Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Ń máwọn Èèyàn Ṣàfọwọ́rá?

Kí Ló Ń máwọn Èèyàn Ṣàfọwọ́rá?

Kí Ló Ń máwọn Èèyàn Ṣàfọwọ́rá?

“Èmi ò kà á kún olè jíjà o, lójú tèmi kò yàtọ̀ sígbà téèyàn gba tọwọ́ ẹni tó ní, tó sì fi fún ẹni tí ò ní rárá.”—ÀLÙFÁÀ KAN NÍNÚ ÌJỌ ÁŃGÍLÍKÀ.

BÍ OHUN tí wọ́n sọ nípa Robin Hood bá jẹ́ òótọ́, kò ka olè jíjà sóhun tó burú. Ìtàn àtẹnudẹ́nu kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé ṣe ni Robin Hood máa ń ja àwọn olówó lólè táá sì kó ohun tó bá jí fáwọn tálákà. Àlùfáà tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí gbà pé kò burú bí tálákà bá jalè. Nígbà tó ń sọ nípa àwọn aláfọwọ́rá, ó ní: “Àánú wọn máa ń ṣe mí ni, mi ò tiẹ̀ rí ohun tó burú nínú nǹkan tí wọ́n ń ṣe.” Ó dábàá pé káwọn òǹtajà máa fi ọjọ́ kan sílẹ̀ lọ́dún táwọn tálákà á fi lọ máa mú ohunkóhun tó bá wù wọ́n nílé ìtajà láìsan kọ́bọ̀.

Síbẹ̀, kì í ṣe òṣì nìkan ló ń sún àwọn èèyàn dédìí àfọwọ́rá. Ní orílẹ̀-èdè Japan, ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ méjì lára àwọn ọlọ́pàá bíi tiwọn tó ń ṣàfọwọ́rá. Ọwọ́ ba ọ̀kan lára ọmọ ìgbìmọ̀ alákòóso ẹgbẹ́ aláfọwọ́sowọ́pọ̀ kan fún ètò oúnjẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà tó ń jalè nínú ṣọ́ọ̀bù ẹgbẹ́ náà. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń jí àwọn nǹkan tí wọn ò nílò, kódà nígbà tówó sì wà lápò wọn. Kí ló ń sún àwọn èèyàn yìí dédìí àfọwọ́rá gan-an?

‘Ó Máa Ń Dùn Mọ́ọ̀yàn’

Ìmóríyá. Ìbẹ̀rù. Agbára. Àwọn nǹkan yìí máa ń kún ọkàn àwọn aláfọwọ́rá, bíi tàwọn ọmọbìnrin méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Bó sì ṣe máa ń dá wọn lọ́rùn ni kì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣíwọ́ olè jíjà. Lẹ́yìn tí obìnrin kan jalè fúngbà àkọ́kọ́, ó ní: “Inú mi dùn. Mo rí i jí, ṣe ni mò ń yọ̀ ṣìnkìn!” Lẹ́yìn bí ìgbà mélòó kan tó ti ń jalè, ó sọ bó ṣe máa ń rí lára rẹ̀ pé: “Ojú ara mi wá ń tì mí, síbẹ̀ inú mi ṣì ń dùn. Ó mú kí n mọ̀ pé mi ò rìndìn. Gbogbo bí mo ṣe ń jalè tọ́wọ́ ò sì bà mí ń mú kí n máa wo ara mi bí ẹni tí kò gbérèégbè.”

Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Hector sọ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tóun ti ṣíwọ́ àfọwọ́rá, ló tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òun bíi kóun padà sídìí olè jíjà. a “Ó ń ṣe mí bíi kí n máa jalè ṣáá, kò yàtọ̀ sóhun tó ti di mọ́ọ́lí. Bí mo bá wà nínú ilé ìtajà kan, tí mo sì tajú kán rí rédíò tí wọ́n gbé sójú wíńdò ilé ìtajà náà, kíá láá sọ sí mi lọ́kàn pé, ‘Kò lè nira láti jí kinní yẹn gbé o. Mo lè gbé e kí wọ́n má sì rí mi mú.’”

Àwọn tó máa ń ṣàfọwọ́rá nítorí pé ó máa ń dùn mọ́ wọn kì í nílò ohun tí wọ́n bá jí. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Íńdíà kan ṣàlàyé pé: “Àwọn afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá sọ pé ìdùnnú pé wọ́n ń ṣe ohun tẹ́nì kan ò gbọ́dọ̀ ṣe ló ń sún àwọn èèyàn yìí. . . . Àwọn kan tiẹ̀ máa ń dá ohun tí wọ́n bá jí padà.”

