Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí àwọn ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 17. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.)

1. Láyé Sólómọ́nì, ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun wo ló ń kó fàdákà, eyín erin, àwọn ìnàkí àtàwọn ẹyẹ ológe lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì? (1 Àwọn Ọba 10:22)

2. Nígbà tó kù dẹ̀dẹ̀ kí Pọ́ọ̀lù kú, kí ló sọ tó fi hàn pé ó mọ̀ pé òun ti lo ìfaradà? (2 Tímótì 4:7)

3. Àlá Fáráò wo ni Jósẹ́fù sọ pé ó túmọ̀ sí pé ìyàn ńlá ń bọ̀ wá mú fọ́dún méje? (Jẹ́nẹ́sísì 41:17-24)

4. Àwọn obìnrin méjì wo ni wọ́n fi Ìwé Mímọ́ kọ́ Tímótì? (2 Tímótì 1:5)

5. Ikú tí ò wọ́pọ̀ wo ni Ábúsálómù kú, báwo sì ni wọ́n ṣe sin ín? (2 Sámúẹ́lì 18:9, 14-17)

6. Owó ọ̀yà wo ni ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san? (Róòmù 6:23)

7. Àbùmọ́ wo ni Jésù lò láti fi hàn bó ṣe máa ṣòro tó fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run? (Mátíù 19:24)

8. Kí lorúkọ ajẹ́lẹ̀ ìjọba Róòmù ní Jùdíà tó fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ ní dídè nítorí pé ó ń wá ojúure àwọn Júù? (Ìṣe 24:27)

9. Kí ni ìwé Ìṣípayá fi hàn pé Jésù ń tẹ̀ láti ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run yóò ṣe pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run? (Ìṣípayá 19:15)

10. Kí la kọ́kọ́ fi kọ Òfin Mẹ́wàá, orí kí la sì kọ ọ́ sí? (Ẹ́kísódù 31:18)

11. Kí ló wu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé káwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni máa fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́? (1 Tímótì 2:9)

12. Nígbà tí Aísáyà ń ṣàkàwé bí Jèhófà ṣe tóbi lọ́lá tó, nínú kí ló sọ pé ó ti ń díwọ̀n “omi”? (Aísáyà 40:12)

13. Kí lorúkọ ilé Ádámù àti Éfà? (Jẹ́nẹ́sísì 2:15)

14. Àwọn ọmọkùnrin Jákọ́bù méjì wo ló hùwà jàgídíjàgan tí bàbá wọn ò fọwọ́ sí? (Jẹ́nẹ́sísì 49:5-7)

15. Kí lorúkọ àwọn odò mẹ́rin tó pínyà láti ara odò tó ṣàn jáde ní Édẹ́nì? (Jẹ́nẹ́sísì 2:1-14)

16. Kí ló yẹ káwọn Kristẹni tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí ṣe bí ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni bá ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀ nípa rẹ̀? (Gálátíà 6:1)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Ọkọ̀ òkun láti Táṣíṣì

2. Ó sọ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́”

3. Abo màlúù méje tó rù hangogo jẹ abo màlúù méje tó sanra, ṣírí ọkà méje tó kíweje sì gbé ṣírí ọkà méje tó kún mì

4. Ìyá rẹ̀, Yùníìsì, àti ìyá rẹ̀ àgbà Lọ́ìsì

5. Jóábù àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ kọlu Ábúsálómù níbi tó fi irun kọ́gi sí tó sì ń mì dirodiro, lẹ́yìn náà ni wọ́n sọ òkú rẹ̀ sínú kòtò ńlá kan wọ́n sì kó òkúta lé e lórí tìrìgàngàn

6. Ikú

7. Ó sọ pé: “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run”

8. Fẹ́líìsì

9. Ó ń tẹ ìfúntí wáìnì

10. “Ìka Ọlọ́run” ló kọ wọ́n sórí àwọn wàláà òkúta méjì

11. “Aṣọ tí ó wà létòletò . . . pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an”

12. “Nínú ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ lásán”

13. Ọgbà Édẹ́nì

14. Síméónì àti Léfì

15. Píṣónì, Gíhónì, Hídẹ́kẹ́lì àti Yúfírétì

16. “Gbìyànjú láti tọ́ [ọ] sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù”