Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Àbí Yunifásítì Tó Pẹ́ Jù Lọ Láyé Nìyẹn?

Àwùjọ àwọn awalẹ̀pìtàn kan láti ilẹ̀ Poland àti Íjíbítì ti lọ wa ilẹ̀ tó wà níbi tí wọ́n kọ́ yunifásítì tó wà ní ìlú Alẹkisáńdíríà ní Íjíbítì ìgbàanì sí. Bí ìwé ìròyìn Los Angeles Times ṣe sọ, àwọn awalẹ̀pìtàn náà rí gbọ̀ngàn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàlá, tí wọ́n tóbi bákan náà, tí wọ́n lè gbà tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] akẹ́kọ̀ọ́. Ìwé ìròyìn náà sọ pé àwọn gbọ̀ngàn yìí “ní ibi gbọọrọ gbọọrọ téèyàn lè jókòó sí, tí wọ́n ṣe ní ìpele ìpele mọ́ ara ògiri, ní ìhà mẹ́ta gbọ̀ngàn náà, wọ́n sì dà bí lẹ́tà ‘U’ níbi tí wọ́n ti pàdé.” Ìjókòó gíga kan, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti olùkọ́, wà láàárín. Awalẹ̀pìtàn, Zahi Hawass, ààrẹ Àjọ Tó Ga Jù Lọ Lórí Ọ̀rọ̀ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé ní Íjíbítì sọ pé: “Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa hú irú gbọ̀ngàn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n kọ́ pa pọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn jáde lórí ilẹ̀ èyíkéyìí tó jẹ́ tàwọn ará Gíríìsì òun Róòmù ní gbogbo àgbègbè Mẹditaréníà.” Ọ̀gbẹ́ni Hawass sọ pé “ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òun ni yunifásítì tó pẹ́ jù lọ láyé.”

Áísìkiriìmù Tí Wọ́n Fi Aáyù Sí Kẹ̀?

Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti máa ń sọ pé bí egbòogi ni aáyù ṣe ń ṣiṣẹ́ lára. Ní báyìí o, ilé ẹ̀kọ́ gíga Mariano Marcos State University ní ìhà àríwá orílẹ̀-èdè Philippines ti ń ṣe áísìkiriìmù tí wọ́n fi aáyù sí nítorí “ìlera” ara, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Philippine Star ṣe sọ. Ìrètí wọn ni pé níwọ̀n bí àwọn àìsàn kan ti wà tí aáyù máa ń wò, áísìkiriìmù tí wọ́n fi aáyù sí yìí á ran àwọn tí irú àìsàn bẹ́ẹ̀ ń ṣe lọ́wọ́. Lára àwọn ohun tó dáa fún ni òtútù, ibà, ẹ̀jẹ̀ ríru, àìsàn tó jẹ mọ́ mímí, làkúrègbé, oró ejò, akokoro, ikọ́ fée, ikọ́ àwúbì, egbò àti orí pípá pàápàá. Tóò, áísìkiriìmù tí wọ́n fi aáyù sí rèé o, ta ló fẹ́?

Ilẹ̀ Olótùútù Nini—Kò Tutù Tó Báyìí Rí

Àgbájọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń gbẹ́ ilẹ̀ abẹ́ agbami Arctic Ocean tó wà láàárín ẹkùn Siberia àti erékùṣù Greenland sọ pé nígbà kan rí, ojú ọjọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ tutù nini ní àgbègbè náà. Ẹ̀rọ mẹ́ta, tó ń fọ́ yìnyín làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ń lò láti gbẹ́ ilẹ̀ abẹ́ òkun náà, wọ́n sì walẹ̀ jìn tó irínwó mítà, ìyẹn ọ̀rúndínlégbèje [1,300] ẹsẹ̀ bàtà lábẹ́ òkun kí wọ́n tó kó erùpẹ̀ tí wọ́n máa lò fún ìwádìí. Àwọn àkẹ̀kù irúgbìn àti ẹranko inú òmi tí wọ́n rí nínú erùpẹ̀ tí wọ́n wà jáde náà fi hàn pé tẹ́lẹ̀ rí, agbami òkun náà kò tutù tó bó ṣe rí lásìkò ìwádìí ọ̀hún. Kódà, Ilé Iṣẹ́ Rédíò Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ̀rọ̀ bá ohun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Jan Backman ti Yunifásítì Stockholm sọ, pé “àwọn ohun tá a rí nínú ìrìn àjò ìwádìí yìí ni a ó lò láti fi mọ nípa ìtàn tó rọ̀ mọ́ Ilẹ̀ Abẹ́ Agbami náà.”