Àwọn Ìdí Mìíràn

Àìmọye èèyàn ni ìdààmú ọkàn ń bá. Nígbà mìíràn, ìsoríkọ́ lè dédé mú kéèyàn hùwà tí ò dáa—bí àfọwọ́rá.

Inú ìdílé tí wọ́n ti rí já jẹ lọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìnlá kan ti wá. Láìka bí nǹkan ṣe rọ̀ ṣọ̀mù fún ọmọdébìnrin yìí sí, ó máa ń ronú bí ẹni tí ò nírètí kankan. Ó ní: “Kò ṣeé ṣe fún mi láti pa ìrònú yẹn tì.” Ó wá di ọ̀mùtí àti ẹni tó ń lo oògùn olóró. Lọ́jọ́ kan, wọ́n mú un níbi tó ti ń ṣàfọwọ́rá. Lẹ́yìn ìyẹn, ẹ̀ẹ̀méjì ló gbìyànjú láti para ẹ̀.

Bí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọlúwàbí bá dédé bẹ̀rẹ̀ sí ṣàfọwọ́rá, káwọn òbí ẹ̀ kọ́kọ́ kíyè sí bóyá ohun kan ń da ọkàn rẹ̀ láàmú. Dókítà kan tó ń jẹ́ Richard MacKenzie, ògbógi kan tó ń tọ́jú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà sọ pé: “Ìwà tó yàtọ̀ yòówù kí ọmọ ẹ hù, mo gbà pé ìdààmú ọkàn ló ń yọ ọ́ lẹ́nu, àyàfi tẹ́ ẹ bá lè rí ẹ̀rí tó dájú pé nǹkan míì ló fà á.”

Àwọn ọ̀dọ́ kan ń ṣàfọwọ́rá nítorí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ làwọn ẹgbẹ́ wọn á fi lè gbà wọ́n mọ́ra. Àwọn ẹlòmíì máa ń ṣàfọwọ́rá nígbà tí gbogbo nǹkan bá tojú sú wọn. Àwọn aláfọwọ́rá paraku kan wà tó jẹ́ pé olè ni wọ́n ń jà jẹun. Ohun yòówù kó fà á, ọjà tó tó àìmọye ọ̀kẹ́ dọ́là làwọn olè ń jí kó láwọn ilé ìtajà lójoojúmọ́. Bẹ́ẹ̀, àwọn kan ló máa rọ́ gbèsè yẹn san o.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

FÍFẸ́ LÁTI JALÈ ṢÁÁ

Maria sọ pé: “Látìgbà tí mo ti wà ní kékeré ni mo ti máa ń fẹ́wọ́. Kàkà kó sàn, ṣe ló ń le sí i títí dìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí jí ọgọ́rùn-ún márùn-ún dọ́là nínú owó táwọn oníṣòwò ń pa lóòjọ́.”

Ó sọ pé: “Kò wù mí kí n máa jalè, ṣùgbọ́n mi ò mọ ohun tó ń gbé mi dédìí ẹ̀. Mo fẹ́ ṣíwọ́ ṣùgbọ́n kò rọrùn.” Nítorí pé kì í lè gbé èrò yẹn kúrò lọ́kàn, ó fura pé fífẹ́ láti máa jalè ṣáá, ló ń yọ òun lẹ́nu.

Wọ́n sọ pé “ohun kan máa ń wà nínú ọpọlọ tó ń mú kéèyàn máa fẹ́ láti jalè ṣáá láìjẹ́ pé ohun tẹ́ni náà jí á wúlò fún un.” Kì í ṣe ohun kan tó ti di mọ́ọ́lí lásán ni o, ṣe ló dà bíi pé ó ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ onítọ̀hún.

Àwọn kan rò pé ohun kan náà ló ń ṣe ẹni tó máa ń wù pé kó jí nǹkan àti ẹni tó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ jalè. Àmọ́, àwọn Dókítà gbà gbọ́ pé àwọn tó ní ìṣòro yìí ò wọ́pọ̀ rárá. Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Ọpọlọ Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé àwọn aláfọwọ́rá tó máa ń wù pé kí wọ́n máa jalè kò tó ẹnì kan nínú ogún èèyàn. Nítorí náà, ó gba ìṣọ́ra gidigidi kéèyàn tó lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ìfẹ́ àtimáa jalè ṣáá ló ń mú kéèyàn máa ṣàfọwọ́rá. Ó ṣì lè ku àwọn nǹkan míì tó ń mú kéèyàn jalè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn òbí tó mọ ìtọ́jú ọmọ máa ń fẹ́ mọ ohun tó fà á tí ọmọ wọn fi ń ṣàfọwọ́rá