Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣíṣàfọwọ́rá Ṣé Eré Ọwọ́ Ni Àbí Ìwà Ọ̀daràn?

Ṣíṣàfọwọ́rá Ṣé Eré Ọwọ́ Ni Àbí Ìwà Ọ̀daràn?

Ṣíṣàfọwọ́rá Ṣé Eré Ọwọ́ Ni Àbí Ìwà Ọ̀daràn?

WO BÍ ohun tá a fẹ́ sọ yìí á ṣe rí ná. Wọ́n ṣí ilẹ̀kùn ilé ìtajà ńlá kan sílẹ̀, àwọn ọmọbìnrin méjì tó wọṣọ àsìkò sì wọnú ilé ìtajà náà lọ. Wọ́n kọjá sí apá ibi tí wọ́n to ohun ìṣaralóge sí. Ẹ̀ṣọ́ kan tẹ̀lé wọn ṣùgbọ́n nígbà tó ku díẹ̀ kó bá wọn, ó dúró ó sì fọwọ́ tẹ̀bàdí. Ó ń wo àwọn ọmọbìnrin yẹn bí wọ́n ṣe ń yẹ ìtọ́tè àti tìróò wò.

Wọ́n ń fẹ̀gbẹ́ ojú kan wo ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ wọn. Ara wọn ò balẹ̀ mọ́. Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin náà lọ sídìí ìtọ́-èékánná tó wà nínú ìgò, ó sì kó bíi mélòó kan. Ó ń rúnmú bíi pé ṣe ló ń yẹ àwọn méjì tó láwọ̀ pupa wò. Ó gbé ọ̀kan sílẹ̀, ó wá gbé òmíràn tó jẹ́ aláwọ̀ búlúù.

Ẹ̀ṣọ́ náà wolẹ̀ díẹ̀, ó sì yíjú sí òdìkejì. Bíi pé àwọn ọmọbìnrin náà ń ṣọ́ ọ ni, kíá ni wọ́n kó ìtọ́tè àti ìgò ìtọ́-èékánná bíi mélòó kan sínú báàgì ọwọ́ wọn. Àwọn méjèèjì ṣojú fúrú, ṣùgbọ́n lọ́kàn wọn lọ́hùn-ún, ara wọn ò balẹ̀. Wọ́n dúró díẹ̀ sí i níbi ọ̀nà àbákọjá yẹn, ọ̀kan ń wo ohun tí wọ́n fi ń dán èékánná, èkejì sì ń yẹ lẹ́ẹ̀dì wò.

Àwọn méjèèjì wo ojú ara wọn, wọ́n forí bára wọn sọ̀rọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn jáde kúrò nínú ilé ìtajà náà. Ẹ̀ṣọ́ náà kúrò lójú ọ̀nà, bí wọ́n ṣe fẹ́ kọjá níwájú ẹ̀, wọ́n rẹ́rìn-ín músẹ́ sí i. Wọ́n sún mọ́ káńtà tí wọ́n to ẹ̀yà ara tẹlifóònù alágbèéká sí, èyí tó dojú kọ akọ̀wé tó ń gbowó ọjà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀ ẹ́ wò lọ́kọ̀ọ̀kan. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ nípa pọ́ọ̀sì aláwọ tí wọ́n ń fi tẹlifóònù alágbèéká sí. Nígbà tó ṣe, wọ́n dorí kọ ẹnu ọ̀nà àbájáde.

Bí wọ́n ṣe ń gbẹ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ lara wọn ń yá sí i, tí ẹ̀rù sì tún ń bà wọ́n bíi pé ẹnì kan máa tó pè wọ́n padà. Nígbà táwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí dé ẹnu ọ̀nà àbájáde, ó ṣe wọ́n bíi kí wọ́n rẹ́rìn ín kèékèé, àmọ́ wọ́n pa á mọ́ra. Bí wọ́n ṣe jàjà bọ́ síta báyìí, inú wọn wá ń dùn. Ìbẹ̀rù fò lọ, ara wọn wá balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Kíá, wọ́n ti tẹsẹ̀ mọ́rìn àmọ́ wọ́n ò lè pa inú wọn tó ń dùn náà mọ́ra. Ohun tí wọ́n ń sọ sínú ni pé: ‘A ti ṣèyí gbé ná!’

Àròsọ lásán la fọ̀rọ̀ àwọn ọmọbìnrin méjì yẹn ṣe o, àmọ́ ní ti ohun tí wọ́n ṣe yẹn, ó bani nínú jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro tó karí ayé ni, ìṣírò fi hàn pé ó lé ní ààdọ́ta ọ̀kẹ́ ìwà àfọwọ́rá tó ń wáyé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan lójúmọ́. Bá a ṣe máa rí i níwájú, àdánù tó ń fà ò láfiwé. Ọ̀pọ̀ lára àwọn aláfọwọ́rá yìí ni ò ka àdánù tí wọ́n ń fà sí bàbàrà. Kódà, àìmọye làwọn tó lè rówó sanwó ohun tí wọ́n bá rà àmọ́ tó tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n jí i. Kí ló ń fà á?