Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbe Omi Òjò Látijọ́ Àti Lóde Òní

Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbe Omi Òjò Látijọ́ Àti Lóde Òní

Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbe Omi Òjò Látijọ́ Àti Lóde Òní

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ÍŃDÍÀ

OMI tó wà láyé láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn náà ló ṣì wà títí dòní. Omi tí oòrùn bá fà mu láti inú òkun àtèyí tó bá fà látara òjò tó bá rọ̀ sórí ilẹ̀ ló máa kóra jọ sójú sánmà bí ìkùukùu tó sì tún máa padà rọ̀ sórí ilẹ̀. Ọ̀nà tí omi ń gbà yí po yìí ń jẹ́ kí omi tó wà láyé pọ̀ tó fún gbogbo èèyàn. Kí ló wá dé tí ọ̀dá omi ń dá aráyé? Ọgbọ́n wo la lè dá láti yanjú ìṣòro yìí? Láti lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀ràn omi ti rí lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

Pẹ̀lú báwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà ṣe ju bílíọ̀nù kan lọ, àwọn ará Íńdíà ti rí i pé omi tó wà láwọn orísun omi wọn ò fẹ́ tó lò mọ́. Ibo ni wọ́n ti wá ń rí omi lò ní Íńdíà? Lápá àríwá, tó jẹ́ ibi tó jìnnà gan-an lórílẹ̀-èdè náà, àwọn yìnyín tó wà nílẹ̀ àtàwọn tó dì lókìtì lókìtì sórí Òkè Himalaya máa ń yọ́, wọ́n á wá ṣàn lọ sínú àwọn odò. Àmọ́, ní ti àwọn tó pọ̀ jù nílẹ̀ Íńdíà, òjò alátẹ́gùn tó máa ń rọ̀ lorísun omi tiwọn. Òjò yìí máa ń rinlẹ̀ gbingbin, ó máa ń mú káwọn kànga kún dẹ́múdẹ́mú, ó sì máa ń mú káwọn adágún àti odò ńlá tó wà lórílẹ̀-èdè náà kún. Kò sẹ́ni tó lè sọ bí ọ̀rọ̀ irú òjò báyìí ṣe máa ń rí nílẹ̀ Íńdíà, kódà wọ́n sọ pé ó “wà lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣòroó lóye jù lọ níbẹ̀,” èyí tó jẹ́ pé “láìka bí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ̀ ṣe gbòòrò tó sí, pẹ̀lú àwọn sátẹ́láìtì àtàwọn kọ̀ǹpútà tó lágbára gan-an . . . , ó ṣì ṣòro láti sọ bó ṣe máa rí.”

Oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin ni òjò alátẹ́gùn yìí fi máa ń rọ̀, ìyẹn bí nǹkan bá rí bó ṣe yẹ kó rí, àmọ́ dípò tí ì bá fi rọ̀ dáadáa jálẹ̀ àkókò rẹ̀, ìdákúrekú ló sábà máa ń rọ̀, kìkì pé kì í rọ̀ níwọ̀nba. Bó bá sì ti rọ̀ bẹ́ẹ̀, ṣe làwọn ìsédò á kún táá sì di dandan pé kí wọ́n jẹ́ kí omi inú wọn máa ríbi ṣàn. Àwọn odò á kún kọjá bèbè, wọ́n á sì máa ya wọ inú oko àti inú ilé. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń dá ilé iṣẹ́ sílẹ̀ àtàwọn iṣẹ́ sọgbódilé sọ̀gbẹ́dìgboro ló ń fa bí wọ́n ṣe ń pa igbó run bẹẹrẹbẹ, igi tó wà nínú igbó ò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́ débi tí ì bá fi máa dá omi òjò dúró tí ilẹ̀ ì bá sì fi ráàyè máa fà á mu. Bó ṣe di pé ọ̀gbàrá ń wọ́ àwọn iyanrìn tó wà lókè eèpẹ̀ lọ nìyẹn. Ẹrọ̀fọ̀ wá ń kóra jọ sínú àwọn adágún omi, tí àyè tó wà nínú wọn sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dín kù débi tí wọn ò fi lè gba omi bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Èyí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ omi òjò tí wọ́n ì bá rí lò máa ṣòfò.

