Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dídáko Sínú Ọgbà Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní

Dídáko Sínú Ọgbà Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní

Dídáko Sínú Ọgbà Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní

ṢÉ Ó wù ọ́ kó o máa dáko sínú ọgbà? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àǹfààní tí wàá máa rí níbẹ̀ kọjá pé ò ń ṣe nǹkan tó ń wù ọ́ ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Independent ti ìlú London ṣe sọ, àwọn olùṣèwádìí ti rí ẹ̀rí pé “tó o bá ní ọgbà tó ò ń dáko sí, ó dáa fún ìlera rẹ, ó máa ń dín pákáǹleke kù, kì í jẹ́ kí ìfúnpá èèyàn ga, ó sì máa ń jẹ́ kẹ́mìí èèyàn gùn.”

Òǹkọ̀wé Gay Search sọ pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ kan tíṣẹ́ bá gbomi mu, ara á tù ẹ́ gan-an bó bá jẹ́ pé bó o ṣe délé, inú ọgbà rẹ lo bọ́ sí tó o sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́.” Kì í wulẹ̀ ṣe pé wàá rí irè kó níbẹ̀ àti pé á máa dùn mọ́ ẹ nìkan ni, ṣùgbọ́n bí eré ìmárale ló máa rí, á sì ṣe ọ́ láǹfààní ju eré ìmárale tó o bá lọ ṣe ní gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ń fara pitú. Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Gay Search ṣe sọ, “eré ìmárale tó dáa tí kò sì gbagbára làwọn iṣẹ́ bíi títúlẹ̀ àti fífi réèkì gbá ilẹ̀ jọ, wọ́n sì máa ń jẹ́ kéèyàn lè yọ́ ooru inú ara dà nù ju kẹ̀kẹ́ gígun lọ.”

Àwọn àgbàlagbà ni títọ́jú ọgbà ń ṣe láǹfààní jù. Bí wọ́n ṣe ń retí ìgbà tí irúgbìn á yọ ọ̀mùnú máa ń jẹ́ kí wọ́n ní ìfojúsọ́nà fún nǹkan tó máa mú inú wọn dùn. Láfikún sí i, Dókítà Brigid Boardman tó wà níléeṣẹ́ Royal Horticultural Society sọ pé “téèyàn bá ń dáko sínú ọ̀gbà, ó máa ń gba èèyàn lọ́wọ́ ìrora àti ìbànújẹ́” tó máa ń bá ọjọ́ ogbó rìn. Ọkàn àwọn àgbàlagbà sábà máa ń rẹ̀wẹ̀sì torí bí wọn kì í ṣe lè dá nǹkan ṣe. Àmọ́, bí Dókítà Boardman ṣe sọ, “tá a bá fẹ́ ohun tá a ó máa bójú tó, a lè máa bójú tó ohun tá a bá gbìn, bá ó ṣe gbìn ín, ká sì pinnu bí inú ọgbà wa ṣe máa rí. Bá a bá ń ṣe gbogbo ìyẹn, a ò ní lè sọ pé a ò rí nǹkan bójú tó.”

Ara sábà máa ń tu àwọn tí àìsàn tó jẹ mọ́ ọpọlọ ń dà láàmú tí wọ́n bá ń siṣẹ́ ní ibi tó lẹ́wà tó sì lálàáfíà. Yàtọ̀ síyẹn, bí àwọn òdòdó, tàbí oúnjẹ táwọn míì á jẹ nínú ẹ̀ bá ṣe ń hù, ẹni tó gbìn wọ́n á rí i pé kò tíì tán fóun, kò sì ní máa fojú wo ara ẹ̀ bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan.

Àmọ́ ṣá o, ọgbà ọ̀gbìn ń ṣe àwọn mìíràn láǹfààní yàtọ̀ sí àwọn tó ní in. Ọ̀jọ̀gbọ́n Roger Ulrich ti ilé ìwé gíga University of Texas ṣàyẹ̀wò àwọn kan lára àwọn tí wọ́n ti fi ìnira dán wò. Ìwádìí yẹn fi hàn pé nígbà tí wọ́n yẹ ìlùkìkì ọkàn wọn àti ìfúnpá wọn wò, ara àwọn tó wà níbi tí ohun ọ̀gbìn hù sí tètè ń yá ju tàwọn tí kò sí níbi tí ohun ọ̀gbìn pọ̀ sí lọ. Ìwádìí kan tó jọ ìyẹn náà fi hàn pé láàárín àwọn aláìsàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣiṣẹ́ abẹ́ fún nílé ìwòsàn, àwọn tí ara wọn tètè máa ń yá làwọn tó bá wà ní yàrá tí wọ́n ti lè máa rí àwọn igi. Tá a bá fi wọ́n wé àwọn aláìsàn míì, àwọn ni ara wọn “tètè máa ń yá, tí wọ́n sì tètè máa ń relé, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ nílò oògùn tó ń dín ìrora kù, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ráhùn tó àwọn yòókù.”