Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Mo Fẹ́ Mọ̀ sí I Nípa Ẹ̀sìn Mi’

‘Mo Fẹ́ Mọ̀ sí I Nípa Ẹ̀sìn Mi’

‘Mo Fẹ́ Mọ̀ sí I Nípa Ẹ̀sìn Mi’

WỌ́N ní káwọn ọmọ kíláàsì Ciara ṣe iṣẹ́ kan wá láti ilé lórí ẹ̀kọ́ nípa ìtàn. Ọ̀rọ̀ kan tó gbàfiyèsí ni Ciara yàn láti kọ̀wé lé lórí ní tiẹ̀, ìyẹn ọ̀rọ̀ nípa inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì. Ciara sọ pé: “Ohun tó mú kí n yan àkòrí yẹn ni pé mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìtàn ẹ̀sìn mi. Ó wù mí kí n mọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà là kọjá nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ tó wáyé lákòókò yẹn.”

Lẹ́yìn tí Ciara ti ṣèwádìí dáadáa, ó fi igi ṣe àpótí aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ kan, ó sì kùn ún láwọ̀ àlùkò. Èyí ló fi ṣàpẹẹrẹ àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò tí wọ́n rán mọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n, láti fi máa dá wọn mọ̀. Ó lẹ oríṣiríṣi àwòrán mọ́ ara àpótí náà, ó sì kọ ọ̀rọ̀ kan sí ara rẹ̀ yí po. Ó wá lẹ lẹ́tà àkàbọkànjẹ́ kan, àmọ́ tó tún ń fún ìgbàgbọ́ lókun, mọ́ ọn. Wolfgang Kusserow tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kọ lẹ́tà náà nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n pa á. Wo Ilé-ìṣọ́nà March 1, 1986, ojú ìwé 14.

Ohun tí Ciara kọ fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n yàtọ̀, wọ́n lè rọ́gbọ́n dá sọ́rọ̀ ara wọn: Bí wọ́n bá buwọ́ lu ìwé kan láti sọ pé àwọn ò ṣe Ẹlẹ́rìí mọ́, wọ́n á dá wọn sílẹ̀. Àmọ́ bí ẹgbàágbèje wọn ò ṣe tọwọ́ bọ̀wé náà jẹ́ ẹ̀rí pé ẹni tó ń dúró ṣinṣin lórí òótọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ciara sọ pé òun rí àǹfààní nínú fífi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe àkòrí ọ̀rọ̀ òun. Dájúdájú ó ti ràn án lọ́wọ́ láti mọ̀ sí i nípa ẹ̀sìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jámánì nígbà yẹn kéré, síbẹ̀ wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an, ìgbàgbọ́ yìí ló sì ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi borí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí wọn.”

Bó bá jẹ́ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́, tó o sì wà níléèwé, ǹjẹ́ ọ̀nà wà tó o fi lè sọ̀rọ̀ nípa ìtàn ẹ̀sìn rẹ?