Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run

Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run

Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run

GẸ́GẸ́ BÍ IVAN MIKITKOV ṢE SỌ Ọ́

Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Àwọn Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB sọ fún mi pé: “Tó o bá dúró ní ìlú wa, o ṣì máa padà sẹ́wọ̀n.” Wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ dá mi sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún méjìlá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni o. Ó rẹ bàbá àti màmá mi gan-an ni, ó sì yẹ kí n máa tọ́jú wọn. Kí ló wá yẹ kí n ṣe báyìí?

Ọ DÚN 1928 ni wọ́n bí mi lábúlé T̩aul, lórílẹ̀-èdè Moldova. a Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún kan, bàbá mi Alexander, lọ sí Ias̩i, lórílẹ̀-èdè Romania, níbi tó ti pàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Nígbà tó padà sí ìlú T̩aul, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun tó ti kọ́ fáwọn ará ilé àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Láìpẹ́, wọ́n kó àwùjọ kékeré kan tó jẹ́ ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jọ ní T̩aul.

Ọmọkùnrin mẹ́rin làwọn òbí mi bí, gẹ́gẹ́ bí àbígbẹ̀yìn nínú wọn, àárín àwọn tó fi nǹkan tẹ̀mí sọ́kàn ni mo dàgbà sí, wọ́n sì fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún mi. Àtikékeré ni mo ti mọ̀ dájú pé sísin Jèhófà máa mú àtakò dání, àti pé ó máa ṣòro. Mo ṣì rántí dáadáa báwọn ọlọ́pàá ṣe máa ń tú ilé wa tí wọ́n bá ń wá àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a kó pa mọ́. Gbogbo ìyẹn ò kúkú dẹ́rù bà mí. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé wọ́n ṣenúnibíni sí Jésù Kristi ọmọ Ọlọ́run gan-an, tó fi mọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Wọ́n sábà máa ń rán wa létí nínú ìpàdé wa pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti máa retí inúnibíni.—Jòhánù 15:20.

Ohun Tó Fún Mi Lókun Láti Fara Da Inúnibíni

Lọ́dún 1934, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà, wọ́n ka lẹ́tà kan fún wa nínú ìjọ wa ní T̩aul, lẹ́tà yẹn ni wọ́n fi sọ fún wa nípa ohun tójú àwọn ará wa tó wà ní Jámánì, lábẹ́ ìjọba Násì ń rí. Wọ́n rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré nígbà yẹn, mi ò gbàgbé lẹ́tà náà títí dòní.

Lọ́dún mẹ́rin lẹ́yìn náà ni àdánwò ìṣòtítọ́ tèmi fúnra mi dé. Nígbà kan tí wọ́n ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní iléèwé, lemọ́lemọ́ ni àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì kan pa á láṣẹ fún mi pé kí ń gbé àgbélébùú kọ́rùn. Nígbà tí mo kọ̀, ó sọ fún gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì pé kí wọ́n gbé àgbélébùú tiwọn náà kọ́rùn láti lè fi hàn pé wọ́n jẹ́ ẹni tó ń fi tọkàntọkàn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ó wá nàka sí mi, ó sì bi àwọn ọmọ kíláàsì náà pé: “Ṣé ẹ fẹ́ irú èèyàn báyìí ní kíláàsì yín? Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ò bá fẹ́ ẹ ní kíláàsì, ẹ nawọ́ sókè.”

Nítorí pé ẹ̀rù àlùfáà yìí ń ba àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, gbogbo wọn ló nawọ́ sókè. Àlùfáà náà bá yíjú sí mi, ó sì sọ pé: “Ṣó o rí i pé kò sẹ́ni tó fẹ́ bá ọ da nǹkan pọ̀. Jáde síta, bí mo ṣe ń wò ẹ́ yìí.” Ní bí ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, olùdarí ilé ìwé náà wá sílé wa. Lẹ́yìn tó ti bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀, ó bi mí bóyá màá ṣì fẹ́ máa lọ síléèwé. Mo ní mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ló bá sọ pé: “Bó bá ṣì jẹ́ èmi ni olùdarí ilé ìwé yìí o, wàá kàwé ẹ yanjú, àlùfáà yẹn ò sì ní rí nǹkan fi ẹ́ ṣe.” Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àlùfáà yẹn ò yọ mí lẹ́nu mọ́ ní gbogbo ìgbà tí ọkùnrin yẹn fi jẹ́ olùdarí ilé ìwé yẹn.