Nígbà tó bá sì yá, ìgbà òjò alátẹ́gùn á lọ. Ní gbogbo àkókò tó kù nínú ọdún ni oòrùn fi máa ń ràn táá sì di pé kí ojú ọjọ́ máa gbóná janjan! Kíá, gbogbo ilẹ̀ á ti gbẹ táútáú, àwọn pápá á le koránkorán, á sì máa bú pẹ̀pẹ̀. Àwọn odò tó ń ya mùúmùú, tí ipadò wọn jẹ́ iyanrìn tó sì fẹ̀ á wá máa gbẹ díẹ̀díẹ̀. Àwọn omi tó máa ń ya wálẹ̀ látòkè á dàwátì. Á di kí wọ́n máa fi ẹ̀rọ walẹ̀ jìn bí ọ̀nà ọ̀run kí wọ́n tó kan omi nítorí pé ibi tí omi wà á ti jin sí i. Nígbà tó bá di pé òjò ò rọ̀ dáadáa mọ́, ọ̀gbẹlẹ̀ á dé, àwọn irè oko ò ní yọ dáadáa, àwọn ẹran ọ̀sìn á máa kú, àwọn ará oko á máa ṣí lọ sáwọn ìlú ńláńlá, wọ́n á sì máa tipa bẹ́ẹ̀ pa kún ìṣòro omi tó wà níbẹ̀.

Àmọ́, báyìí kọ́ lọ̀rọ̀ rí nígbà kan o. Látijọ́, káàkiri Íńdíà, àwọn èèyàn mọ̀ pé kò yẹ káwọn máa gbára lé omi odò àti ti adágún nìkan nítorí bí wọ́n ṣe máa ń gbẹ táútáú nígbà tí àsìkò òjò bá lọ. Wọ́n jágbọ́n bí wọ́n á ṣe máa gbe òjò bó bá ṣe ń rọ̀. Wọ́n máa ń lò nínú ẹ̀ lójú ẹsẹ̀, wọ́n á sì tún tọ́jú dìgbà tí òjò ò bá rọ̀ mọ́.

Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Gbe Òjò Pa Mọ́ Lóde Òní

Ẹnì kan lè rò pé pẹ̀lú ọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ ayé òde òní àtàwọn ìsédò ńláńlá táwọn èèyàn ń gbẹ́, tó fi mọ́ irin tí wọ́n ń rì mọ́ inú omi àtàwọn ọ̀nà tómi ń bá lọ sídìí irúgbìn, tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì pọ̀ nílẹ̀ Íńdíà, kò sẹ́ni táá máa ronú kan ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbèjò látijọ́ yẹn mọ́. Àbí, nígbà tó ti di pé àwọn èèyàn lè ń pọn omi ẹ̀rọ nínú ilé tàbí lábúlé wọn, wọ́n ti ń pa oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbe omi òjò tì. Ṣùgbọ́n ṣá o, wọn ò tíì lè fi ẹ̀dọ̀ lérí òróòro. Ìdí ni pé àwọn arabaríbí iṣẹ́ tí ilé iṣẹ́ tó ń pèsè omi gbé ṣe láàárín àádọ́ta ọdún tó kọjá ò tíì lè máa pèsè omi tó tó fáwọn ará Íńdíà tí wọ́n ò yé pọ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń tìdí iṣẹ́ àgbẹ̀ bọ́ sídìí iṣẹ́ tí wọ́n ń fi ẹ̀rọ ṣe. Iye omi tí wọ́n tíì rí kò tó orílẹ̀-èdè náà lò.

