Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“A Kì Í Sọ̀rọ̀ Àlùfààṣá Lédè Tiwa”

“A Kì Í Sọ̀rọ̀ Àlùfààṣá Lédè Tiwa”

“A Kì Í Sọ̀rọ̀ Àlùfààṣá Lédè Tiwa”

KÍ LÓ ń jẹ́ ọ̀rọ̀ àlùfààṣá? Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The American Heritage Dictionary, pè é ní “èébú, ọ̀rọ̀ rírùn, tàbí ìsọkúsọ.” Ìwé atúmọ̀ èdè míì ṣàlàyé pé: “Kéèyàn sọ ọ̀rọ̀ èébú, ọ̀rọ̀ àrífín tàbí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ (sí ohun mímọ́)” ló ń jẹ́ “sísọ̀rọ̀ àlùfàáṣá.” Ó bani nínú jẹ́ pé lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, ọ̀rọ̀ àlùfààṣá yìí ló wà lẹ́nu mùtúmùwà. Látijọ́, ẹnu àwọn ọkùnrin nìkan la ti sábà máa ń gbọ́ irú ọ̀rọ̀ rírùn bẹ́ẹ̀, àmọ́ lónìí, àwọn obìnrin náà ń sọ̀sọkúsọ bó ṣe wù wọ́n, kódà wọ́n fi ń tayín ni. Síbẹ̀, láwọn ibì kan, ìgbà kan wà tí ò sẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ àlùfààṣá. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbọ́ bí Ọ̀gbẹ́ni James Kaywaykla tó jẹ́ ẹ̀yà Apache lórílẹ̀-èdè India, ṣe jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà.

Ọdún 1873 ni wọ́n bí James sí ìlú New Mexico, nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Lọ́jọ́ ogbó ẹ̀, nígbà tó pé ọmọ àádọ́rùn-ún ọdún, ó sọ báyìí pé:

“Láàárọ́ ọjọ́ kan, ohùn bàbá bàbá mi tí mo gbọ́ ló jí mi lójú oorun. Bàbá jókòó síwájú ilé wa lábẹ́ àtíbàbà tí òdòdó hù bo orí rẹ̀, ó kọjú sápá ibi tí oòrùn ti ń yọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọrin tá a mọ̀ sí Orin Òwúrọ̀. Orin yẹn ni wọ́n fi máa ń yin Ussen, . . . tí wọ́n á sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹ̀ nítorí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn pàtàkì tó fi ta wọ́n lọ́rẹ, ìyẹn ẹ̀bùn ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Ohun mímọ́ sì ni ẹ̀bùn yìí jẹ́ lójú àwọn Apache. a Wọn kì í fọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ṣẹ̀fẹ̀, ìyẹn ló ṣe ń yà wọ́n lẹ́nu báwọn Aláwọ̀ Funfun ṣe máa ń ka ọ̀rọ̀ ìlóyún àti ìbímọ sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n lè fi dápàárá. Lójú àwọn Apache, ẹ̀ṣẹ̀ tó burú tó pípe orúkọ Ọlọ́run lórí asán ni fífi ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ dápàárá. Mo lè fi yàngan pé a kì í sọ̀rọ̀ àlùfààṣá lédè tiwa. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba Adẹ́dàá pé ó fún wa láǹfààní láti máa mú ọmọ jáde.”—Ìwé Native Heritage, tí Arlene Hirschfelder ṣe olóòtú rẹ̀.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” Ó tún fi kún un pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìdúpẹ́.”—Éfésù 4:29; 5:3, 4.

Báwo la ṣe lè gba ọ̀rọ̀ àlùfààṣá àti ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn lẹ́nu àwọn èèyàn táá sì kúrò lọ́kàn wọn? Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sáwọn ará Fílípì lè ran gbogbo wa lọ́wọ́, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ará, ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìgbàgbọ́ àwọn Apache ni pé Ussen ni ọba adẹ́dàá.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]

Gbogbo fọ́tò: Ibi Ìkówèésí ti Congress, Prints & Photographs Division; àmì àwọn Apache: Dover Publications, Inc.