Inúnibíni Ń Le Sí I

Lọ́dún 1940, orílẹ̀-èdè Soviet Union gba ẹkùn Bessarabia tá à ń gbé. Ní June 13 àti 14, ọdún 1941, gbogbo àwọn gbajúmọ̀ nínú òṣèlú àti láwùjọ ni wọ́n kó lọ sí Siberia. Wọn ò kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ wọn ṣá o. Àmọ́, látìgbà náà la ti ń fi ìṣọ́ra ṣèpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù wa.

Ní ìparí oṣù June, ọdún 1941, Ìjọba Násì ti ilẹ̀ Jámánì yọ́ kẹ́lẹ́ kọ lu orílẹ̀-èdè Soviet Union lójijì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jọ ń ṣe pọ̀ títí dìgbà yẹn ni. Kò pẹ́ sígbà náà táwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Romania fi gba ẹkùn Bessarabia padà. Bá a tún ṣe padà sábẹ́ àkóso orílẹ̀-èdè Romania nìyẹn o.

Ní àwọn abúlé tí kò jìnnà sí wa, wọ́n mú àwọn Ẹlẹ́rìí tó kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romania, wọ́n sì sọ èyí tó pọ̀ lára wọn sẹ́wọ̀n ogún ọdún pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n ránṣẹ́ sí bàbá mi láti àgọ́ ọlọ́pàá, nígbà tó débẹ̀, wọ́n lù ú nílùkulù nítorí pé ó jẹ́ ajẹ́rìí. Wọ́n tún fagídí wọ́ èmi náà láti iléèwé lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣe ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì.

Ogun Àgbáyé Kejì dédé yí bìrí. Lóṣù March, ọdún 1944, àwọn ará Soviet Union gba àríwá Bessarabia láìsọsẹ̀. Nígbà tó fi máa di oṣù August wọ́n ti gba gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà yẹn.

Nígbà tó yá, wọ́n rọ́ gbogbo géńdé ọkùnrin tó wà lábúlé wa sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Soviet Union. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí ò kúrò lórí àìdásí tọ̀tún tòsì wọn. Nítorí náà, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá mẹ́wàá. Lóṣù May ọdún 1945, Ogun Àgbáyé Kejì parí nílẹ̀ Yúróòpù, nígbà tí Jámánì juwọ́ sílẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè Moldova ló ṣì wà látìmọ́lé títí di ọdún 1949.

Àwọn Ìpọ́njú Ẹ̀yìn Ogun

Lẹ́yìn tógun parí lọ́dún 1945, ọ̀dá kan dá lórílẹ̀-èdè Moldova tó burú jọjọ. Pẹ̀lú bí ọ̀dá yìí ṣe lágbára tó, Ìjọba orílẹ̀-èdè Soviet Union pàpà tún ń sọ fáwọn àgbẹ̀ pé kí wọ́n máa mú èyí tó pọ̀ nínú irè oko wọn wá gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀. Èyí wá fa ìyàn kan tó burú kọjá àlà. Lọ́dún 1947, mò ń rí òkú àwọn èèyàn nígboro T̩aul. Bùrọ̀dá mi Yefim kú, ebi sì mú kó rẹ èmi alára débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè rìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀. Àmọ́, nígbà tí ìyàn náà kásẹ̀ nílẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí tá a ṣẹ́ kù níbẹ̀ ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ. Abúlé wa lèmi ti ń wàásù, àmọ́ bùrọ̀dá mi Vasile tó fi ọdún méje jù mí lọ máa ń lọ wàásù láwọn abúlé tó wà nítòsí wa.

