǹkan kì í ti í lọ bó ṣe yẹ kó lọ yìí, kì í ṣe àwọn tó kúnjú ìwọ̀n jù lọ ni ipò àti agbára sábà máa ń já mọ́ lọ́wọ́.

Kò ṣòro rárá fáwọn Kristẹni tòótọ́ láti ṣe ohun tó yẹ bó bá dọ̀ràn ipò ọlá. Ẹ̀rí ọkàn wọn tí a ti fi Bíbélì kọ́ máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má ṣe máa wá ipò ọlá. Àmọ́, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe lábẹ́ ipò èyíkéyìí, sí ògo Ọlọ́run, wọ́n á sì fi ìyókù sọ́wọ́ rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Àwọn Kristẹni máa ń ṣiṣẹ́ kára láti dé ibi tí wọ́n bá lè dé tó bá di ọ̀ràn bíbẹ̀rù Ọlọ́run àti pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ṣé Ọlọ́run fẹ́ kí Ábúráhámù máa wá ipò ọlá ni?