Wọ́n Ti Ń Lo Pátákó Tó Ń Bá Kọ̀ǹpútà Ṣiṣẹ́ Nílé Ìwé

Ìwé ìròyìn El Universal ti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ròyìn pé láwọn yàrá ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún [21,000] lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, pátákó tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ ti rọ́pò pátákó aláwọ̀ ewéko, ẹfun ìkọ̀wé àti ìpàwérẹ́. Pátákó yìí tó nǹkan bíi mítà méjì níbùú àti mítà kan lóòró, wọ́n sì máa ń lò ó fáwọn àkẹ́kọ̀ọ tó wà ní kíláàsì karùn-ún àti ìkẹfà. Ìwé méje tó wà lórí kọ̀ǹpútà náà wà fún kíkọ́ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀kọ́ nípa ìtàn, sáyẹ́ǹsì, ìṣirò, ẹ̀kọ́ nípa ayé àtàwọn ẹ̀kọ́ míì. Wọ́n tún lè fi fídíò hàn wọ́n lórí rẹ̀. Nítorí èyí, olùkọ́ kan wà táwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ ti “wo àwọn ilé olórí-ṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó wà ní ìlú Tikal àti Palenque, wọ́n ti rí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ẹ̀yà Maya, wọ́n sì ti gbọ́ orin [wọn] lórí fídíò.” Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀? Olùkọ́ náà sọ pé: “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ ń tẹ́tí sílẹ̀, òye túbọ̀ ń yé wọn, wọ́n sì túbọ̀ ń kópa nínú ìjíròrò.”

Àádọ́ta Ọ̀kẹ́ Èèyàn Ló Ń Fọwọ́ Ara Para Wọn Lọ́dún

Nínú gbogbo ikú oró tó ń wáyé lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, pípara ẹni ló kó nǹkan bí ìdajì. Ó tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń para wọn lọ́dọọdún, àwọn tó sì ti para wọn títí di ọdún 2001 ti pọ̀ ré kọjá gbogbo àwọn tí wọ́n ṣekú pa àtàwọn tí ogun gbẹ̀mí wọn. Ní gbogbo ìgbà tí ẹni kan bá para ẹ̀, nǹkan bí èèyàn mẹ́wàá sí ogun ló ti gbìdánwò àti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ṣeé ṣe. Àjọ Ìlera Àgbáyé, tó wà ní ìlú Geneva, lórílẹ̀-èdè Switzerland ló gbé àròpọ̀ iye àwọn tó ń para wọn yìí jáde. Àjọ náà ṣàlàyé pé ní gbogbo ìgbà tí ẹnì kan bá kú, “ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ará àti ọ̀rẹ́ lọkàn wọn á bà jẹ́, tí wọ́n á pàdánù ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan wọn náà, tí àtijẹ àtimu á sì le koko fún.” Ìròyìn náà fi hàn pé lára àwọn nǹkan tó lè dẹwọ́ pípara ẹni ni “kéèyàn gbà pé òun ṣì níyì láwùjọ,” kí tẹbí tọ̀rẹ́ máa gba tẹni rò, kó máà sí ìjà kó máà sí ìta, kéèyàn sì máa fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ẹ̀sìn.

Ìkìlọ̀ Nípa Ìjì Eléruku

Ìwé ìròyìn The Times of London sọ pé lílo àwọn ọkọ̀ tí táyà wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin máa ń di ilẹ̀ mú gírígírí láwọn aṣálẹ̀ “ti pa kún pípọ̀ tí ìjì eléruku pọ̀ sí ní ìlọ́po mẹ́wàá káàkiri àgbáyé, ó sì ń ba àyíká àti ìlera aráyé jẹ́.” Ńṣe làwọn ọkọ̀ náà máa ń ba ojú ilẹ̀ aṣálẹ̀ tó ti bú pẹ̀pẹ̀ jẹ́, tí afẹ́fẹ́ á sì fẹ́ eruku lẹ́bú tó wà níbẹ̀ dà nù. Ọ̀jọ̀gbọ́n Andrew Goudie, ti Yunifásítì Oxford sọ pé: “Ní báyìí o, irú àwọn ọkọ̀ yìí tó ń rìn gba aṣálẹ̀ ti wá pọ̀ gan-an ni. Ní àárín gbùngbùn Ìlà Oòrùn, àwọn alákòókiri tí wọ́n máa ń gun ràkúnmí tẹ́lẹ̀ ti ń fi àwọn ọkọ̀ náà kó agbo ẹran wọn báyìí.” Yàtọ̀ sí kíku eruku sáfẹ́fẹ́ ní aṣálẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Goudie kìlọ̀ pé, “ìjì eléruku máa ń ku àwọn oògùn tó ń pa èpò àti oògùn tó ń pa kòkòrò tó wà lórí ilẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn, dà sáfẹ́fẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ló sì tún máa ń ku eruku tó wà nínú àwọn adágun gbígbẹ táútáú sáfẹ́fẹ́.” Ọ̀pọ̀ kòkòrò tó wà nínú erúku tó ń sọ lálá náà sì lè kó àìsàn báni. Èyí tó ń dun àwọn onímọ̀ nípa àyíká níbẹ̀ báyìí ni pé ó ṣeé ṣe ká rí àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà tí wọ́n á ti kàgbákò ọ̀dá ọlọ́jọ́ pípẹ́, irú èyí tó wáyé láàárín ọdún 1930 sí 1939. Ohun tó fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni títúlẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ àti ọ̀dá, ó sì ba àwọn ilẹ̀ ọ̀gbìn tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà jẹ́.