Bó ṣe di pé iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí ń rinlẹ̀ sí i báyìí, àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ wa lójú méjèèjì. Iṣẹ́ ìwàásù wa, tó fi mọ́ bí a ò ṣe lọ́wọ́ sí òṣèlú àti iṣẹ́ ológun mú kí ìjọba orílẹ̀-èdè Soviet Union bẹ̀rẹ̀ sí tú ilé olúkúlùkù wa láti lè rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń kó wa dà sí àtìmọ́lé. Lọ́dún 1949, wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí kan láti inú àwọn ìjọ tó wà ní tòsí wa lọ sí Siberia. Ló bá tún di pé káwa tá a kù sílẹ̀ gbìyànjú láti máa fi ọgbọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa.

Àìsàn kan wá dá mi gúnlẹ̀ nígbà tó yá, ńṣe ni àìsàn náà sì ń burú sí i. Àwọn dókítà sọ fún mi pé àìsàn ikọ́ fée ló ń bá egungun mi jà, nígbà tó sì di ọdún 1950, wọ́n gbé sìmẹ́ǹtì sí ẹsẹ̀ mi ọ̀tún.

Wọ́n Kó Wa Lọ sí Siberia

Ní April 1, ọdún 1951, wọ́n kó wa lọ sí Siberia, èmi àtàwọn ará ilé mi àti àwọn Ẹlẹ́rìí míì, sìmẹ́ǹtì ṣì wà lẹ́sẹ̀ mi nígbà yẹn o. b Níwọ̀n bí wọn ò ti fún wa láàyè tó láti múra sílẹ̀ dáadáa, oúnjẹ kékeré la gbé dání. Kò sì pẹ́ tá a fi jẹ ẹ́ tán.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tá a lò nínú ọkọ̀ ojú irin, a dé ìlú Asino ní àgbègbè Tomsk, wọ́n sì dà wá sílẹ̀ níbẹ̀ bí màlúù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibẹ̀ tutù rinrin, ó ṣáà dùn mọ́ wa pé a rí afẹ́fẹ́ àlàáfíà gbà sára. Lóṣù May, nígbà tí yìnyín tó wà nínú odò bẹ̀rẹ̀ sí yọ́, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi kó wa rìnrìn àjò ọgọ́rùn-ún kìlómítà lọ sí Torba, tó wà nínú igbó igi gẹdú tó tutù rinrin ní Siberia. Níbí yìí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí fi wá siṣẹ́ agbára, wọ́n sì ní a ò ní kúrò níbẹ̀ títí ayé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ àṣekára tá à ń ṣe níbí yìí yàtọ̀ sí ti ọgbà ẹ̀wọ̀n, ńṣe ni wọ́n ń ṣọ́ wa lójú méjèèjì. Inú ọkọ̀ ojú irin ni ìdílé wa máa ń sùn pa pọ̀ sí lálaalẹ́. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, a kọ́ ilé kótópó kótópó tí ìdajì rẹ̀ wà lókè, tí ìdajì yòókù sì wà nínú ilẹ̀ ká bàa lè máa ríbi sá sí nígbà tí òtútù bá dé.

Nítorí pé sìmẹ́ǹtì ṣì wà lẹ́sẹ̀ mi, wọ́n yọ̀ǹda pé kí n máa ṣiṣẹ́ nínú igbó kìjikìji, wọ́n kàn ní kí n máa ṣe ìṣó ni. Iṣẹ́ tí wọ́n fún mi ṣe yẹn jẹ́ kí n láǹfààní láti máa dọ́gbọ́n ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì. Wọ́n máa ń yọ́ mú àwọn ìwé yìí dé àdúgbò wa láti ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù tó wà ní ẹgbẹẹ̀rún kìlómítà sí wa.