Àwọn onímọ̀ nípa àbójútó àyíká àtàwọn aláṣẹ tọ́rọ̀ náà kàn ti ń rí i pé ó yẹ káwọn wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá káwọn èèyàn lè mọ̀ pé ó yẹ káwọn máa ṣọ́ omi lò. Wọ́n ti ń rọ àwọn aráàlú pé kí wọ́n máa gbe òjò ní gbogbo ilé, ilé iṣẹ́, ilé ìwé àti níbi gbogbo tó bá ti ṣeé ṣe láti máa gbe omi òjò. Kódà, ọ̀pọ̀ ìlú àti ìpínlẹ̀ ti sọ ọ́ di dandan pé kí wọ́n máa ṣe àwọn ohun tí wọ́n á fi máa gbèjò sára ilé tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́!

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mílíọ̀nù lítà omi òjò ló ń rọ̀ dà nù, ńṣe ló kàn máa ń gbẹ tàbí kó ṣàn padà sínú òkun. Àmọ́ tí wọ́n bá sọ ọ́ dàṣà pé kí wọ́n máa gbèjò, ibi tí òjò ti ń rọ̀ náà ni wọ́n á ti máa gbè é, olúkúlùkù láá sì ní omi tó ń gbè. Ọ̀fẹ́ sì tún ni omi òjò, kò dà bí omi inú ìsédò àti tinú odò tí wọ́n gbẹ́ táwọn èèyàn á máa fowó rà, èyí tó máa ń tipa bẹ́ẹ̀ di ìnira fáwọn aláìní!

Wọ́n Mú Ọ̀ràn Yìí ní Ọ̀kúnkúndùn

Nígbà tọ́rọ̀ ti rí báyìí, àwọn èèyàn tọ́rọ̀ náà ká lára ní Íńdíà wá bẹ̀rẹ̀ sí kira bọ ọ̀ràn títọ́jú omi pa mọ́. Àwọn kan ti gba ẹ̀bùn àmì ẹ̀yẹ kárí ayé lórí ọ̀ràn yìí. Lára wọn ni Rajendra Singh, tó gba Àmì Ẹ̀yẹ Magsaysay látàrí iṣẹ́ ìdàgbàsókè ìlú tó ṣe lọ́dún 2001. Ohun tí Singh ṣe ni pé, lábẹ́ àsíá ilé iṣẹ́ kan tí kì í ṣe ti ìjọba tó dá sílẹ̀, ó mú kí Odò Aravari tó ti gbẹ tẹ́lẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí lómi nínú. Èyí sì ṣe ìpínlẹ̀ Rajasthan lóore tó bọ́ sásìkò nítorí pé ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó wà lórílẹ̀-èdè náà ló ń gbé ní ìpínlẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún omi tó wà lórílẹ̀-èdè náà ló wà nínú ìlú yìí. Láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, Singh àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ gbin àwọn igi, wọ́n sì ṣe àgbá omi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀. Àwọn àgbá yìí làwọn ará ìlú mọ̀ sí johads, èyí tí wọ́n fi máa ń gbe omi òjò, ó sì ń ṣàǹfààní fún àwọn ará abúlé náà. Àwọn míì náà ń ṣe ohun tó yẹ, káwọn èèyàn bàá lè máa gbe òjò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò rí wọn, ṣùgbọ́n inú wọ́n dùn pé ohun táwọn ń ṣe ń ṣàǹfààní fáwọn ẹlòmíì.

Àwọn onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ti ń rí àǹfààní tó wà nínú gbígbèjò láti lè máa fi kún omi táwọn olómi ìlú ń pèsè. Ní iléeṣẹ́ kan lẹ́yìn òde ìlú Bangalore ní gúúsù Íńdíà, wọ́n ṣe ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ kan tó rọrùn tí kò sì wọ́nwó. Omi òjò tó máa ń ṣàn lọ sójú títì tẹ́lẹ̀ tó sì máa ń ṣòfò wá di èyí tó ń rọ̀ sínú ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀, táá sì máa tibẹ̀ ṣàn lọ sínú àgbá kan tó lè gba omi ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì lítà. Nígbà òjò alátẹ́gùn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà lítà omi tí wọ́n bá gbè lójúmọ́ ni wọ́n á sẹ́ tí wọ́n á sì máa fi fọ àwọn ohun èlò ìdáná, wọ́n sì máa ń lò ó láwọn ilé ìdáná tó wà ní iléeṣẹ́ wọn. Wọn kì í lò lára omi tó wà fún ìlò àwọn ará ìlú láti ṣe eléyìí.

