Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wá Kọ́ Nípa Ohun Tí Bíbélì Sọ

Wá Kọ́ Nípa Ohun Tí Bíbélì Sọ

Wá Kọ́ Nípa Ohun Tí Bíbélì Sọ

◼ Ojú ewé 32 ni ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ní, bí ìwé ìròyìn tó ò ń kà lọ́wọ́ yìí ló ṣe rí. Ìdí tá a fi ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí ni láti jẹ́ káwọn èèyàn lóye àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ inú Bíbélì. Kedere ni ìwé yìí fi nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn hàn, ó sì sọ àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé a ní láti ṣe ká bàa lè rí ojú rere Ọlọ́run. Lára àwọn ẹ̀kọ́ fífanimọ́ra tó wà nínú rẹ̀ ni “Ta Ni Ọlọrun?,” “Ta Ni Jesu Kristi?,” “Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?” àti “Kí Ni Ìjọba Ọlọrun?”

A rọ̀ ọ́ pé kó o béèrè fún ẹ̀dà kan tàbí kó o lọ wò ó ní ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àdírẹ́sì ìkànnì náà ni www.watchtower.org. Ìwé pẹlẹbẹ náà wà ní èdè tó ju àádọ́talérúgba [250].

Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lápá ọ̀tún yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́ mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.