Wọ́n Mú Mi, Wọ́n sì Jù Mí Sẹ́wọ̀n

Ní ọdún 1953, wọ́n gbé sìmẹ́ǹtì ẹsẹ̀ mi kúrò. Àmọ́ nígbà tó yá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń ṣọ́ra ṣe, gbogbo bí mo ṣe ń wàásù tí mo sì ń ṣe ẹ̀dà àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn nǹkan míì tí mò ń ṣe ló ti dé etígbọ̀ọ́ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB. Látàrí èyí, wọ́n mú èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì, wọ́n sì jù wá sẹ́wọ̀n ọdún méjìlá. Àmọ́, nígbà tí wọ́n ń ṣẹjọ́ wa, gbogbo wa la láǹfààní láti wàásù nípa Jèhófà Ọlọ́run wa àti nǹkan rere tó fẹ́ ṣe fún aráyé.

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n kó àwa ẹlẹ́wọ̀n lọ sí àgọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní iyànníyàn ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà léti ìlú Irkutsk, lápá ìlà oòrùn. Nítorí kí wọ́n lè máa ríbi fìyà jẹ àwọn tí wọ́n bá kà sí ọ̀tá orílẹ̀-èdè Soviet Union ni wọ́n ṣe dá àwọn àgọ́ yìí sílẹ̀. Láti April 8, ọdún 1954 títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1960, mo ṣẹ̀wọ̀n ni méjìlá lára irú ọgbà ẹ̀wọ̀n bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé mi lọ sí ibi tó jìn ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kìlómítà níhà ìwọ̀ oòrùn, níbi ọgbà ẹ̀wọ̀n onílé púpọ̀ kan tó wà ní Mordovian, ní irínwó kìlómítà lápá ìwọ̀ oòrùn gúúsù ìlú Moscow. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo láǹfààní láti pàdé ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí olùṣótítọ́ tí wọ́n kó wá láti apá ibi tó pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Soviet Union.

Àwọn aláṣẹ ìjọba Soviet Union mọ̀ pé bí wọ́n bá gbà káwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n máa ráyè dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, ńṣe làwọn náà máa ń di Ẹlẹ́rìí. Nítorí náà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Mordovian yìí, èyí tó ní oríṣiríṣi àgọ́ tí wọ́n ti ń fàwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣiṣẹ́ tó sì fẹ̀ tó nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí máa dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó sí àgọ́ wa ju irínwó lọ. Ní bíi kìlómítà mélòó kan sí ọ̀dọ̀ wa, ó ju ọgọ́rùn-ún arábìnrin tí wọ́n kó sínú àgọ́ míì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yẹn.

Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n wa, mò ń ṣiṣẹ́ kára láti lè ṣètò àwọn ìpàdé kí n sì lè máa ṣẹ̀dà àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti bá wa dọ́gbọ́n mú wọnú ẹ̀wọ́n. Ẹ̀rí wà pé àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n mọ̀ nípa nǹkan tí mò ń ṣe. Láìpẹ́ sígbà yẹn, lóṣù August ọdún 1961, wọ́n ní kí n lọ fi ọdún kan gbára lọ́gbà ẹ̀wọ̀n burúkú kan táwọn ará Rọ́síà dá sílẹ̀ ní ìlú Vladimir tó fi nǹkan bí igba kìlómítà jìnnà sí ìlà oòrùn Moscow. Ibi tá à ń sọ yìí ni awakọ̀ òfuurufú kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Francis Gary Powers, tí wọ́n fìbọn já bọ́ ní May 1, 1960, nígbà tó ń fi ọkọ̀ òfuurufú ṣe amí ilẹ̀ Rọ́síà, ti ṣẹ̀wọ̀n títí di oṣù February, ọdún 1962.