O lè máa rò ó pé bí ‘ẹni ń bẹ́tọ́ sókun nìyẹn.’ Ṣùgbọ́n ká sọ pé o ní àkáǹtì kan tó ò ń fowó pa mọ́ sí lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní báńkì. Ojoojúmọ́ lo máa ń gbowó tó o bá nílò níbẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ o gba kọjá iye tó o fi sínú àkáǹtì náà. Bó pẹ́ bó yá, wàá gba owó èlé ní báńkì náà lọ́jọ́ kan. Àmọ́, ká ní láàárín oṣù bíi mélòó kan nínú ọdún, o ṣiṣẹ́ tó o fi lè rówó tó ju iye táá tó gbọ́ bùkátà rẹ lójoojúmọ́, wàá rí i pé owó inú àkáǹtì rẹ á máa pọ̀ sí i ni dípò kó máa joro. Ó yá, wá lo ìlànà yìí lórí ọ̀ràn ṣíṣọ́ omi lò. Wo adúrú omi tí wàá ní tó o bá ń tọ́jú omi pa mọ́ fún àkókò gígùn. Wàá rí i pé omi tó wà láwọn orísun omi á ti pọ̀ sí i, omi inú ilẹ̀ á sun wá sókè sí i, omi tó wà nínú àwọn ìsun téré téré náà á ti pọ̀ sí i, omi tí wọ́n á sì máa rí lò á lè wà, tó bá dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí òjò ò rọ̀ mọ́ bí ìgbà téèyàn fẹ́ lọ “gbowó” tó tọ́jú sí báńkì. Má gbàgbé o, ó níwọ̀n tómi tó wà láyé pọ̀ mọ; tí kò bá sì sí omi tá a tọ́jú pa mọ́, kò lè sí omi tá a máa rí lò nígbà tí omi tó wà ò bá tó lò.

Bí Ìṣòro Omi Á Ṣe Yanjú

Ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí tó wa lò dáadáa. Àmọ́ látàrí báwọn èèyàn ti ṣe ń fi ọ̀kánjúwà lo gbogbo ẹ̀ nílòkulò láti bí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, láìro tọjọ́ iwájú, ti mú kí wọ́n máa ba ayé jẹ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn tó ń gbé láyé. Láìka gbogbo ìlàkàkà àwọn ẹni tó ń tiraka tọkàntọkàn sí, àwọn èèyàn ò lè yanjú gbogbo ìṣòro tó ń dojú kọ àyíká pátápátá. Inú wa dùn pé Ẹlẹ́dàá àgbáyé ti ṣèlérí pé òun yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé” àti pé òun á mú kí òjò máa rọ̀ bó ṣe yẹ tí “omi yóò [sì] ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.” Àní, “ilẹ̀ tí ooru ti mú gbẹ hán-ún hán-ún yóò sì ti wá rí bí odò adágún tí ó kún fún esùsú, ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò sì ti wá rí bí àwọn ìsun omi.” Ìtura ńláǹlà nìyẹn á mà jẹ́ lórí ọ̀ràn gbígbe omi òjò o!—Ìṣípayá 11:18; Aísáyà 35:6, 7.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Wọ́n Ti Padà Ń Gbe Omi Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbè É Látijọ́