Àwọn Tó Ń Pọ́nkè Ń Jìyà Àìbìkítà Wọn

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún níbi tí wọ́n ti ń pọ́nkè. Òkútà tó ṣàdédé já bọ́ tàbí àìsàn àìròtẹ́lẹ̀, bí àrùn ọkàn, ló ṣekú pa àwọn kan. Síbẹ̀, bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, Leipziger Volkszeitung ṣe sọ, àìbìkítà ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa ikú jù lọ lórí òkè. Àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tí kò ní ìrírí nìkan kọ́ ló ní ìṣòro yìí o. Bí Miggi Biner, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Tó Ń Muni Rìnrìn Àjò Lórí Òkè ní abúlé Zermatt, lórílẹ̀-èdè Switzerland ṣe sọ, “tá a bá mú ti ìrírí kò ṣe ìrírí kúrò, ohun tó sábà máa ń fà á ni dídá ara ẹni lójú jù tàbí àìkọbi-ara sí bójú ọjọ́ ṣe rí àti bí òkè náà ṣe wà.” Àwọn kan tí wọ́n tiẹ̀ mú tẹlifóònù alágbèéká dání ti dára wọn lójú jù, wọ́n gbà pé hẹlikópítà máa wà tó máa gbé àwọn bí ọ̀ràn pàjáwìrì èyíkéyìí bá ṣẹlẹ̀.

Ìgbì Omi Tó Ń Ṣàdédé Ru Gùdù

Ìròyìn fi hàn pé ó tó ọkọ̀ òkun ńlá méjì tó máa ń rì sómi lápa ibì kan ṣá lágbàáyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kódà, àwọn ọkọ̀ gbàgbàrà tó máa ń gbépo àtàwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá tí wọ́n fi ń kẹ́rù, tí òmíràn máa ń gùn tó igba mítà ti ń rì sómi báyìí. Ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn ni pé ìgbì omi tó ń ṣàdédé ru gùdù ló ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn àjálù náà. Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́ pé agbami tó ń ru gùdù lè ri àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá, ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ pé ìtàn àsọdùn táwọn awakọ̀ ojú omi máa ń sọ ni. Àmọ́ ṣá o, ìwádìí kan tí Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe ti wá fi hàn pé kò sírọ́ nínú irú ìtàn bẹ́ẹ̀. Wọ́n ti fi àwọn ìtànṣán sátẹ́láìtì yàwòrán agbami òkun, wọ́n sì ti rí ipa àwọn ìrugùdù tó le gan-an nínú fọ́tò náà. Bí Wolfgang Rosenthal tó léwájú nínú ìwádìí Süddeutsche Zeitung náà ṣe sọ: “A ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbì omi tó ń ṣàdédé ru gùdù wọ́pọ̀ dáadáa ju bí ẹni kẹ́ni ṣe lè rò lọ.” Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́tà lẹ́nu ìwádìí náà, wọ́n ti ṣàwárí oríṣi mẹ́wàá, ó kéré tán. Lálá báyìí ni ìrugùdù náà máa ń ròkè, ó máa ń ga tó ogójì mítà lóòró, ó lè ya lu ọkọ̀ òkun kó sì bà á jẹ́ tàbí kó tiẹ̀ rì í pàápàá. Ó lójú ọkọ̀ òkun tó lè ya lù tí nǹkan kan ò ní ṣe. Rosenthal wá sọ pé: “Ní báyìí, a ní láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwádìí wa ká lè mọ̀ bóyá á ṣeé ṣe láti mọ̀ ṣáájú bí ìrugùdù yìí bá máa wáyé tàbí kò ní wáyé.”