Nígbà tí mo wà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Vladimir, torí kí n má bàa kú nìkan ni wọ́n ṣe ń fún mi lóúnjẹ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ebi ti hàn mí léèmọ̀ rí nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, kò ṣòro fún mi láti fara da ebi ọ̀tẹ̀ yìí, ohun tó ṣòro fún mi láti fara dà ni òtútù tó mú hóí hóí lọ́dún 1961 sí 1962. Páìpù tó ń gbé ooru wọnú ẹ̀wọ̀n náà bẹ́, látàrí èyí, inú túbú tí wọ́n fi mí sí tutù ju yìnyín lọ. Dókítà kan rí ìyà tó ń jẹ mí yẹn, ló bá ṣètò bí wọ́n á ṣe gbé mi lọ sínú túbú tí kò burú tó ìyẹn tí ọ̀sẹ̀ tí otútù tó burú jáì yẹn á fi mú fi máa kọjá lọ.

Ohun Tó Fún Mi Lókun Tí Mo Fi Borí Ìṣoro

Téèyàn bá lo oṣù bíi mélòó kan látìmọ́lé lóhun nìkan, èròkerò lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì, ohun táwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n sì ń wá nìyẹn. Àmọ́, mo máa ń gbàdúrà wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, ẹ̀mí Jèhófà àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo bá rántí sì máa ń fún mi lókun.

Nígbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Vladimir ni mo wá mọyì ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣùgbọ́n a kò há wa ré kọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣùgbọ́n kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbájáde rárá.” (2 Kọ́ríńtì 4:8-10) Lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n dá mi padà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Mordovian. Lọ́gbà ẹ̀wọ̀n onílé púpọ̀ yìí ni mo ti parí ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún méjìlà tí mò ń ṣe, ìyẹn ní April 8, ọdún 1966. Nígbà tí wọ́n fi mí sílẹ̀, orúkọ tí wọ́n fún mi ni “ẹni táyé ẹ̀ ti bàjẹ́ kọjá àtúnṣe.” Ohun témi ka ìyẹn sí ni ẹ̀rí pé mo jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

Wọ́n ti bi mí lọ́pọ̀ ìgbà nípa bá a ṣe máa ń rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbà àti bá a ṣe máa ń ṣe ẹ̀dà rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Soviet, pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń dí wa lọ́wọ́ ṣíṣe é. Olóṣèlú ará orílẹ̀-èdè Latvia kan tó lo ọdún mẹ́rin ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn obìnrin ní Potma sọ pé ó lójú àwọn tó mọ àṣírí yẹn. Lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lọ́dún 1966, ó kọ̀wé pé: “Ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí sáà máa ń rí ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbà lọ́nà kan ṣá.” Lójú tiẹ̀, “àfi bíi pé àwọn áńgẹ́lì kan máa ń fò láàárín òru tí wọ́n á sì wá ju ìwé náà sílẹ̀.” Ká sòótọ́, ìránlọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ló ń mú ká rí iṣẹ́ wa ṣe!

Àkókò Tí Mo Lómìnira Díẹ̀

Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀, àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù sọ fún mi pé kí n lọ sí ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Moldova kí n lọ ran àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ ará Moldova lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ṣẹ̀wọ̀n rí, táwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB ṣì ń ṣọ́ tọwọ́tẹsẹ̀, ó lójú ohun tí mo lè ṣe. Lẹ́yìn ọdún méjì, àti pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn á jù mí sẹ́wọ̀n, mo ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Kazakhstan níwọ̀n báwọn aláṣẹ ibẹ̀ yẹn kì í ti í yẹ àwọn ìwé ìgbélùú wò. Nígbà tó sì wá di ọdún 1969 táwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ àìsàn tó le, mo kó lọ sí orílẹ̀-èdè Ukraine láti lọ máa tọ́jú wọn. Níbẹ̀, nílùú Artyomosk, lápá àríwá ìlú ńlá tó ń jẹ́ Donetsk, ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB kan halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn á rán mi padà sẹ́wọ̀n, bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