GBÍGBE OMI LÁTORÍ ÒRÙLÉ: Ó rọrùn, kò sí wọ́nwó. Tí wọ́n bá ṣe òrùlé ilé tó dami, òjò tó ń rọ̀ sí i á lè máa lọ sínú páìpù, tí páìpù náà á sì máa gbé omi náà lọ sínú àwọn àgbá tá a dìídì ṣe síbẹ̀. Wọ́n á fi àwọn, iyẹ̀pẹ̀, òkúta wẹẹrẹ àti èédú ṣe asẹ́ tí wọ́n á fi sẹ́ ẹ kó lè mọ́. Wọ́n á ṣe àrọ tá máa gbé e lọ sínú àwọn táǹkì abẹ́ ilẹ̀ tàbí èyí tó wà lókè. Wọ́n á dí ẹnu táǹkì náà pa pinpin débi tí atẹ́gùn, tàbí oòrùn tàbí àwọn kòkòrò kò fi ní wọbẹ̀; álọ́ọ̀mù ni wọ́n máa fi sí i kó bàa lè silẹ̀; wọ́n á sì fi àtíkè tó ń pa kòkòrò sí i láti lè pa àwọn bakitéríà inú rẹ̀. Wọ́n máa ń bu irú omi báyìí rin ohun tí wọ́n gbìn sínú ọgbà, wọ́n sì fi máa ń fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti aṣọ. Tí wọ́n bá tún tọ́jú rẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó lè di omi táá ṣeé mu. Tí omi ba pọ̀ jù, wọ́n lè darí ẹ̀ sínú kànga tàbí kí wọ́n jẹ́ kó máa ṣàn lọ sínú ilẹ̀ kó lè fi kún omi tó wà lábẹ́ ilẹ̀. Èyí ni wọ́n máa ń lò jù láwọn ìlú ńláńlá.

NAULAS: Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe èyí ni pé wọ́n á fi òkúta ṣe àwọn odi sínú odò láti sé e. Wọ́n á wá gbin igi tó lè ṣíji bó odò náà sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kó lè dín bí oòrùn á ṣe máa lá a kù, lẹ́yìn náà, wọ́n á wá ju àwọn irúgbìn tó ní èròjà egbòogi sínú odò náà kí omi tó wà níbẹ̀ lè mọ́.

ÀWỌN ÀGBÁ ONÍHÒ, TÀBÍ RAPAT: Wọ́n máa ń ṣe àgbá tí wọ́n á gbé sórí iyanrìn tàbí ilẹ̀ tó ní àpáta láti fi gbé omi òjò. Wọ́n á rí díẹ̀ lò nínú omi tí wọ́n gbè sínú ẹ̀ ṣùgbọ́n ìyókù á rin jáde lábẹ́ àgbá náà á sì wọ inú ilẹ̀ lọ, èyí tó máa ń jẹ́ káwọn kànga lómi nínú.

BHANDARAS: Èyí ni àwọn àgbá tí wọ́n gbé síbi tómi ti ń sun kí omi báa lè máa sun sínú wọn tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ máa gbé omi lọ sínú àwọn táǹkì tó wà fún lílò aráàlú.

QANATS: Èyí ni àwọn ògiri tó wà ní apá ibi tó ní òkè láti lè gbe omi òjò. Omi tó bá rọ́ sínú rẹ̀ á máa ṣàn gba abẹ́ ilẹ̀ lọ sínú ohun tí wọ́n fẹ́ gbe omi náà sí, èyí tó máa ń jìnnà gan-an síbi tí ohun ìgbèjò náà wà.

ÀWỌN ÀGBÁ TÓ TÒ LÉRA: Wọ́n máa ń to àgbá lé orí àgbá débi tí àwọn àgbá yìí á fi lè gbé omi látẹnu ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ lọ sínú àwọn àgbá mìíràn.

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda: Ẹgbẹ́ S. Vishwanath Rainwater Club, tó wà nílùú Bangalore, lórílẹ̀-èdè Íńdíà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Fọ́tò UN/DPI tí Evan Schneider yà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Fọ́tò UN/DPI tí Evan Schneider yà