Mo wá rí i nígbà tó yá pé ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà wulẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ mi ni. Kò lè rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti fẹ̀sùn kàn mí. Níwọ̀n bí mo sì ti pinnu pé màá máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lọ, tí mo sì mọ̀ pé ńṣe làwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB á fojú sí mi lára ní gbogbo ibi tí mo bá lọ, mi ò fọ̀rọ̀ ìtọ́jú àwọn òbí mi ṣeré. Àwọn méjèèjì fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà ni títí tí wọ́n fi kú. Bàbá mi kú ní oṣù November ọdún 1969, ṣùgbọ́n màmá mi ṣì wà títí di oṣù February, ọdún 1976.

Nígbà tí mo padà sí orílẹ̀-èdè Ukraine, mo ti pé ọmọ ogójì ọdún. Nígbà tí mò ń tọ́jú àwọn òbí mi níbẹ̀, èmi àti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Maria jọ wà nínú ìjọ kan náà. Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni nígbà tí wọ́n kó òun àtàwọn òbí ẹ̀, bí wọ́n ṣe kó àwa náà, láti Moldova lọ sí Siberia lóṣù April ọdún 1951. Maria sọ pé òun fẹ́ràn orin tí mo máa ń kọ. Ibi tí ọwọ́ wa tí bẹ̀rẹ̀ sí wọ ọwọ́ nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwa méjèèjì ló dí nínú iṣẹ́ ìwàásù, a pàpà máa ń ráyè fúnra wa títí tá a fi dọ̀rẹ́. Nígbà tó fi máa di ọdún 1970, ó ti gbà láti fẹ́ mi.

Kò pẹ́ sígbà yẹn la bí Lidia, ọmọbìnrin wa. Lọ́dún 1983, lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tá a ti bí Lidia, ẹnì kan tó ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ ṣòfófó mi fáwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ KGB. Lákòókò yẹn, mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo bí ọdún mẹ́wàá lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò, iṣẹ́ yẹn sì ti gbé mi káàkiri ìlà oòrùn Ukraine. Àwọn alátakò lẹ́nu iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni lọ wá àwọn tó máa bá wọn jẹ́rìí èké tì mí nígbà tí wọ́n ń ṣe ẹjọ́ mi, bí wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún nìyẹn.

Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, wọ́n fi mí síbi táwọn Ẹlẹ́rìí míì ò ti ní rí mi. Àmọ́, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe yà mí sọ́tọ̀ yìí náà, kò sí ẹ̀dá kankan tó lè dí mi lọ́wọ́ àtibá Jèhófà sọ̀rọ̀, Jèhófà sì máa ń tọ́jú mi ṣáá ni. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún fún mi láǹfààní láti máa wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n míì. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́rin lẹ́wọ̀n, wọ́n dá mi sílẹ̀, mo sì láǹfààní láti padà sọ́dọ̀ ìyàwó àtọmọ mi, inú mi dùn pé wọ́n dúró gbọin-gbọin ti Jèhófà.

A Padà sí Moldova

A lo ọdún kan sí i lórílẹ̀-èdè Ukraine, lẹ́yìn náà la wá kó lọ sí orílẹ̀-èdè Moldova pátápátá níbi tí wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì nírìírí dáadáa. Lákòókò yẹn, àwọn aláṣẹ ìjọba orílẹ̀-èdè Soviet Union fáwọn èèyàn lómìnira láti máa rìn bó ṣe wù wọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. A dé ìlú Bălţi lọ́dún 1988, níbi tí Maria ti gbé rí kí wọ́n tó kó wọn lọ sí ìgbèkùn lọ́dún mẹ́tàdínlógójì ṣáájú ìgbà yẹn. Lọ́dún 1988 ọ̀rìn-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín márùn-ún [375] làwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀; àmọ́ báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìlú tó tóbi ṣìkejì lórílẹ̀-èdè Moldova yìí tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500]! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Moldova là ń gbé, mo ṣì ń ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè Ukraine.

Nígbà tí wọ́n fi máa forúkọ wa sílẹ̀ lábẹ̀ òfin nílẹ̀ Soviet Union lóṣù March ọdún 1991, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni ò lè fara mọ́ bí ètò ìjọba Kọ́múníìsì ṣe kùnà mọ́. Gbogbo nǹkan tojú sú ọ̀pọ̀ èèyàn, wọn ò sì ní ìrètí gidi kan fún ọjọ́ iwájú. Nítorí náà, nígbà tí orílẹ̀-èdè Moldova di olómìnira, ńṣe làwọn aládùúgbò wa bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Bíbélì, tó fi mọ́ àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀! Lẹ́yìn tí wọ́n kó wa lọ sígbèkùn lọ́dún 1951, ẹ̀ta hóró làwọn Ẹlẹ́rìí tó kù sí Moldova. Àmọ́ báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè náà kéré, térò ibẹ̀ ò sì ju nǹkan bíi mílíọ̀nú mẹ́rin àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [4,200,000] lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ báyìí lé ní ẹgbàásàn-án [18,000]. Àwọn ìrírí àgbàyanu tá a ti ní ti jẹ́ ká gbàgbé gbogbo ìyà tó ti jẹ wá sẹ́yìn!

Ní nǹkan bí ọdún méjì sí mẹ́ta sí 1995, ara mi tí ò le dáadáa mọ́ mú kí n fi iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò sílẹ̀. Láwọn ìgbà míì, bí ìlera mi ṣe rí máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́. Síbẹ̀, mo ti wá rí i pé Jèhófà mọ ohun tó máa ń mára wa yá gágá. Ó máa ń fún wa níṣìírí tá a nílò lásìkò tó bá yẹ. Ká ní mo lè padà di ọmọdé ni, ǹjẹ́ máa dáwọ́ lé ohun mìíràn tó yàtọ̀? Ó tì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun táá wù mí ni pé kí n túbọ̀ jẹ́ onígboyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kí n sì túbọ̀ lè lo ara mi fún iṣẹ́ náà.

Mo gbà pé Jèhófà ti bù kún mi, ó sì ti bù kún gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ láìka ipò yòówù kí wọ́n wà sí. A ní ìrètí tó dájú, ìgbàgbọ́ tó wà láàyè àti ìdánilójú pé láìpẹ́, nínú ayé tuntun tí Jèhófà yóò mú wá, gbogbo èèyàn yóò ní ìlera pípé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ tí orílẹ̀-èdè náà ń jẹ́ báyìí, ìyẹn Moldova la ó fi máa pè é nínú àpilẹ̀kọ yìí, dípò àwọn orúkọ tó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ bíi Moldavia tàbí Moldavian Soviet Socialist Republic.

b Lópin ọ̀sẹ̀ méjì àkọ́kọ́ nínú oṣù April ọdún 1951, àwọn aláṣẹ ìjọba Soviet Union ṣètò kan tí wọ́n ti múra sílẹ̀ dáadáa, èyí tó jẹ́ kí wọ́n rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹbí wọn kó. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń gbé lápá ìwọ̀ oòrùn Soviet Union tí wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin kó lọ sí ìgbèkùn ní Siberia tó wà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lápa ìlà oòrùn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ilé tá à ń gbé rèé nígbà tá a wà ní ìgbèkùn ní Torba, Siberia lọ́dún 1953. Bàbá àti Màmá mi rèé lápá òsì, bùrọ̀dá mi Vasile àti ọmọkùnrin rẹ̀ nìyẹn lápá ọ̀tún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ́dun 1955

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn arábìnrin wa rèé ní Siberia nígbà tí Maria, lápá òsì nísàlẹ̀, wà ní nǹkan bí ẹni ogún ọdún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Lidia ọmọbìnrin wa rèé láàárín èmi àtìyàwó mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Nígbà tá a ṣègbéyàwó lọ́dún 1970

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Èmi àti Maria rèé lónìí